Ẹ̀kọ́ ìgbà àtijọ́
From Wikipedia
Sheba, Theophilus Rotimi
SHEBA THEOPUILUS ROTIMI ÈKÓ ÌGBÀ ÀTÌJÓ
Èkó ìgbà àtiijó dára púpò
Ó sì tún gbayì láwujò
Bí ènìyàn kò bá kó èkó
Bí èni wáyé asán lohúwarè jé
Láyé àtijó, ètò èkó dára púpò nítorí ìbèrù wá láàrin akékòó sí olùkó rè, bí akékòó ayé àtìjo bá fé bá Olùkó rè sòrò, ìrèlè ni yóò fi so ó fún olùko pàápàá mòhun ara rè lódò akékòó ó sì mo ohun tí ó tó sí òhun láti so sí akékòó. Eléyìí wá mú àrífún kúrò lódò àwon méjéèjì, ìdí nìyí tí akékòó fi bèrù Olùkó tí kò fi gbó gbójú gan-an síi ní ayé ìgbànáà. À kò lè fí èkó ìgbà àtíjo wé tòde-òní, nípa pé, àwon onkòwé tó wà bélè dàbi alárá sí ti òde-òní àti pàápàá, àwon akékòó tó kó èkó kò pò nígbànáà bíi ti ayé òde-òní. Nítorí pé, kí òbí tó lé rí owó ilé-ìwé san ìsòro ńlá ni ó jé àyàfi àwon tí òbí rè dán tó. Bí àwon akékòó ti se ń kékòó dára ju ti tò de òní fún àpeere, bí ènìyàn bá fé bèrè ìlé-ìwé alákòóbèrè, won yóò kókó fún nípatákó láti máa fi sisé sí, léyìn èyí yóò wà bèrè pèlú ìwé-kíkà sùgbón lóde-òní, ìwé kíkà ni wón fi ń bèrè wón ti fagi lé pátákó. Ìlò pátákó yìí jé ohun tí ó ń se tàbí tí wón kóo sùgbón òlàjú ti mú gbogbo rè doríkodò, àyípadà bi dé bá won. Àwon òjògbón bí wón kékòó gboyè kò pò látijó rárá, eléyìí kò mú ìwé kíká pò àti pé kòsí yíya isé sótò fún àpeere, ìmo science, commercial, tàbí Arts. Sùgbón ní ayé òde-òní àwon irúfé isé wònyí ti ya sí ipá. Ìmò ìjìnlè ayé òde-òní tí mú kí òpòlopò èrò amúséyá wà lórísirísi fún àpeere, àwon èrò ayárabíàsá, èro àntèwé àti béèbéè. Eléyìí mú kí ètò èkó gbòòrò láwùjo, ní ìdàkejì ìwe ó bá ètò èkó jé nítorí kò mú akékòó máa lo sí ilé-ìwé déédéé, ohun ti o si fa nípa won yoo ni awon ero wonyi sile ohun tí wón bá ń se tàbí tí wón ń kó won ní ilé ìwé gbogbo rè ni yóò máa gbélé gbó. Èyí ló fàá tí akékòó mìíràn kò fi mo nnkankan rárá àti pé àwon akékòó ní ètó kòòkan tátijó, sùgbón ní ayé òde-òní, akékòó kò ní ètó kankan mó. Ohun bí ó tún se pàtàkì jùló tí ó jé kí ìmò ètò èkó dára nipé, bí wón ti ń kó won ní ìwé béè won ń kó won ní ogbón tí ènìyàn fi ń gbé ìlé-ayé àti ìmò ìbílè. Látijó, sekondirì kò kokáa modern 3 nígbànáà sùgbón ló de-òní, ó ti pín sí ìpele méta kí won tó wo ilé-ìwé gíga. Lótìító, la ríi pé àwon ohun amúséyá òde-òní dára, sùgbón ó mú kí àwon ènìyàn ya òle, ó kúkú dára kí a má ni won rárá nítorí, gbogbo ohun tí àwon ènìyàn bá fé se orii rè ni wón tí ń se wón. Èkó ìgbà àtijó kò gba òle láàyè, ó sì se ànfàní púpò fún akékòó tí ó dáńtó, ó sì tún tára nítorí ìmò ìjìnlè tí so rò mó o. Bí ènìyàn bá ka ìwé látijó, inú òbí a máa dùn sí irú omo béè láì tíì parí èkó láso títí kó ní àkísà bí àgbà, kò sí bí ènìyàn se ka ìwé tó lóde-òní tí ó máa dàbi ti omo àtijó. Òlàjú mú kó èkó òde-òní gbòòrò síi, eléyìí lá fàá tí àwon òjògbón orísirísI fi se ìwé jáde lópò yan buru àti àwon èro amúséyá tó tún wà tún mú kí ó derùn fún won láti se, ó wá mú kí ètò èkó gbayì gbèye. Látijó, tí kò tí sí àwon èro amúséyá wònyí ètò èkó tún dárá, ó tún gbayì nígbàáàju tòde-òní àti pé, èkó àtijó yìí fún wa ní agbára ó sì tún so ènìyìn di ńlá lojú àwon ènìyàn, ìrú eni béè sì kógo já láwùjo. Eléyìí ló mú ni so pé èkó ìgbà àtijó dára ó sì tún seémúyengàn, bí ohúnrarè kò bá èkó, bí eni wáyé asán ni, nítorí eni tó kàwé látijó bí oba lórí.