Culture
From Wikipedia
ÀSÀ YORÙBÁ
Àsà ni ohun gbobgo tó je mó ìgbé ayé àwon asùwàdà ènìyàn kan ni àdúgbò kan, bèrè lórí èrò, èdè, èsìn, ètò ìsèlú, ètò orò ajé, ìsèdá ohun èlò, ìtàn, òfin, ìse, ìrísí, ìhùwàsí, onà, oúnje, ònà ìse nnkan, yíyí àyíká tàbí àdúgbò kòòkan padà. Pàtàkì jùlo èsìn ìbílè, eré ìbílè àti isé ìbílè ni a lè pè ní àsà. Ohun ti o je orírun àsà ni ‘àrà’, ó lè dára tàbí kí ó burú. Ìpolówó Èkìtì – iyan rere, obe rere; Ipolowo Ondó Ègin – (dípò Iyán) èbà gbon fee. Àsà Ondó ni kí wón máa pe iyán ni èbà nítorí pé èèwò won ni, won kò gbódò polówó iyán ni àárín ìlú.
Àsà je mó ìgbàgbó àpeere; àbíkú, àkúdàáyá. Àsà je mó isé onà ti a lè fojú rí tàbí aláfenuso. A lè pín àsà sí ìsòrí méta èyí tí ó je mó:
(a) Ogbón ìmò, ète tàbí ètò tí a ń gbà se nnken, àpeere ilà kíko, irun dídì abbl.
(b) Isé onà bíi igi gbígbé
(d) Bí a se ń darí ìhùwàsí àwon egbé/èyà kan Ara àbùdá àsà ni pé: Kò lè súyo láìsí ènìyàn; èmí rè gùn ju ti ènìyàn lo; Ó je mó ohun tí a fojúrí; Àsà kòòkan ló ní ìdí kan pàtó; Àlàyé wà nípa àsà. Àsà lè jeyo nínú oúnje: Òkèlè wó pò nínú oúnje wa. Àkókó kúndùn èbà, Ìlàje-pupuru, Igbó orà-láfún. Àsà lè jeyo nínú ìtójú oyún/aláìsàn/òkú; ètò ebí/àjosepò; ètò ìsàkóso àdúgbò, abúlé tàbí lara dídá nípa isé onà. Bí ó tilè jé pé àsà máa ń yí padà nípa aso wíwò, ìgbeyàwó abbl lóde òní ètò èkó àti ìwà òlàjú tó gbòde kan ti se àkóbá fún àsà ní ònà yìí:
(a) Ìwoso wa kò bójú mu mó
(b) Àsà ìkíni wa kò ní òwò nínú mó
(d) Kí’yàwò ilé má mo oúnje ìbílè sè mó
(e) A kò mo ìtumò àrokò tí a ń kó àwon omo wa mó.
Àwon ònà tí àsà máa ń gbà yí padà nì wònyí:
(a) Bí àsà tó wà nílè bá lágbára ju èyí tó jé tuntun lo, èyí tó wà télè yóò borí tuntun, àpeere aso wíwò.
(b) Àyípadà lè wáyé bí àsà tó wà nílè télè bá jé dógbandógba pèlú àsà tuntun, wón lè jo rìn papò, bí àpeere àsà ìgbéyàwó.
(d) Bí àsà tuntun bá lágbára ju èyí tó wà nílè télè, yóò so àsà ti àtèhìnwódi ohun ìgbàgbé, àpeere bí a se ń kólé.
Tí a bá wá wò ó fínnífínní, a ri wí pé àsà lópòlopò ìtbà máa ń dá lé:
(a) Ìmò isé sáyénsì
(b) Ìse jeun wa
(d) Ìsowó kólé
(e) Isé owó ní síse
ÀKÍYÈSI:-
Èdè àwon ènìyàn jé kókó kan pàtàkì nínú àsà won. Kò sí ègbón tàbí àbúrò nínú àsà àti èdè. Ìbejì ni wón. Ojó kan náà ni wón délé ayé nítorí pé kò sí ohun tí a fé so nípa àsà tí kì í se pé èdè ni a ó fi gbé e kalè. Láti ara èdè pàápàá ni a ti lè fa àsà yo. A lè fi èdè Yorùbá so ohun tó wà lókàn eni, a lè fi korin, a lè fi kéwì, a lè fi jósìn àti béè béè lo. Láti ara àwon nnkan tí a ń so jáde lénu wònyí ni àsà wa ti ń jeyo. Ara èdè Yorùbá náà ni òwe àti àwon àkànlò-èdè gbogbo. A lè fa púpò nínú àwon àsà wa yo láti ara òw àti àkànlò èdè. Nítorí náà, èdè ni ó jé òpómúléró fún àsà Yorùbá àti wí pé òun ni ó fà á tí ó fi jé wí pé bí àwon omo Odùduwà se tàn kálè, orílè-èdè kan ni wón, èdè kan náà ni wón ń so níbikíbi tí wón lè wà. Ìsesí, ìhùwàsí, àsà àti èsìn won kò yàtò. Fún ìdí èyí, láísí ènìyàn kò lè sí àsà rárá.
REFERENCE TEXTBOOKS:
1. Adeoye C.L. (1979) Àsà àti ise Yorùbá Oxford University Press Limited
2. J.A. Atanda (1980) An introduction to Yoruba History Ibadan University Press Limited
3. Adeomola Fasiku (1995) Igbajo and its People Printed by Writers
Press Limited
4. G.O. Olusanya (1983) Studies in Yorùbá History and Culture Ibadan University Press Limited.
5. Rev. Samuel Johnson (1921) The History of the Yorubas A divisional of CSS Limited.