Ìkọ́ni
From Wikipedia
GBADAMOSI TEMITOPE THOMAS
ÌKÓNI: TEACHING
Kíní a mò sí ìkóni?
Ìkóni túmò si ìlànà ti àhún gbà láti fii òye hàn láti ìran kan dé òmíràn àti láti ènìyàn sí elòmíràn. Ní ìdàkejì èwè, ìkóni lèè túmò sí ìbáwí tàbí ìtósónà láti òdò enití ó ju eni lo. Àmó ki a máa fi òpá pòòlòpoolo pa ejò, ìkón tòní dá lórí ti Òye, Ìmò tàbí Èkó.
Tí bá ní kí a woo bi ìtàn ìkóni sé bèrè, a máa tó òpòlopò odún séyìn. Akòleè so pàtó ibi ti ìkóni ti bèrè, nítorí pé orílè èdè kòòkàn àti àkójopò àwon ènìyàn níbikíbi lóní ìlànà ti wón ń gbá kó àwon ènìyàn tiwon. Sùgbón orílè èdè bíi Gíríìsì (Greece) tí ìsirò ti bèrè, ile Lárúbáwá (Arabia), ile isreeli ati béè béè lo, wa nínú àwon irú ènìyàn tí ó tayo nínú ètò ìkóni. Àmó ètò ìkóni bí a sè mò ti di àtowódówó débi wípé olúkúlùkù lóti gbàá ti wón sì ti fi tún orílè èdè won tò.
Bí a ti se ń kóni se òtòòtò láwùjo, bí ati se lèe kó omodé yàtò sí bí ati se lèe kó òdó lángba béè ni ti òdó langba náà yàtò sí ti àgbàlàgbà. Gbogbo wa lamò wí pé omodé a máa tètè kó èkó láti ibi àwòrán, àwò àti àfihàn. Nítorí ìdí èyí, àwon ìwé tí alákòbèrè bíi aláwìíyé dára púpò fún èkó àwon omodé.
Èwè, tí àwon omodé wònyí bá déé ilé èkó girama ìlànà kíkó àti mímò won yóò ti yàtò díè sí ti ilé èkó alákòbèrè. Ní pele yìí, a óò tí máa fi yé won bá wón se leè fi owó ara won see àwon ohun tí wón ń kó won wònyí, béè gégé ni won oo ti máa gbáradì fún ilé èkó gíga. Ní ilé èkó girama èwè, àwon ohun ti àwon akékò óò máa há sórí – àkósórí àwon akékò yóò din kù, yàtò sí tii ilé èkó ‘Jéléósimi’.
Njé tí abá dé ilé èkó gíga, òpòlopò ìyàtò ni yóò ti wà nínú bi ase ń kóni. Ilé èkó gíga ilé ogbón, ilé èkó gíga ilé òmìnira. Ní ilé èkó gíga akékò ní ànfààní lati se ohun tówùú nígbà ti ó bá fé tí kòsì olùkó tí yóò yèé lówó wò. Ìkóni nílé èkó gíga yàtò gédégédé sí ti ilé èkó girama tàbí alákòóbèrè.
Ní ilé èkó gíga, akékò ló nílò láti se isé jù, nítorí péé; ní òpòlopò ìgbà, olùkó yóò kàn wá láti tó akékò sónà ni, akékò ni yóò se òpòlopò isé fún ra rè.
Ìkóni ni orílè-èdè yi ti dojú kó òpòlopò ìsòro tí ósì ti ń se àkóbá fún ètò orò ajé àti ìdàgbà sókè ilè yí. Tí abá ni kí áwòó láti ìgbà ìwásè fún àpeere, ètò ìkóni dára ni ilé èkó alákòbèrè, èdè Yorùbá ni afi hún kó akékò láti ilè kí àtó kii èdè òmíràn bòó, àmó ni báyìí èdè gèésì ni afi ń kó akékò tí òpòlopò won si ń so èdè Yorùbá nílé. Èyí lómú kí ó jé wípé òpòlopò kò leè so èdè Yorùbá kó já gaara láì má fii èdè gèésì kòòkan bòó, béèni òpòlopò kò sì leè so èdè gèésì dáradára. Òrò wa dàbíi “eni tí ófi àdá pa ìkún, ikún sálo àda tún sonù”.
Kí ń tó fí gègéèmi sílè, gbogbo wa lamò wí pé ni àìsí ìkóni kòleè sí ìmò, ni àìsí ìmò láti ìran kan dé òmíràn; kò leè sí ìdàgbà sókè, ni àìsí ìdàgbà sókè èwè, kò leè sí ìlosíwájú, ìlú tí kò bá sì ní ìlosíwájú ti setán láti parun ni. Fún ìdí èyí a óò ri péé ìkóni jé ohun kan gbógì tí a kò leè fi seré ní àwùjoo wa.
Èkó dára púpò
Èkó lóni ayé táawà yi sé
Èkó lóhún gbéni dépò gíga
Èkó lóhún gbéni dépò olá
Èkó dára púpo
Èkó lóni ayé tí awà yí sé.
ÌTÓKASÍ (REFERENCE)
i. D.F. Odunjo - ‘Alawìye Apa keta’
ii. B. Onibonoje – ‘Iwe Ikoni Yorùbá
iii. White Shear – ‘ Teaching skills’