Ètò ìnọ́nwó
From Wikipedia
wo Itan Atijo naa
Ajayi, Emmanuel Oludare
AJAYI EMMAUNEL OLUDARE
ÈTÒ ÌNÁWÓ
Sé Yorùbá bò wón ní “Se bó o ti mo eléwàà sàpón. Ìwòn eku nìwòn ìté.” Won a sì tún máa pa á lówe pé “ìmò ìwòn ara eni ni ìlékè ogbón nítorí pé ohun owó mi ò tó ma fi gògò fà á, í í já lu olúwarè mólè ni” Láyé òde òní, àwon òdó tilè máa ń dásà báyìí pé “dèédèé re, ìgbéraga ni ìgbérasán lè.” Wón máa ń so èyí fún eni tí ó bá ń kojá ààyè rè ni. Gégé bí òro ogbón kan se wí pé “ni àtètékóse ni òrò wà,” béè náà ni ètò ti wà fún ohun gbogbo láti ìpilèsè wá. Ètò ní í mú kóhun gbogbo rí rémú. Olorun ògá ògo to da ayé. Ó fi eranko sígbó {àwon olóró}. Ó tún fi eja síbú. Ó fi àwon eye kan sígbó. Ó fi àwon mìíràn sílé. Àdìmúlà bàbá tó ju bàbá lo tún fi ààlà sáààrin ilè, omi òkun, àti sánmò. Ohun gbogbo ń lo ní mèlò-mèlo. Bàbá dá àwa omonìyàn kò fi ojú wa sí ìpàkó. Kò fi esè wa sórí kí orí wá wà lésè. Elétò lOlórun gan-an. Kíni ètò? Ètò jé ònà tí à ń gbà láti sàgbékalè ohun kan tàbí òpòlopò nnkan lójúnà àti mú kí ó se é wò tàbí kó se é rí tàbí kó dùn ún gbó sétí. A sèdá orúko yìí gan-an ni. Ohun tí a tò ní í jé ètò. Èwè, ìnáwó ni ònà tàbí ìwà wa lórí bí a se ń náwó. Ohun pàtàkì ni láti sètòo bí a óò se máa ná àwon owó tó bá wolé fún wa. Ní àkókó ná, èyí yóò jé kí á mo ìsirò oye owó tó ń wolé fún wa yálà lósè ni o tàbí lósù, bí ó sì se lódún gan-an ni. Bákan náà, yóò tún mú kó rorùn fún wa láti mo àwon ònà tí owó náà ń bá lo. Síwájú síi, ètò yóò ràn wá lówó láti le ní ìkóra-eni-níjàánu lórí bí a se ń náwó wa. Bí a bá ti mú ìsàkòtún tán, tí a tún mú ìsàkòsì náà, ìsàkusà ni yóò kù nilè. Tí a bá yo ti ètò kúrò nínú ojúse ìjoba pàápàá sí ará ìlú, eré omodé ni ìyókù yóò jé. Gbogbo àwon eka ìjoba pátá-porongodo ló máa ń ní àgbékalè ìlànà tí won yóò tèlé lati mo oye owó ti won n reti ati eyi ti won óò na bóyá fún odidi odún kan ni o tàbí fún osù díè. Èyí ni wón n pé ní ‘ÈTÒ ÌSÚNÁ’ Ìdí nìyí tó fi se pàtàkì fún gbogbo tolórí-telémù, tònga-tònbèrè ki kúlukú ní ètò kan gbòógì lónà bí yóò se máa náwó rè. Yorùbá bò wón ní, “eku tó bá ti ní òpó nílè, kì í si aré sá. Bí a bá ti se àlàkalè bí a óò se náwo wa yóò dín ìnákùùná kù láwùjo wa. Ìnáwó àbàadì pàápàá yóò sì máa gbénú ìgbé wo wá láwùjo wa. Mo ti so léèèkan nípa àwon eka ìjoba métèètà orílè èdè yìí tí wón máa ń sètò ìnáwó won. Àwon wo ló tún ye kó máa sètò ìnáwó? Àwon náà ni àwon òsìsé ìjoba, àwon onísòwò, àwon omo ilé-ìwé, níbi àseye. Àwon òsìsé ìjoba gbodò sètò ìnáwó won kó sì gún régé. Ìdí ni pé, èyí ni yóò jé kí owó osù won tó í ná. Eni tó ń gba egbèrún méwàá náírà lósù tí kò sì fi òdiwòn sí ìnáwó rè nípa títò wón léseese le máa rówó sohun tó ye láàákò tó ye nígbà tí ó bá ti náwó rè sí àwon ohun mìíràn tó seése kó nítumò sùgbón tí kì í se fún àkókò náà. Irú won á wá má ráhàn owó tósù bá ti dá sí méjì tàbí kí wón je gbèsè de owó osù mìíràn. Síwájú sí i, àwon onísòwò gbódò máa sètò to jíire lórí ìnáwó won. Nípa síse èyí, won óò ni ànfààní láti mò bóyá Oláńrewájú ni isé won tàbí Oláńrèyìn. Níbi tí àtúnse bá sì ti pon dandan, “a kì í fòdù òyà sùn ká tó í nà án ládàá,” won kò nì í bèsù bègbà, won óò sì se àtúnse ní wéréwéré. Àwon omo ilé-ìwé gan-an gbodò mò pé ká sètò ìnáwó eni kì í sohun tó burúkú bí ti í wù kó mo. Gégé bí omo ilé èkó gíga, béèyàn bá gbowó fún àwon orísirísi ìnáwó láti ilé lórí èkó eni, ó seése kí irú eni béè máa ná ìná-àpà tó bá dé ààrin àwon elegbée rè. Irú won ló máa ń pe òsè tí wón bá ti ilé lódò àwon òbí won dé ní ‘Ose ìgbéraga’ Èyí kò ye omolúàbí pàápàá. Ó sì ń pè fún àtúnse. Síse ètò tó gúnmó lórí ònà tí à ń gbà náwó kò pin sí àwon ònà tí mo sàlàyé rè sókè yìí. Mo fé kó ye wá pé a le sètò ìnáwó wa níbi àwon orísisi ayeye bí ìsomolórúko [tàbí ìkómójáde], ìgbéyàwó, oyè jíje, ìsílé, àti ìsìnkú àgbà àti béè béè lo. Yóò ràn wá lówó láti fi bí a se tó hàn wá ká le mo ohun tí a óò dágbá lé níbi irúfé àseye tí a bá fé í se. Nípa béè a ò ní í sí nínú àwon tó máa ń pa òwe tó máa ń mú kí won kábàámò nígbèyìn òrò. Òwe won ni, “rán aso re bí o bá se ga mo.” Èyí tí won ì bá fi wí pé “rán aso re bí o bá se lówóo rè sí.” Bí eni tó ga bá rán aso rè ní ‘bóńfò’ bó se lówó mo ni, kò sì fé í sàsejù. Irú eni béè le ti mò pé alásejù péré ní í té. Bí a bá wá fé láti sètò ìnáwó wa, ó ye ká mò pé ìtòsè ló lÒyòó, Oníbodè lo làààfin, enìkan kì í fi kèké síwájú esin. Iwájú lojúgun í gbé. Ìnáwó tó bá se kókó jùlo tó sì ń bèèrè fún ìdásí ní kíákíá ló ye ká fi síwájú bí a se ń tò ó ní eseese. Bí a bá wá kíyèsí pé ètò tí a là sílè ti ju agbára wa lo, e jé ká fura nítorí pé akéwì kan wí pé:
“E fura óò!
E fura óò!
Páńsá ò fura
Páńsá jááná
Àjà ò fura
Àjá jìn
Ońlè tí ò bá fura
Olè ní ó ko o…”