Gardening
From Wikipedia
ADENIRAN ADEBAYO SAMUEL
GARDENING (OKO ÀROJE/OKO ETÍLÉ)
Oko Ehinkunle
“Oba làgbè, èmí tí ò jata, èmí yepere, èmí tí o jata, èmí túntún, è bá jé ká sàgbè, ká gbin isu, gbin ègé, ká gbin ewébè séyínkùnlé kí ounje lè sùnwá bò”.
Àpeere yìí fi bí isé àgbè se jé pàtàkì láwùjo àwon Yorùbá, bí àwon baba ńlá wa bá dá oko ní ayé àtijó, wón ń se èyí kí oúnje lè sùn wón bò ni àti wí pé kí won lè máa ní owó láti gbó bùkátà won nínú ilé. Ní òpò ìgbà ni àwon bàbá yìí máa ń ní ìyàwó bí méta, nínú isé àgbè tí wón yóò láàyò.
Kíni a ń pè ní Oko etílé tàbí Oko òròje?
Èyí ni ònà tí a ń gbà se àgbè lónà tí yóò fi máa ní ewébè tàbí oúnje mú ní àrówóto eni, èyí jemó oko etílé tàbí oko àkùrò, láti lè máa fé orísìírísí èfó lóòréékòòrè, tí kò sì ní mú wàhálá kankan lówó, nítòótó, Oko etílé ni a má ń wá ní ìtòsí ilé, a tún lè rí irú oko báyìí ní ojú férémù wa, tàbí ní Òdèdè bí síse àmújúto àwon òdódó eléwà láti lè mú kí ewù bá inú ilé. A tún lè rí irú oko etílé yìí ní bí ilé ìtura, ibi ìgbafé, àti àwon ibi ìse nken ìbáyé lójo sí. Ní iru àkókò yìí a ní láti gba eni tí yóò máa mójú to ogbà náà tàbí àwon òdòdó tí a gbin, àwon wònyí ni a ń pè ni Olùsógbà.
Orísìírísí oko àroje tàbí oko etílé ló wà
(1) Akókó ni oko eja, níbi ni Olutoju yóò ti máa mójú tó àwon eja fún títà pèlú jíje. Oko eja yìí ni èrè lópòlopò fún àwon tí ó bá mo ònà ti wón lè gbe gbà.
(2) Ònà kejì ni oko àkùrò, níbi tí a ti ń gbe orísìírísì ewébè bíi, ewédú, èfó, efó gbàgbá, Sokoyòkòtò, èfó yanrin, èfó tètè Abbl.
(3) Ona keta oko Òdòdó, èyí ni won ń lò lati lè bu iyì kún ilé tàbí ilé ìtura tàbí ibì ìgbafé.
(4) A tún lè ní àwon ònà leun bíi bi a gbin òdòdo sí inú agolo tàbí inú apèrè láti lè gbe sí inú ilé tàbí enu ònà láti lè bu iyì àti èyè kún irú ilé béè’
ÌYÁTO ATI ÌJORA TÓ WÀ NÍNÚ OKO ETÍLÉ ÀTI OKO ALÁDÀŃLA
Ní ònà àti mú kí oúnje máa pò síi ní àwùjo wa ni àwon méjèèjì wà fún. Oko aládàńlá ni èyí to je pé ònà ìgbàlódé ni a gbée gbà, bí lé a lo katakata láti lè fi palè fún oko, sùgbón oko etílé wà fún késébú, fún ìgbàdùn àti láti lè pèsè oúnje fún ìdílé rè nìkan nínú èyí tó lè lo okó àti àdá.
Oko etílé je mó ònà tí a ń gba láti lè jé kí ònà tí owó fi ń wolé gbòòrò àti láti le máa fi se eré idáràya nígbà tí owó bá dilè, sùgbón oko aládàńlá dúró fún ònà tí a n gba sisé tàbí láti lè máa mú owó wolé fún irú eni béè, èyí tó mu lílo ilè tó gbòòrò láti dá oko, sùgbón oko etílé kò nílò ilè púpò, ilè kékere ti tó fún won, ní òpò ìgbà, ni a máa ń wá ònà láti lè mójú tó oko etílé, fún àpeere ònà ìmójúto àdòdó tó wà yíká inú ilé tàbí oko èfó tí wà ni èyìnkunlé.
Ònà yìí jé kó rorùn fún ènìyàn láti le rí ohun tí won ba nilò fún oúnje nígbàkúùgbà, ìdí yìí ni wón fi máa ń so pé “Bí oko kò jìnà, ilá kìí kó”, èyí tó túmò sí pé tí a bá gbìn ilá sí oko èyìnkùnlé, láti lè lo kó èrè rè kò ní jé wàhálà kankan rárá. Ní ayé àtijó, tí arìnrìn àjò bá run ìrìn àjò lo sí ìlú kan, tí o sì rí ohun èso tó jé tuntun níbè, tí kò sì sí ni inú ìlú tirè, yóò gbíyànjú láti mu irú eso yìí wá sí inú ìlú tirè láti gbìn, ní síse èyí, àwon ohun ògbìn ń womú ara won láti ìlú kan sí èkejì.
Ní ìparí isé àgbè kò seé fi owo ró séyìn láwùjo àwon Yorùbá nítori pé wón gbà pé ó ń mú owó wálé, ó sì ń jé kí ètò òrò ajé wa tèsíwàjú pèlú àwon orílè èdè míràn, ìdí nìyí ti won fi máa ń korin kan báyìí pé,
“Isé Àgbè nisé ile e wa.
Eni kò sisé, a máà jalè,
Ìwé kíkó, láì sí Okó àti àdá
Kò ì pé o o o, ko ì pé o o o.