Mysticism
From Wikipedia
OWOLABANI JAMES AHISU
OHUN ÌJÌNLÈ TÍ Ó JU OGBÓN ÈNÌYÀN LÁSÁN LO (MYSTICISM)
‘Mysticism’ gégé bí ìwé atúmò èdè Gèésì Collins se sàlàyé: Mysticism is the belief in or experience of a reality surpassing normal human understanding or experience, esp. a reality perceived as essential to the nature of life.
Èyí tí ó túmò ní èdè Yorùbá sí: Èyí túmò sí ìgbàgbó nínú tàbí níní ìrírí nípa ohun tó ju ogbón èníyàn lásán tàbí òye won lo, pàtàkì ni èyí tó se kókó sí ìgbé ayé. Láti inú èdè Greek (mystikos) “an initiate” tí ó túmò sí “ìpìlèsè” ní ìlépa nínú ìdàpò tàbí mímò dájú pèlú mímò sínú nípa nnkan, òótó tí ó gbèyìn ohun ti òrun, òótó ti èmí tàbí Olórun nípa ìrírí tààrà, ogbón inú tàbí àwòsínú; àti ìgbàgbó pé irú ìrírí jé orísun ogbón pàtàkì, òye àti ìmò. Àwon ìgbàgbò tí a ní nínú ìsènbáyé lè jé ohun tó tayo ojú ayé lásán, tàbí ìgbàgbó pé àwon ohun tí àwon ènìyàn n rò tayo ohun tí a lè tojú lásán tàbí ti alákòwe wò. Enikéni tí ó bá wádìí tàbí tí ó wo inú àwon nnkan wònyí jinlè ni à lè pè ní Eni tó mo ohun àsírí tí ó ju ogbón ènìyàn lásán lo.
Ní òpò ìgbà, àwon ohun tí ohun ìjìnlè tí ó ju ogbón ènìyàn lásán lo àti eni tó ní ìgbàgbó nínú àwon ohun náà dale lórí ni bí a se lè dé ipò tàbí kí á wà padà pèlú Olórun tí ó je orí. Àkòrí tí ó gbájúmò nínú ohun ìjìnlè tí ó ju ogbón ènìyàn lásán lo ni pé òun àti eni tó gbà á gbó jé òkan. Ohun tí ó fa ìkópa yìí ní láti rí ìsòkan nínú ìrírí, láti tayo ohun tí a moni mó àti láti jé kí á moni mó gbogbo ohun tí ó wà. Orúko orísìírísìí ní ìsòkan yìí ni láti ìsòrí kan sí òmíràn: Ìjoba tí Òrun (The Kingdom of Heaven), Ìbí ti Èmí (The Birth of the Spirit), Ìjí lojú orun Keta (Third Awakening) Ìdàpò (tí onígbàgbó), abbl. Ohun tí à n so ni pé ohun tí a pè ní “ohun ìjìnlè tí ó ju ogbón ènìyàn lásán lo jé ohun tí òpòlopò èsìn so mo. Kò sì sí èsìn tí kò ní ohun àsírí tí ó jinlè ju ohun tí enikéni lè tú tàbí mo ìdí rè lo.