Ètò ajé
From Wikipedia
Oro Aje
Ajibola, Olaniyi Olabode
AJIBOLA OLANIYI OLABODE
ÈTÒ ORO AJÉ
Yorùbá tò wón ní kí la ó je làgba kí la ó se, abálájo tí ètò ajé fi mumú láyà gbobgo orílè èdè àgbáyé tóó bè. Gbàrà tí ònà káràkátà oní-pà sí pààrò tayé ojó tun ti dotun ìgbàgbé ni ètò ajé ti dotun tó gbòòrò síwájú sí. Awon ènìyàn wáá bèrè síí ní lo àwon ohun èlò bíi wúrà àti jàdákà láti máa fii se pàsípààrò àwon ohun tí wón nílò. Eléyìí mú kí káràkátà láàrín-ín ìlú àti orílè èdè tún gbináyá síi nígbà tí àwon kù dìè ku die tí ń fa ìdílówó nínú káràkátà onípàsípàrò ti kúrò ní bè. Tí abá kókó gbé ètò ayé ní orílè èdè aláwò dúdú yè wò fínní fínní, aórìí pe ohun erè oko ló jé lájorí orò ajé àwon ènìyàn yìí. Àwon erè oko wònyí ni wón si ń fi ń se pàsípàrò láti tán àìní ara won sááju alábàápàbé won pèlú àwon aláwò funfun. Sísa lábàápàdé àwon aláwò funfun yìí mú kí àwon aláwò dúdú ní ànfàní àti sàmúlò àwon ohun èlò míràn bíi: Jígí ìwojú, Iyò, oti líle àti àwon ohun míràn béè béè lo, àti ibí yìí ni wón ti kó àsà lílo àwon ohun èlò táati dárúko sáájú yìí dípò pà sí pààrò tó mú òpò wàhálà ló iwó. kèrè kèrè, ìlànà àti máa lo owó wá sí ojútáyé, tí ètò orò ajé sì wá búréké. Sùgbón pèlú ìbúréké orò ajé yìí, ìyípadà díè ló dé bá ipò ò sì tí àwon aláwò dúdú yìí ti wà télè télérí. Èyí tó pòjù nínú èrè orò ayé ìgbà ló dé yìó lóńlo sí òdò àwon òyìnbó aláwò funfun. Kàyéfì ńlá ló jé pé bí òrò àwon aláwò funfun yìí tí ń pò sin i òsì túbò ń bá àwon aláwò dúdú fínra sí. Kàyéfì òrò yìí ò sèyìn ìwà imúni sìn adáni lóró tí àwon aláwò funfun yìí fimú àwon gìrìpá tó ye kó fi gbogbo opolo àti agbára won sisé láti mú ayé ìròrùn wáá bá ilè won àti àwon ènìyàn won. Nígbà tó ye kí àwon gìrìpá aláwò dúdú máa sisé idàgbàsókè ní ìlú ìbílè won, ìlè àwon aláwò funfun ni wón wà tí wón ń bá àwon ènìyàn yìí sisé àsekúdórógbó. Àwon aláwò funfun yìí ńlo àwon aláwò dúdú láti tún orílè èdè ti won se, àti láti pilè orò ajé tó lààmì láka. Gbogbo ìgbà tí ìmúni lérú yìí n lo lówó, tí ilè àwon aláwò funfun yìí sì ń tè síwájú, kò sí eyo isé ìdàgbàsókè kan ní orílè èdè aláwò dúdú. Ìgbà tí ìmúnilérú dáwó dúró, léyìn ìgbà tí àwon aláwò funfun yìí ti gòkè àgbà díè ń se ni wón tún yára gba ètò ìsàkóso ìjoba lówó àwon àláwò dúdú, tí wón sì so pé, òlàjú ni àwon féé fi wo àwon aláwò dúdú yìí tí èwù ìdí nìyí tí àwon fi te wón lóríba tí àwon sì fi pá gba ijoba won. Òtító tó dájú nip é, àwon aláwò funfun yìí ríi pé ilè àwon aláwò dúdú dára fún àwon isé ògbìn erè oko kan bíi: kòkó róbà, èpà, àti kofí èyí tí ó wúlò lópòlopò fún ohun èlò àwon ilé isé ńláńlá tí wón ti dá sílè. Wón wá fi tì pá tì kúùkù sò ilè àwon aláwò dúdú di oko Ògbìn àwon ohun èlò tí wón ń lò tí àwon ilé isé ńláńlá ti won. Ipò Ìsé àti Ìmúni sìn yìí ni àwon aláwò dúdú wà tí tí fi di ìgbà tí wón so pé àwon funfun won ní òmìnira. Ipò òsì àti àre tí àwon aláwò funfun fi àwon ènìyàn yìí sí kò jé kí wón ó lè dá dúró, kí wón sì dáńgbájíá láti máage àwon ohun ti wón nílò ní ilé isé ìgbàlódé ti won fún raa won. Àwon aláwò funfun yìí ló sì wá ń dá iye owó tí ohun erè oko tó ń wá láti ilè àwon aláwò dúdú yíò jé, èyí ti ó ń túmò sí pé, owó àwon aláwò funfun yìí ni dído lórò àti òdìkejì àwon ènìyàn aláwò dúdú wà. Owó àwon aláwò funfun yìí ni ètò orò ajé àgbáyé wà, tó bá sì se wùn wón ni wón ń lò ó. Abálájo tó fi jé owó tí wón ń ná nílùú won fińse ìdíwòn pàsípàrò ojà ní ojà àgbàyé. Kódà, àwon orílè èdè kan tó ní àwon ohun àmúsorò kan tí àwon aláwò funfun yìí ò fi béè ní, bíi epo ròbì ò he è dá ohun kan se lórí ohun àmúsoròwon yìí láì sí owó àwon aláwò funfun yìí níbè. Abálájo tó fi sòro láti rí orílè èdè aláwò dúdú kankan nínú àwon orílè èdè tó ti gòkè àgbà. Òwó àwon aláwò funfun ni agbára ètò orò ajé àgbéyé wà, àwon ló sì ń pàse fún àwon orílè èdè tó kù ní pa onà tí won yíò gbà se ìjoba àti ònà tí won yíò gbé orò ajé won gbà, tí wón bá fé àjo sepò dídán mórán pèlú àwon.