Animism
From Wikipedia
ADENIRAN ADEBAYO SAMUEL
ANIMISM
Ìgbàgbó Yorùbá Nípa OLórun
Kókó ló kó dé orí, kí irun tó hù níbè, èyí ni pé kí àgbàdo tó dáyé, ó ní ohun tí Adìye ń je. Nígbà tí igbá kò tíì lalè so nínú oko, nígbà tí ìtóò kò tíì lalè hù légàn, ó ní ohun tí a fi ń lùlù fún Aláàfin Òyó. Kánkándìkán ni wón fi ń lùlù fún Aláàfin.
Kí èsìn ìgbagbó àti mùsùlùmì tó dé ilè Yorùbá ni Yorùbá ti gbàgbó nínú Olórun, èyí ni wón mò sí Olú Òrun, gbogbo ènìyàn sì fé mo ibi tí wà. Tí wón bá ń lo nínú oko tàbí lójú ònà, tí wón bá rí ohun abàmì kan, tàbí igi tó dúró bí ènìyàn, kíá ni won yóò ti máa boó, ti won á sì máa fi orí balè fún igi náà láti lè fi títóbi Olórun hàn.
Yorùbá gbà pé Òkànlénírinwó irúnmolè ni Olódùmarè rán wá sí ilé ayé láti ìsálú òrun, tí wón sì rò sí oótù ifè, gbogbo àwon iránmolè yìí ni Yorùbá gbà pé wón jé iránsé Olódùmarè láti òrun.
Bí a bá gbó tí àwon Yorùbá bá ń sopé “orí mi o” tàbí “Olójó-òní o” Olódùmarè ni wón ń pè ní “orí” èyí tó dúró fún elédàá orí àti olójó-òní, èyí tó dúró fún eni tí ó ni ojó òní. Tàbí tí Yorùbá bá rí ohun tó ya ni lénu, wón a ní “Baba o” èyí tó túmò sí Olódùmarè.
Yorùbá gbà pé Olórun tóbi ju gbogbo èdá lo, ó sì jé eni tí wón gbódò máa bolá fún. Láti bolá fún u àti láti fi ìteríba won hàn fún Olódùmarè, wón ń fi isé owó rè pè é. Wón á ní Elédàá, èyí tó túmò sí eni tó dá òrun àti ayé; Òyígíyigì, èyí ni eni tó tóbi tóbè gée tí kò sí ohun tí a lè fi wé.
Oba awamaridi, èyí pé Olódùmarè jé oba tó ju gbogbo oba lo, Oba tó nínú rode àti tó sì dá gbobgo ohun tí n be lábé òrun ayé àti òrun. Láti fihàn pé Olórun ni Arímú-róde, Olùmò-okàn ni àwon babaláwo fi máa ń dífá pé:
“A mòòòkùn jalè
Bí Oba ayé kò rí i
Ti òrun ń wò ó”.
Ó tún jé ìgbagbó àwon baba ńlá wa ní pé, “Ayé ni ojà, òrun ni Ilé”, fún ìdí èyí, èdá gbódò hu ìwà rere kí o lè dé ilé rere, àti kí ó sì lè rí èsan rere gbà, won a tún máa so pé: Àjò ni Ilé ayé yìí, àjò kò sì dàbí Ilé, bí o ti wulè kí a pé lájò tó, àdúrà kí a kó èrè àjò tàbí ti oko délé ni Yorùbá máa ń se nítorí náà àwon Yorùbá máa ń gba àdúrà àti fi ojó rere lo sí òrun, èyí tí wón gbà pé ó jé ilé fún won.
Ohun pàtàkì tí Yorùbá tún gbàgbó nípa Olórun ni pé, “Àkúnlèyàn èdá, ni àdáyébá won, èyí ni wón fi máa ń pa òwe pé “Àkúnlèyàn òun làdáyébá, a kúnlè a yàn tán, a dé ayé tán ojú ń yán ni, ìsebo, ìsoògùn bí a ti wáyé wáárí oun ni aárìí”. Ó jé ìgbàgbó won pé gbogbo èdá ni ó ti bá Elédàá rè dá àníyàn kí wón tó wá sí ilé ayé.
Yorùbá gbàgbó pé tí ànìyàn bá sípò padà tàbí tí ènìyàn bá kú, pé o ti di abàmì èdá pé ó ti lo sí ilè míràn tuntun, wón gbà pé ó fé lo jìnyìn isé tó se nílé ayé fún Elédùmarè ní òrun, ìdí niyí tí wón fi máa ń so pé “má jòkùn má je ekòló, ohun tí wón bá ń jè lájùlé òrun ni kí ó máa báwon je”
Ìgbàgbó Yorùbá nípa Àkúdàáyà ni pé tí ènìyàn bá kú, pé o seé se kí o lo fi ara hàn fún àwon ènìyàn rè tí kò tíì gbó pé ó ti se aláìsí, nígbà míràn, ènìyàn tún lè rí eni tó ti kú ní ìlú míràn láti lè lo bèrè ìgbé ayé tuntun.
Irú àwon àkúdàáyà yìí ni o seé se kí wón máa rí won ní ojú àlá tàbí tójúran.
Àwon Yorùbá fi Oorun we ikú, pèlú ìgbàgbó won, wón fé mo ohun tó mú oorun, àlá àti ikú wá.
Gbogbo àwon èsìn ni wón ni ìmò nípa Olórun yálà èsìn àdáyábá ni tàbí ti òde òní (Ìgbàgbó tàbí mùsùlùmì) Àwon igi tàbí òkè, tàbí àpáta ni àwon Yorùbá mú gégé bí Olórin, pèlú eléyìí ni àwon orísìírísì eni tí Olórin dà sínú ayé fi ń kó sínú irú àwon igi tàbí òkè yìí tí jé pé ohunkohun tí wón bá béèrè, tí wón bá ti se ìrúbò fún igi yìí, gbogbo rè ni yóò di mímú se, fún ìdí èyí, wón mú won gégé bí Olórin.
Fún ìdí èyí, gbogbo Yorùbá ló fe mò nípa Olórin kí èsìn àkùnrínwá tí wo ilè Yorùbá.
Ní àkókò yìí, Òpòlopò àwon orílè-èdè lo sì ń lo irú ètò yìí fún isé ìsìn won, àwon bí; Thailand, Laos, Viet Nam, Combodia, pèlú oko ìresì àti agbègbè àwon tó ń se isé àgbè ní ilú Indonesian.
Gégé bí isé èsìn ní òde òní, àwon elésìn mùsùlùmí (Islam) àti Krìstían (Christianity).
Ní ìpari, fún bíi egbèèmú odún séyìn, wíwó Olórun nínú àwùjo Yorùbá ti pín sí orísìríìsí ònà, se a lè so pé wíwó Olórun yìí yorí sí rere bí?