Awọn itàn ayé-àtijọ́
From Wikipedia
Akosile, Olawale Johnson
AKOSILE OLAWALE JOHNSON
ÀWON ÌTÀN AYÉ ÀTIJÓ
Nígbàkan òbìnrin kan bí omo kàn omo na si léwà púpò sùgbón nígbàtí wón bí òrò ló bèrèsí iso ó ní ‘A! báyìni ayé rí! kíni mo ha wá sí n kò mò pé bóyì ló búrú tó! Mo sebí yío ma dán bi òrun ni! A! e wo koto ewo gegele, e wo ìmú eran ní ìgboro ìlú! ewo ìdòtí laarin òdè, mo gbé nà wàyí nkò mà ní pé pada lo sí òrun nítèmi ojàre. Nígbàtí ó so báyì tan àwon tí ó wà níbè lai enu sílè won ò sì le pádé nítorí ìsèlè mériri ni ó jé. Omo abàmì yíi kò jé kí enì kankan gbé òun ó bó sínu yàwá, ó mú kàninkàn ó mú ose ó we ara rè dada ó sì woso. Ní ojó na ó je àkàsù èko méfà nlá nlá, ìbá je jube lo sùgbón èkó tán ni. Òkìkí omo yi ti kàn kakiri ìlú wón sì bèrèsí wá wò sùgbón inú omo yi kò dùn si. Nígbàtí ódi ojo keje tí wón fe so omo na ní orúko àwon òbí rè fi ilé po otí wón fi ònà rokà, nígbà ó tó àkókò láti fún-un ní oríko ó wípé: ‘Àjàntálá lorúko mìí. Ó yà àwon ènìyàn lénu wón sì bèrèsí wípé: Omo ogede ni ipa ogede, Àjàntálá ni yio pa ìyá rè. Babaláwo kan wà ní ìlú yi, olóògùn pátápátá ni láti ìgbàtí ó ti ngbó òrò nípa omo yi ó bèrèsí fónnu, ó ní kò sí nkan tí ó lé níbè sùgbón nígbàtí ó dé ibè Àjàntálá fi ojú re han èmò, ó naa gbogbo èyìn rè bó. Bàbá yi sáré lo ilé Àjàntálá naa si tèle ó naa délé kí ó tó padà. Òrò Àjàntálá sú ìyá re í sì mu lo sí inú igbó ó sì fi ogbón tàn ó sì fi sílè. Ibití Àjàntálá ti n rìn kiri nínú igbó ó bá àwon eranko marun pàdé àwon eranko naa ni Erin, kìnìún, Ekùn, ìkokò, Ewúré. Àjàntálá bè wón kí wón jékí òun máa bá won gbé kí òun máa se ìránsé won ó sì gbà. Ní ojó ken Ewúré jáde lo láti lo wá oúnje Àjàntálá sì tèle, nígbàtí àwon méjèjì dé inú igbó, ewúré wá oúnje sùgbón Àjàntálá n siré. Nígbàtí ewúré wá oúnje tán ó pe Àjàntálá pé kí ó wá gbé erù sùgbón kí ni Àjàntálá gbó eléyì sí ó mú ewúré ó nàa gbogbo ojú re sì wú gúdugùdu. Nígbàtí wón dé ilé àwon eranko tí ó kù bèrè lówó ewúré pe kí lo sé tí ojú re fi wú gúdudúdu ó sì paró wípé àwon agbón ni ó ta òun nínú igbó níbití óun ti ń wá oúnje. Báyì ni Àjàntálá se sí gbogbo won tí gbogbo won sì pin láti fi Àyíká yen sílè nítorí kí ó máa ba gba èmí àwon. Níkehùn Àjàntálá di àlánnkiri sínú igbó o. Èlédà ri bi àjàntálá ti ń rìn kiri ó ránsé láti orí ìté rè wá, wón sì mú Àjàntálá lo sí òde òrun.