Film
From Wikipedia
Iwa Odaran
C.O. Odejobi
C. O. Odejobi (2004), ‘Àyèwò Ìgbékalè Ìwà Òdaràn nínú fíìmù Àgbéléwò Yorùbá’., Àpilèko fún Oyè Omowe (Ph.D), DALL, OAU, Ifè, Nigeria.
ÀSAMÒ
Isé yìí se àyèwò sí bí isèlè inú àwùjo se jé òpákùtèlè ìwà òdaràn nínú ìsòwó àwon fíìmù àgbéléwò Yorùbá kan, b.a. ‘Ogun Àjàyè’, ‘Owo Blow’, ‘Aséwó Kánò’, ‘Agbo Òdájú’, ‘Saworoide’, ‘Ìdè’, abbl. Àlàyé wáyé lórí ònà ìgbékalè òràn nínú fíìmù àgbéléwò Yorùbá, bákan náa ni a sì tún se àyèwò ipa tí fíìmù àgbéléwò ajemó òràn dídá ń ní lórí àwon onwòran, òsèré lókùnrin-lóbìnrin àti àwùjo lápapò. Isé yìí se àyèwò ohun tó ń mú kí àwon asefíìmù ó máa se àgbéjáde fíìmù Yorùbá ajemó òràn dídá tó lu ìgboro pa báyìí, a sì tún wo orísirísi ìjìyà tí àwon òdaràn máa ń gbà.
Tíórì ìmò ìfojú ìbára-eni-gbépò ni a lò kí a lè fi òràn dídá inú fíìmù wé tí ojú ayé. Ìfóro wá àwon asefíìmù lénu wò wáyé láti mo ìdí tí wón fi ń gbé fíìmù ajemó òràn dídá jáde. A tún fi òrò wá àsàyàn àwon òsèré lókùnrin àti lóbìnrin àti ònwòran lénu wò láti mo ìhà tí wón ko sí fíìmù ajemó òràn dídá àti ipa tí wíwo irúfé fíìmù béè lè ní lórí àwon ènìyàn nínú àwùjo. Àwon fíìmù àgbéléwò Yorùbá tó je mó isé yìí ni a wò tí a sì tú palè. Ní àfikún. Olùwádìí tún lo sí ilé ìkàwé láti ka òpò ìwé bíi jónà, atíkù, ìwé isé àbò-ìwádìí láti lè mo àwon isé tó ti wà nílè.
Isé ìwádìí yìí fi hàn pé ìyàgàn àti àìní tó je mó owó, ipò, obìnrin àti àwon nnkan mìíràn tí èdà lépa ló ń ti àwon ènìyàn sínú ìwà òdaràn. Isé yìí se àkíyèsí pé lára àwon tó ń lówó nínú ìwà òdaràn ni a ti rí òré, ebí àti àwon agbófinró. Bákan náà ni isé yìí tún se àfihàn onírúurú ònà tí àwon òdaràn wònyí ń gbà dá òràn.
Ní ìparí. isé yìí gbà pé àwon ìwà òdaràn tó ń selè ni a lè kà sí òkan lára ohun tí ìsèlè àwùjo bí àti pé ìjìyà ti a ń fún òdaràn máa ń ní ipa nínú ebí won nígbà mìíràn.
Alábòójútó Kìíní: Òjógbón T.M. Ilésanmí
Alábòójútó Kejì: Òjògbón B. Àjùwòn
Ojú Ìwé: 249