Ìtàn àkọọ́lẹ̀ Yorùbá
From Wikipedia
THOMAS PETER TAIWO
Ìtàn Yorùbá se di kíko sí lè (Yorùbá Orthography)
Láti ayébáyé, èdè Yorùbá lábé ìpínsí sòrí tí ògbénì thamstrong (1964) se fún àwon èdè gbogbo èdè Yorùbá bó sí abé ìpín èdè “KWA”. Èyí sì jé béè nítorí pé èdè olóhùn (tonalanguage) ni Yorùbá jé. Gégé bí a se mò pé télè-télè rí, a kì í ko èdè Yorùbá sí lè, sí so nìkan ni a ń so ó lénu. Sùgbón nígbà tí àwon òyìnbó aláwò funfun dé tí òwò erú si bèrè ní pere wón bèrè sí ní í kó àwon omo bíbí ilé Yorùbá lérú lo sí òkè-òkun. Èyí tèsíwájú fún ìgbà pípé kán-fin-kése títí di àsìkò tí ìjoba àpapò àgbáyé gbìmò pò ti òpin sí òwò erú yìí. Fún ìdí eléyìí, ó di òranyàn kí á dá àwon erú wònyí padà sí ibi tí wón ti sè wá. Èyí ló mú kí òpòlopò àwon ení tí wón jé omo bíbí ilè Yorùbá padà sí ilè won. sùgbón ní owó àsìkò ti wón fi wà ní oko erú yíì ni wón ti ń se èsìn jíjé-omo-léyìn-kírísítì (chiristanity) Àwon òyìnbó amúnsìn yìí sí rí i ní òranyàn pèlú láti se agbára lórí i bí èsìn yí yóò se máa tèsíwájú láàrin won. Èyí gan-an ló mú kí won se akitiyan lórí bí won yóò se se àyípaà ìwé-mímó nì –Bíbélì sí èdè Yorùbá. Nínú sí se eléyìí ó se pàtàkì láti rí i dájú pé omo bíbí ilè Yorùbá tó sì jé gbédè-gbijò èdè náà wà ní bè àti kí ó sì kó ipa takuntakun nínú sí se àyèwò, àfikún, àyokúrò àti afótónu tó yaarantí ló rí isé náà. Àwon ènìyàn bíi Humnah Kilham (1891) John Rahar, Gollmer and Bowdich (1817) àti Àjàyí Growther (1815) ló bèrè isé lórí kí kó létà àti àwon ònkà jo. Okùnrin kan tí ń jé Bowdich ni eni àkókó tí ó kókó si sé lórí i àwon ònkà Yorùbá bí i, óókan, ééjì, ééta títío do ri i ééwà-á ó sì se àwon isé yìí í ní odún (1817). Hamah Kilhar ní (1828) náà sísé lórí kíko sí lè èdè tí à ń ménu bà yìí. Ó fún wa ní ìlànà méjì tí ó se pàtàkì jù nínú isé rè.
(a) Ó dá bà á kí á máa lo àwon ìlànà tí Roma bí i – a e i o u.
(b) Ó tún ní àwon òrò tí ó ní kóńsónántì méjì tí ó tè lé ara won.
- House - Ile
- Fire - Ina
- Hoe - Oko
Òkan nínú àwon akoni oníyanjù yìí òmíràn ni Edwin Morris ni odun (1841) Òhun náà sisé lórí faweli and Kóńsónántì Yorùbá. ó sì so pe: A ní àwon fáwélì eléyò ó a àti I, a ati u, e ati u, e ati I àti béèbéè lo
Ó tú kíyèsí pé a ní àwon kóńsónántì (i) ts (ii) g (iii) j (iv) ng (v) ch (vi) hh. O ko awon oro kan kale díè nínú nìyi
axe - edidu , akike, adding .
bed - akete, akite, ebiso
back - en
ants - ehrung abbl.
Eni tí ó tún sísé tí a le è kà isé àseparí ni Ajayi Crowther ní odún (1843) ó sì pè é ní (Vocabulary of the Yorùbá Lang.). Àwon Fáwèlì àti kóńsónántì rè nì wònyí. a, b, d, e, f, g, h, i, j, k, l, m, h, o, o, p, r, s, t, u, w, y. Ó sì tún ní àwon kóńsónántì oníbejì bí i. gb, ng, sh. Crowther ko ni e ati o sùgbón o mo pe yàtò gedegbe wa laarin “o” ati “o” ati láàrin “e” ati “e” ti o si fi han nipa ki o won bì:
e - eh = Ẹ̀wà
o - oh = Ọjà
Léyìn Crowther, a ò gbodò gbàgbé àwon yeekan-yeekan bi, Henny Venn (ijo CMS), Àlùfáà Charle Andrew Gollmer (German), Alufa Heny. Townsend, Samuel Johnson abbl. Tí wón se akanse ise takun-takun lórí bí èdè Yorùbá se di kí ko sèle. Akiyesi pàtàkì kan ti a lee se nínú gbogbo atotonu lórí bi èdè Yorùbá se di kiko sile yin i pe nínú gbogbo àwon to sise yi ti won je àwon oyinbo atohun rinwa alawo dúdú kan ni a timenu ba, sùgbón èyí ko fi bée ri be. Àwon dúdú ti won ko pa nínú ise yìí naa po jojo sùgbón fún ìdí kan tàbí òmíràn ti a ko ni lee sòro nípa won. Ìwònba kéréje tí a leè ménu bà nínú ìtàn bí èdè Yorùbá se di kíko sílè nì yí.