Ẹ̀kọ́ nípa eré-orin
From Wikipedia
Oladejo Kafaya
` OLADEJO KAFAYA
OHUN TÍ ORIN JE
Ní pàtàkì okan nínú àwon èyà, ewì ní orin jé. Ònà kan ò wojá orísìírísìí ní oríkì tí àwon ènìyàn tí ó jé onímò tí fún orin.
C.M. Bowa so wí pé:-
Songs one purposeful atlempts to put
Into coherent words, thoughts
And feelings which may in their
State be fair from coherent
“Ohun tí a lè pè ní orin ní nnkan
tí a rò lókàn tí a sì ko jáde
nígbà tí o dàbí eni pé a rí àwon
nnkan lo sàjòjì tàbí ju agbára
wa lo; nígbà tí a rò pé òrò enu
lásán kò ní í le sàlàyé bí ohun
yìí se ká wa lára tó.”
ÈKÓ NÍPA ORIN
Orin jé òkan lára lítírésò alòhun Yorùbá sùgbón ní òde-òní òpòlopò àwon lítírésò alohùn Yorùbá ni ó wà ní kíkosílè. A gbà pé lítírésò alòhun ní orin sùgbón kí ní lítírésò? Lítírésò tí ó wà ní opolo àwon bàbá wa lítírésò tía sòrò nípa rè le jé òrò geere, ewì? Eré oníse tàbí onítàn, Àwon oní gèésì kò gbà pé Yorùbá ní lítírésò nítorí ohùn ní àwon Yorùbá fín gbé lítirésò won jáde sùgbón àwon onímò tí o ti fun lítírésò ní oriki, sùgbón oríkì òjògbón Adébójè Babalolá (1967:7):- káàkan àgbáyé ó hàn gbangba pé ohnu tí ń jé lítírésò ní àkójopò òrò ní èdè kan tàbí ìjìnlè òrò tí ó já sí àrofò ìtàn, ewì, àló, ìròyìn tàbí eré onítan, ere akónilógbón sùgbón ORIN ní mo fè woo gégé bí àpeere lítírésò Yorùbá. Orin jé ìkan tí o wópò láàárin àwon Yorùbá nítorí orin jé ìkan tàbí ohun ìdárayá, ere láàrín omodé, a fí orin bá ènìyàn tàbí àwùjo sòrò. Orísìírìsii orin sí lo wa ńilè Yorùbá àpeere orin tí mo fé yèwò ní ORIN ÌGBÉYÀWÓ tí a si mò sí EKÚN ÌYÀWÓ àti ORIN OMODE
ORIN ÌGBÉYÀWÓ
Orin Ìgbáyàwó wópò láàrín àwon Yorùbá nítorí ìgbéyàwó jé ìkan ìdùnú láàárin àwon Yorùbá, ohun èdùn gidi ní ó jé pé púpò nínú gbògbò àti ìdí igi àsà Yorùbá tí a ba wo-wá-wèhìn nípa àsà àti èsìn abínibí àti àdá yébá Yorùbá kòòkan, a o ri i pe àmúlùmálà tí fere gba Yorùbá lowo wa pin, òpòlopò ènìyàn ní o ge ìyàwó tí won tí gbe nípa ekún ìyàwó sùgbón ní ayé àtijó o je ìkan o- kunkudii fún omo tí o losí ilé-oko láti sun-u. ojó ìbànújé papò mo ayò ni, sùgbón lójó yìí ìbànújé a teri ayò ba. ìbànújé yóó te’rí ayò ba nítorí pé odo iya ati bàbá ní omobinrin yìí tí n gbe láti ojó tí a tí bí i, ó mo níní-t’àní àwon òbi re, ó mo àsírí obi re awon obi re mo tire náà. omobìnrin náà ní àyè nílé bàbá re, ki a wa wo sunsun ki a so pe a yo omo náà kúrò bàbá re bí eni yo jiga. Aimo ohun tí omobinrin yóó ba nílé oko, àimò ìwà tí àwon ènìyàn tí o n lo ba níbe yóò máa si i orisiirisii nnkan ni o ma farahan nígba tí omobirin bá sunkún. àpeere méta
(i) lelele ní omobrin yoo maa ké wupe ki àwon obi àti agbaagba o súre fún òun
(ii) pèlu, ekun lójú ní omobinrin yóó maa fí opé àti imoore re han si awon obi re
(iii) pèlú èkun lójú ni omobinrin yoo fi ma se ìdárò ìpínyà oun àti àwon òré rè. láàárò ìyàwó yóò ti bó sóde léyun tí àwon òbí rè bá ti júwe ibi gbogbo tí yóò dé fún un tán àwon egbé rè, omoge tí kò ì woléko yóò tèle léyìn.
Ìyá mí ní d’ódò èyin
Nó gbá ìre tèmi kí n tóó máa lo
Ire owó, ire omo
Ire, kí má fí àbíkú sewó
Ire kí n má rìn rìn se àgbà
Mo bí, mo bí n t’omo kóóko
Mo pò mo pò n’t’ omo mèrùwá
Àbí-jà-gì-lá’jà n’ t’èkútée lé
Ire, àbíkú l’elédèé bí, elégbé mo ní o
Orí ó níí fún mi l’àbì gbìn omo.
Èmí ní ng ó ma máa lo nùun
Èmi àkóbí onídùndún mo olórí osó
N ó máa lo nù-un
N ò nì í lò ìlo eja, t’ ó lo
Tí ò dé’ núu ‘ bú
N ò níí loìlo akàn.
Àní tó lo tí ò d’ odo.
ORIN OMODÉ
Orin omodé náà pò ní orísìírìsi ònà nítorí òrin ní a tí dárayá láàrín àwon. Àwon omodé náà fí orin náà kó ara won lékòó tàbí kí won fí bá ara wón wí lórí ìwà ìbàjé tí wón. Àpeere orin omodé ní :- (i) Búúrù o
(ii) Eni bi eni
(iii) Bóóbo
(iv) Worú Búúrú o, bààrà o,
T’òtún yo, t’o si yo
E p’ara mó o,
T’ agbedeméjì yo fó fó!
Olórò bo o!
T’ohún yo, tòsì yo.
Sé kí n si i?
T’agbedemeji yo fó fó! si í!
WÒRÚ
Wòrú, o, wòrú, oko
Wòrú, ó, wòrú odò
Wòrú pa, ‘ka f’eiye je
Mo dé ilé mo rò fún baba
Baba na wòrú jojo,
Wòrú dà? Eye ti gbé e lo
Lábé ògèdè lábe òrombó
O ti se d’ abe ata
Ide wéwé nit í orisà
Sekesete ni ti ògún
E ba mi kìlò fún bálè
Kí o fún mi lododo pakájà
Gbogbo wa lo’ògún job í o,
ORIN ÌDÁRAYÁ NÍ ILÉ-ÌWÉ ALÁKÒÓBÈRÈ
Nínú àwàdà náà ní a tí ń mo òótó. Ó se pàtàkì láti kókó tóka sí i wí pé àwon àgbà ní ó sèdá àwon orin yìí fún àwon omode tí wón jé omo-ilé ìwé alákòóbèrè. Ète ní won pa láti ko àwon omo ile-ìwé ní èkó ní ònà tí o lè rorùn fún won ju láti máa rántí. Lóòtó ní àwon orin yìí wa fún ìdárayá súgbón síbè, orín yìí nnkan ní wón dá dé lórí ní pàtó, tí wón jé kókó inú àwon omo yìí.
Àwon kókó inú àwon orin ìdárayá yìí je móàwon àsà àti ìgbàgbó àwon àwon Yorùbá lórísìírísìí, èkó ìwà tí o dára ní àwùjo àtí gbígba omodé ní ìmòràn, àsà ìsèlú, isé òòjó, eré òsùpá {fún ìdárayá} ìmótótó àti ìnáání ohun tí ń se teni. Ohun mìíràn ní ìlànà èkó-ìwé kíkà bí i ìsirà. Ìgbàgbó èsìn òkèère àti ìtáákà èdè. A lè pín àwon kókó yìí sí abé ìsòrí méta
(i) Àsà àti Ìgbàgbó àwon Yorùbá
(ii) Ìlànà èkó ìwé kíkà
(iii) Ìdárayá.
ÀSÀ ÀTI ÌGBÀGBÓ ÀWON YORÙBÁ
Ìgbàgbó Yorùbá á lórí ìbà jújú kì í se kékeré rárá nítorí ÌBÀ jé nkan lára àsà àti ìgbàgbó Yorùbá. Yorùbá gbàgbó nínú ajunilo, nítorí náà ó se pàtàkì láti kó omodé nípa ìbà jújú láti fi pon ènìyàn lé. Tí omodé ba seré, tí àwon àgbà be ń ní ìkàlè, omodé gbódò júbà. Àpeere ìbà jújú ní ilé-ìwé alákòóbèrè:-
Í ba, Í ba, Í ba ba
Ìbà
Ì ba, Ì ba, Ì ba ba
Ìbà
Ìbà fún àwon tó o layé o
Ìbà fún àwon tó nilè o
eni bá jì nínú igbó
a júbà fún eni tó nigbó
Ìbà Ìbà Ìbà Ìbà
Ìbà fún omodé to bá seré
Tí omodé ba júbà àgbà
Ó dájú kò ní í sìse
Eti, Eh, Eh, Eh,.
ÌLÀNÀ ÈKÓ KÍKÀ
Àwon olùkó máa ń lo ìlànà orin láti ko àwon omo-ilé ìwé nì n nkan tí o máa sí won ní opolo. Nkan tí ó mú àwon ohun yìí wa yè ní àsà mò-ón-ko, mò-ónkà
Ìwé kíkó
Láìsí oko àti àdá
Kò ì pé o, kò ì pé ò
Ise àgbè ní isé ilèè wa
eni kò sisé, a màa jalè.
ÌDÁRAYÁ”-
Àwon omo-ilé-ìwe máa ń fí àwon orin dá ara won lára yá. Wón lára le ko irú orin béè láti se èfe tàbí fi se èébú. Àpeere orin ìdárayé láàrín àwon omo ilé-ìwá:-
Kí lagba fún won?
Bóòlù
Kí la lò fún won?
System
Èló la fún won?
4 – 0
(2) Ebí ń pa tísà
Ó yígbó èynìn lo
Tákútè mu lésèè
Ó rugi àkóba
(3) Kin mo fe fí olè se
láyé tí mo wá?
kí mo fé fi olè se
láyé tí mo wá
laiye fí mo wa
kàkà ki jalè
ma kúkú se erú
kí mo fe fí olè se
láyé tí mo wá.
Ení bá jalè a délé ejó
Eni ba jalè a dele ejó
A délé ejó
Adájó a wa fi èwòn tí lesè.