Ẹ̀kọ́ nípa èdùmarè
From Wikipedia
Awodele, Oluranti Eunice
AWODELE OLURANTI EUNICE
ÈKÓ NÍPA ELÉDÙMARÈ
Yorùbá gbàgbó wípé elédùmàrè ni ó dá ayé àti òrun pèlú gbogbo ohun tí ń be nínú won. Yorùbá sì gbàgbó wí pé kò sí ohun tí elédùmarè kò le se, òhun ni wón fí ń ki elédùmarè wí pé oba àìkú, Oba àtíyìn, aláyé gbelegbele bí eni láyin, Oba atélè bi eni téní, Oba até sánmo bí eni téso, àlorun-làye-alàye-lorùn, olowó gbogbo ti yo omo rè nínú òfìn aterere káríayé. Bí a bá ti ojú inú wò ó á ri wí pé àwon oríkì yìí fib í olódùmarè se jé hàn láwùjo Yorùbá. Ohun tí a ń so ni wí pé òpò ìtàn iwásè ló so wípé bi olódùmarè se dá ayé àti òrun. Èrò Yorùbá ni pé kò síohun ti a lè fi wé elédùmarè nitorí àwon àwòmó tàbí àbùdá rè tó tayo awari èdá. Fún àpeere, elédàá, àlèmí, oun ló ni osán àti òru, olójó òní, òní omo olórin òla omo olórun òtunla omo olorin, ìrèmi omo olorin, òrún ni omo olórin. Yorùbá máa ń so wí pé isé olórun tóbi tàbí àwámárídì ni isé olódùmarè. òrúnmìlà ló fèyìntì, ó wo títítítí ó ní èyin èrò òkun, ero òsà n jé èyin ò mò wí pé isé elédùmarè tòbí. Olódùmarè gégé bí alágbaára láyé àti lórun a dùn ń se bí ohun tí elédùmarè lówó sí a sòro se bí ohun tí elédùmarè kò lówó sí, a lèwí lese, asèkanmákù, ohun tí Yorùbá rò nípa elédùmarè ni wí pé kò sí nnkan tí kò le se àti wí pé ohunkíhun tí ó bá lówó sí ó di dandan kí ó jé àseyorí àti àseyege. Ní ònà míràn Yorùbá tún gbàgbó wí pé olórun nìkan ni ó gbón, ìdí ni ìyí tí Yorùbá fi máa ń so omo won ní Olórungbon elédùmarè rí óhun gbogbo, ó sì mo ohun gbogbo arínúríde, olùmòràn okàn. Yorùbá gbàgbó wí pé ojú olórun ni sánmò Yorùbá so wí pé amùokùn sìkà bí oba ayé kòrí o, Oba òrùn ń wò ó, ki ni è ń se ní kòkò tí ojú oba òrun kò tó. Yorùbá gbàgbó wí pé elédùmarè ni olùdájó ìye ni wí pé elédùmarè ni adájó tó ga jù láyé àtòrun, òun ni oba adáké dájó, àwon òrìsà ló, máa ń je àwon orúfin níyà sùgbón olorun ló ń dájó. Bí àpeere ní ìgbnà kan láyé ojóun àwon òrìsà fèsùn kan òrúnmìlà níwájú elédùmarè, léyìn tí tòtún tòsì won rojó tán elédùmarè dá òrunmìlà láre. Odù ifá kan o báyìí wí pé Òkánjúà kìí jé kí á mo nnkanán-pín, adíá rún odù mérìndínlógún níjó tí wón ń jìjà àgbà lo ilé elédùmarè, nìgbà tí àwon omo irúnmolè mérìndínlógún ń jìjà tani ègbón tan i àbúrò, wón kí ejó lo sí òdò elédùmarè, níkeyìn elédùmarè dájò wí pé èjìogbè ni àgbà fún àwon Odù yókù. Yorùbá gbàgbó wí pé onídájó ododo ni elédùmarè ìdí nì yí tí Yorùbá fi máa ń so wí pé olórun mún-un tàbí ó wa lábé. Pàsán elédùmarè Ní ònà míràn Yorùbá gbàgbó wípé ota àìkú ni elédùmarè Yorùbá máa ń so wípé rèrèkufè a kì í gbó ikú elédùmarè. Ese ifá kan ìyen ni ogbè ìyèfún so fún wa wí pé: -
Rèròfo awo àjà ilè
Ló dífá fún elédùmarè
Tí ó so wí pé won ò ní gbó ikú re laalaa.
Ní àkótán Yorùbá gbàgbó wí pé oba tó mó Oba tí je ni èérí ni elédùmarè ń se. Òun ni àwon Yorùbá ń pè ní alálàfunfun òkàn àwon Yorùbá gbàgbó wí pé bí àwon ángélù ti jé olùrànlówó fún elédùmarè lóde òrùn béè náà ni àwon òrìsà jé orùrànlówó fún elédùmarè lóde ayé. Awon òrìsà wònyí sì ni wón jé alágbàwí fún àwon ènìyàn lódè elédùmarè.