Ẹ̀kọ́ nípa ìhùwà
From Wikipedia
Asawale, Paul Oluwole
Asawale
ASAWALE PUAL OLUWOLE
ÈKÓ NÍPA IHUWA
Ìwa ni Yoruba pen i oba awure. Eyi ni pé tí ènìyàn ban íwà rere, ohun gbogbo yoo máa lo déédéé fún un, àseyorí yóò jé tirè, kò sin i se aláinì. Kí ni ìdí èyí? Ìdí èyí nip é ìwà rere rè yóò je ki o máa pàdé àláàánú àti olùrànlówó ti yóò gbé e dé ibi ire. Omolúàbí ni a ń pe irú u won. Kì í se eni tí ó bá lówó lówó nìkan ni a wá ń pè ní “Omolúàbí” o, kìí sì íse gbajúmò tàbí òjògbón, kodà olówó, ojògbón tàbí gbajúmò ní àwùjo mìíràn lè má jé omo lúàbi. Eni ti a bá pè ní omolúàbi ní eni ti ó ko gbogbo ìwà rere pò tí o sì jé eni ti élégbé àti ològbà kà sí ajúlówó ènìyàn. Yorùbá bò wón ní “ìwà rere lèsó ènìyàn, àti pe “orúko rere sàn ju wúrà àti fàdákà lo. Láti inú oyún ni Yorùbá ti n ko àwon omo won ni iwa bi a ti se n hùwà omolúàbí. Fún àpeere, Yorùbá á ní Èèwò ní fún aláboyún láti jalè tàbí mú nkan ti kìí se tirè. Kìí se nitori aláboyún yìí fúnra ara rè, sùgbón kí omo inú ré ba à máa se àfowora. Wón gbà pé omo yìí lè kó ìwà yaa rè ni inú oyún. Eyí kì í sí ì se ìwà omolúàbí. Wón n kó omo náà ní ìhuwaàsí rere ni. Wón tun ní aboyún kò gbodò jé ìgbín. Wón ní ìdí èyí ni pé omo náà yóò máa da itó ní igbà ti ó bá dàgbà. Ìwà ki a maa fón itó tí a bá ń sòrò, tàbí wakó ti a bá n sun, kìí se ìwà omolúàbí, Yorùbá a ti fi máa kó omo láti inu oyún: Bí a ti se ń bí omo Yorùbá ni a ti ń ko ní bí a tí ń fi ègbé eun pèlú ònà ìté sí ibusun rè. Tí a bá tún ń wè é, a ó nàá tòtò, a ó so ó sókè sódò láti máa fi ko o díè díè bi á sé ń mójú to ara eni ki a maa baà je oló-kùnrùn sí omolúàbí láwujo won. Ekó ilé se pàtàkì nínú ìwà omolúàbi ní ilè Yorùbá. Èyí si bèrè láti ibi ìkíní. Omo tí ó bá pàdé àgbàlágbà lónà tí ó kàn kojá, tí kò kí àgbalàgba náà, wón á ni kò ní èkó ilé, tàbí àkóìgbà ni o ń seé. Ìdí nìyí ti o fije pé lati kékere ni àwon òbí omo ti maá kó omo rè bí a se ń kí ènìyàn. Okùnrin gbódò dòbálè kí obinrin sì kúnlè ti won bá ń ki ení ti o ju wón lo. Eyi yóò yo ìwà ìgbéraga kúrò ní ilé ayé omolúàbí Yorùbá yóò si fi ìwà ìrèlè àti ìbòwò fágbà kóo. Ona mìíran ti Yorùbá fi n kó awon omo won ni ìwà omolúàbí nì ààló, ìtàn, ààrò, ìmó ati béèbéè lo. Ninú aalo apagbe Yorùbá ni awon itan to da lorí orísírísí awon nnkan ti o wa mí ayìka nla ti a ti hun itan kan mo lati ko ní logbon ihunwasí lawujo, o le je nipa wa ijapa kan, Igi iroko, Igbin, abuke, osupa, eera ati béèbéè lo. Aalo yi le fi han pe iwa ole tabí odale ko dara ní awujo. Awon owe Yorùbá paapaa ni ko wa ní ona iwa omolúàbí. Yorubá le ní “karìn ka po yìye níí yeni”. Eyì fi han pe a n ko ìwà ibaraenigbepo tí o n mu awujo toro. Latí keekere nì àwon obì omo Yorùbá tì maa n ko wa láti má lè pe nnkan okunrin wa tabí tí obìnrìn wa ní oruko. Eyí mu owo wa fun ihoho okunrin ati ti obinrin eyi ko fi aaye gba àwon ti ko ba tí dagba to ni aye tabí oko latí maa sese oko ati aya, eyì ni latí maa ba ara won ní asepo tí o ba to akoko latí loko tabí laya obì nì o n ba ní wa oko tabí aya, won a sí ní alárenà ti yoo moju to ayorísí eyì. Won kìì je kì won ba ara se isekuse depodepo pe won le tìbe ko arunkarun bíi ti aye ode oní (AIDs). Ti wa ba tile tun se igbeyawo tan won a tun wa ní abe eko awon obí fun itónìsona nipa iwa omolúàbí nínú ebì. Won a maa ko bí a ti n jé bale rere atí aye rere. Iran Yorùbá kìí ya ile ní aye igba ken, odede kan-naa ni baba, iya, omo ati iyawo omo ati omo-omo jo maa n gbe. Bí won tile gbe ní otooto bì tí aye ode oni, iya oko a maa lo loorekoore si ile awon omo re yìí lati mo ihuwasì won, lati to won sona, ati lati fi to baba-oko naa leti. O di ìgbá ti baba oko ati ìya oko ba ku nki aya tuntun ati oko rè yìí to bo lowo idanileko iwa omolúàbí awon obì yìí awon alagbaagbe ati ibatan won nì o ku ti yoo waa maa ko won lo pelù orìsìrìsì irìrì atì ayorìsì iwuwasì awon enìyàn lawujo. A ko gbodo gbagbe latí fi ye wa pe Yorùbá gba pe oju mejí ni o n bì omo sùgbón igba oju ni o wo o, ti o bar ì bee, a je pe awujo Yorùbá naa ní ko omo yato sì awon obì, koda Yorùbá a tun maa so pe omo ti ko ba gbon nile, ati ita nì a ti maa n ko o wa. Idí eyí ní iyawo tí o bo wa sinu ebì mìíran gbodo fi iwa omolúàbí han nínú ebi tuntun tí o dara pó mo bi bee ko won a ní boya ko ti ile rere wa tabí pe kó kan gbá eko ní. Obìnrin gbodo mo bì a ti se n toju ile - gbale, foso, dana, okunrin gbodo mo bi a se n sìse daadaa latí toju ebì nì aye atijo ise agbe nì ko gbodo maa na iyawo re. Titi dì ojo iku ni Yorùbá n ko eko nì pa ihuwa nìtorì iwa omo eda ko duro loju kan o n yì iwa pade nì ojoojumo ojoojumo naa sì nì a n ba ènìyàn orìsìrìsì pade pelú iwa otun. Eyi n ní kí eko kííko nìpa ihuwa eda gbooro sí ti eda sí fi n kogbo sìí koda tí ènìyàn bat í ku tan Yorùbá a tun ma koo nì eko nipa ihuwa lorun won a nì mojokunrin ma jekolo ohun ti won ba n je lajule orun nìkì o ma ba won je eyí nip e kì o jowo ma tapa sì awon iwa omolúàbí tì won n hu lawujo orun o. Agbalogbagbo wa ni pe eko ihuwa rere ni mu alaafa ba awujo eyí ti o n mu ibára eni gbépò rorùn. Èyí si ni afojusun awon Yorùbá ti won ti n ko omo lásò láti kékeré bí imolè gégé bí àsá won. láti inú oyún ní èkó ìhùwá ti bèrè nitori wón gbà pé òwú ti ìyá gbon ní omo yóò ran, ki o má baà wá ran èyí tí kò tonà, wón a ti máa fi òfin àti èèwo ìdílé tó ìyáare sónà omólúàbí. Yorùbá sí tún gbà pè ìwà wá nínú èjè, nítorí náà àwon òbí méjéèji ni lati roara se kí omo le kó èkó rere láti inú èjè wá nitorí “Bomo kò jo sòkòtò yóò jo kíìjìpá” Mo ní láti fi hàn pé èsìn kíristíànì àti ti lárúbááwá, tit a àti èkó ìmò mòóko-mòókò ayé òde òní ti ba òpòlopò ànfààní ti a wí fùn ìdánilèkó ìhùwà jé. Àwon òbí kò ráyè láti tí àwon àsà tí ó n kín yìí han tàbí kó omo wón mó Òmíràn kò tile mo ó mìní won. opé púpò lówó àwon onímò ìjinlè lórí èdè àti àsà Yorùbá tí wón so èdè àti àsà yìí dí ohun tí a ń kó ni ilé èkó gíga gbogbo. Kódà àwon òyìnbó ti n ti ìlu wón wa kóo. Bí ko jé béè ni, òpòlopò ònà láti kó èkó nípa ìhùwá omolúàbí Yorùbá ni kò bá parun. Obìnrín Yorùbá mìíràn kò mo aso ríró mo, sòkòtò ló wópò. Eyi ti o mo aso ríró kò mo itan pípadé bi o bá jókóò láàrin àwùjo. Ebí wón kó, wón kò gbé ilé gba èkó sùhúrù alábàato ni wón lo. Won kò sì ko won. Ìyàwó ko le gbé oúnje fún oko rè pèlú ìkúnlè lórí ese méjèèjì mo. Ebi rè kó, wón kò kó o nìlé. Èkó èmi kò jù o ìwo kò jù mí nì á ti kó o. Èyi sin i ko jé kí awùjo gún. Okunrin kò le sisé àgbè mó. Òle gba ayi ka kán isé díè owó nlá ni wón ń wá kiri. Eyí kii se ìwà omolúàbí won kó fi kó wá ní ìgbà ìwáse. Òsèlú àto òkada ni àwon omo ń lé ká. Èyí ko jé kí wón le tójú ilé bí o ti to. Awujo kò wá gún régé. Sùgbón ìgbàgbó wa ni pé oun gbogbo a padà bo sip o. Ayé á si re ibi aná tori “láálá to ròkè ilè ni o ń bó” A ko ni omolúàbí púpò láwùjo mó nítorí aiko èkó ìhùwàsí awujo