Ìmọ-ẹ̀rọ
From Wikipedia
SALAU IDAYAT OLUWAKEMI
ÌMÒ ÈRO
Bí a bá ń sòrò nípa ìmò èro bí akò bá sòrò nípa ìmò sáyénsì, a jé pé à ń rólé apá kan nìyen. Báwo ni a ó ò se pé orí ajá tí a kò níí pe orí ìkòkò tí a fi sè é? ìmò sáyánsì ló bí ìmò èro. Sáyánsì ni yóò pèsè irinsé tí ìmò èro máa lo láti fi se agbára.
Ònà méjì ló ye kí á gbé àlàyé wa kà nígbà tí bá ń sòrò nípa ìmò èro.
(1) Ìmò èro àbáláyé (Anciant technology)
(2) Ìmò èro ìgbàlódé (Modern technology)
ÌMÒ ÈRO ÀBÁLÁYÉ
Ní ìgbà àwon baba ńlá wa, tí ojú sì wà lórúnkún, ònà láti wá ojútùú sí ìsòro tó wà láwùjo bóyá nípa ilé gbígbé, aso wíwò oúnje jíje ló fà á tí àwon baba ńlá wà fi máa ń lo ìmò sáyénsì tiwańtiwa láti sèdáa àwon nnkan àmúsagbára lásìkò náà. Òpò nínú àwon ìmò èro ìgbà náà ló di isé ò òjó tí àwon baba ńlá wa ń se lásìkò náà. E jé ki á mú lokòòkan.
Oúnje jíje
Yorùbá bò wón ní:
“Ohun tá a jé làgbà ohun táá se. Wón á tún máa so pé bí oúnje bá kúrò nínú ìsé, ìsé bùse”. Ìdí nìyí tí wón fi wá ohun èlò lati máa se àwon isé òòjó wón bi Isé àgbè.
Ìsé àgbè ni isé ìlè wà. Àwon baba ńlá wa máa ń lo orísìírísìí irin ìsé láti wá ohun jíje lára won ni àdá, okó, agbòn, akóró àti béè béè lo.
Isé Ode,
Isé ode jé isé idabo fún ìran Yorùbá. Ìdí ni péwu ló jé nígbà náà. Isé àgbè gan an ni ojúlówó isé nígbà náà lára àwon irin-isé tí àwon ode máa ń lo ni, okó, àdá, ìbon, òògùn àti àwon yòókù.
ASO WÍWÒ.
Nígbà tí a ba jeun yó tán, nnkan tó kù láti ronú nípa rè ni bí a oo se bo ìhòhò ara. Èyí ló fà á tí àwon baba ńlá wa fi dógbón aso híhun.
Bí ó tilè jé pé, awo eran ni wón ń dà bora lákòókó náà, sùgbón won ní òkánjùá ń dàgbà ogbón ń rewájú ogbón tó rewájú ló fàá tí àwon èèyàn fi dógbó aso hihun lára òwú lóko. Láti ara aso òfì, kíjìpá àti sányán ni aso ìgbàlódé ti bèrè ILÉ GBÍGBÉ.
Bí a bá bo àsírí ara tán ó ye kí á rántí ibi fèyìn lélè si. Inú ihò (Caves) la gbó pé àwon eni àárò ń fi orí pamó sí í sùgbón bí ìdàgbà sókè se bèrè, ni àwon èèyàn ń dá ogbón láti ara imò òpe, koríko àti ewéko láti fi kó ilé.
ISE ARÓ (ALÁGBÈDE)
Bí a bá ń sòrò nípa ìmò èro láwùjo Yorùbá bí a kò ménu bà isé alágbède, a jé pé àlàyé wa kò kún tó. Isé aró túmò sí kí a ro nnkan tuntun jáde fún ìwúlò ara wa. òpò nínú irinsé ìmò èro tí àwon àgbè ńlò ló jé pé àwon alágbèdé ló máa ń se e. Irinsé àwon òmòlé, ahunso, àwon alágbède ni yóò ròó jáde. Irinse àwon ode, àwon òmòlé àwon alágbède ló ń ro gbogbo rè.
Ìmò èro gan-an lódò àwon alágbède ló ti bèrè. Tí a bá se àtúpalè ÈRO yóò fún wa ni
e - mofiimu àfòmó ìbèrè
ro - òrò-ìse adádúró
e + ro ---- > ero.
Ríró nnkan ntun jáde ni èro ìmò sáyénsì gégé bí ń se so sáájú ló bí ìmò èro. Ó ye kí á fi kun un pé, opón ìmò èro ti sún síwájú báyìí. Ìdí èyí ni pé ìmò èro to ti òdò àwon òyìnbó aláwò funfun wá ti gbalégboko. Àwon ònà tí a ń gbà pèsè nnkan ríro ti yàtò báyìí.
ÌMÒ ÈRO ÌGBÀLÓDÉ
Léyìn ìgbà tí òlàjú wo agbo ilé Yorùbá ni ònà tí a ń gba se nnkan tó yàtò. Ìmò ero àtòhúnrìnwá tí mú àyè rorùn fún tilétoko. Sùgbon ó ye kí á rántí pé ki àgbàdo tóó dáyé ohun kan ni adìye ń je. Àwon nnkan tí adìe ń je náà lati sàlàyé nínú ìmò èro àbáláyé. Isu ló parade tó diyán, àgbàdo parade ó di èko. Ìlosíwájú ti dé bá imò èro láwùjo wa. E jé kí á wo ìlé kíkó àwon ohun èlò ìgbàlódé ti wà tí a le fi kó ilé alájàméèdógbòn tàbí ju béè lo.
Ìmò èro náà ló fáà tí àwon mótò ayókélé fi dáyé. Àwon nnkan amáyéderun gbogbo ni ó ti wà. Èro móhùnmáwòrán, asòròmágbèsì, èro tí ń fé ategun (Fan), èro to n fé tútù fé gbígbóná (air condition) Àpeere mìíràn ni èro ìbánisòrò, alagbeeka, èro kòmpútà, èro alukálélukako (Internet).
Gbogbo àwon àpeere yìí ni ìmò èro ìgbàlódé tíì máyé derùn fún mùtúmùwà. Àwon àléébù ti won náà wa, sùgbón isé àti ìwúlò won kò kéré rárá.