Web Analytics

See also ebooksgratis.com: no banners, no cookies, totally FREE.

CLASSICISTRANIERI HOME PAGE - YOUTUBE CHANNEL
Privacy Policy Cookie Policy Terms and Conditions
Oríkì - Wikipedia

Oríkì

From Wikipedia

Litireso

Ajoriiwin

Contents

[edit] ORÍKÌ AJOJRIIWIN

Omo ibú owó, Omo orilè bo yìgì Omo aninure tó dára Omo inú u re ò bòsumàrè Omo Aláo téè dabù èrin Wón á láró laáfúsá fé a re, À tó bòkùn ye e. Abisòkòtò bí ìgbókin mefà nilé Aláró, Òpó ilé kìrì mole Esin oba kó máa móko je Eyin le fòfè móba loyòó Lení kóba ó gbó kóya ó tó, Ìlú ò jísé omo a jísé e re fóba. Èyin le fòfè móba loyòó Téni kóba ó gbó, kóya ó tó O ò fóhùn ògìì. Baba à mi, ó sì fin nu se o o Àjàlá ògbó, baba à mi, ó sì fún mi se Omo Arówá lá mole, Baba a mi ó sì fún mi se Omo Arówó òkè yá ìwòfà, Omo òletù lagbàlá, Abéyé e sisé oko, baba à mi, ó sì fún se Omo íwù ló wù ìjòkùn, Èyí té e dúdùú èlú Omo Aláró lá a fun láso, ó sì jòkìn ye Omo bàbá Epééle, Baba à mi, ó sì fún mi se Ìlu, ó sì dá a o ,

Ìlú s sì tòrò Yóó tòrò títí bí omi a faro pon, Baba à mi, ó sì fún mi se Àjàlá òkò, Baba à mi, ó dúró léyìn mi Omo Epééle, omo ìwù ló wù jòkùn tée dúdu èlú Omo Aláró láa rún laso re, ó kù jòkùn re Ò ò gbó bó ti n kì wón O kìjàlá owó tán. Àpóo lórigi, n lèrún pekun óná o, Wón lé lááyinba ti I jásé omo Boò pekun poyáaá Olúuwa à mi moo pekún pa yinniyinni À ó máa darijo pèlé ò rín. Emi le ní kómo eranko ó mó ri mú je Omo ò ji lóru tìnrin, tinrin rin Oluùwa à mi, mo be ròrò loòkùn Ma wulé, ó wùjòkùn-un Báyìí kée dúdú èlú Omo on a múlé tegbó Oníkèé gbàmí baàsàlè Omo on kan dúdú gbó jònù À á se é bókan oya, kan ni, Àkanlú òkín Omo Èjìgbà ìlèkè Omo òkan ti i féé sowó aso funfun ní lala ní lala. E è póluuwa mí oo, Omo a bá à gbàjà, Àpó o lóri igi èrin pèkún enu o o.

O ò gbó bó ti wi yìí o, Adénìólá Ake o, èdú, Adé ni, Baba dada Ojúolápe Ajojo, a boju were Omo ò fi bere bóyin wi

Baba à mi lomo o fi béefe bóyin jà Omo Baba ó jà, bábá á, O nílùú kú tán, ó jalé tàjá book Olúáyé, oya a kiri aye oba ó roku Omo a ì bóba ja ni mèfe Baba à mí, oya méta ìjà ò fi èn Oníbùdó yeja, O n yiki, bó ti jókòó è jéjé éjé Omo amuni lóòle, ò mohun ti i se ni

O ò gbó bó ti n kì won Omo a gún léyinjú ú Máa double dú tewutewu Èwù ògún lójú elégàn Baba òdétólá Agogo ò, bi eni ti n tení se O ò gbo bó ti n pàjàó ó o Ajàó ògun omo òkún yéye Àkànbí èdú, omo òjéléye Pópóolá omo ara táako Omo a yí gbìgbi yi gbigbí lóko Omo a fògún yi gbìrìgbìrì lajà Omo a fògún yi gbìrìgbìrì lajà Omo apa èkúré e lé, won ò káwùsá Pópóolá omo a yi gbigbi ló gbé won Onílé oko, omo àrélu oba Erúmosá, omo ateko tó ó mu bé wu lórí gbegbeegbe Béè ló sí ti é gbèjè dànù lorà kan Tétu taáyán tóde àyín Erúmosá ta ni a wa, eniree ó mú pa Eniire kò ó lóun ò ní jade, Idà babà à mi kò lé won ò wàkò E è bá mi sìpè fàdá kó wàkò Eniire ni perí mórìn ìlú ò jísé. Omo a jísé e re fóba .

Odérìnólá a, Àkèó òdú, Adérin baba Dàda, Ojúolápé Ajolóriwin Olálomi, Agbéjà lójú olálomi Omo a dugun nlá tó subu lawo A-kí-ni, kò mòjàlà ìsègùn Yèké ò ri yèké, yeke ni yeke Yéké ò lépà ni pa oba Òtòsì, nilé olúmòká nib o lùgìn è jéjé Olálomí, olówó wa ni bo o le bi awo Òòsà jé n tótá, n là lofà Kí n fo ó luri awo yèrú ògbóbi Nibi igi tó n sunyé kéte A bi i lófá , ó kiri, ó bìkàlò Ìjàlò wón fayé lò wón, oláálomí A ki i fowó leni a bi loaf kó dìnde Láomí, omo oyege olú se.

A ti pe tòní, aadéolá Àmòri òpó, baba ni n o máa pè ó Bó dòla ò o Adéolá, omo epééle e, Omo iwù ló wu u jòkin À ni ké e dúdu èlú Omo a yoró làbú táso rè ò jòkin re Omo a rówó olá mole, Baba à mi lomo a ráwó-fà-ya-wòfà Omo on ò létù lagbàlá, omo abaye Ní won on sisé oko À tip è ní tòrú o Àmòri-ilá, àwon baba a ni n o máa pè o, bó dòla Baba re ti gbéràlé abate O mí máa helá a wà lérí Baba yísá, ó gbo te pénpé té e deri arè Baba a mi, erú n gbe áwà Aténi gbò ò ni gbà á Ládiípò, omo ògèdè, won ò yàgèn À tì pè ni tònìí lónìi í o

Wón mú e sin ta pòlé o o, À tólé àpá, omo jékó Wón ò ni ke kari iba ìsàlè Onílé láyinba ti jájó omo Omo o ‘tago o rugi tèrù èkò Oko ò mi, o muji teko abare fagbe leyìn Omo a sole digbo, omo a sògbé dìgboro o Olùúwa a mi, o sì yá a sààtàn dojà Yóó so kèèké fidàní dìgbéjó Omo a múnlé kangbó, E ò rolúuwa a mi o Òtá á lé yóò gboyè lábé Adéolá kó somo gbogbo níbaníba A à sì pè ni tònì í o Báyìí, baba ní o máa pè ó bó dòlá Adéolá, iba Ajolórínwin A sí pè ní tònì í Baba ni n ó máa pè o bó dòla o Adéolá ìbá, a-jo-lorí-iwu Omo opó ó ó. Ládéjobi Àhéjajùkú, À sì pè ni tònìí, ládéjobí Ahéjàjúkú, Baba ní n o máa pè ó bó dòla Ládéjobí, omo olówó tí I ni bí ose Baba à mi ò bè mi owó rúrú, òpòtò mose ìwè

Ahe ni ó to o rì yè egbèje Béè ni òfà won ònjò Àhéke, àhèkè nílé àmòri to jège rèké Ládéjobí,. Opa ile, opa oko Ni i pa je. Opa má pami je hain o lu Opa má pamí je hain de júkú Ládéjobí omo olówó ti i ru bi ose Baba à mi obe mi owo riru òpòtò mose ìwè Ahe to bí nìkú ibi abéré Wón n yájú, wón n pera won lókinni Ilé e re o jegbàá gbèje lo, Níbi a gbé bi o lómo Ajíbóròjí, ó jegbàá gbèje lo Ajíjolá, ó jegbàá gbèje lo Omo ekée re tó méku fóba Baba a mi, òpò ò sì yá a tà kà Ìyàwàrà, Oko i jà lojà, larogún digbe nlé Orogún digbé nlé mòóòko Orogún digbe nlé mò ó òkété Ajíjólá, omo ojú tí o gbélé jegbe oko Òjé n wónyò, omo abéré won lókó Owú ni ó ti ò jé kó o lókò obìnrin láyibi Èwà okò tí o je o bomo olórò méjì gbélé Awon ni bó ò bomo olórò méjì gbélé Ajíjolá bi eni fomo óba lojúpo ló jo O mo fomo omo lójúpo mò ón òpo Ajíjola oya, sola gberú, o sola gbesin Béè ló wòòyàn tàfà, ó foya gba lo gà Elénté ni ó, béè lo ò yoko Baba à mi, o sì yènà Kò rook, ò yènè O mo n kun fúya je mi òko O nihin ti fáya je mò ó òkété Ajíjolá omo ojú to o le genge sóko Oje yoo ó omo àbèrè òko.

Kiisi

[edit] ORIKI OBA KÌÌSI

Wón ni e jé á wolé è léyìn-ín wó ó, Yóò jé a jówó lówó ikú a-jo-kòjo o Yóò jé a kígbe kárá ìlú òun lólá yánkú, Ode ti n sunkú eran. Irúfe onigbìn, omo afebinuyanoè Omo bónlé sìkinringìndín, Bo gbó buburukú tìjága jigijìgí Omo bónlé ò sìn, sìkinringìndin Omo bejakùlé ò sùn Omo pé lékùlé e titi O pe titi, oorun a gbe bale ilé lo sùn Tí pómo oba orúkú ní yìgì O n nib a re pe ó ma sàsùn pewà Òrò ìlú ti mo gbo rè é Ti n o gbó bí wón ti n wi Wón lékan, ònà kan Kò je yáa máa bode síkeke ìlú Báa búsin nú mò, oba afebinuyanpè Omo òbà àlàrákú, wón lá won ò mekun sun Oba Alàrúkú, wón lá won ò mààwè é gbà kókóókó la fi dóya ní yìgì Ni gbogbo wón bá n hu, bí aja jòngbeni Won lánkú ode léti gbére Ìlu tá a gbé sìn, omo afebinuyànpè Omo oba ti o jóólú yero Lólóko wón ti wi, ode dúdú lá a lé è lo. Tòrò ìlú ti mo gbó rè é Ti n ó gbó bi wón ti n wí Wón lónkú, ode ti n máwobora ìlú Taajísìn, omo afebinuyànpè Bàbàrú, omo bónlé sìnkinrìngindín.

Tani ó bá lóbá méjì, tí o fáyé ó rójú Omo ògúndijo? Bó o lóba nijàwó, wón lóba méta Omo òdò òrògún ò yèkan. E wá, e jé mó sìpa Omo à sìn kònà pagun láyà, baba àgbà Ká tó rirú karanjágbín, Ó digbó, omo lálónpe ìbà Yé é re, béè ni a dèyìn wò Omo a sèsó wolé e ìgbéjó Eye bí òkin, dòhun, Oko ayaba ti i polómose, E wi e jé mó sìpà, obe ìtòló yìí o léè. Omo ò gbó buburúkú, ìsàkàsiki E ba mi pé lóóyè, omo sàbì Giiwá oko ayaba, pmo oba ninú ìlú yanyan Afinjú oba tí i korá òsìn lójú Baba ládìgbòlù, òtòtò osìn Omo òjòrògún ni I se báyìí, Baba ògúndíjo

Opadijo

[edit] OLÚAYÉ ÒPÁDÌJO

Baba ló gbe n lé èkìtì ògàn

Baba Akande soko lóru lákànjì Olúnikàn sìbii Baba látóójayé, ó gbé nle apá Ó pelému tantan, Elemi ò rótòòtò Oro akàngbé, ò rirà òwón Káwi karò, baba látóójayé, Afinjá níkànyin. Ìjà ò súnwon kan ò yé e wi, Adáná lókàn, won ò gbódò pesin olúáyé je Oko ayaba jàìnjàn ni baba ògà E pè é tún , béè ni i jé Omo a-ku-fáyaba, ki wón ó pàyá lóròòdo Olúáyé! Omo a nilu ìlú yanyan, Kó mó sìpa, oko ayaba Oba làákó ò dùn mí, òkè ibadàn Omo n lé ka dún ni, é é kààwò Òrò Àkàngbé so nip é ò tó gbó A-bi-kaja, baba kátóójayé A dana lókan, won ò gbógò pesin Gúáyé je Olúáyé, iba a nihulu yanyan, E è pe fún mi béè ni I jé, Baba latóó jayé

Olodungbe

[edit] ÀKÀNGBÉ OLÓDÙNGBÉ

Oko ayaba, àìríbi sáàgbon Àdìkalè ewà, Oko ayaba tó o bá won nijà wààlà Kó bá won níjà léèdi ilé é Ti o ba ponílù, a pàrìnjó, Ojú télékún, a peni ti n jó A peni ti n dárin. E é pè é fún mí, béè ni je e Omo jagunjagun to mòdì o dànìrè Omo Àkàngbé tó dológìnní ìgbé Olú, baba ogbìn omo Baba omo olúáyé ìbà A mú yanyan E è pomo, ò gbòre bubúrúkú jìjàba jigi Jagunjagun, a ji pofò ìpè Ká tó rírú karanjángbón O digbó , omo lábósìnde. Ìtèkùn bí erin, èyin a dàyìn wò Omo ò gbó buburúkú, sìgà jà jígí Erú òkin lòri, Bá n bá rù tèdè, Àkàngbé bá n bá rù tèsé Baba olúáyé, iba Omo olúáyé, omo a jí bokoni tosan tòru Oko olú lo.


Lagboro

[edit] LÁGBÒRO

Ìgbà tí ó sì láyé o o. Lákan-lákan n ni bí àgbá Ó ku fómo eni gbòòkí aládogun Tènì kara okùnrin Ogun léè siwó Baba mówáare Pèlú òyó ní í jó, Baba ládìgbòlù Sònàdìgbé, Aláso finni àárò ò jísé fún baálè Apéjókè, kànnàdìjó lu, Baba ògúndíjo pókúterí gba aro gba nínú ìlú yanyan Dúdú mòó dú baba ògúndíjo Teyin baró, baba Adéwoyin Dúdú mòó dú, iba aréèyìn kè Oko ayaba dúdú tán, ó feyin sòòjé Iba, la du-máa-dan, ogun akangbe ní kànyìn Ìjà ò sunwòn, won o se é wí Iba dúdú janjan, baba ògúndíjo Oko ayaba dúdú mò ó-dú, Tí ó sì táyé mó, baba ògúndijo Ká sun lo sìn si légbèé Ká kú lakandídí à n gbá Alájogun, Tìmìkara, Akínwùmi Ló pogun ilée sírá, Baba mówaare Tó kòsùpá ní í gbéjó, Baba ládìgbòlù Òsùmàrè eegun òdé Jàgùdà, sònà dìgbé, Aláso fínní à n ro oósé fún, Baálè a-pé-lówó ó, òsùpá nígbèjóó Oko ayaba Tóòsábí o Òòsà loko bàràwé, Fíríjígógó, eléwele, Abakefiri kìkì ìde Àbàkí mówu níyì, omo ìbàlà Wón ní ó lé mo lójú àlá Bóo rí loso gege Atoó tí, baba mówáare. Ìran ìjèsà, won a sì máa lóso òwú Wón a ni bówó le rò apòmù Sònà dìgbè, à ní kò sí Ola-lo-n-seni jogo jègé Lákandídí, àbá Alájogun Oko ayaba, a fèyìn jarakùnrín Ogun lé è sí o lagba Ní wón fí í kó won lójú ogun, baba mówáare A pò ma ma bá kun nápòmú tòsùmàrè Ifè Jàgùdà, sònà dìgbé, bólúkínní-ìn sòtà Baálè baba móriolá, omo akunrijìgbin porí ogun Ò ró gbàngbàlà dàgbo omokùnrin nù Omo dójú àlá, bale ibá omo sàbí Wón ni aféfé tí n fé e fún won lókun Tòkun ni i se Gbogbo èfùfu lèlè, ti n jó lódò òsà Tòsà ni è Gbogbo musulumi tí n be lékù òsù, Erú oba ni won n ja, Arójó gbòrò Òjò leegun èèkí, ó ró Iná burada, gbàdàmósí, omo arékèke-mó-se Ò ró gbàngbàlà, dàgbo omo kùnrin nù O rook ayaba ti fàìmo o jó Òsùpá nígbèjóó, sàngó ojú àlá Lálékè tó béso béwúù saájú sere Baálè, iba omo sàbì Ohun rigirigi, baba moríolá se è wá lágbe Alájogun, òtàtà èèyàn ló fonílù òsùmàrè gbòngbò Ènìyàn méjó ni sòònà dìgbé, Bó wí bá a lá ò fé Oko ayaba jùmòké, bá a lá ò fé Baálè baba móríólá, Adégbàálésè Òòsà loko bàràwé, Firijégógó, eléwele Àkààkí kìkì ide, Àkàkí mógun níyì fomo gbà Òsoògùn, soògùn, Oko ayaba tó se fónlé ìgbá ló ó . Òsùpá nígbèjóó, lákékè ti se hunhu re Oorun lé e kìlá, baba mówáare Ìgbà ti omo ilé e síra ò ò súmó o Wón ni e so pé ta lo nírú oòni, Isún wa ò parun, Oko ayaba a wa be ò sì padá, Òsùmàrè gàngàn, lókun lóngé nigbèé Tètékú, omo Adépèlé Igba omo da ò bí ó n múrá, Lóngé nigbèé Adédòkun Àjùwòn, iba omo Bòòdé Alótu nlé, iba omo móríbi, kàngbò majè lawè Jànkágún àgá dá mo ní, baba yéjídé Kékéèkè lóko nígboro Adéyemí, ó ló pùró puró, won a maa jora won O ló kòrebete to bènté jo sòkòtò jèbètè Baba ló-ngé Wón léni tí hùwà à bà jé Ló le méè iba Oko sòro o, Yètékú, omo adépèlé Lógun mójà, ni baba ba sòro Ikú to sebo ti mó n rójú Lógun mójà, baba to de wá ki Lóngé ni I je lógun mòjà Ni baba to de, Gíiwá, Baba Yéj;idé Erin kú ága kò yé baba yéjìdé Erin kú ága wòyé, Erin kú iba wò ná Oko kú, omo lálékan, oko mórì-ni Oko ayaba, ìwo lo ni gbogbo won Aloti nlé, iba omo olú kú ewu Kò níi to ó bo párá, Ikú tí sebo, ti mo n rójú Ki oko ayaba, mó-yo-nnkan Tóóbalá, iba omo olú kú ewu bi ègbé eéré ka Olódòdó, oko moyeni Àjùwòn, iba omo Bòòdé Ayóoyo, oko ayaba dale je n le òfe Aládòkun, Aato òsùpá ní ba dóju kara Oko omo.

Onisanbo

[edit] ORÍKÌ ONÍSÀNBÒ ÒGBÒÒRÒ

Nìgbínrín nilé onísànbò

Ará ègbinrín ni wá èé sòdodo

Mo rálá kí pakún ara wa òkùn se rògbòdò jalè

Kìkùnmì ló mú kowéèdá lóró

Won daro ‘gba, gbìngbìnrìn an ò gbódò rinso

Won a sì dá tìkòkò a ò gbód o debè

Ìdó a won dáró lè légbé

Àwá regbá àwá rèwo a sì rèkòkò baba ìsasùn

Omo dìdìbálè faso bò ó

Torí èmi mo bí o lómo

Béèni èyìn mi mo fi pon o dagba

Omo odò méta tí n be lálàde gbé

Mo yó késé mo bu yalúmo

Mo bòsùsì mo sì i sansè

Òkan yòóku ni n be láje òmó ni pópó owá

Èyí àwon àjòjì ò gbodò de bè

Òyájú àjòjì tó ti débè tó bù fójú

Títí ó délé ariwo ekún a so

Níbè ní n selé onísègùn

Ló deléèkínní wón ni wón n ponísogbò lóyó n lókó gbogbo wa

Ó deléèkejì èwèwè wón sì ní wón ponísanbò lóyó o lórúko gbogbo wa ò

Àlo onísanbò yoó ma gùn baka

Àbò onísanbò a sì ma gun òtòtò ènìyàn

Nítorí onísanbò lègbón, ori oba làbúrò won

Omo agúnpopo kó sórí omi

Omo aganjú oró ta òrò méjì sènbù sènbù Àkókó wolá òbé dìé omo esin oba ò se gùn sè

Esè oba n jó ta méní tonífè ebù ni ò

Èsin tí ò dìjó ta mí n ò sì jónà doko

Lígbín n lé mi, omo póró pa

À á è n bínú n ó mo bè ó lóhùn ni

Wónyínólá omo asubú o tó joba


Àtóké àwon babà òdò sokùnrin làwò

Omo sèjìdé won á pà dábàké n pópó owá

Eè nlé dohun mi baba oyin

Omo ògùnpàtà bérìn lorò lé won só

Ilé ìjéwùmí omo ajolóríiwin

Níbè ní n selé àwon baba tèmi

O ò gbó bó ti n ponísànbo

O ò gbó bó ti n poko ìyá mi, omo owúré

Wón láwon mo onísànbo pè dandan

Wón ni kí owúré kó ponísànbo

Ó ní onísànbo ni

Wón ní àgùntàn bòlòjò tó sì lóhun

Moníganbo pè jojo

Wón ní ó ponísanbò káwon ó gbó

Ó lónísanbò men

Adìe òkòkò ó lóhun monísanbò pè jojo

Wón ní ó ponísanbò káwon ó gbó

O lonísanbò ke

Ológìnní wá só sí ólóhun monisanbò pè jojo o

Wón ni ó ponisanbò káwon ó gbó o

Omo agúnpopo, ológìnní ní

Onisanbò léwuwo ‘mo léwúuwo

Omo mejì sèpà tológìnní ló wá mo

Onísanbò pè jojo

Omo agúnpopo kó só róhun mo

O jé rèé wélòmìì ò do bàbà

Mojami esè wélòwò àgbà

Òòsà èjìdé omo apàjé pò mo ní pópó owá

Olóòfin oko ìgàn ni baba oyin

Òyò pàtà bó ti mule dekùn mojami esè ni ràwò àgbà

Níbè ní n selé oníbebò mo asúdede

Adéjoké mó dáké a ò mo ponísanbò sèbèsé omo ìyáyò

Ará ègbinrín nilé àwon baba tàwa.


Ará ègbínrín won è kúkú sòótó

Ará ègbínrín won èé sòdodo

Iró la fi n pa fúnra wa

Òkè a dìde rògbòdò jalè

Òkò won ò mòlú wón n porín ìdáró

Wón ró igbá àyé mi wón darò bó dòle

Wón sì da tìkòkò àwa ò gbodò debè

Ìyàwó tó ri àwa ni n lóni ó omo agúnpopo

Àwá sì á ràwo a sì re kòkò baba ìsasùn

Gbà ta ò róhun re mó ará egbínrín

La ràkísà oko omo agúnpopo


Won ò rí ewúré ná ni wón ni kí won ó pèrun; ó ní onókí

Meme mònìwò

Ò ni n ó ni ki ó pè eranko ma lo

Omo àgùntàn kan mìnnìjò

Olóhun ó ni kí won ó pèrun

O lóni kí han sè bo lápá bo ní kun wón ní won ò ní móní

Kì í sè yen ko mo lo.

Omo adìe òkòkò olóhun monísi pè omo ajolórí iwin

Ìn wón ni ponísin ká gbó

Olónisin bo lápá bo nítan

Won ni ò nì monisìn pè eye oko mo lo o

Ológìnní bo si òlóhun monisìn pè

Moléwú ogbo, wón ní ìn ponísìn ká gbó

O lónísìn sanbo sanbo àkóko lá o dó dìyé òhun lotórí won

Òun ló monìsìn pè omo agúnpopo

Kósó róhun mo mo dodo molò yokùn niràwò àgbà

Mòjò èjìdé mo é nì ó sì tún gbápa jó

Eè lese oko ìgàn ni baba oyin

Oò lóbìnrin ní bi domo ìyá àwa oba ò

Oò lóbìnrin gungunnu kì i pe moléwú bu ara egínrín nilé àwon babà mi

Babà re náà ó gbè ó Adé oké omo agúnpopo

Mòkèmòkè ní ko lóyè, omí gbóná won a ma pa

Bolójoi ejò kò kà ín-ín

Omí gbóná a sì ma polóju

E ò pé taló bí adédòkun Adisa

E ò pé taló bí farélá Adédòkun

Àdìsá Adédòkun Farélá omo Agúnpopo

Kósó róhun mo, ò jéèyàn clóòsà omo àgbà ràwò

Dòkun lomo kò si bi òlé bò

Gbogbo e ló le bi i táko

Àjìnàkú biná gbèdu gbèdu

Wón ni erín de, erin kó bùrubùru

Efòn náà dé wón n kó bùrubùru ò

Bùrubùru Àjànàkú bo te fòn mole

Babà mi lóhun tájánàkú gbójú sé

Ìyawó lé ògún ti fi n se ró gbèdugbèdu níwájú ode

Àbí àjànàkú ò sì mò mode loko ìyá òun

Omo ajánmólá, omo àpé olójò ofà

Jáamólá oba tí n délé tejiteji

Baba Dòkun ló léhin sálà mo ya gbà mi níre níkùn babà mi

O ní oba séríkí olóhun nìkan nib n gbani lówó ohun tó tóbi tó juni lo

Òsùnmòrè ni n gbéjó baba lárèhìn

Wón láwon ò mo ohun ti oba jáamólá tí baba mi jet ó i pón roro bí igbá epo

Won ò mo ohun àfin ó je tá pón lese bí òsùmàrè

Òjó àwón n fopo nijàyè òjèpà

Nílé Alárá òje sèsè epo làwón dáse àtìó dójò ofà n ba ti délé tijiteji

Òun ló bí Adédòkun

Òòsà àwon baba ni o gbó gbè ò

Móyóólá omo ìyá ìlòrí

Oyìnyín omo Abíóyè oba ìjerin

Móyóólá omo ajolú o tó joba

Olówo lòyokùn ni ràwò àgbà

Babà mi Àkìnó òun ni ó mo gbóro gbè

Ìyá àtomo mójóólá omo agúnpopo ooo

Babà mi lo gba kékèke ìjàyè

Mèdùndún odérìndé ó bá kógun won dà á lé Ní re níkùn babà mi baba Bángbádé

N reti kúnrunmí baba won tó kó won wagon

Ó lédè ò gbá baba won náà tó kó won wagon abèké tìnrìn tìnrin

Orínpolá oba bii tápoba bìdì òké tómo sòwò abokun sòkòtò sowa láyà pa

Baba Èkúnbùnmi Erinpolá oba bí i tápo

Awon náà ni ó se dé bi àríke lórùn re ò

Oba Ajánmólá omo ò jokan òjòkàn

Àdéolájibu táa ríjà ni mòdà

Nire níkùn babà mi eni o kuru

Wón tán puru kan, àgbà tó bùrú n bèrè

Àwon àgbàgbà àwón n wolé

Wón n wolé òòsà nlá baba Èkúnbùnmi

Erínpolá oba bí i tápo

Babà mi ò kuru béè ni ò wùnbè

Apé ò kò béè ni ò ríkú sá

Nire níkùn babà mi gbangba ló dúró níwájú jagunjagun

Àfinolájìbuoba ó láya lókùnrin ò

Erinpolá oba bii tápo

O ò pé ta ló bí Adédòkun Àdìsá agbo pé ta ló bí Adédòkun, tó bí

onísànbo tó bí Farélá Adédòkun okùnrin rògbòdò bíi ikó òwú, ìpé té pé yìi, ìpò te pò yi òòsà ó mó je raran Dòkun

E è bá mi se kábiyèsi f’Adédòkun ò

Àdìsá omo mórínólá

E tún bá mi se kábíyèsi f’Àdédòkun

Adédibú omo Adésiyan omo òjóló gbóò

Agídí omo, enimojò, mòjó

Èmi sì mòjó olúkùlóyè agídì omo’nú òjó ti bá biyamo ti ba téni alé

Èmi sì mòjó tí bábíyamo jà téè lasa

Èmi sì mòjó tí jókòó tolówùú má ran

Babà mi ó fèsòsò yóò mówó rebi ìdi rè

O ní n gbàti olódùú òjà, ó ní ti olówùú ò bínú Àmòdó baba lápàdé ni

Kó oko olówùú ó jà se

Baba náà ní ó omo gbóran gbù ò

Àmòdó baba lápàdé ni o selépè Àjíké lódò re móyóólá ye Adétóyin

Èmi náà mòjó, àjé torí ò gbodò pomolagun

Níwájú baba wa, àwon sèkà sèkà

Won ò leé somo sùgùdù loògùn

Babà mi ní sùgùdù t;I n se gbónnkú gbón nkù gbónnkú

Àmòdó baba lápàdé oba ni e fìdé è bomi

Ojúróngbé abaso gbé kóko bánu

Mòlú òtéété é gùnmólè oko ìlú

Arítókòsí pewure ìyá rè je ojúrongbé oko bákin.

ÌBÉÈRÈ ÌDÁHÙN

(1) E ki onísànbò mó ìràwò -

omo osú kan náà ni ìràò, ògbòòrò àti tedé.

(2) Kín ni ègbínrín -

Orílè onísànbò

(3) Kín ni Baba -

Kétékété

(4) Kín ní Agunjú -

Orílè wa ni

(5) Kí ló pa Onísànbò àti Aláàfin pò -

ìyá kan náà ló pa wón pò

[edit] Baba yín ló dáko sínú igbó

Ó wí éè jiyàn alákedun Ó kò kò siyàárà éè jiyàn òjò Baba àgbà ló dáko si gbèri àwéré Gbágbède yò gbéwú solá Ó wi bómi le kó ki máa kó mo Àyé ò yéké, oyún éè y’olùnrin abo loyún ye Àbòdémògún músé owó se oya À ó tómiíyò omo s’alè rè Sìmí kárelé tolóyan jì dó o Omo Afoláyanká omo omiyéke abé ota Àkòlórò loyàn omi méta òtòòtò È yó n be lóyan gìdó Ìkan á ké mérin lo òun kò dòkun nínú nílé yin Òkán á ké mágbò mòmò kó kóhun dòsì Òkán á ké mákùko òtàlà làngà wá Kó n mú dagún lókò niyèrú Ìyé mérin lá kò è le dòkun Èyí a mágbò mòmò kò eè le dòsà Èyí a mákùko òtàlàngà kò náà ló dágun lókò niyèrú o Omo omi yéké abé ota àkò lórò loyàn Ilé àyinlá tí mo mò ó pégégbèje Àyìnlá bile ìyá dùn gbónkókó Alébíosù abilé baba bí ení láyin Èjèjì ló dùn adùnpò A wa júwejuwe è lé ò mónúle e wa Asàkàjúwe sàkàjúwe e lé ò mònà Tani ò wá mòpópó Adégborò lójà oba? Erí bá le bá mi sé Ki n wá jolówò nínú ilé e wa A fi séríkí je balógun Oyíndàólá Àbíké yé lo je ‘yálóde

Àbíké èmú n ló je mùnísìpà nínú eléré Ire lónìí o omo Ejídándólá erì mi afire Enìní lààlá awúrò ni gbò Obáyomi omo agúnbíagodi aworo Ìwòbùbá a suwòn labìrì àpà Àìtòwórìn ejò, nílé Adébínpé nílé Afoláyanká Ní án sé paá lódodún Bóká bá seé jú lódodún Bólúmòmi bá wó ròrò ní tejò lehìn Bába tani éduro nílé agbólúmolé N é sàjé sòsò mo pani tán bé so ára Mo mùjè ènìyàn, si ‘àn labìrì àpà Wón pe sisí bilé ò Nílé Agbólúmolé won pe olùbòsí bode Wón gbé esi ni eé je àbénìyàn È è ní jènìyàn àpà kí an má mú mi lósó Adébínpé ebora inú lé e yin ní n jé Sagúnmòmí, pákelúmoja, sèkùní báwon sorò lasèrì àpà Iru lé nìí erì mi à fi re Móje ò kó só mo wá kuwo bí ení ku réfe Mo fi kònkòsò kuwò mi lùnùlùbù Ògùnràn ‘lá ni án rán mi á wò Won è rán jujó omo elòmiì lo Àyìnlá òkín, irú re sòwón láyé Omo foláyanká tó táyé ro bi agogo Pupáyemi elérìnèye lénu Abìrìn asà lehìn esè mejèèjì O è rìnrìn àsà ki o dégbèésèré Afoláyanká gbogbo e ló bá o láa jo Òjé ni ó mo wójè é lè mi Àrè àgbà èyí monà meji Òjé òkó só mo kuwo bí ení ku réfe

Mo fi kònkòsò mo mú kuwo mi lùbùlùbù Erí ahun è ni burú nínú agbá o Àyìnlá eri re è ní ourú Òràn yí pu ó láyò baba è ní jé kí pu ó lékún Ò kàn ní móso tì láabò Ò wá dowó òbosi omo Afoláyanká Ò wá dowó ìkúnlè abiyamo Gbèhìnsí ayère kò kúkú ni bu ó ní rú O ò ní pòfo roof gégébí isé ago O ò ní fèwòn lògbà kí o má denìrahù ayé ti o wá Òràn yí pu ó láyò baba è ní jé kí pu ó lékún. O ò kàn nimóse tì laàbò Ire ló nìí erí mi afire ìrènímògún yará yoyo Bi an bá wá bèèrè wi ta lo korin èyí sínú àwo E wí emi àbíké oyíndà ògúnfúnké o Omo Àrìndé omítóyìnbo omo Foláyanká Baba wa ló yúnso mógùn jíga yará ìlágbède Omo èlùbó èsí bàká jé Ta pé yapebénu abèlùbó sírì àjà kale nirè Ìlú Èdúmowó oun nìlú mí Bí mo tí du lójú ni n e máa du lénu N é sàgbòn ìsàlè yóò yáà nirèbè Ire lo nìí eri mi à fire Baba wa ló térí bo lé aró o Baba wa náà ló tètè lówoo sílè koyìnbó ó tó ní Ìse mo wí èè sé bìnrin nínú ilé wa Ìyà náà è ní jooìnrin ònà ìrè Gbìnrin ìrèmògún Èyí ó bá ti wí ìyà n je’un E wí kí máa lo sínú ilée baba re Àyé lé n lé ti mú ya rè wá Torì kéjégé n é ká yè mi Gègègè mo káyà mì jìnà

Gégé-gègè-gègé mo káyà mi dòdún ojó Ìsé mo wí è sébìnrin inú’lé wa sé Igbá sékété n la mú won wó eyo Mògún sèje mògún sèsán Omo ota yi gbíriririri Ò dajú omi Amònà òkàn nìnù Kìkà kí n káìn mo rè síéjú Aré wéjú ni é máa sú yará ìlágbède Mo finá ni é máa sú yará ìlágbède Omo òfówó iná kù terí bo’lé aró Alébíosù omo foláyanká o Ìwo lomo òfòwó ìná kù terí bolé aró Baba yín ló tètè lówó sílé koyìnbó ó tó ní Omo alóko nídìí ògun omo olábíwon nínú Omo àkékèlé egun èrè won è gbodò sìjè Ìrè è sìjè èé jé kí won mú ‘rè bògún lówá Lurín níjó yará ìlágbède Mo foná yayaya mórin Ire ló nìí erí mi à fire Mo tún á dé o bí mi tí dé o Mo rìnrìn gbèrè lójú u búnibúni Mo yo kóntá dugbe lójú u búnibúni Nítorí pègàn pègàn won è lókàn awèrè Aténilóde è lódó lówó Binkín laso abúni n se Ilé Ayìnlá tí mo mò ó p’égbèje Àyìnlá lomo ò káso ‘lè kerù baláso Omo yíkéti Alébíosù omo Foláyanká o N lomo yíìkétì, omo fowórorí Omo àwíná owó mo ní éè ti è yeni Omo àgbàbò sòkòtò eè yomo ènìyàn Bí è bá fún won lese a sò wón N ení ní ní báni láá jo

Baba an oun ló ràpékù òdìdè èyó dábéré ko líìlí Líìlí mo wi éè fi ti è ránso Òdìdè è ní fi ti è tafà Bí wón bá wá won níjà be è bá rí Adé oba kée náa mú tagí nínú o o mo tírékété Ònà è ti je níbè e nì mo o O wa dile omo Adégúnlolá Olójèé òkósó Mo kuwo bí ení ku réfe Mo fi kònkòsò kuwo mi lùbùlùbù Won èé rájekù erin nínú igbó o Won èé ri tefòn lárìnjù Kìkà ki e rájekù baba nínú igbó Adégúnlolá Won é gbélè bíríkótó Won á gbélé kan bìrìkòtò Won é à dojú opón dèpèlè òti Babá ni n kí e lòjé e lé Babá wí n kí o òjé òde Babá wí n kí o éè bá wà nínù lé Omo eégun fi gbíngbin jéni Sòrò lokùn han nígbàlè E è á ní kìjàbé ké fonísàn le Yèkan ara won ni án nse O wádì lé olódìí sèkun Ògàín sègun gòkè O wá deléè kínní Omo olódìí de ólóun é mà ti è mawo Bó b á se wó é mawo O o gúnyán erù méta O o sùlèlè erù mejì O o gbe sípàkèlè atókun Níbi eégun tip o mariwo Omo olódìí gúnyán erù méta Ò sù lèlè erù mejì

Béè ni mo sì ti wìnnìkìnkìn Mo re jekùn jalè, ìdí àmù jóóró o Eléyà mí àjè n já ló pàtàri, nígbòho wá ò Eè ní jé n mú towóolá o Se room kékeré jòjòló Náà ni n salé patá ní nìgbòho Agbe ò ní siré kádìye ó gbàgbé òkun Mòrìkò ò ní siré kó gbàgbé òsà Òhun ni ò jé kilé ó gbàgbé ìyá láíláí Olárànmi nìyí àgbà òje ni Oyé ni wón olúbekun béèni ilèkùn tiwon ò gbodò kèyò ‘Mo àyònyò tán ekùn tí n gbórí opó bola ló nìí ni wón lo békùn ton Won a kùn kan tiwón n fori jeran O o sì jé lólá olórun omo omi ni tí bú kókó wúwo Omo àyònyò tán ekùn, ti n gbó ri opón bola Títí báyìí lè é Alépátà n gbòho Wón lo békùn ton béè mo se wìnìkìnkìn Mo i jelùn jalè, Ilé yín ilé ìyá àgbá mi ni Ta ló dùn bi ilé ìyá àgbà mi Ìté orí ìté oba oko ìyá mi kèrèkún Ìrù léhìn gbàgede Àsèbáyìi ni gbàyí gbe bé òkùn o Ìkún abiyamo ni ó ma mú sun Àbíkún ilé abiya rèurùjè Omo titun òun ni ó wole tòwá A ò ré lòmíì sérí sí oba Àpèwá déwù lonà òsì Mobá à joji kí won lókan ò ni se é tó Bo bá tó won kéré ide ní ró gbongan Nílé wón á gbo gbùrin wòn re ké gbèji lé èkinni won lápinni ilé èkuni.

Ìyà ke kú yá jemo kálá abojú yebe Ò sì se kái sálaì lè tuwo O ò pale Alépátà o, kó pàlé Alépátá n ‘gbòho Àwon elérí ode gègèlè òún ti lodò sàyà Ìsànyà ò tómi lese lábò ti ponti Tí n sé sí mi lénu Bá won jábenugbo Àjòjì ò gbodò gòkè, àjòjì tí è é Geri òtin-ìn-ìn tán omo bíbí inú won Òun ni bá won lo, nílé òhun nílé Alépátà nígbòho ni Alágbon nó omo lápotio bí ìrì aka Ìrì àké tí mo kébàápon lénu odi Béè mo tegbèfà mo fi rà sasùn Wón bá bi mi wón lori kíni Mo ní terí kéni ó leè joko lójú Owó ló té orí lé pé aláwòn ni jo júmó Ni baba n gbá mi nígi lénu Ìgbà ké tí mo kégbà á kana Mo sì kegbàfà mo fi rà sasùn Ìgbà ké ti mo má móyè lábé Nibo ni n kólá títí mo domo gbogbo níbaníba Alágbon ni é ba bale ní gúngùn gbooro Kò sì ní le ràrìn rá, séni ti ò ran Kè é kú nílé onílé Iko òníkéjò léhìn odigun kò ní gba létà ìbànújé Ògùn ò ni kojú ìjànbá fún gbogbo wa ò ní ríjà omi Tolètolè ò ní rí n kó tòdè gbogbo lo Gbòrò wòn ti ni n de tutu Kénu máa wá onígbòho Kénu máa wá kénu máa rìn láàpin baba Gbooro wón ti n te kuku



Agbé ó jé tiré kádìyè ó gbabú òkun Gbalépátà bá n gbó tí baba bá sì n gbóhun mi Kó sì máa sàmín àse. N tí mo bá so ‘làwúrò yìí arò ó rò mo ni Àfi tóbe ò bá besu, àfi bóbe ò bá Gégi gbe, à fi book ò bá role Tóò bá fèjè mó déhìn aso nímébora la Mòpémòpé lobì n gbòwú Ota báyìí orógbó won ò lójú aáwé Òtá ò ní ráyè gbó tìe Èlà ìlèkè ò lójú àtokùnbò Òtá ò ní ráyè gbó tìe dandan Gégé bí ení sáye lóyin pèlé Alépátà Nigbòho omo olórí ode Gègèlè lodò sànyà, ìsànyà ò tómi lábòlábò Kini poki n sési ni lénu se, n sì n sé Si mi lénu àlókè kan tí n bá won jé Abenugbe won à té lé gbòodì Won à lé bá òtá Èése pé ìran tìe ní kúkú ye ò Òta ò ní ráyè gbó tìe N e ti tí o bí méjì nígbòho ni gbogbo won O bá ti mú kan lòbokosi Ò bá ti mú kan bò sànyà Ò bá ti mú kan yòókù jerú wá Nílé onígbòho more omo atapete inú omi Ilé ìyá mi gègèlè òun sì lodò Sànyà N e tí tí ó bí méjì mígbòho mo gbàgédé gbòwó san léè kó Babá ní kí o beere, kó ma rá Bere n sì n rá beere mà lókè kan Ti n já won já benugan lojo oni ti baba ba tì n gbóhùn mi Kó sì ma sàmín àse Àfi tóbe ò bá besu Ejó mí wá deléè-keta

Omo òjè kúyàwó e jé n wí bè léèkan kun Bá se bóse ò bá o esu, à ti bádàá Ò bá gégi gbe à fi oókó bá role Tó ò bá fèje mádé laso n ní mébora la Òta ò ni ráyè gbó tì e dandan E è gbó Alépátà nígbòho baba e ma gbo Ibi téè bá n gbádùn léèdè wa E è ní té níse kí é sàmín è daadaa Ògun ò ni kojú ìjà dà yín gbogbo omo wa e ò mi ríjà omi, òtá ò ní ráyè gbó tèyin, èé sì jáde ayò, èé sì seríire, se mò pé béèni età n gbódò je ni È n ta lòwúrò yìi é je Oba pátápátá ti n be nígbòho ni mo korin yìí fún o yóò sì ye yin Àtèyi tó ti kú àtèyi ti n be lóyè yi Kékeré ìjèsà ti n jólóye bò wá .


ÌBÉÈRÈ ÌDÁHÙN

   (1)     Kíni igbá Rekété        -       igbá funfun àdému tí omo àgnà Ìjèsà yóò 

gbérù máa jó nígbà òkú àgbàlagbà (2) Nìlèbé ilé - Àlàjé àwon ìjèsà (3) Jìmi Àgbé - Àwon olóòlà ní n jé béè (4) Kannakánná - Àlàjé ni

       (5) Òjèjé                   -       Àwon olóòlà ní n jé béè         
            (6) Enini                   -       Ìrì tó sè sórí ewéko 

(7) Àrélù - Àwin ìlókó là n kì béè (8) Tètú - Àwon ìlòkó ló n jé béè (9) Ìsànyà - Odò ìgbòho ni (10) Olóbòroyè lábé - Oba tó bá je mó Aláìfin (11) Àgbónni - onílè (12) Ségi sóòrùn - Àdúrà nip é, Olórun ò ní jé bánújé ó bá Oba yìí bó bá tip é lóyè tó. (13) Mò pèpé - Ìgbà àse lówó àwon eégún (14) Made - Oun tí mo bá so kó se

              (15) Atepété                 -       Alaje Oríkì ùdílé Oba   

(16) Awojínníjà - Àpónlé enílè ilé baba won (17) Ràgùdù - Tí ó tóbi (18) Bàyamù - Olóòlà tí ó tile Igbón wá.

  (19)     Eléyòmí         -       Gbogbo eni tó tile Olóyé wá. 

(20) Jìnán-àn-bè - Ilé Olóòlà ni (21) ká lo sálà ká lè tuwo - Oríkì alépátà (22) Abenugbó - Òrìsà ìgbòho ni, àlejò kìí ri (23) Bímonímowó - Ìjèsà là n pè bé è. (24) konsi odò - Odò ni Nígbòho










[edit] ORÌKÌ OBA ÒKÈ-IHÒ

OBA OBÀTÚMÒ TORÍOLÁ ÈRÈOLÁ LÁTI ENU ÌYÁÀFIN GRACE OMIGBÌRE ILÉ OBÀTÚMÒ, ÒKE-IHO

Ogunlabí oo Baba mi ò ò Ase-é-perí omo Okúlé Lójù Abèro Dálémofófí Omo anáwó fáhun lo Léèbó lóbìnrin Tárúgbó se níyàwó Lomo Adéniyì Òkè baba Dèjì Òkè baa Baba Dèjì oko Abí o Àse-é-perí ló ní n má a lo Èrù ò ní bà mí o a Adébáyòò Elérímodé-gbèélé ò Baba Rábí Oròbádé Oba wa tí ò se é perí o Iyálémòsó Baba Mopélólá Obìnrin tì ò lóro o………. Lórogun ò màrùn Oko ayaba Kò màrùn tí n sèun Oko Mopélólá Òkè baba Mókúnmi Orogún ìyá kún lé Kò sú wa ní táá pótó Baba Dèjì Àkànbí Loba kan Òseléyá seégún



Baba Moyoyin Ò seléyá dàpò mófá Omo Adéníyì Òkè omo È-è…. Òkè omo Èsùú Ase-é-péri ló lo nílè yìí Ò dé mó Onjò Oníbìíyá afigba kérú Oróo jamo jamo omo pò Opò ayaba nínú eégún oo Sànpònná, Sàngó Won pò lórìsà Irú ajá baba, Já bàbá Baba tí í járúgbó A tobi má ránró Onbìíyá Oko wa o pò lókùnrin Giwá egbe tí n be n lé jorò bí omú oge Mo ní tí ò bá sí Omú omo ìmúnmúná Tí n be láyà obìnrin Bí ò sí èjìgbà ìlèkè Tí n be nídìí ìyàwó Baba Mopélólá A-jáde-má-tán-n-lé A-tóbi-má-ràn-án-ró Onbìíya Oko wa tó léwà jobìnrin lo. Oko mi léni-sányán wù ó rè lorin Ilorin nile aso Baba Mojoyin Eni àrán wù ó rèbàdàn

Àsàdú ògò Eni àbàjà àrán wù ó lò Kógbówé A-jáde-má-tán-nílé Tóbi-má-ràn-án-ro Bi eyé méjì gbàga ni Òkè baba Mókúnmi Ogunlabi o o Baba mi ò A-tóbi-ma-ràn-án-ró Baba Mopélólá Ajáde-má-tán-nílé Onbìíyá N ó sì máa pe baba mi Òyó ló ti gbóyè wá Omo Abíólá Onpèéde Baba tó tbóyè sáàfin Mo mòmò súrè mo délé Obádìjí baba Mopé o o A-tóbi-má-ràn-án-ró Onbìíyá Tí mo se bi n ó ri N ò rí i Mo mòmò sáré mo dé kòbì Àrèmú Akande baba Mplé o o A-tóbi-má-ràn-rò Onbìíyà Tí mo se bí n ó ri N ò rí i Mo relé obádìjí Baba Mope o o A-tóbí-má-ràn-án-ró Onbìíyá

Tí mo se bi n ó rí ì N ò rí i N-wón-wé-róró N- wón-wé-ròró Omo Abíólá Onpèédé Wón fi kú omo Adéniyì sí bèru Ìbèru ni kú oko kún’tómo Baálé Fásèye Ìbèru ni kú oko Aláyò Èrè omo Àdùkéé A-dùn-ún bá-jayé Baba wa ròyó ò wálé mó ò a a Adébáyòò Èrín ní í rí í konijà lójù ò Baba Mogbónjú Ogunlabi o o Baba mi ò ò Èrèolá omo àrán-òrófó Omo Eégún légi Afínjú oba tí í bèèbó lówó Baba Múlíká A-jáde-má-tàn-án-nílé Folánmí N ó sì máa pe baba mi Giwá egbé tí n gbe n lé Joro bí omó oge Kó ko ó mo se é lo Okè má wòó Kí n má wòó Kí n má wòó Òkè omo Dèjì Òkè oo Omo Dèjì Àlàmú o o Ase-é-perí tó lo n lè yìí


Ó dé mó ò a a Adébáyò Pè-éni-béè-níí-jé ò Baba Mopé é N ó sì máa ròyìn àjò Èrèolá o o Baba mi ò ò N ó má a ròyìn àjò, Bó mo bá dé nú ilé A-tóbì-má-ràn-án-ró onbìíyá N ó máa rò léyìn odi Giwa egbé Igi lo ri bí owó eyo Arí’an má sòjo Oko wa lò rí powó ìlú dà Òkè omo Dèjì Òkè o o Omo Dèjì Àlàmú o o À se é perí ló ní n máa lo eru ò nib a mi o ba Adébáyò o o W’orú-ù-ké-koto Baba Múlíká Ogunlabí o o È rèolá o À ní bí ò bá si omu Omo oto Omo ìmúnmúná ló jù aro Dálémofótí Omo a ní ó báwon lo Bí ò bá sí èjìgbà ìlèkè Tí n be nídìí ìyàwó Baba Mopélólá A-jáde-má-tàn-án-nílé Folárànmi oko wa tó léwà jobìnrin lo

Giwa egbé Igi lorí bí owó eyo A rì’an má sojo Oko ayaba lò rí powó ìlù dà. Òkè omo Dèjì Òkè o o Omo Dèjì Àlàmú o . A-se-é-perí oba tó tèlí Ò ní í jé ó tú o a Adébáyò ò Pèé ni béè níí jé o Baba Rábí.


Ìfòròwánilénuwò lóri àwon òrò tó ta kóko

Ìbéèrè: kin ni ìtumò olórímodélé ti e pè wón yìí Ìdáhùn: ìtúmò rè ni pé òun (oba) ni olórí gbogbo ìlí. Ìbéèrè: E pé wón ní ò seléyá pò mófá. Èèrè ìdí rè? Ìdáhùn: ìdí ni pé gbogbo odún pátápátá ni oba máa n se. Ibéèrè: A jáde má tàn-án nílé nkó? Ìdáhùn: ìdí ni pè ó máa n dá àwon erú re àti ayaba si méjì tí ó bá n lo sí òde. Àwon ìdajì á bà a lo. Ìdajì a sì wà nílé. Ìbéèrè: Eése tí e fi kì wón pé òyó ló ti gbóyè wá sílé? Ìdáhùn: Nígbà tí ó joyè, Aláàfin n rán ni pè é ní òyó, ó sì bó sí àsìkò eègún wà. O rán onìsé sí aláàfin sùgbón kò gbà, ó ní àfi bi òun gan-an bá wá. Nígbà tí ó sì lo òkú rè ni wón gbé wale! Òyó ni wón ti fi joyè, òyó náà ló kú sí. Ìbéèrè: kin ni ìdí tí e fi pé iìbèru ni kú oko Aláyò? Ìdáhun: ibéru ni ikú rè je nítorí àìsàn kò se é fi jáde nílé tí ó sì jé pé òkú rè ni wón obé bò Ìbéèrè: A tóbi má ràn-án ro nkó? Ìdáhùn: Bí ó se lólá tó nnì, kì í rán ró fún enikéni. Ìbéèrè: E pè wón ní Dálémofótí. Kin ni ìdí rè? Ìdáhùn: ó jé eni ti ó máa n foti se alejò dáadáa. Nítorí ìdí èyí, odidi yàrá kan ni o fi máa n kó otí pamó sì, kò sèsè ní í lo ra otí bí aléjò bá dé.








Iseyin

[edit] ORÌKÌ OBA ÌSÉYÌN

OBA ADÉYERÍ LÁTI ENU (PA) ÁLÍMÌ AJÉYEMÍ ILÉ ALUSÈKÈRÈ NÍ ÌLÚ ÒYÓ


Adéyení omo Alájogun

Adéyení omo wúràólá

Adéyení omo wúràólá

Ìyàndá a-báni-sòrò-má-tannìje

Adéyení omo Alájogun

À n bó’bo, òbó hun

Adéyení omo alájogun

Òbo kìkì are rè.

A à féná à ní ò jò

A féná tán

Oníkálukú n gbénu ú sá kiri

Àká baba ìrókò

Asawo lode ò febè paní

Adéyení omo Alájogun ònà ìbàdàn la ò gbodò rìn

O n káà koko

Adéyení omo Alájogun

Òjò pa kòkò rè gbìn-gbìn-gbìn

Òjò tí ì bá pa tápà

A dòtúbáté

Adéyení omo Alájogun

Elébùrú ìké

Omo Alájogun

Òbo kìkí are rè.

N ó k’aséyìn oba àrànse

Oyinbó omo Èjìdé àgbé

Gbógun léye

Àsoba jagun

Oyinlolá Oláwóore

Peranborí

Peran bofá


Oláwóore a bèyìn àrò gele-mò-gelé-mò.


Kò se é mú ròdá

Ò se é mú

Gbógunléye

Àsobajagun

Nlé Oláwóore

Baba enìkan ò gbin yánrin

Baba enìkan ò gbin gbòrò

Omo èjìdé Àgbé

Fúnra rè lóhù

Aséyìn Oba àrànse

Oyinlolá Oláwóore

A gbó onísé Oba má mà dúró

Omo èjìdé àgbé tí í gbónísé onjò

Tí í tún fìlà se ge-ge-ge

Oyinlolá

Oláwóore

Àsán-àn-jòmì-eye

Oláwóore

Ekùn-abi-làà-làà-ìjà-layà

Láwóore ekun-abi-làà-làà ìjà-layà

Agbógbe má gbóyàn

Oba Àyínde

Oyinlolá

Láwóore Àbe

Afàdàmò-ragun-jànyìn-jànyìn

Oyinlolá omo Èjìde Àgbé

Dákun má gbéná

Oba àrànse

ohinlolá

Láwóore

Nígbà tí ò sí mó

Aséyìn ò ti è parun

Oyinlolá


Oláwóore

O kan Adégbìté

Sùkú-séré Adégbìté

Omo alálè-òrun

A-jó-kí-de-ó-ró

Baba ori dagogo

Àrán kún lé

Baba odún sàrìnnàkò ààlà yìgì

Ààlà yìgì baba ò dé títí dodún

Omo afòkú sòwò

Àrèmú Arówólóyè

Àbíkú oníjànmón

Baba ládépé

N-n-gb ó gbinrin lówó òtún

Sùkú-mì-séré

Mo se bálágbède òrun ní n lurin


A-jó-kí-de-ó-ró

Baba orí dagogo, n-n-gbó gbinrin

Lówó òsì, Adégbìte

Mo se bálágbèdè-òrun ló n lurin.

A-jó-kíde-á-ró baba orí dagogo


Èmi-ò-tetè-mo-pówó-fá-gùn-má-ràjà-gún-gbe

Arówólóyè

Àbíkú oni jànmó

Baba ládépé

O dèèkínní onísé ìbàdàn dé wón lógun jà ni

Mókín ilé

Arówólóyè Oba èse

Wón ní mo kí séríkí

Mo kí Balógun

Mo kótùn-ún

Mo kósì

O dèèkejì èwèwè

Onísé ará ìbàdàn dé

Wón lógun jà ni mòkín ilé

Arówólóyè

Wón ní wón ó kí séríkí dáadáa

Wón ó kótùn-ún

Wón ó kósì ìbàdàn

O dèèketa èwèwè

Onísé ará ìbàdàn dé

Wón lógun jà ni Mòkín ilé


Arówólóyè

Oba èse

Wón lógun le fún séríkí

Ogún le fún Balógun

Ogun le fótun-ún

Ogun le fósì

Kóso kó kí e má le è kó won

A-jó-kí-dé-ó-ró

Baba orí dagogo

Sèkèrè kó ní e má le è sétè

Tètè kò pé e má le è kójèbú

Arówólóyè

Abíkú onijànmó

Baba ládépé


Járun-járun

Kó máa jáwon lo

Jósèèké jósèèké


Kó pé e má le è kójèbú

Arówólóyè

Abíkú oníjànmó

Baba ládépé

O kan Olúgbilé

Ìgbà tí ò sí mó

Aséyìn ò ti è parun

Olúgbilé

Eléwu oyè

Òmùdún kókò

Oba asàwòlòlò

Oní jànmó alátise

Olúgbilé


Aberan nílé bí ode aperin

Afàlùkò-jèjèè

Jejèé-nílé-oníjànmó

Jejèé-lóde

Olugbile tó tó baba

Láwóore re i se

Aborí esin báá-báá lónà komu

Abìrù esin tìkòtìkò


Lónà ababja

Sèrùbàwón baba Àjíà

Ológòdo ègi

Olúgbilé


Aberun nlé bí ode aperin

Rèwó-rèwó ní e má ti è rèwó mó

Ológòdo egi

Olúgbilé ni bá a bá lo

Emi ni í máa se ní wàye


Mo ní jà mo jùlo

N-n-jù-tòsun-lo

Òmùwè tí n wè lódò òsà

Kó múra kó lè wèé já

Iba mi olúgbilé aláwòye

Òmùdún kókò oba asàwòlòlò

Ìfòròwánilénwò lóri àwon òrò tó ta kókó

Ìbéère: kín ni ìtumò gbólóhùn yìí “A à féná, à ní kò jò?

Ìdáhùn: ìtumò rè ni pé nígbà ti ìnà kò ì jò ni à n dúró, tí iná bá ràn tán ènìyàn ó ho.

Ìbéèrè: kinni ìtúmò omo Alájogun.

Ìdáhùn: omo jagun jagun Ìbéèrè: kín ló fa ‘ona ìbàdàn la ò gbodò rìn?

Ìdáhùn: Nítorí pé ológun jo ni wón.

Ìbéèrè: Abèyìn àrò gelemò-gelemò nkó?

Ìdáhùn: ó jé eni tí í máa n ni eran nílé ní gbogbo ìgbà tí ó sì máa n fi í se àlejò.

Ìbéèrè: kínni ìtumò Ekùn abi làà-làà ìjà layà?

Ìdáhùn: Jagun-jagun tí ó le ni à n pè béè.

Ìbéèrè: ìdí tí e fi n pè é ni Oba àrànse?

Ìdáhùn: Onírànlówó ènìyàn ni ó n jé béè. Ó n ran ènìyàn lówó.

Ìbéèrè: Omo aláte-òrun nkó?

Ìdáhùn: Eégún baba won ni aláte-òrun tí a fi n pè é béè.


Ìbéèrè: kin ni ìtumò àbíkú oni janmo?

Ìdáhùn: E ni tí n dákú.

Ìbéèrè: kín ni ìdí tí a fi so pé ó se ori esin báá-báá Lónà kòmu?

Ìdáhùn: ìdí ni pé kòmu ni oko rè.

Ìbéèrè: òmùdún kókò a sàwòlòlò nkó?

Ìdáhùn: Oba tí ara tè ndán ni eléyìní.

Oyo

[edit] ORÍKÌ ALAAFIN TI ÌLÚ ÒYÓ

LAMIDI  OLAIWOLA ATANDE ADEYEMI III

LÁTI OWÓ ÀLGÀÁJÌ SHÍTÙ ÀKÀNÓ ALUSÈKÈRe

Láíwolá omo Alésu lépò, àkóbi bódéjóko Láíwolá ayé re ìdèra ni, Ojó gbogbo bíi odún omo baba Móríye Tótó ki n mómo ri òrò ò gbayaba Ò gbà léyo bé è Omo baba Àkèè, Láíwolá ta gbékèlé Ò ni kú, sákì Oba lomo Adéyemí Ewé gbígbe tíí fojú diná, omo ìyá Àkèé, baba Babátúndé oko ìyá Núúrù Àkóbí Bádéjókó, èkúté ò mòwòn are rè N dájó súúná, óní kólógìnní ko Kálo kó lo wòran, a mo wo Àbò won, àbò won o sé se Láíwolá, Akéréburú, omo láwoyin Òkè gbogbo lo o f’ajélè é si Baba Babátúndé, àkóbí Bádéjókò Láíwolá Oba lomo lawoyin Okú olúkókun, pòjù, oko ìyá Abioye Ató báa ti n pé, oko Ràmótù Ti n jélébóló, baba kábíèsí Oko súúlá, láíwolá ayé re ìdèra, Láíwolá omo olúkúewu, okú olúkókun Òsónúlé o béjìré, babamótáyé Àkóbí Bádéjókó, baba omo méjì láàfin Láíwolá oba lomo láwoyin Tótó ki n mó ri òrò ayaba ò Gbà léyo bé è . Àwon bàbà re àgbè n won, o Fowó ti o kó o pé títí

Ónlé oró, omo ìyá òkè Àsàbí Adé, Adéwínnbí, lájoólù Látúnbòsún, omo ogbón le n Nímò, eni ògbèrú alé mólo Ikú pupa tééré oko sobadiwin Sún on sóhùn oba gbogbo wa, Nílè eèpò, òkiri ò fìjàlò Eléwele èjìòbò ró etí àá wón Yéri ogun ódì. Látúnbòsún omo arólúa kúndùn Níkàrè Ìkàré omo egun oju Òsí lèkùn o to joba O fìdí oko rumo gègè O yo s’ógun lórùn omo Àwùsàn, àgbasà, bórí kan sun òn A sì rangba orí, ori ògè Àkàndó Ló sunòn ló ran òyó Alé mólo, ófori rerú, o forí romo Ayé èjìòbò ró laségìtà n là Hán yérí ogun ódì Latunbosun omo arólúa kúndùn Níkàrè, o pàlú méje pò Adéwínbí n bá gbogbo won jagun Àgó agódóngbó won o gbodò Rogun, òjòngbòdú ò gbodò rodò Odòfin o mo ònà kò dúró Delégàn ìlú, omo ajà léyìn Sóóró gidi, Adéwínbi, olúkúewu Kàngí bòòlì, Àtàgbániyògò Ekùn gbálájá oko òwérùn Apani mo mógun jo oko Ìyá Nàso Ikú pupa tééré oko sobadiwin


Sún on sóhùn Oba wa nílè eèpò Nítiri méje làá polúkúewu Kó tó jé ni, Ilá tiiri ilá kó Aláàfin ikàn tiiri, ikàn wèwù èjè Ìkònkó só Ìwò tiiri peja Okà bàbà tiiri polóko Oní bómo kékèké ilé, omo ìyá Òkè Àsàbí, bí o bágbà jehun Adéwínbí nítiirí ni tiirí Òkèrè nítiirí mómò wó baba Kúdééfù Eléwele èjìòbòró etí à á won Yérí ogun odi Bí mo bá gbé lákàndó Ògè Àkàndó omo ìyá òkè Àsàbí Oba lélèlelè, ikú pupa tééré Ma bóba ni lílelíle Hàharan gbangbà, ègun, bàtàbútú Ni líìlí pèyìndà, omo ìyá Òkè Àsàbí Igba ajá o le e mu Adéwínbí ògùn o lo rí Alé mólo, won bi ó won lómo Tani í se be e, o léyin o Moromo Àsàbí tó joba sílè eèpò Èyí ti n dawo owó lùwón Lájoólù, látúnbòsún omo arólù Akúdùn níkàrè, ìkàrè omo ègún


Ojú, ìgbà ti o sí mó Aláàfin o parun, ó tún bímo Tó ju omo lo, ó bí Adékáfé Omo sùnbò Àlàó, torì náà Ajagun mógberin, ìdòòmì okùnrin Bówó tíí pé lo o pè, Oko ayaba, asokùnrin ní Gbóngbódó omo aíkan ìyá Ò sun gbèdè jí gbèdè Aláàfin A námónáwó owó o tán Adélù làlàlà olújìdé jàlàlá Asáarí, ò gbélékalè o mo Osìn, omo òra nísèkè Okó etilé òhun ègbin Adéyínká omo oromojogbo Aláàfin àdàpò òwò òhun ìyà Ònà gburugudu Adélù Àlàó Látòbàárìn omo sàngó Alaafin Olújídé omo Oromojogbo Asokùnrin ní gbóngbódó Omo aíkan ìyá, ònà gbugudu Adétònà Àlàó, Látòlàárìn Olúkúewu lo tun kú ola Fi saya, omo ewé rare Nísèkè tó bí kúola ìyá Àlàó Nínú Adétònà làlàlà Olújídé Omo òra nísèkè Ìgbà to kú Aláàfin o parun O bímo tó jomolo Adéseéró, Asesese bi eléèmò Adéyemi igi jégédé


Alówólódù, òpádíjo bàtà ba n Súa, Ajígbonrí Àrán, Abegun omú dáranjè Bámúbámú, irúmì okùnrin Okùnrin abegun apá lo bi kúsanrín Òròkí, amólésè bíí òsùmòrè Táyé se májáyé bó Okan tó e kú alówó lódù Baba òókán esin Adéyemi ode ni baba láwoyin Káà kan ìbon Káà kan ètù Káà kan àkádésí Òpádíjo, Adéyemi abílé gbogbo Ní jíje, ní mímu Okú aláàfin omo Moluru, agbàlú olú àjo Bánánbanàn Lójú òrun, boun boun Omorí igbá fi túlásì jókò Táyé se májáyé o bó Òkan to e bado loju Ìgbà ti o sí mó Aláàfin o sí mó Aláàfin o parun Obímo tó tún jomo lo Dúrósinmí, mósaléwá Bangbádé omo Olúkúewu Ìgín-rìn-tádé Adédèjì Ládìgbòlù, Àjò Àkànní Òkúmorà èyí ka mo pe Láwánì Aso oko òkúbánké ofiafia


Ní wóndo eléyín ni jogún Èrín omo sèfíánátù Omo Àrìbà, ìgbà to ní sèfi Níyà tan, òtukóko améyò Gún emi lo ni sèfí Lobìnrin se, Dúrósinmín omo Olúkúewu Ajírérìn òkinkin, Dúrósinmí Omo olúkúewu, Aláàfin Àtìbà Siansian, o ri n tó s’àgbìbà Òtukókò améyò gún to fi Dékun èrin rin Adédèjì, Bángbádé Omo olukúéwu, láfìàgi Adùn Àkànní o omo ara iroko Sùúrù baba ohun gbogbo Sùúrù baba ìwà, àgbàlagbà Tóní sùúrù lo n se bóhun Gbogbo lóní, mósaléwá, omo Olúkúewu ìgbà ti ò sì mó Aláàfin o parun Obimo tó tún jomo lo Òkan kúnjó omo sulolá Omo láaróyè omo èsù Àkèsán Soládèmí Aido la se toto Fun, Adégbóyèga Òdugbàngbà dura Ikúòjó aráleé íléwomo Adégbóyèaga àrólé láwánì Àrèmo Àwèró òkúmorà Omo Àjùòn Àkànní kú mo pe A i johun mo e pe n mi Oko ofun onílé nlá ojó


O tójó Aítúnjí, Mósaléwá Gíwá o, jo gbajagbì Sóládèmí Lójó tomo onílé àrán o fogun Tì omo wòwò lode Sókè Agodi Ikú o jó gbogbo omo ojo Won sa kíjokíjo Adégbóyèga omo òbùn tò ó Sòkòtò dìgbòlù omo ògè Òní mobèrè monàró omo Onílé àrán oní ibi to ba wu Ìbon nìbon tí í ba jagunjagun Ikúyó ara ilé Bíléwomo Adégbóyèga òràn dìgbòlù Àkànní Tótótó fùn-ún èrè agogo Ìgbà tí o sí mó Aláàfin o parun O bímo to tún jomo lo Èèbó Adé Agboolá, Bónlékojú Oba aláyélúwà Òré Adéòtí oko Moyíólá Baba kábíyèsí aláàfin ìdèra Ààrinolà, oba lomo olúkúewu Tótó kin mo ri òrò ayaba O gbà léyo be Ijo lo jo de kàdúná Omo Móyíólá, rárá lo sun wo Jungbu sérìn ànfààní baba Kábíyèsí ohun lo rin dójà eréko Ààrinolá oba lomo Láwoyin N nì hún tàlá oko ábí, n Hùn níhùn tálá lónà òkè ògùn Àlàbí oko Àdísátù Àlàbí Agboolá baba káyíyèsí

Lo mú mi lo mògbòho, àwa Aarinlolá lajo de kútúwenji Àwa kábíyèsí la jo le dójà ìlorin Aarinolá omo olúkúewu Ìgbà ti o sí mo Aláàfin o kúkú parun Súàrá Adéyanjú olóde a ún Dáró baba mojísólá, Bánjókò Modékùnrin tòótó Koko lológun rojú oko yoyin Ládéjo wò mi lójú omo Ládìgbòlù Àjékùnrin Abèèmò layà Omo Tèllà, èèyàn tan konú E, Àkèé ti o konú ara re Gbénú-edé báláró jowú Oko yoyin- Ládèjo ì ran Àgbon Atiba, e dára tì Ìgbà ti o sí mó aláàfin O parun, o bímo o ju omo lo Láíwolá, Akéréburú baba Àsìáwù Àtàndá baba Babátúndé Oko ìyá Núrù, Ibi ònà to lo yán Baba Babáúndé, baba kábíyèsí Mó yà silé mi. Láíwolá Oba lomo Láwoyin Tótó ki n mo ri òrò Ayaba o gbà léyo be . (1) sákì - kábíyèsí (2) Akéréburú ko ga o si lágbára (3) ikú pupa tééré- oríkì Aláàfin Àtìbà (4) Àharan gbàngbàn –Aliun-eranko kan (5) Igi jégbédé – Eni ti o ga (6) Ewé gbígbe ti fojú diná – o laya

[edit] ORÌKÌ OBA ARÈSÀ-ADÚ

LÁTI ENU ALÀGBÀ OYÈKANLÈ

ÀLÀDÉ(OMO ISÉ FOYANMU

1. Ìrìn mi gbèè, ó dilé wa lohunun ooo Témi bá n lo sónà ibè mo monlé wa Omo Arèsà tó lépo níkèté, omo serúbóba délé o … Dèku ràpò òrí elégbàá Ìresà Búra mójòrí omo Oba gbándú igi òpe Baríolá omo Oba gbándú eti ekoro Ì na sòkòlònbó aa gbátà sebè. Omo àkókó méta ètí òkun Àrèrè kotì-kotì eye òsà Òtàátàá leye Àágberí jé Eléyun nì lomo Oba tó jesin-jesin té e gbéso sórí isin Tóbo sí enu àwon àgbìgbò Póbó tó lo ó bó ó denu àtíòro Òkan lomo Oba tí í jepo Òkan lomo Oba tí í joyin Kò tètè wi fún mi pohun ó jòrí ikin ìna àbo omo dágun Ìyèkan Oníyèkán Ìyekan Oyínyèkán Ìyekan tìgè tàdùbí Oníìkèyé

2 Àdùbí ONíkéyè anumo bí eye Èyí tó jí ni kùtù kùtù, tó ti jí ní fèlí ìdájí O wá ló perú re sagbàlá níjó ojó sí Ún wá n pé erú mi àrùn wo leyin? Àrùn wo lèyi? Erú ní àrùn kan, àrùn kàn tíí geo mo ni poríkí-poríkí owó O sì tún berú rè léèrè wò Ó ní erú mi àrùn lèyí ? Àrùn wo lèyí Erú ní àrùn kan, àrùn kàn ti í gé omo ní porìkì esè dànù Erú bínú wonú igbó , ó gbérin lójú pàá erin sáré ikú Lo mòngodo-mòngodo O fìbínú bo sí àwón esè òdàn Òun náà bá tefòn láyà Òun náà bá tefòn láyà Efòn sáré ikú lo mòngàlà-mòngàlà Ni won n péni tó bá bègè Àdùbí nísé ara rè ló bè Kò ni pápaà jé, Oníkèéyo gbengberí-olá, omo ajolú joba Òun lògèdè àgbàgbà ti somo rè kó dèèrè Onípònná omo ikú méta àfiri ogun Àparò méta òyòòyò méta à loràn Òkan ní n se e jé á ba, e jé ába

3 Òkan ní e jé pòkòkò ká re káè lafònjá, ìlafònjá ilé ò je pànbóló Un la ba kolúrón adé, la bá roba jó geere Ataresa ò bá won pé jì njòwòn àlò Eléyun nì n lomo Oba túpe áà; omo Oba tùpe, Omo Oba òmìnì to a gbó àasà Omo Oba túàgbá Omo Oba Ògún òroke Èé tó fìbòòsí ta lo sáàfin Òyó lé njó ojósí O ní ó síkin ládàálè táale mó o bo Oba ni ó mó o lo sínú ilé Ó ní bóbá dojó méje òní, Oba ní kó sérí kó wá Kí ojó méje ó tó pé ò ò ò ò Esin baba won, ó kú gbó olóòwá Ó rànrú sílé Oba a loràn

4 Ó fagbedegbédé sílé Obàdíwò maa róhún nú lebo Aráa gbó olówa dé won ò gbodò yagada kí won ó kunran esin Eran esin kò sì gbodò rà á bè Lóòtó ni béè ni òdodo Wónranse lo o lé olúgbon, wón ní ó fún ni lobe àáfí kunran esin O lóhun ò lobe ti han fí kunran esin Lóòtó ni béè ni òdodo ni Wón ránse lo sílé Olórà wón ni o fáwon lobe àáfi kunran esin Ó lóhun ò lobe tó han fi kunran esin Wón wa ránsé lo sílé èrìmòjé omo a fò lérìn Elérìn ó wá fún won lobe merin àwon wá kunran esin Gbà tí hán kunrab esin náà tán Wón bá n gbé apá Olúmokò ló n gbé mèmèsì àyà Ògáálá nìkan n ló jolori kórà kófà a gbórí esin Omo Baríolá ni ò tètè dé ni wón bá e rò mónrù esin

5 Lóòtó ni béèni òdodo ni N ní han fí sèrù esin làwon fì bo nlé ìresà Bariolá omo Oba gbándú eti ekoro Témi bá n lo sónà ibe mo monnú ilé won, ènì ò bùrà kò jòrí aará ìresà. Búra mo jo`rí elégbàagi ope Baríolá omo Oba gbándú etí ekoro Ni ìgbà tó di ní sègbè ooo Gbogbo egbé mi lo sí oko igi, èmi sì lo sì oko igi Gbogbo egbé mi ségi wale Mo se kèkéè wale Mòmó rimi lókèèrè, mòmò fekún si èmi ferin si Mo ni táa bá ségi wálé emi ni mó on se? Mòmò lémi ò wa mò ni pé omo Oba kéke, omo Oba kèke Omo Oba kèké fújà lalò Wón lémi ò wa mò ni pé omo Oba kéke, omo Oba kèke, Omo Oba kèke fújà merìndínlógún

6 Tí won n joba nínú ilé ìresà Baríolá omo Oba gbándú eti ekoro ìna sòkòlònbó máa gbátà sebe Témi bá n lo sónà ibè mo monú ilé waa Arèsà dúdú lègbón pupa làbúrò Inú ló konú ni won e fomo fúnra won Lóòtó ni béèni òdodo ni Ìran kánhìndé un ni joba Ìresà dúdú Ìran Táyéwò un ní joba Ìresà pupa Ìdòwú nìkàn, tí í somo ìkányìn won lénje-lénje ni n joba ìnísà Témi bá n lo sónà bè mo monú ilé wa, èdè bùrà ko jori aa rá ìresà. Búra mó jòri elégbàágí òpe Baríolá omo Oba gbándú eti ekoro Ìna sòkòlònbó aa gbátà sebe. Àlà e wà bí o , gbogbo ilé ti ri o o o ? Inú ilé gbogbo kàà sí nkan ni ti wa Omo Oba túpe, omo Oba tùpe, omo Oba òmìnìtúá igbó àasà Omo Oba túàgbá, omo Oba Ògún ò rokin 7 Témi bá n lo sónà bè mo mo lé wa a Àlà e wá bí o, gbogbo ilé ti rí ? Inú gbogbo kàà sí n kan ròdò- rodo pòòmú aara Ìresà Arèsà dúdú lègbón pupa lààbúrò Lóòtó ni béè ni òdodo ni inú ló konú ni wón e fomo fúnra won Ìran kánhìndé a joba Ìresà dúdú Ìran Táyéwo nìkàn ní joba ìresà pupa Ìdòwú nìkàn tíí somo kányìn won lénje-lénje, ìdòwú nìkàn ni n joba ìnisà Témi bá n lo sónà bè mo mole wa Bá n fènì si, èmi ò fènì si eléyunnì N ní mo on bí ìresà nú Bóólé kóo bupo ló yá mode lára Témi bá n lo sónà bè mo mole pón ròdò-ròrò Àlà e wà bí o, gbogbo ilé ti ri ooooooooo Inú ilé gbogbo kàà sí nkan kan an ni ti wa Ròdò-rodo pòmú aa rá ìresà Kálo o lé lónìí elégbàagi òpe Baríolá omo Oba gbándú etí ekoro Ìná sùn kólónbó n la gbátàà sebè Àlà e wa wà bí ? Inú ilé gbogbo kàà si nkan kan an ní ti wa Témi bá n lo sónà bè mo mo on lé e wa Àlà e wà bí ò ò mo a pón bépo ré ò ò ò ò Ròdò-rodo pòòmú aará Ìresà

8 Búra pòó jòrí eelégbàagí òpe Témi bá n lo sónà bè mo mo on lé wa a Àlàfà ke wa bi o ? ilé ti rì ò ò ò ò Oyèdépò orí Olóyè sáájú ò ò ò ò, in won ó ràn o lówó won a so tìkanyìn ní Oyèdépò mó ón gbórò enu un mi Témi bá n lo sónà ibè mo mo on lé waaa Omo Oba Túàgbá, bórí won ó ti mo on ran ló tó ò pin ni Témi bá n ló sónà bè, mo mo on lée waa ‘Dépò orì gbogbo Oba tó je bí won ó ti- mó on ràn ó lówó tó ò pin ni Àlà e wà bí inú ilé gbogbo kaa si nkan ni ti wa, ròdò rodo pòòmú aará Ìresà.


Orin: Edé odì ò níresà Mi ò gbàgbé n ó pèyin ò níresà Ègbè: Èdè odí o níresà Mi ò gbàgbé n ó sìnyin ò níresà Ègbè: Èdè odí o níresà Mi ò gbàgbé n ó sinyin ò níresà 9 Ègbè: Èdè odí o níresà Èmi kòkòyín n ó sinyín ò níresà Ègbè: Èède odí o níresà a a a.


ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA KÓKO NÍNÚ ORIKÌ OBÁ ARÈ SÀ

1 Omo ìyá kan náà ni Oba Arèsà-Adú, Aresà-Apa. Apa.àti

Oba  ìnìsà.
Arèsà-Adú ni kéhìndé
                                    Arèsà-Apa ni Táíwò
                                     Oba Ìnísà ni Ìdòwú


Ikoyi

[edit] ORÍKÌ OBA ÌKÒYÍ

LÁTI ENU ALÀGBÀ OYEKALE ALADE

OMO ISÉ FÓYÁNMU)

Ùn n lo ilé wa lóhun ò ò ò ò Nílé ìkòyí omo erù ofà Olóòótó omo gbáà, omo gbèdu Yánbínlólú omo Arágáláká kee fikú pogun

1 Àrònì gbonra jìgì dagi erù oògùn nù Omo gbélé Omo gbégbèé Omo gbé ijù, gbébi Ò-gbódi-gbé-yàrá O gbebadan ò kè pé, o gbákínmòórìn, o gbáawé Ò-gbé-fìdítì-gbewàré O gbákínelé, o gbéléefón run O gbélé kúata, òtè ò tán e e bibì làá dé si Kú fúnwon rérìn-ín Olóyè n ni baba mi Ó níbi táa bá gbé, ibe nilé eni Jagunjagun lèrò ìkòyí jé, omo oba a jò lápó wòròwòrò Ogun ló bámi ni gbo Mo dolú igbó N lé mi lóhùnún ma dòsó esin Bí bá n rogun Èrò òdàn bamii lódan mo dèrò òdàn Ogun ló bámi pàlàpálá mee dòpá à bon Àsé Olú nìkòyi jé omo eèru Ofa Témi bá n lo sónà ihè mo mo on lé wa Olúkòyí àfeji, àfeji n lo bí onikoye àfòjò àfòjò Olúkòyí àfòjò àfòjò, un lo wa bí Olúkòyí èèrùn gan gan gan

2 Olúkòyí èèrun gang an gan N ló bí Olúkòyí ìrìwòwò Olúkòyí ìrì wòwò, un ló bi Oníkòyí òdá gbágbá Olúkòyí òdá gbá gba, un ló bi Oníkòyí ò koko Un ba won tó pón kángun síkoto níjóhun Témi bá n sónà bè mo monú ilé wa, Eléyun nì taa lóbí, taa lóbí ? Un ló bí òkéré lèrù gan gang an Òkéré-lèrù gan gan gan gàgbon n baba won àgbà took tó kori òde ìsálayé N lé ìkòòòyí omo eerù ofà Olóòtó omo gbáà omo gbèdu Yánbíniólú omo arágálá efikú pogun Témi bá n lo sónà be mo molé wa Omo Oba ìjí peké-peké N lé ìkòòyí omo erù ofà Àwon ni, àwon lomo Oba ìjí pokùn-pokùn Ìjí mó pokùn mó Igi àtòrì ni ko yá mó on pa Ìji mó pagi àtòrì mó Igi àtòrì òun nigi àse

3 Igi àtòrì òun nigi òrìsà òwójì Láwòójì n be nlé owínsí dara Omírìn dara lóri ofa òòò Ota rìn dara lóri omi ò ò ò Làwa n pèkòyì omo eerú ofà Olóòtó ègi yánbinlolu omo arágálá e fikú pogun. Àrònì gbonra jìgì dagun erùù oògùn nù N lé ìkòòyí omo eerù ofà Àlà e wà bí, inú ilé gbogbo kààà sí nkan kan nítiwa Omo sírò n togun Omo gbàro n togun Omo jìgan n tode Omo jìgan-jìgan láà rùkú alaigbodoràn mote serù bòtè Mo letí mo fi n gbóràn láyé òòò Enikéni kó mó rúmí gbajú òde baba mi lo olórí ogun Àwa lomo òsèsè ‘kòyí Tí mo réèrín gán án ni kú Tú kí n dérin, elégbà ni mo di pèle níjó tí mo fi lo gán án ni ogun ìlànlá omo èrù oofà Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa Ìkòyí omo eerù ooofà 4 Olóòtó omo gbáà, omo gbèdu Èyin obìnrin ìkòyí e mó pagbòn lágbòn mó Gbogbo obìnrin ìkòyí tí bá n pagbòn lágbòn wón n rán oko won léti ogun ni Lóòtó ni béè ni òdòdò on yùn Àkà kè wà bí, inú ilé gbogbo káà sí n kan ní tiwa ìlànlá omo gbáà erù ooofà Olóòtó omo gbáà omo gbèdu yánbínlólú omo arágálá omo e fi kú pogun

Orin: Eruwa nil é omo agbòn, ta n níkòyí ò nílé Omo agbon ? Ègbè: Eruwa ni lé omo a Lílé: Ta n ni kòyí ò ni lé omo agbòn Ègbè: Èrùwà nilé omo agbòn Lílé: Ta n níkòyí ò nílé omo agbon? Ègbè: Èrùwà nilé omo agbòn on on.

Ìrìn mi gbèrè ó dilé wa lóhùn ún òòò Àdesítèé oníkòyí òòò Ìkòyí omo eerù oofà Adésítèé loba tí nbe lé kòyí omo agbàawà


5 Olóòtó omo gbáà, omo gbèdu, yánbímilólú omo arágálá e fikú pogun, Àrònì gbonra jìgì dabo erù oògùn nù Okùnrin gbon gbon gbon bí ojó kanrí Adésítèé, Okùnrin gbòn gbòn gbòn bí eni fìbon tì Ìsépo méjì omokùnrin Adésítèé mo o bá tòde baba a re lo Ìkòyí omo gbáà, omo gbedu yánínlólú omo arágálá e fi kú pogun Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa

Orin: Tapó tapó ;à á bómo ogun Tapó tapó là á bomo ogun Ìgbà ìkòyì ò tó déedé Ègbè: Tapó là á bómo ogun Lílé: Èsò kòyí ò rìkú sá Ègbè: Tapó tapó làá bómo ogun Lílé: Àgbà à kòyì ò ríkú sá Ègbè: Tapó tapó làá bómo ogun Lílé: Àgbà kòyí ò ríkú sá Ègbè: Tapó tapó làá bómo ogun Lílé: Àgbàà kòyì ò ríkú sá Ègbè: Taapó taapó làá bómo ogun un.


ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA KÓKÓ NÍNÚ OBA ÌKÒYÍ

1 Olúkòyi je jagunngagun tí kì í gbélé kò se inú ìgbé. Ìdì nìyi to wón fi máa n so pé èrùwà nilé omo agbòn.

[edit] ORÍKÌ OBA ÒGBÓMÒSÓ

LÁTI ENU ALÀGBÀ OYÈKALÈ ÀLÀDÉ

(Omo Isé Fóyámu)

Ògbómòsó òle ò gbé Ògbómòsó òle ò gbé, eni ó bá lágbárá ni gbébe 1 Lóótó ni béèni Òdodo ni Ògbómòsó ‘mo ajekà ká tó mùko yangan Ògbómòsó ‘mo a jòrépo-tú-yì Àlà e wà bí o ? Inú ilé gbogbo kàà sì n kan an ní tíwa. Ògúnlola lorúko sòún àkókó je Soun kéìtán iwin lábérinjo Àísá Òkin onígùru-gùrù kéta Adàdá mówù moja àpà Oba tóbá onígògòngò jagun àlùsì àpà Eléyun ni ni oòòò Òun loba tó kókó tèlú ògbómòsó òòòòòò Un lókó tèlú Ògbómòsó dó Lóòtó ni, béèni òdodo ni kì gbogbo Oba kí won ó tó mó on je N gbà tí ò dè si eléyun nì mó o Ògbómòsá òle ò gbé eni ó lágbára ní gbébe Temi bá n lo sónà ibè mo monú ilée wa Èyi loríkì ti ògbómòsó ajílété Béè náà ni Oba ajísegírí niilé wa E dáké Ògbómòsó òle ò gbé Eni ó lagbara ni gbebe. Ògbómòsó, Ogbomojúgun Temi bá n lo sónà ibè mo monú ilé wa Báàbá bára wa tan, a fògbó kògbó nnú lé Àlà e wà bí ò ò ò 2. Inú ilé gbogbo kàà sí n kan ní ti waaa kótó wá kàjàyí-Olú-Ògídí oníkànga àjí pon Aíléwólá agidingbi lójú Ogun Àtilé atona ni baba mi Àrèmi fi sá nka ìjà á sí Béènáàni Aíléwólá agidingbi lójú ogun O lájá ti n be nínú ilé méì wulè gboni, Ènìyàn Àjàyí té e rí ò gbodò ya só o mó lásán Béè náà ni omo aráyé nì n kóba lóro Ìgbà ti ò dè si eléyùn nì mó o N ló wa kan Oba Ajagunbádé Témi bá n lo sónà ibè mo mo on mi ilé wa Ìbísùnmí, Lákanngbò, oko aràgan Ajagungbádé Onídugbe Àráráriri, Gbángbóyè ìrèlè baba òkè Kójú ó torì, kóràn ó dòrìsà Òrìsà mo kaàbá Bábà bá yè Ajagungbádé Jánjanjan ní mo ón dunni Ajírèrín Òkeke Àdàgbàlagbà Sinyan àgbìgbò nìwòn Ìbísùnmí ní n tósàgbònìwòn té e dékun èrín rín Tobá segúnnugún a kowo móri eyin Nnkan to sàjààsá té e délé ìbàdàn Tóbá solówó erú ni, à bá ti rérú è mó pátápátá 3 Atìbàdàn wá joyè bí omo jógíoró Okùnrin pon pon pon bí ìbon ògodo Gbongbòn janran baba mi ìbisùnmí tó wúwo bí àte àdí Aja-n-gba-da-gírì-jagi Ò-jebòlò jegi ìdi rè Sara-sara làá kina bolé Òjò pàà pàà ti tújà Abomo on mú sànpònná kàrà-kàrà nìgbà osàn Ó yi éyìn osè, o pomo òsú lékún O sìkà osumí ògódó ó kanga oní kanga Báni bù ú wò omo òkèèbàdàn Àlá ó ba bùú, ó ní iyán lémo Témi bá n lo sónà ibè mo mo on nú ilé waaa Ìgbà tí ò dè sí eléyun nì mo òòòò N ló wá kàlàbí Òyéwùmí Oyèwùmí Ládiméjì, Ládèjo Afolábí omo Tinúuwin Ajíkobi Dèjì omo iwin ìgbàlè Dèjì omo Àsààkún eni tó bá wolodumare ní dá lólá Òkìkí ò posù, ariwo ò ní pojó

4 òkìkí ò nó somo onílè ni n kankan Ojo ò tòòjó, ojó ò tojò Ojó táwon kenimoni gbórí àbíkú kale lójàajagun Eni tó kúrú n wón n tiro Ènìyàn tó gùn n bèrè Àlàbí ò gùn béè ni ò kúrú Ó dúró gbangba, óbálábòsí wijo Níwájú òyìnbó ajélèèèè o jàree abínú eni Orí ewúré sunwòn itú ló bí Tàgùtàn sin àn ó bí yàgbò Ìpàdéolá abesin gbórùlé jìgbàró Orí baba Láléye sin àn tó bárá Ìbàdàn tan A rí bí won tí n sojú oko Olúgbódi Àrán inú àpóti oko Efúntádé Àrìnjó káàkótó oko ògboyà Méèle nìkàn sùn, méèle nìkàn dájí Nílé làlàbí òkín lóti málàké ròòde Témi bá n ko sónà ‘bè mo monú ilé wa Agbe tori omo rè dáró Àlùpò dùdù tori omo rè kosùn Lèkélèké gbàràndá ó torí omo rè déwù aso funfun

5 Torí Àbáké lo fi ránmo láyédé Torí Àbáké lo fi lo o kóògùn aremo Àsoba sàrìnjó tí n gbonílù tí fi gbèwù àrán Oyèwùmí Àlàbí n ní gbomo Ológbàó tí fí wé gèlè genga Eléyelé ìyàwó, oko jólásún Ará ilé Àdùnní, OLókan aya bale ajísomo Dèjì Àlàbí oko látúndùn Oyèwùmí Àlàbí ló fi Ládùnní rópò ara rè tó dip ó térí gbaso Témi bá n lo sónà ibè mo mo on nú ilé waaa Òun loládùnnúnní Àkànó Oba tí n be lógbomòsó òòòò Oba ògbómòsó tí n be lórí oyè ní ìsinsin in Témi bá n lo sónà ibè mo on lé wa Ìbà baba mi Àkànó Oládùnúnní òòò Oládùnúnní Oba tó rojó ilè tó jàreee Bémi bá n lo sónà ibè mo monú ílé waaa O jàre gbogbo àwon ìjòyè tí n be lórí ilè náà Àlàa`fíà ke wà bí o Témi bá n lo sónà bè mo molé wa Eléyelé ìyàwó òko Lárónké òòò Ará ilé Àbìó ò ò ò Oyèwùmí Àlààbí

6 Oyèwùmí Àlàbí Oládùnní Ajagungbádé kan Olá òkan ò jòkan aya Bale ajísomo Dèjì Àlàbí Oko Túndùn Témi bá n lo sónà bè mo monú ilé won *Àwon lomo Ìbàrùbá niwón elégùn esè Ìbàrùbá niwon elégùn esè Olàyankú omo ode bárán eti oya Omo Abérisé Omo Agbònkájù Omo Ajijoperin Ìbàrùbá omo olójà n lìkì Ìbàrùbá mojà lójà Ilé yìí, ilé àwon baba mi Mo bá e dó kááda oníkáadé Oníkáda won ò sì ní gbèsab àwò ò ní tánmo lórùn n lìkì Omo pákí nimi, mé je sìgo Omo nàmù-námú, erú ò joòrì Omo kékeré Ìbàrìbá téerì ò gbodo jáwé apá sié lánlán Ìbàrùbá Olákòndórò, Oláyínnkú, omo ode bare eti oya Omo abérinsé, omo agbònkájù, omo ajíjóperin Looto ni béèni òdodo ni Ìbàrùbá won èé sunlé àjà Won a ní e bámi wéké yógùn nanana ki ni róhun kólé

7 Ìbàrùbá onílè lìkì Ìbàrùbá won è é pèkùlù Won a ní e kálo o lé lóhunún ká lo rèé kédò erin Ìbàrùbá Olákòndórò Oláyankú Omo amérin wá á mòlú, omo aréfòndiyàyà Àrá abowó òjà lálálá Baba mi ògìdán tí fowó ìjà ralè Óní bí elérèé ò bá réni Tí ìjèsà ò bá tajà láwìn A kòí molésà lásán Òyíìrí lápó Oládòkun èjè ti ti ti lénu esin Tayérunwón, Tègbésòrun Agbesin lówó Olúpaje Aare akòta sùsùsù ofà Sòún abiléfà n wájú Kéètán abilé ofà léyìn Dáùsí abilé ofà láàrin Baba wa ló soró kan bí agogo A fìbènbé ooró kù bi òjò Eléyun ni nú ò ò ò Àwon Oba tó tògbómòsó o Jógioró akandehunso, àpáti Olúmokò tí kogun lójú tòsán tòòru

8 léfá wolé, lóòsà wolè kò jé ki elénpe bòdé mó o gbesin lówó Olúgbaja, ààre a-ko-ta-sù sù ofà témi bá n lo sónà bè mo monú ilé wa Ìgbà ti ò dè sí eléyùn nì mó ò ò ò ti jógioró kú ò Eranko orí ráre tii dún mònnàhun-mònnàhun Témi bá n lo sónà bè mo mole wa N ló wá kan Ik’’umóyèdé Àjàsá alátò oyè lábé Oba lábé bánbóba bánbóba Oba tóláya márùn-ún táwon márààrún ti an bímo oyè Wórókòòkan Oba ni wón je Témi bá n ló sónà ibè mo mo on nú ilé wa Eléyun nì óòòò` Taa lóbí, taa lóbí òòò? Òun ni baba Àjàjí Olú ògidí òòò Olúwùsì Àjàyí Lóòtó ni béè ni òdodo ni Olúwùsì Àjàyí Onísòro sègì òpónrororo, baba mi akòtòpò iyùn Òbá jègbè ìlèkè Àjàyí ebí láàrin lòbá mó on gbé Ailéwólá o yanjú Olá gandangbon Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó ò ò ò Taa lóbí, ta a lóbí ò ò ò ? N lókàndòwú bólántà a wùwón

9 ìdòwú Bólántà a wuwòn on bólá bá dojúdé a súwon súwon Àkèyìn sí olá kì í rò Ìdòwú Olóde Àgbánká Fárónbi abesi kan kúro lójú ogun Gúdúgúdú abojú légbèé Àlùkojú órun àpinti Adáso mó fágírí, oko ògúnyìnmí Agbinni mó gbinsè, oko Ajíbólá Ògòngò gongo nírìhànló Oko òjíbù ti jájolá Ayìndòwú nibon kò kú, a tomo jógíoro lóra o mú gbogbo e je Ògbó dì ofà tii semú wìlìkí O ní kòsí oya òòòò Ogun a kólé e rá òòò Bí ò sí olùfòn ogun a jà lérìn Tí ò bá síi lákidófà Ìdòwú Ogun ni jòsogbo Ó gòkè òrá, o seré nà fún gàmbàrí Ò se rebee níjó dósogbo Ògbèkè n gbekè, rábesè gbékèlé Ó fàtògòrò, ó súwon lóòrógàn títí Ó gbójúlé lé jagun níjó ogun níjó ode Èdù òkin ti fóhnn sà Témi bá n lo sónà bè molé wa Ìgbà tí ò dè si eléyun nì mó ò ò ò

10 lówá kan Akíntúndé òwè ìsòlá Tí jówólè Oòni Akíntúndé Apébu Apéébu wóló, atìdí yògòlò Amúlé gbolófófó Àwa la múlé gbelé aseni Ilé aseni won ò jìnnà ó jà Àbá molé olórò ni, a ò sì molé aseni Àbá mole aseni, òràn won a tètè tán N lèmi pogunlabí Òwè ò jejò kínní o feran ejò se lénu Yàkàtà yakata kò jé a rí ìdí ìsápá Ìbíkúnlé ìbàdàn, won ò je á sodún arò ní nkankan Ìgbì tí n gbìkúnlé A jade tòun tòbùrù gege bi elégbára ègbè léyìn gbogbo àgbà Bàdàn. Òháhá ilé lógundégèlé ò eruku esin lofi légún Déyemo Awon ará Òòyì, àwon n won ò gbón Àwon n won ò mònràn Won ò mò pérúukú lòwò o báwí

11 Ogunlabí kójúmó tó mo lo kó gbogbo won lóóde Òlémo gbó Àsàmú baba Àb áàsì Ìgbà ti ò dè sí eleyun nì ìn mó òòòò` N mí Oba márun òòòò Lóòtó ni béè ni òdodo ni in Temi bá n lo sónà bè mo monlé wa Ó wa kàbàrí Olúòyó, ebìíyà Àbàrí OlúÒyó, Oyèédòjun, Látiri abólugun-Oba Oba táaké ké ti ò juke Oba táa gègè tí ò jugè Òrìsà tí ò jugè, ojú pópó ní gbé Dúdú fílàní n lomo lákan lé fi modi Pupa re ní sàatà, ìdùkúrùkú Témi bá n lo sónà bè, mo monú ilé won Ìgbà tí ò dè sí eléyun nì mó ò Témi bá n lo sónà ibè mo mo on lé e wa a In ló wá kàlàó, Onísòrosègi Àlàó témi bá n lo sona Òun ni baba Àtàndá Ògúnwèndé òòò Àlàó táa wí yìí, òun ni baba Àtàndá Ògúnwèmdé òòò Òun ni baba Láoyè tíí jórumogegege

12 Apásánlá abaralómú, lómú omo kélébe Ààre asòkò senbe àbàjà Sòún dáìsí Oláoyè ni baba ònpetu Bàbá lelébùrú àásáká Oláoyè abìlé gbogbo lóógunlóógun Odán nigi àwúre Òpè nigi ìràdà Àgbà ti n féni láfèé lólé Iwo nlá ni fólúwa re je Té lésin, bàà lésin Òkètè n ketè, a mò ón gùn jomo àgbè Àtùké bóun àsá baba lágbéndé pinpin pin lórí esin Òpòló tóo yírò òo se é to Oláoyè okólé baba re lóbá kan kórí Alùfáà a pàkòi, Oúnlé orí omo kélebe Témi bá n lo sónà be momolée wa Ìgbà ti ò dè si eléyun nì ìn mó o N ló wá kàntá Olóndé omo Omídélé òòò Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa Bá à kègbón taní kàbúrò Mo kókó fe e lo sílé baba itabiyi Témi bá kó n lo sónà bè mole wa 13 òjó aburúmoku ò ò ò ò Témi ba n lo sónà bè mo monlé wa Kékeré àsá omo ajùújù bala Àgbàlagbà àsá omo ajùújù bala Kékeré làdàbà subu táwon tí n je láàrin òtá Olóumí kékée lo ti n soko won nílé Kekere lo ti n soko won lóki Kékeé lòjó ti n soko won lóna ijù Oníyòówón, Inásírù, Ibasòrun Kínyodé Iba tíí begun wolé e rémo lo Iba tí n bá n bò, a kòdi órun Òfesè mejeèjì gungi òbobò Eléyun nì ní ò ò ò Òun ni baba ìtá Olóndé omo Omídélé ò ò ò Òré ò sí, Olórun Oba dada Ináwolé baba kóta Ó ní Ifá firipò nínú igbó Òpèlè firipò laàtàn Òrìsà ké kè firipò lágbède agodi Ináwolé baba kóta 14 Témi bá n lo sónà bè nmo monlé wa Tí ún bá n lo sónà tòkun, òkun lolórí omi Ìgbà ti ò dè si eléyun nì mó ò ò ò ò N lówá koláyodé ò ò ò Adékúnkèé, Adégòkè oko pàte Oláyodé omo egúngún oko Àrà n baba mi Àatàndá Adégòkè omo iwin ìgàlè Lékèélékèé eléwù akese Ahan ran mòjàngbòn, eléwù pànpànkusà Ògbómòsó ní wón gbé, won ó mo lòó sàyonuso, sí Láyodé omo egúngún oko Ò-déyìn-ìlèkùn-di-baba-àgbàlagbà Òmìmyín-mìnyín té e rí ò le è meyín erin Èfúùfùlèlè n won ò leè mi òkun Won ò sì leè mi òsà Ìse tí èfúùfùlèlè táwon n se sókè lorùn Àtàndá Òkín Olóun Oba nu ò joke ó wó Àsá n ta, kò leè tagba raso Àwòdì wón n rà, won ò le e rewin ìgbàlè Títí tí àwòdì òkè tée gbélé ò ile mò pé ojú eye oko a mó on ri íri-íri Ìse ègbón, n wón n pe àbúrò Àbúrò ìba sègbónm ojú won n pón

15 Àbúrò ìba sègbón, ojú won a pón kankan bí oju alala, orùn won a wò pèrè-pèrè bí èwù àgbàlagbà Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó o Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa Ó wa kan Ajíbnólá, Adogun Eléèpo àrán Ajíbólá Oba to kobi sóyi Témi bá n lo sónà ibè mo monú ilé wa Ajíbólá Oba tó kobi sóyi sógun Àlà e wà bí, gbénkan dùgbè-dùgbè Un ní pé Olóun Oba gbàmi Oba séríkí, in ní gbani lóhun tótóbi ní nla tóbi Sòkòtò èfà mi ò òn balè Adìgún ni kásá paà lówó lówó Táa bá ti lówó lówó gbogbo e níí tóní Àlà e wà bí ò, inú ilé gbogbo kàà si nkan nítiwa. Agbà ti ò dè sí eléyun nì mó o Ó wa kòkò lánipèkun 16 Témi bá n lò sónà an bè, mo mo on nú ilé wa aa Àlàáfìà ke wà bí o ? Òkè Olánipèkun? Òkè kéé kèè ké, mó on jólè rè sánpónná Kóniyangí kó mó on jélégbáa Òkè tó lo sóòwu òbò Eléèé tó lo sóowu ò dé Adéowó dáké mo joke kóòwu jojololá omo Bádéjéorúko Òkè ni ò ri powó awon èlèdà Àlà e wà bi, inú ilé gbogbo kàà si n kan nít iwa Ìgbà ti ò dè si eléyun nì mó o In ló wa kan Olátúnjí Eléèpo àrán Olátúnji omo gbángbéfun Àrágada sí bààmú lójú oko Oyèládùn Kòlù-kòlù mó kolùmi Olátúnji ò ò ò Eni Olátúnjí Àlàó Àlàó bá kolù yó febo jura Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó o N ló wá kolágidé, Olágíde Àjàgbé òkin baba Lúfójè Témi bá n lo sónà bè mo monú ilé waaa

17 Òyìnbó funfun ò doable fóba láàfin sòún ri o Níjó títáláyé ti dáyé ò ò ò Béè náà ni, níwájú omo Odérónké ti n wó tuuru Níjó tó fòyìnbó párì joyè Àlà e wà bí inú gbogbo kàà si n kan ni tiwa a Àjàgbé Òkin baba ìlúróyè Tí ùn n bá tún lo sónà bè mo mo mole wa Ìgbà tí ò dè si eléyin ni mó ò Ó wá korímádégún àjààgbé Òkin, Tí ùn bá n lo sónà an be mo nú ilé wa Salami Àjàgbé, omo ìtá Olónjó, omo Omídélé Òré Òsú, Olóun Oba dàda Ináwole baba kóta Gbogbo won pata-pátá táa wí yí òòò Orílè ti wón ti wá Gbogbo won lomo ìbààrú onílè lìkì Oláyankú omo ode báré etí oya Ìbàrùbá won è é sunlé àlà Won a ni e bami wéké yógùn nanana kí n róhun kole adodo 18 ìbàrùbá oonílè lìkì Ìbàrùbá niwon eledin ese, omo ode báré eti oya Òun ni baba tó se gbogbo wón lè pátápátá pogodo Nílé è bààrú onílèe lìkì.




ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA KÓKÓ NÍNÚ ORÍKÌ OBA ÒGBÓMÒSO

1. Ìran ìbàrùbá ni sòún ògúnlolá, ode ni ó se dé ibi ti a mò só Ògbómosò lónìí yìí. Sòún Ògúnlolá àwon kan pàdé nínú igbo, gégé bí ìtàn ti so, èéfìn iná ni wón fi mò pé àwon kan tún wà nínú igbó nàá. Lára àwon kan tún Ògúnlolá bá pàdé ni Aálè èyí tí ó jé bale Òkèelérin, òbé ti ó jé bale Ìjérù, ìran Ègbá ni Òbé jé, nígbà tí Aálè jé ìran Tápà, gbogbo won jo n se ìpàdé ní òdò Sòún Ògúnlola, wón sì fi se alága.

2 Ìtumò Ògbó mòsó: Ìyàwó Sòún Ògúnlólá jé eni tí n pon Otí tà, orúkootí náà ni oti ewe. Ìyàwó Ògúnlolá je bábá ìjèsà kan ní Owo, nibi ti wón ti jo n sòrò lówó ni Sòún Ògúnlolá wolé, èdè àìyedè dé láàrin Ògúnlolá àti baba náà, Sòún si lu bàbá náà pa. wón fún Sòún Ògúnlolá ni àrokò pé kí ó lo fun Aláàrin, bí ó ti débè, ó so fún Oba pé òun yóò bá won ségun elémòsó ti n pa ará Òyó. Ògúnlolá bá elémòsó jà ó sì paá ni ó bá gé ori rè, o sì gbe fún Aláàfin. Ògbórí elémòsó ni o di gbomoso. Akínkanjú ti Ògúnlolá jé yìí ni o jé kí ó jé Olórí fún àwon Oba aládé tí ó wà ní agbègbè Ògbómòsó.

Lára àwon Oba aládé náà ni Oba Arèsà, Oba Ònpetu abbl. 3 Ìtumò Otí ewe: Otí erèé ni à n pè ní otí ewé .


==ORÌKÌ OBA ÒNPETU ÒJÉ== lati ENU LÀGBÀOYÈKALÈ ÀLÀDÉ(OMO ISÉ FOYÁNMU)

Ó dilé wa lóhùn-ún òòò Témi bá n lo sónà token òkun lolórí omi, in Mo fé lolé Oba bí adé ò mèedi òjé aa dígò sorò

1 Lótùú olójà lodòjé ilé Omo afínjú eye tíí mumi lágbada tòdò tí mo n bà lonà èbì, Òró gangan ni wón fomo odó fún odó òòò, N lé ni lóhùn ú nose okúmorò lónpetu, Lóòró gangan gan táwo todò lónpetu Ìda kàlà n baba mi àgbà kan ó tó mùko àdò mònyàn Ìyá ò dámi ní àgbalè rí, n dúró gangan le fi múmi ní omo Obí n jesu kò wale írí, Mo bá tòde baba mi lo, Omo obí tàlùpò lówó won ò wasà, Obí, obí te túkùú ò gba toríigi keke Omo Oba gbélo, gbébò lebì. Mo pàdé egún kan lókè lààká o Ojó ò t òòjó, oojó ò tojò, Tí mo pàdé egún kan lókè lààká o, Mo rò pé were ò tètè dami mo pemi ni in, Témi b á n lo sónà be mo monlé e wa, Ó ní banyan ò gòkè, tó dòkè kó mo on rókè, kómó on bo á sísàlè èè

2 Ó ni ò ní bóun dé pálò baba òun Mo ní n bo ni in? Olóun lomo èbì òjé a dígò soorò Mo bèèrè, mo bèèrè lówóo láyèwú n jósí òòò Ólólúefón leni tó kókó joba lójèé O lólú eyìn ló tèle Mo níró loo pa Mo ní àwon lomo Oba mínrin, Àwon lomo Oba mìnrin Omo Oba òmìnrìn mínrín tolú òmínrín tó kókó tile-ifè wá jònpetu, Eléyun nì baba tó bi Obandí, Obándé un ló bí ògánndolè Ògándolè un lóbí Ona dede Obadede un lóbí ifátólú Ifátólú un baba Àsàmú Atóèbí eni tó kókó degbó òòjé tó ò parun Àsàmú òhún un ló sore onílè À sore onílé Un ló sore Olóólà Un ló dìyekan won

3 Tí an bá pónko olóólà òhún tí jé Olóólà ohun nííjé abú-bí ekùn-mo-pani-je Aké kaaka kí olórò ó gbo baba òtún àgòrò Òtún àgòrò, kó tó kolúdé, òkìkí amúlè bí ìbon Òkè léyìn pòrò Akìí kamo fónbí, un ó bi t`mi pòpò Oba mèdì òjé maa dígò sorò Lókùú Olójà lodòjé ilé Omo afínjú eye tí í mumi lágbada Témi bá n lo sónà bè mo mo on lée waaa Ojó ò tójó Ojo òò tojò Ìyàwó Olúòjé ó lo sí àwon ona èyìnkùlé Ó lo rèé sègbònsè O rógun lókèè odò loogun bá sú dededee Un ló bá sáré wolé Ó ni baálé wa, òlóòdè e wa Ó ni wá wogun lókè odò, ogun sú dededee N baálé re bá kápó, ó kórun Olúòjé ó kófà N ló bá sòló Ó wàgbo sòló N ló bá lógun lo

4 Ìgbà tó di ni sègbè eléèkejì yi èwèwè wè, Ìyàwó lo sí ònà àwon èyìnkùlé n N ló bá rógun lókè odò n logun bá su de de de, Ó ní baálé wa, olóòdè wa O ní wá wogun lókè odò ogun sú de dè dee, N ní baálé re, n lo ba kápó, N ló bá kórun Olúòjé ba wàgbo sàlàà, n lo ba wàgbo sòló, n lóbá lógun lo Lóòtó ní, béè ni, òdodo ni Ìgbà tó di ní sègbè eléèketa yí èwè wèwè Lóòtó ni béèni òdodo ni Baálè, ìyàwó bá lo sónà oja N ló bá rógun lókè odò, N logun bá sú de de de N ló bá sáré wolé wá Ó ni baálé won, òlóòdè wa O ní wáá wogun lékùlé re ogun dé dan dan dan an

5 N ló bá w’`agbo sàlà, o wàgbo sòló N ló bá kápó N ló bá kórun N ni ún bá n lógun ún lo Ó lógun ti ti ti Owó re ò bógun O lógun tí tí tí, lówó re ò bógun Ìgbà tó lógun tí tí tí ogun jìnnà N logun bá polúòjé ò ò ò Ó polúòjé so sáàrin ììgbé òo Won retí Olúòjé tí tí tí, won ò ri Ìgbà tó dojó èkejì Ni wón bá fín wá Obi á kiri Igbà ti an waja Obi ti an fi woba kiri títí Wón bá koba láàrin ìgbé òo Níbi tógún paá si ò ò ò ò, In wón bá kàn-án níhòhò Kò sáso kankan lára re Wón léèse, Èétirí enìkan kìíri, enìkan kìí rùkú oolójà nihòhò, N wón bá mája Oba

6 N wón bá pa á Ni wón bá bó awo re Ni wón bá fi bo Oba Ni wón bá n pé àbáà dáso epínrín lé epínrín, Kòtíì táso òjé mu ròrun aso aláso ni, Èbáà dáso kókò lagbàlá alé Kòtíì táso táwon òjé mú ròrun aso alaso ni, Kée dáso kókò láàrán Kèè táso tólúòjé múròrun aso aláso ni Awo ajá pélénjá pèlènjà pélénjá N laso òjé é mú pèkun Moparun yékété etí I yemetu Ìrà mokò un o sòkùn fún won lónà tèbì Omo gbálújobi,

7 Mo sùsú lódò kan oso ti í je weru Sùsú lelénmò bínú, eléruku jámò Akìí bèèrè àgbà nílé Olúòjé mo olórí adé ò ò ò N jé nú lé lóhùn-ún san àbi ò san Bí ò bá san mó, baba anìnùn ló dà hun un Témi bá n lo sónà an bè è, mo mo on le e wa aa Àlàfià ke wàà bí o ? Àjàmú ní n be lólúòjé níhà hin ò, Àjàmú ní n be lólúòjé mó on gbórò enu mi Tí ùn n bá n lo sónà be mo monlée wa Bóri gbeni gbeni bá gbeni, Àtàrí gbènyàn gbènyàn tí an ba n gbàwon ènìyàn Oò póríi taa ní ó mo gbè è o o o ? Lóòtó ni béè ni òdodo ni, Òri sàlàkó, oníìlí ò fé ó tú Agbara-bi-awú abáni gbélé ní se bée Òjúòjú elérù gbérù Ó tì lójú elégàn mo rèé tamó baárú Sàlàkó, ni kúrú níhìn-ín, lóhùn-ún

8 Lèkùn òjòwú, wón tìgbásè gbó tútú Aso pami un kú in ní lu kára bí ajere O láì wíni loran kó sìì di teni Oníkálùkù kó yáa senu ti è láàbò Bóri gbeni gbeni báa’gbeni, Atari gbènyàn, bí won bá gbawon ènìyàn, Oò póríi taa ni ó mo on gbèè ó o ? Àjàmú mó on gbórò enu mi Abídoyè Àjàmú tí n be lólúòjé lòò ni o, Òò pórí taa ní ó mo gbèè o o ? Lóòtó ni, béè ni òdodo ni, Oríi Bóládé, bí ó ti mo on gbè ó tòó pin ni Àwon omo Atóbatélè kó tó wáá joba Bémi bá n lo sónà bè mo molé wa aa Àjàa`mú àró afúgò sorò Àjàmú àró okúmorò lónpetu mo aparun jékété etíi yemetu ìlá mokò un ò sokùn tún won lónà an tèbì Témi bá n lo sónà be, mo monú ilé waa

9 Oò pori ta ní ó mo gbe ó ò ò ò ò ? Orí Adéolé bí ó ti mó on gbèè ó ótóópin in in Ò póri ta ni ó mo gbèè ó o ? Orí òsékùnmólá, bí ó ti mó on gbè e o tóò pin ni, Ò pórí ta ni ó mo gbèè ó o ? Orí Atóyèbí bí ó ti mó on gbè è o tóò pin ni in Ó póri ta ni ó mo gbèè ó o ? Orí Atóyèbí atówúrà sabàjà Atóyèbí Alárìnje è baaka, abi kété kété babaáje ní tako tabo Ìbaaka bàbà sojú òtún ní kànnà kànna kànna O ní, kì í se pésin baba enìkan màrà Kìí jé pésin baba enìkan mo òn jó Sùgbón esin Atóyèbí N lo mò ón jó ju taráyòókù lo Abi kété kété baba á jó wariwo ojú ogun Àbénté ta, n lorúko tó bí baba Oba lómo Àbèntè ta, n lorúko tó bí baba Oba lómo káloolé lónìí mo jákàn mo on jììgan bìbaaka bàbá soojú òtún kànnà O pori ta ní ó mo gbè ó ò ò ò ò ?

10 Orí Àmódù, bí ó ti mo on gbè ó tó ò pin ni, Eja ló nibú, bí ó ti mó on gbè ó tó ò pin ni O pórí ta ní ó mo gbè o ? Adédoyin, Àgbàkiri Òsùn sí, N wón n yoko Efúndélé lénu O fárí kondoro o fiyawo kan, babaa lúfóyè Bóri won bí ó ti mó on gbèè ó tóòpin ni in Témi bá n lo sónà bè mo mo on le e waa Ò póríi ta ni ó mo gbèè ó o Témi gbogbo Oba sónà bè mo mo on le wa Bórí gbogbo Oba wònwònyi dááko bórí won ó ti mó on gbèè o tóò pin ni Témi bá n lo sónà bè mo mo on le wa aa Àlà e wà bi ilé gbogbo kàà sí nkan kan an ní tiwaaa?

11 Tí ùn n bá n lo sónà tòòkun, nkun lolórí omi Ojàre òsà làbábi níyìn yò Àjeku, a jèkàà làbá lókèrè Èmi náà làbá bi lókì orin mi Orin láwèéréke, orin àwérèke Orin asínsínndada, asìnsínndada Bàtá ògèdè Saworo Òkótó Atiro ò yàrìnjó Àrìnjó ò yeni ti n tiro E kilo fún mo lárìnjó

          Ki molárìnjó mó on mésè rè le le le 
          Témi bá n lo sónà be mo mo on lé e e wa a a 
          Omo Oba n mínni 

Omo Oba minni Omo Oba òmìnnì mínní tolú òmínní to kókó tile-Ifè wa jònpetuu Témi bá n lo sónà an bè mo mo on lé e wa aa Bóri won bí ó ti mó on gbèè ó tóò pin ni in Tí un bá n lo sónà bè mo mo on lé e wa aa 12 Àlà e wà bí òòò? Inú ilé gbogbo kàà sí nkan kan an ni tiwaa, Èbì òjèé a bidò sorò Lótùnún Olójà lodoje ilé, Omo afinjú eye tíí muni inú agbada Orin: Àlùfáà ni ò ya ní wá Ègbè: Bódún dé aá fòkó sebo Lílé: Àlùfáà ni ò yà ní wa Ègbè: Bódún dé aá fòkó sebo Lílé: Àlùfáà ni ò yà níí wa Ègbè: Bódún dé áá fòkó sebo Lilé: Àlùùfáà ni ò yà nííu wa Ègbè: Bódún dé aá fòkó sebo o o o .

ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA KOKO NÍUN ORÍKÌ OBA ÒNPETU

1 Omo Odùduwà ni ònpetu kí ó tó wá je Oba ni Òjé Ilé. 2 Oríkì Òrànányàn Òrànmíyàn Akòtún Akin nílé Akin lógun Òràn ni mo yàn, un ò yankú Òràn mo yan, un ò yàrùn Baba ni á yènà àyèbá Ó ní a yenú òwú, a rook abé re.

[edit] OLUKOYI OBA BAMITALE OTUNLA

Ó dáa béè ó dùn mo mi

Móo gbó bi mo se n wí omo Arógundádé

Olánínlólú Àjàdi móo gbálàyémi

Yísá Bámitálé, Olúkòyí mó o gbó omo sànsí òtunla

Rógundádé omo olórí ogun jèníàgbè omo akúdá gbèdu àkàlà

Ogún ká n mógbó mo darágbó

Olúkòyí ogún ká n módàn mo dèrò òdàn

Ogún ká n mo Mòkitì mogiroro

Igioro ní hulé esun, èsó ò délé pé

Lábíntán omo gbéjù gbeègi

Gbebàdàn gbétakínnòórìn gbóko gbááwé

Òtòtóbìkan àágbé sóngbé ilé ibi à n gbé ní selé eni

Mògbó tikán gbólógun lójú ara ò jé á mònà òtè

Omo òbe yína, omo òbe yìna

Omo òbe lààlàgbàjá, baba mi á pa sísè á pàisè

Olúkòyí ló bùrìnbùrìn tó soníbàtá èkannabuse


Omo kólúèdé omo abólórun sèléri ikú

Yánbínlólú lomo akúróun dogun

Elégbà omo a sùn roundogun. Èsó nù láàlà

Yánbínlólú lebá puró tan gúnnugún je

Igún lóun ó balè lóun ó jojú o

Àkàlà ní tóun bá balè lóun ó jèdò

Àwon tetèré ori àgbon yèwú n kó ?

Tí on ba balè won a jèdò akoni ti n solírí ogun

Ìkòyí ogún dùn won a pèje, ìkòyí ogún dun won apèfà

Ogún dùn ogun ò dùn èsó pa méìndínlógún

Omo a bà wón je n lé olúgbón,

Ajagunjagun wón gbé n lápata orun lo

Ajágun ò gbéran mi, èrogun èrolè

Èsà tí n bówólé omo a sale mó sàfóórá

Yánbínlólú ìkóyí móogbálàyé mi

Bíolú mo tantantan ti mo bómi tan

Ìlú mi mò jáa’gún, omo labalábá eti wéruweru

Ogún ká n mógbó mo darágbó o

Ogún sì ká n módàn mo dèrò òdàn

Ogún ká n mó mòkítì mogiroro

Igiroro ní n hulé sun

Èsó ò délé pé, la fi n jé omo gbégbó

Gbéjù gbéègi, gbébàdàn gbéta

Gbákínmòórìn gbóko à á gbé,

Sóngbé ilé a bá n gbé ní selé eni

Mògbó tikán gbólógun lójú ara ò jé á mònà òtè

Yánbínlólú ìkòyí móo gbóhùn enu mí

Jálànígbó omo a kú dágbèdu àkàlà

Yánbínlólú móo gbó bí mo se n wí

Omo àá kú fepo télè kòtò

Rógundádé móo gbórò enu mi

N jé ní mo bóbà mí n lé Olúgbón

Òòjó mo bóbà mí n lé olúgbón ajagunjagun

Wón gbé n lápata orún lo

Ajagun ò gbérànmi, èròogun èròolè

Omo asolè mó sàfóórá

Yánbínlólú móo gbóhùn enu mí

Ó dijó kìn-ín-ní yánbínlólú

Baba wa o dagboòfálè níkòyí ilé yánbínlólú

Apònfunyòyò dagboòfálè, eèni dagboòfálè mó

Omo arógun bérí, mi mó lónpetu le è mo dagboòfálè mo

Òsààsàrà kéni mí mó sìse ò sóró

Eyín kan n ne lénu ejò tó gbédè jeyín eku lo

Mògbó tikán gbólógun lójú ara ò jé a mònà òtè

Yánbínlólú móo gbóhùn enu mi

Ijó tí Olúkòyí, tó dógun lè níkòyí ilé

Ògbó lolúkòyí fà lówó, aso lósán

Apata ní fi n jagun,

Jálànígbón ní n jalè lèyìn won

Jálànígbón omo akúdágbèdu àkàlà

Yánbíngbón móo gbóhùn enu mi

Jènígbè omo olè lósì

Omo arógunmósàá omo arógun dádé

Móo gb óhùn enu mí

Omo jagunjagun lógbénu lápata orún lo

Ajagun ò gbéràn mi, èrogun èrolè

Fàsánsì omo asolè mó sàfórá

Abímo níkòyí ilé, omó n sunkún

Omo ò dábò ekún sun,

Omo n sunkún òun ò bógun, òun ò bógun

Bóò bá bógun edùn ni binlólú

Emilóba bógun èmí lo yánbínlólú ìkòyí o

Olódùmarè kappa ayé le lówó

Ogun ò ríbí iyán o, Olúkòyí ogun ò ríbi èko

Bíolúìkòyí omo akúdágbèdu àkàlà

Yánbínlólú móo gbálàyé è mi

Ìkòyí omo o bà bà won jé nílé olúgbón

Òòjó mopó báà bàmí n lé olúgbón

Jagunjagun wón gbé n lápata orún ùn lo

Jèníàgbé móo olè níkàbì

Rógundádé móo gbó bí mo se n wí

Omo apóyapo omo ofàyofà

Omo orúnyórun, omo èlírígbàjò tó dógun lé níkòyi ilé

Bíolú ìkòyí omo olè ní kàbà òkè

Yánbínlólú ìkòyí baba móo gbóhùn enu mi

Jálànígbón omo a kú bá won dágbèdu àkàlà

Ijóti Olúkòyí, yánbínlólú

Tí n finú gbofà níkòyí ilé yánbínlólú

E pórin kínní yánbínlólú ko lójú ogun?

Tí n se kínríndin-kínrìndin o

Bó mobáyótán a fikùn han baba

Lólúkòyí bá finú gbofà níkòyí ilé

Ijó tí Olúkòyí tí n fèyìn gbofà níkòyí ilé

Yánbínlólú, ó ni èyìn èyìn lèsó fi n rìn

Èyìn èyìn, lolúkòyí bá fèyìn gbofà nikòyí ilé

Rógundádé ìkòyí lolódùmarè kápá aye lé lówó

Níjó ti Olúkòyí, ti n fèyìn gbofà níkòyí ilé

Yánbínlólú ni n pójú ògbó laj, èyìn ògbó lajà

Ojú ògbó yèréyèré, èyin ògbó yèréyèré

Lolúkòyí bá omo Oba, Jèníàgbé omo dè níkàbà òkè

Yánbínlólú lomo ojú oró o

E è jé sèye kótóbi lómi, òsíbàtà ò jómi Obà ó tòrò

Bí ò si kònkò, bí ò sí ànkèré

Emi lèbá ró n múbò, bá á tó òsun

A tó bajagun tééré atí opa

Á tóbòsà kan òsà kan, tí n be nípèkun sèkere

Won ì í jíyán, won ì í jèko

Tí ojúmó bátimó, ogun baba wa á tolóoba

Obá kò won ò sígun, òtòsì won ò sesèdà

Obá ní a fodún ni kàgbo ofe, èmi soògùn ìlàyà

Tóbádòní, odún méta òni n ko

Ogún n be n le, ogún n be lóoba

Béèni òbebe, bí ení ti n busú je

Jálànígbón omo akú dágbèdu àkàlà

Rógundádé, Rógunmótìdí omo olófà asòlèlè

Yánbínlólú móo gbálàyé mi

Ìkòyí omo bà óbàwón jé nílé Olúgbón

Òòjó mogbó mobà ó bà mi n lé olúgbón

Ajagunjagun wón gbé n lápata orún lo

Ajagun ò gbéràn mi, èrogun èrolè

Yánbínlólú ìkòtí o, Olódùmarè kápá ayé lé lówó

Yánbínlólú móo gbóhún enu mí, òdanle yánbínlólú


E mó sèdí n dan móo bógun lo

Àpèrè mí, e sèdi pìrùn kale lojà

Làpálàpá ìkòyí ló fara kégùn-ún èsó ìlú n lá

E é pàá, e é mu té è bá rogun

Èyin le mò béè le è pá , èyin le mò béè le è mu

Èyin ò rù nnkan dùgbèdùgbè mó o já mò olòtè

Yánbínlólú ìkòyí móo gbóhun enú mi


Omo arápata tikú n kóògùn si, wón peléwà ni

Yení Olúsádé omo àgbàrá bojú ònà jé

Yánbínlólú o yá a wá, e wá à tónà baba yín se

Omo a lérikan fota Oba, òrugùdùgbè tomi bò lósì

Òsàsàrà kéni mí mó ì se òsósóró mó

Eyín kan n be lénú ejò, tógbédè jeyín eku lo

Mògbótikán gbólógun lójú ara ò jé à mònà òtè

Bíolú moó bàwón jé n lé olúgbón

E gbóhùn enu mí

Bámitálé omo sànsí Òòtunla

E mó o gbó babá je kódàólú omo è sì joba

Yánbínlólú omo Olúkòyí

Omo o bà ó bà wón jé nílé Olúgbón

Òòjó mo bá bábá mí n lé Olúgbón

Ajagunjagun wón gbé n lápata orún lo

Jèní n gbó mògbó omo olójà oko ò kùtà

Bínlólú móo gbó bi mo se n wi

Omo a kú rónudoogun, eléwà asùnroundoogun

Èsó nù láàlà yánbínlólú

Le bá puró tan gúngbún-ùn je

Igúnnugún ní tóun bá balè, oún ó joyú

Àkàlàmàgbò ní tóun bá balè, a sì mó jèdò

Àwon tètèré orí òpéyèkú n kó?

Ti òn bá balè, won á pakoni ti n solórí ogun

Ìkòyí ogún dùn won a pèje

Baàmi ìkòyí o, ogún dùn won a pèfà

Ogún dùn ogun ò dùn, èsó pa méìndínlógún

Omo o bà ó bà wón jé n lé Olúgbón

Ajagunjagun wón gbé n lápata orún lo

Yèni à gbé omo olè ni kàbà òkè

Yánbínlólú, yàwó Olúkòyí won ò jé pagbòn níkòyí ilé

Níjó on bá pagbòn nìkòyí ilé

Ojú ogun ni baba wa móo n rè

Yèníàgbé omo akú dágbèdu àkàlà

Rógundádé e móo gbo

Olúkòyí òsun lolúrí Olúkòyí, òsun odún lóhùn-ún

Òsun odún dágbèdu omo àkàlà

Òsun ni odún baba, baba tó bí a lóòòmó

Olúkòyí omo Obà ón bà ón jé nílé Olúgbón

Yánbínlólú je, ìkòyí móo enu tèèemi

Mójànkoko bí lànkáti o, Olódùmarè kápá ayé lé lówó

Bínlólú móo gbó bi mo se n wí

Yánbínlólú ìkòyì móo gbógùn enu mi

Èmi ò mò pólè n jolè n lé yánbínlólú

Olúkòyí ròde rè kólé, kótódé lolè lé kó lé è lo

Pèkínrèkí, wón pàdé Olúkòyí lónà

Olè bé Olùkòyí lórí, omo òkégé

Orí wón yí lo bí lénílé, orí yánbínlólá

Gbà tó dijó kokàndinlógún, orí yánbínlólá

Wón bóri Olúkòyí, móo bi mo ti n wí

Wón bé Olúkòyí lóri, omo òkàkà

Ori n yí lo bíbàdàn, bí Ògbómòsó bí áwé

Yánbínlólú gbà tó dijó kokàndínlógún

Ori baba wá yídé kórì Olúkòyí ó tó dé Esin n gbamú Olúkòyí kóólé

Ó n gbàpàkó Olúkòyí góòde, ó ní sànpònná

Sàngó, Oya náà ní ò pàde

Tóbéri n lo àròní omo arógunbérí

Rógunmótìdí akúdágbèdu àkàlà

Rógundádé móo gbó, bínlólú koyí móo gbóhùn enu mi

Aràpàtà rikú kógùn sí ní n peléwà ni

Jèní-Olúsádé, bínlólú ìkòyí móo gbóhùn enu tèmi


Jèníàgbé omo akú bólóun sèlérí ikú

Yánbínlólú móo gbóhùn enu mí ìkòti o

Olódùmarè kápá ayé lé lówó

Yánbínlólú mo kí baà mi ìkòtí o

Olódùmo-morè kápá ayé lé lówò

Rógundádé, ò bá móo gbóhùn enu tèmi

Jèníàgbé omo akú bá n dágbèdu àkàlà

Móo gbó bí mo se n wí, ò bá móo gbó i

Omo èlérí ìgbàjò, n náà ló dógun-ún lè rí kòyí lé

Yánbínlólú

Ká tó gba bàbà wa ní owó eranko weere

Kólúèdé omo o bà bá wòn jé n lé Olúgbón

Rógundádé, Rógunbérí

Jèníàgbé omo a kú bólórun sèlerí ikú

Yánbíàgbé móo gbóhùn enu tèmi ìkòtí o

Olódùmarè kápá ayé lé lówó

Omo akúróhun doogun, omo eléwà a sùn roundoogun

Yánbínlólú omo a béebógun lo

Òsà ti n bówó jé omo asolè mó sàfoórá

Yánbínlólú omo rúebó bógun lo

Jèní n gbónmòkú omo olójà oko ò kùtà

Bínlólú móo gbó

Ìkòyí dorí àwon baba wa ni

Yánbínlólú ìkòtí o Olódùmarè kápá ayé lé lówó

Èmi ò mò pé ìran kòyí o won ì í jókété

Yánbínlólú lóròde rè é kólé

Yánbínlólú omo yánbínlólú ìkòyí

Omo akúbóndá gbèdu àkàlà

Omo labalábá eti weruweru

Ogún ká n mógbó mo darágbó Ogún ká n módàn mo dèrò òdàn

Ogún ká n mó mìkítì mogiroro

Igiroro níhulé esun, èsó ò délé pé

La fi n jómo gbégbó gbééjù gbeègi

Gbebàdàn gbéta, gbákínmòórìn gbóko gbáawé

Òtòòtánbìkan à á gbé, sóngbé ilé ibi a bá n gbé

Ní selé eni, mògbórì kán gbólógun lójù

Ara ò ké á mònà òtè

Ilé Olúkòyí tómi pè níjó méèje, yánbínlólú ìkòtí o

Olódùmarè kápá ayé lé lówó

Òòrè ni ò réni fìpééta ní fi n pé n ba tagi oko

Òòrè ni ò réni fìpée’ta ní fi n pé n bá tagi okó kiri

Omo kólúèdé, omo akú modágbèdu àkàlà

Rógundádé, Rógunbérí moo gbóhùn enu tèmi

Yánbínlólú omo asápópó bónú apata

Òpòlopò fà balè sogun làìlàì

Bí ò sí kònkò, bí ò sí àkèré

Emi lè bá róhun múbò? Bá tó bòsun

Atóbajagun tééré, etíopa

Àtobòòsàkan òòsà kan, tí n be nípèkun sèkere

Won ì í jiyán, won ì í jeko

Tí ojúmó bá ti mo, ogun n baba wa

N bá tolóun oba, obá rò mo

Won ò sígun, Ìkòyí ogún dùn ogun a pèfà

Ogún dùn ogun ò dùn, baàmi Ìkòyí

Yóó pa méìdínlógún, omo bà wón jé nílé Olúgbón

Òòjó ti mo bà bàmí nílé Olúgbón

Ajagunjagun, wón gbé n lápata orún lo

Yánbínlólú ìkòtí o, Olódùmarè ká kápá ayé lé lówó

Rógundádé, Rógunbérí ìkòtí o

Olódùmarè kápá ayé lé lówó

Rógunbérí móo gbálà là yé è è è mi


Olúkòyi omo a kú wáà gbà wà

Yánbínlólú omo tantan ti mo bómi tan

Ìlú mi mòjáágún, omo labalaba eti weruweru

Jènìágbé omo olè losì, e móo gbó Rógundádé

Ìkòyí tó mi pè níjó méta, jálàní gbó omo olè losì

Omo akúróhundoogun, móo gb óhùn enù mí Àdìsá o

Bí mo se n so lé è e e enu mí Àdìsá o

Olójè oko Mùíná ní n wí

Kóni bí a ti n náwó baba Sínmíá

Dìsá mo ri nnkan osù mí, kólóun ó jé ó domo

Mo rógun mó sàá

Bínlólú kòyí móo gbóhùn enu tèmi

Jènìàgbé omo olè ní kàbà òkè

Rógundádá kòyí ní á pa sísè kápàìsè

Olúkòyí ló bùrìnbùrìn tó soníbàtá èèkanna

Kànnàbùsè omo kannakánná eti omo

Yánbínlólú, ó di léèkin-ín-ní

Wón ni á gbéle kan kótó ikòtò

Wón ní á gbélè kan ikòtò ikòtò

Wón ní a gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A gbélè kan kótó, a gbélè kan kótó kótó

A gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

Mololá Olúkòyí, o láàtí dójú oróórì baba òun

Wón ní ká lo sáàrin ìta gbùngbùn

Ká sin Mololá Olúkòyí si, omo yánbínlólú

Wón ní á gbélè kan I kótó

Wón ní a gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A gbélè kan i kótó a gbélè kan i kòtòkòtò

A gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

Wón ní Moloá Olúkòyí

Ó láà ti dojú orórì baba òun

Wón nógbo la á tòó dójú orórì baba re

Wón ni é bó àa`rin yàrá, ká soélè kan kótó

Ká gbélè kan i kòtòkòtò,

Ká gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A bó sáàrin yàrá, a gbélè kan kótó

A gbélè kan i kòtòkòtò,

A gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

Molalá Olúkòyí, ó láà tí dójú orórì baba òun

Wón nígbó la á tò ó dójú orórì baba re

Wón ní á bó ààrin pálò, ká gbélè kan kótó

Ká gbélè kan kòtòkòtò ,

Ká gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A bó àa`rin pálò, a gbélè kan kótókótó

A gbélè kan kòtòkòtò

A gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A gbé Mololá Olúkòyí débè, Mololá Olúkòyí

Ó láà tí dójú orórì baba òun ìkòtí o

Olódùmarè kápá orórì baba òun Ìkòtí o

Olódùmarè kápá ayé lé lówó

Yánbínlólú n bo la á tò ó dójú oróórì baba re

Wón ní á bó ààrin òdè gbùngbùn

Ká gbélè kan kótó, ká gbélè kan kòtòkòtò

Ká gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A bó ààrin òdè gbùngbùn, a gbélè kan kótó

A gbélè kan kòtòkòtò

A gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A gbé Mololá Olúkòyí débè

Mololá Olúkòyí ó láàtí dójú orórì òun

Wón nígbó laá tòó dójú oróòrì baba re

Wón ní á bó ààrin òdàn, ká gbélè kan kótó

Ká gbélè kan kòtòkòtò

Ká gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A bó ààrin òdàn, a gbélè kan kótó

A gbélè kan kòtòkòtò

A gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A gbé Mololá Olúkòyí débè

Mololá Olúkòyí ó láà ti dójú orórì baba òun

Wón nígbó la á tò ó dójú oròórì baba re

Wón ní á bó ààrin ààtàn, ká gbélè kab kótó

Ká gbélè kan kòtòkòtò

Ká gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A bó ààrin ààtàn, a gbélè kan kótó A gbélè kan kòtòkòtò

A gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A gbé Mololá Olúkòyí débè,

Mololá Olúkòyí o láà tí dójú orórì baba òun

Wón nígbó laá tò ó dójú orórì baba re

Wón ní ká bó ààrin àpata, ká gbélè kan kótó

Ká gbélè kan kòtòkòtò 

Ká gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

A bó ààrin àpata, a gbélè kan kótó

A gbélè kan kòtòkòtò

A gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

Mololá Olúkòyí o láà tí dójú orórì baba òun

Ó nígbó la á tò ó dójú orórì baba òun

Wón ní ká lo sáàrin ìgbé jùngbùnrùn

Wón ní á lo sáàrin ìgbé jìnàjìnà

Ká sin Mololá Olúkòyí sí

A bó ààrin ìgbé jìnàjìnà, wón ní á gbélè kan kótó

Wón ní á gbélè kan kòtòkòtò

Won ní a gbélè kan òjingbur-jingbùn jingbunkúnrin

Mololá Olókòyí

Ó nígbà yìí la tó dójú orórì baba òun

Bè lá gbè é, ìgbé laá ti là wánu lé


Yánbínlólú omo a kú fepo télè kòtò

Yánbínlólú abádan méje egbèje, abádan méfà egbèfà

Abógodè gbóngbó omo eléégún

Wón ti n jawo èyíde méje egbèje

Le fi n jómo olórun à á mú rebi

Ibààbà mefà egbèfà

Le fi n jé molúwadè òròmò dè díàgbá nílé Olúfón

Èyí òkotè gbóngbó, tómo eléégún fi n sawo

Le fi n jé òjògbìn ará ògbojò ògbólúké

Ológbojò báwíde omo abìroko,

Mógáinmógáin alalópo lógbín dùn momomo

Èyí eyelé funfun, le fi n jé òsèsè ìkòhyí

Tí mo rérìn ín rè kokú lójú

Rógundádé omo olóri ogun

Yèníàgbé omo akú mónà iyì

Yànbínlólú ìkòyí tó mi pè níjó méta

Yánbínlolú ìkòtí o Olódùmarè kápá ayé lé ló

Jèní n gbó mòkú omo olójà oko ò kùtà

Rógundádé Rógunbérí omo olórí ogun ìkòtí o

Olódùmo more ká kápá ayé lé lówó

Òòrè níjé ajítafà n gbònnà

Ogun ló kó on kà á dóje

Elérí ò bo bàtà ló dógun lè n kòyí ilé

Yánbínlólú kénlé omo, kúnlá orí n dogun

Yèníàgbé omo olè níkàbà òkè

Yánbínlólú òòrè ni ò réni fì pééta

Níbá fi n tagi okó kiri

Yèníngbónmòkú omo akú dágbèu akàlà

Rógundáde omo elégìíìrì

Won ò jówu Obà ó tòrò, omi Obà bá tòrò

Eyè kí lè bá róun mú b obà? Ká tó bòsun

Ká tó bajagun tééré eti opa, átóbòsà kan òsà kàn

Tí n be nípèkun sèkèrè ilé,

Won ò ní fiyán èni yèko, tójúmó bá ti mó

Ogun baba wa a móó tolóba

Obá kò oba ò sìgun, òtòsì won ò pèsè dà

Baba ni á fofún nì í kàgbo ofe

Èmí so ògùn ìlayà, tó bá dèní

Odú méta oní, ogún n be nílé ogún n be lóoba

Jèními òbebe bí eni n besú je

Jèníàgbé omo akúdá gbèdu àkàla

Yánbínlólú ìkòyí móo gbóhùn enu mi

Yánbínlólú ìkòòtí o, Olódùmarè káp ayé lé lówó

Yánbínlólú móo gbó bí mo se n wí o ìkòtí

Olódùmarè kápá ayé lé ló

Rógundádé omo o bà bà wón jé nílé Olúgbón

Òjó mo gbóbà bà wón jé nílé Olúgbón

Rógunmótìdí omo olójà oko ò kùtà

Ogun ò ríbí iyán o ìkòyí ogun ò ríbí èko


Sapólosoo omo agbòn tí n yáà rùn òtè

Bínlólú ìkòyí e e jagun à béè jagun?

Yáníàgbé ogun oba wón tit ó lo

Yèníàgbé omo olè níkàbà òkè

Rógundádé ìkòyí móo gbóhùn enu tèmi ìkòti o

Olódùmo morè ká kápá ayé lé lówó

Yànbínlólú ìkòyí móo gbóhùn enu mí

Yànbínlólú ìkòyí omo akúmónà niyì

Omo a kú yanyan bòtè lerù

Yànbínlólú ìkòyí móo gbóhùn enu tèmi

Ìgbé la á ti là wánulé

Rógundádé Rógunberí omo olóríogun

Yèníàgbé omo olè losì


Ìkòyí ti o ti mo mò pé témi ó ò

Ìkòyí omo arógunmótìdi Rógundádé


Yèníàgbé omo olè losì


Èsèsè ìkòyí móo gbóhgùn enu mí

Jèníngón mòkú omo akú bá won dágbèdu àkàlà

Ogún ká n mógbó Yánbínlólú ni mo darágbó

Ogún sì ká n módàn ni mo dèrò odan

Ogún ká n mó mòkitì mogiroro

Igiroro ní n hulésun, èsó ò délé pé

Lo fi n jómo gbégbó gbééhjùgbèegi

Gbebàdàn gbéta gbákínmòórìn gbóko gbááwé

Òtòtò níbìkan à á gbé

Sóngbé ilé ibi a bá n gbé ni selé eni

Mògbó tikán omo akúdágbèdu àkàlà

Rògundádé ìkòyí é rogun à béè rogun?

Ogun Obá, wón tit ó lo

Jèníàgbé omo akúmónàniyì

Rógundádé ìkòyí torí àwon baba mí ni

Sapó ósòó omo ó bà ó bà ó bà wón jé nílé Olúgbón

Òòjó mopó bo bà mí jé nílé Olúgbón

Ajagun jagun wón gbé n lápata orún lo

Èrogun, èrolè

Sànsí omo asolè mó sàfóófá

Abímo níkòyí ilé, om;ó n sunkún

Omo ò dábò ekún sun, omo n sunkún pónu ò bógun

Òun ò bógun, bó ò bá bógun edùn ni

Yànbínlólú ìkòyí emi lé wa bógun èmí ì lo

Òsàsàrà kéni mi mó ì se òsosoro

Eyín kan n be lénu ejò tó gbédè jeyín eku lo

Mògbó tikán I gbólógun lójú ara ò jé mònà òtè


Rógundádé ìkòyí móo gbóhùn enu tè tèmi

Aríkú mó sàá omo olófà asòlèlè

Yánbínlólú ìkòyí móo gbóhùn enu mi


Omo akúta kó torun

Omo apòfun yoyo dagbofà lè

Eèní dagbogà lè mó Rógundádè

Ikin lè é mo dà sórùnmo

Jèníngbó mòkú omo o bà ó bà wón jé n lé olúgbón

Rógundádé ìkòyí móo gbóhùn enu mí

Jáàlárógúnmó yòmo obà a tèlèwùsì

Rógundádé móo gbó

Òsèsè ìkòyí tí mo mórèrín rèé ko kú lójú

Yánbínlólú móo gbálàyé è mi

Bíolú ìkòtío Elédùmarè kápá ayé lé ló

Rógunbéri ìkòyí móo làbárè enu mí

Bántálé omo sànsí Òtunla

Rógundádé móo gbó bí mo se n wí


Bántálé je, ó joba baba è sì joba

Obá wá di méjì lá à obá di méjì láàrin àwon Oba

Bíolú omo kúnlé orí dogun

Jènìngbómòkú omo abólórun sèlérí ikú

Yánbínlólú ò, mo tan ti mo bó o omi tan

Lúmòjáágún molabalábá etí weruweru

Mo à kú fepo télè koto 

Rógundádè Rógunberí omo Olúkòyí

Móo gbóhùn enu-un-unun tèmi

Jèníngbó mòkú omo a kú dágbèdu àkàlà

Òsèsè ìkòyí omo rérìn-in rèé kokúlójú

Yánínlólú mo rúbóo bógun lo je

Yèníàgbé omo akúólórun sèlérí ikú

E wàgbòn sèsè kée gbámùré kà n lórí

Olója bèbí omo agbónsinsin tìntolóko lénu

Jèníngbónmòkú omo a kú dágbèdu àkàlà


Ìkòyí é rogun à béè rogun?

Ogun Oba wón tit ó lo

Jèníngbónmòkú omo olè ní kàbà òkè

Rógundádé móo gbó bi mo se n wi

Òòrè ní jájítafà n gbònnà

Yánbínlólú òòrè náà ni ò réni fì pééta

Ní bá fi n tagi okó kiri

Omo pérúèdé, omo abólorun sèlérí ikú

Yánbínlólú omo àgbàrá bojú ònà jé

Yánbínlólú omo àgbàrá bojú ònà jé

Omo àgbàrá sojú ònà jé yánbínlólú

Omo àgbàrá sojú ònà kotonporì loaf

Omo àrógun mó sàá Bínlólú ìkòyí

Móo gbóhùn enu tèmi

Jènimósàá mòkú omo o bà wónjé nílé olúgbón

Rógunmósàá móo gbó omo Olúkòyí

Yánbínlólú ò, mo so béè léèkan póbìnrin ìkòyì

Won ò jé pagbòn níkòyí ilé

Jó tí ón bá pagbòn níkòyí ilé

Odi ogun tóri ni wón mó n lo

Yánbínlólú ìkòyí tí Olódùmarè kápá ayé lé lówó

E móo gbó, ìbílè ìkòyí won ì í jòkélé

Yánbínlólú atúgun n baba wa n fapá ewú se

Àsèìnwá àsèìnwá àsèìbò mo rólúkòyí

N bi tí gbè n fitan òkété jèko

Rógundádé, é rogun à béè rogun

Yánbíolú ogun obá ti tóòlo

Arikúmósàá omo olófà a sòlèlè

Omo òbeyína, omo Òbe yàlàgbàjá

Yánbínlólú olé lóòmo fíkanlé, fikan lójú ogun

Yánbíolú ìkòtío Olódùmarè kápá ayé lé lówó

Èmi bánré Àdìsá olójè oko Mùiná

A kóni bá a tí náwó baba sínmíá

Èsó olójè ni tèmi, Àdìsá gbajúmò arèkú eléégún

E móo gbó bí mo se n eí, gbálàyé mi Bínlólú

Èmi omo arógunmósàá Bìolú

Èmi bániré ò dékùn eni, a sèìndeni ò wópò

Sàsà èèyàn ní féni léyìn báà bá sí n lé

Bánré bándélé tajá teran ni feni feni lójú eni

Olúkòyí omo bò bà wón jé nílé Olúgbón

Yánbínlólú omo olúkòyí mi ni

Yánbínlólú omo sápópó bonu apata

Arikú ó sàá omo olófà a sòlelè

Yánbínlólú ìkòyí e é jagun à bé

Yánbínlólú ìkòyí omo a kú bó n dá gbèu àkàlà Molódomlé Yánbínlólú

Rógúndádé e móo sèdi didan móobógun lo

Apèrède e sèdí pìmù kale lojà

Làpálá ìkòyí n ló faara pédun èsó ìlú n lá

A á pà á, a á mu

Là á bá rogun, èyin le mò béè le pà á

Èyin le mò béè le mu

Èyin bò kan dùgbèdùgbè mojágbón olòtè

Ó dìgbà a bá pàrapòtònlò, ká tó gba bábá à wa

Ní owó eranko weere

Omo kólúèdé, omo abólórun sèlérí ikú

                       Yánbínlólú  mo, mo lo tantan tí mo bómi tan 

Ìlú mòjàágún omo labalábá etí weruweru

Omo o bà bà wón jé nílé Olúgbón

Bíolú ìkòtío, Olodumo morè kápá ayé lé lówó

Rógunmósàá omo arógundádé o

Ìkòyí bóogbóhun mí o dìde

Oníkòyí omo o bà bà wón jé nìlé Olúgbón

Rógunmósàá Rógundádé

Móo bò lódòo wa

Ìkòyí omo a bà ó bà wón jé nílé Olúgbón.




Àwon Ìbéèrè àtki ìdáhùn won ní sókí lórì oríkì Oba Olúkòyí


(1) Ogún ka n mó mòkìti mogiroro

Mòkìtì yì í ni olú tí máa n hù ti àwon baba wa fi máa n jeun ní ayé àtijó

(2) lábíntán omo gbéjù gbèègi

gbéjù yìí túmò si gbígbé inú igbó. Gbeègi tímò si gbígbé ààrin ìlú.

(3) Baba mi á pa sísè á pàìsè

Èyí túmò sí pé á pa eni tó sè àti eni tí kò sè lójú ogun.

(4) Olúkòyí ló burin burin tó so níbàtá èkennabuse

Soníbàtá èkennabuse yìí túmò sí pé onílù ó salo lójú ogun tógun bá le tán.

(5) yánbínlólú lomo akúrónu dogun

Elégbà omo a sùn ronudogun Èyí túmò sí pé ó sùn dológun kótó wá dìde láti máa jagun.

(6) Àwon tètèré

Èyí ni àwon eye eye tin-in-tin-in

(7) wón gbé n lápata orún lo

Apata orún ni ohun èlèogun tó dàbí apó ti àwon ológun n kó nnkan ogùn sí.

(8) Ajagun ò gbéràn mi

Pé jagunjagun kò le gbé ìran mi.


(9) Omo a sole mó sàfoórá Pé Olúkòyí kì í kèrù elérù lójú ogun

Sùgbón ó máa n gbé àwon ìyàwó tó bà rewà lójú ogun.

(10) Ogún ká n mó mòkitì mogiroro

Èyí ni igi mòkítì tí wón sá sí nígbà ogun

(11) Èsó ò délé pe

Èyí nip é iye àwon tí wón lo sí ogun Olúkòyi kó ni wón padà wá lé.

(12) Omo òbe lààlàgbàjá

Oríkì ni eléyìí


(13) Omo à á kú fopo télè kòtò

Èyí ni ètùtù tí won máa n se kí wón tó sin àwon akíkanjú


(14) Apòfunyòyò dagbofàlè

Èyí ni pé p máa n po ofá òògùn lè.

(15) omo apóyapo

Túmò sí ohun èlò ogun bí apó àti ofà

(16) jálànígbón omo akú bá won dágbèdu àkàla

Èyí niu gbèdu tí won máa n dá tí wón bá joba tán láàfin.

(17) Yánbínlólú ní n pójú ògbó lajà

èyòn ògbó lajà

Ògbó yì í náà jé ohun èlò ti wón fi n jagun

(18) Obà kò won ò sígun

Èyí ni náà kò jagun.

(19) Yánbínlólú ìkòyí o, Olódùmarè kápá ayé lé lówó

Èyí túmò si jagunjagun tí won kó apata tàbí ohun èlò ogun lé lówó.

(20) jèníàgbé omo a kú lólóun sèléri ikú

Èyí nip é ó ti múra ikú lo sí ojú ogun pé ti ikú bá yá ó ti yá náà ní.

(21) Ò ru gùdìgbè tomi bò losì

Gùdùgbè yìí ni ohun èlò omi.

(22) Sànsí, Òtúnla, kódàólú

Gbogbo wón jé orúko oba olúkòyí.

(23) Àwon tètèré orí òpéyèkú n kó ?

Èyí ni òpe tí tin-ín-tin-ín-ín bà lé lórí.

(24) Yèníàgbé omo olè ní kàbà òkè

Èyí túmò sí bíbejú wolé ológun

(25) Àwon yàwó Olúkòyí won ò jé pagbòn níkòyí ilé

ìdí èyí ni pé atúgun ni baba won náa n fi agbòn se.

(26) Òsun lolórí Olúkòyí

Èyí nip é òsun ni ìran baba Olúkòyí máa n bo.

(27) Òsun odún dágbèdu omo àkàlà

Gbèdu yìí ni ìlù tí won máa n lù ki wón tó lo sójú ogun.

(28) Aràpàtà ríkú kógùn si ní n peléwà ni

èyí ni pé wón kòógùn sínú apata ogun.

(29) Ò dìgbà tá bá pàra pòtòlò

Àra àti pòtòlò yìí jé orúko àwon irúfé eranko tó lágbára nínú igbó.

(30) Omo a kú róhun dogun, omo eléwà a sùn ronudogun.

Èyí túmò sí pé Olúkòyí máa n díbón lójú ogun bí eni pé ó ti ku.

(31) Òtòòtánbìkan à á gbé

Èyí ni pé ibi gbogbo ni ológun le máa gbé lójú ogun.

(32) Olúkòyí omo a kú wáà gbà wà

Igbá ìwà ni igbá tí jagunjagun gbà nigbà tó bá ségun lójú ogun.

(33) Mololá Olúkòyí

Èyí ni orúko ìyá olúkòyí kan tó ti je oba ri.

(34) A gbélè kan òjingbúnjingbùn jingbunkúnrin

Èyí ni kòtò ti a gbé tó jìn gan-an.

(35) Wón ní ká lo sáàrin ìgbé jìngbùnrùn Èyí túmò sí ààrin igbó tó jìnnà.

(36) A bó ààrin ìgbé jìnàjìnà }

Wón ní á gbélè kan kótó }


Wón ní á gbélè kan kòtòkòtò}


Ìtumò àwon gbólóhùn métèètà yìí ni pé a sin

Mololá Olúkòyí sí ààrin ìgbé jínjin èyí tó túmò sì pé ìgbé la á ti là wá inú ilé.


(37) Mógbáinmógáin

Èyí túmò sí ológbojò tí í se ìran eléégún.

(38) Rógundádé, Rógunbérí

Àwon yìí jé oríkì olúkòyí.

(39) Omo àgbàrá sojú ònà kotònporì lofà

Kotonporì yìí ni pè àwon kòtò ojú ònà Olúkòyí jìn púpò.

(40) Atúgun n baba wá n fapá ewú

Pé òkété jíje jé èèwò fún ìran Olùkòyí torì wón fi máa n se ètùtù nígbà ti wón bá n lo sójú ogun ni.














[edit] AKESÌN ti ÒRA

OBA PROF. OLÓLÁDÉ AFÓLÁYAN LÁTI OWO ASÌMÁWU OGUNKAYODE- IPERIN (ILE OSÓLÒ)

Omo awùlú wará è omo Awóbínpé

Lójèé òkésó, mo kuwo bí eníkurégbe

Mo fi kònkùsò kuwò mi lùlù

Àyè Òjé bí mo gbénà bi è pé

Mo gbégi rékété kóba àyè à pagi dà a dènìyàn

Omo enígbó máyà mayà su

Omo enígbó máyà mayà tò

Omo enígbó máyà mapètú

Omo onígbó kánrin kése

Àjèjì é gbodò wò

Àjòjì é wogbó wean n kó

Àyún la rí a è rábò re

Awo ló pa mú je

Aìráyekù erin nínú igbó

Aànírí t’efòn lánìjù

Kì fòn ó kì kà kí

Arájekù baba nínú ibú

Agbélè kan bí i kòtòngìrì

Adòdòbálè afàgbònwómú

Adòdòbálè afàgbònwó mú

Babá wí n kí o lòjé e lé

Babá wí n kí o kìbáà wálé

Omo ojúrógun ó le mo yàgbàlàgbà oyè leyò

Àkórí mo mú gbòkán sàwídíwídí

Omo Síngínnigín awo

Gbà won bá gbé ayaba ‘lé oni ní tuni lára

Omo àwówò yàrà

Omo akáso wégùn jàgàjígí yaráà ján sò lóló

Omo olókó emery

Ìkà kán kí n kányìn ni pèsán

Péjú ni é sure léran pa

Amònà ìkeyìn nirè

Omo èlùbú èsí bàká je

Ba pée n lé a pée lénu

Abèlùbó tìrì àjà balè nirè

Omo oníkáà oyè omo jáwé lémo lérí

Ki n jáwé lémo lérí mògún ján

Mo já kerú mo já kayaba

Mo já jàjòjì gòdògbò yí n be lódò mèjá

Mo mú yókù mo mú kayaba ki ri n tójú

Omo ní mògún sèje ní mògun sèsán

Omo olókó emery àbòwolè ní tòsà

Omo oníkáà oyè omo Ejíbbojó yará ìlágbède

Mo múrin túnrin ro, òkè àlosò nirè

Aìbínúmo nírè ká pose

Abó owó laá gbé kayaba

Nímògún sèje nímògún sèsán

Omo ajídáre bí omo òkè àlobò nirè

Iyèjan Fákáyòdé mògún ìyèkan aráfúnmi láso

Abòdìdì aso pèlèmò

Omo àkóbó fàrí n be lónà ìrò

Ó yan kúngbonna-kúngbonna

A yan kùngbonna-kùngbonna

Eè kàn mò pókó ni án ro nírè won èé rook

Omo alágbède àtètèkàn yìí jíogúnrennìlékún

L’ójú ení jé bá n gbéwúgege

Ò bá bá n gbéwú àìlágbède omo ojúdúró

Ìbán nirè omo fowórorí

Omo àkóbó kan ònà ìrè

Yòó ti dé bòyí àrémó ri

Bo’bá yan kúngbonna-kúngbonna

Asàì yan kùngbonna-kùngbonna

Eè kàn mò ókó ni ó ran bile won èé rokó

Baba wa ló dáko sínú igbó

Èyí éè jiyàn alákedun

Ó kò kùrò si ì áyà éè jiyàn òjò

Ò dáko si gbèri àwéré

O bomi lé ko ma ki ma kó ma

Bògún sèje omo ajídára bí omo òkè àlobò nirè

Lóyan gìjó omo onuyéké abé ota

Àkòlórò loyàn omo táyàn lékù

Omo Olóri egbé

Òtènté làlá aríkùn táyàn lé

Ilé ìyá à re omo akútorí ègún sònà.

Ire lónìí o orí mi à mà fire

Iré lónìí o orí mi à mà fire

Nítorí tani, nítorí olójèé lù kó só

Lója lù kósó

Mo a kuwo bí ení réte

Ma fi kònkòsò kuwò mi lùwèlùwè

Mo júwe júwe o èléo mo lée wa

Mo sàkàjúwe èléo mònà

E ò mò pópó Adégborò lójà Oba

B’órí mi bá le sé

Bí n bá jolójomò láàrín ilée wa

Dúpé a je balógun

Ma f’Odúnolà ìjomò

Ire ló nìí erí mi à mà fire

Bó wù mí dún bi eégún o

Bó bá wù mí ma fohùn bi ènìyàn

Kè é hun mí kè é hùn’ran mi

Ìyá mi làrè lojè monà mejì

Lóje lù kósó lójowòn nì ya à mi

Omo wùlú wará è omo Awóbínpé o

Omo ògbàìgbé ésàrun ni mò n ké sí

Omo afélélé wogbó awo

N lé omo enígbó máyà mayà su

N lé omo enígbó máyà mayà tò

Omo enígbó máyà mapèdó o

Omo enígbó o kánrin kése

Àjèjì won è gbodò wò

Àjèjì yó sá wogbó be nà n kó o

Àyún la ri a ò rábò re

Omo olójà yée mú gbanó

Igba egúngún ni wón n mú ná be ò Omo àgbákan lè yagédé

Àwàkan lè yàrà

Àwàkan òun àwàkàn kán wa lè orò nílé asánlú

Omo Òdù mefà omo èrèlè

Ètá gbóná èta kò gbóná

Agbada gbóná tinútinú

Wón lu kósó lónìí orí mi kò jo

Wón lu yànda mi è pasè dà

Obìnrin bìrìn ló sowó sóbìrì pèté lorí mi dìde

Orí mi dìde nílé asánlú o

Orí mi dìde nílé asánlú o

Òyó layé wà àtùgbà erò Ológbà awo ògbarìwò




ÌBÉÈRÈ ÌDÁHÙN

1 Onigbanaya mayato, Onigbo maya su

Inú igbo eegbun ti won ti n ségún, baba Akesin ni n ségún. 2 Afélélé wogbó awo

Baba Akesin, aso funfun ni o maa n wo 

nijo ìségún eyi ti yóò máa fé lélé bó bá ti n wogbo lo.

[edit] Mo wá dé bí mi ti dé o

Àbíké èmú omo Òrò nirè Jurín nijó yará ìlágbède Mo kina yaya mórin dùgbè lehìn ewùrì Omo òfowó ìná kù teri bolé aró Mo dé bí mi tí dé o Àbíké èmú omo orò nirè N ó wá lo sílé e bàbá re Alébíosù omo afoláyan ká o Omo òdù nlá ferí làlú Omo eja nlá ferí labú omi omo olójèé òkósó. Mo kuwo bí ení ku réfe Mo ri kònkòsò kuwò mi lùbùlùbù Ègàn è gan gbá mo wí ègàn é gàn àwo Ègàn é gàn kòkò baba ìsasùn Ègan é gàn ó òrín lòó rín Elégàn n gòkun, òkun n tóbi lómi Ègàn n gòsà, n bodò mole Ègàn è gàn ó èrín lòó n rín Omo Afoláyan ká Bá à bá ní puró báà ní sàwàdà Ojú òrun téye fò láì mapá kanra won Bá à ní puró báà ní sàwàdà Olá n be níbì ran babà re Omo Àyánpónlé omo Afoláyanká Olá n be níbì ran babà re fa Ògùnrà lá ni ón rán mi wá won è rán mi ní jó Ògùnrànlá eléjìká òré Pupáyemí eléjìká òré Abìrìn àsà lese mejèèjì Èrò ìkòyí omo agbòn yí è ríkú sá Yánkídolú ò ní mokú lápó Yé lo rèékú lórun Àrònì è gbélè n lé oníkòyí Oníkòyí è simi ogun Àrònì è gbélè oníkòyí è gbélè Eníyàá ìlù dúró má je ‘lù jorin lo O jé n wá k’Olóta yìn ó o Omo Ota gbáná n sérin Èfà won ò gbodò tàkàn Níjó èfà yóo ta méjì niyèrú ilé Erú èfà ye pà ní sun ìwòfà wéfà we pà nísin Omo bíbí ìrè Ìrè ló ti wé pà ye pà kó Lámèká méjì ogbè èyí bawo lójú opón Ésàrun n lóta ògìrì òjè láwaríkò lojè Agungi soro Ìmélé lànlá yará lù yàkóyó Omo nú opa ti n jó réfe lóri awo Òfìfà yé fa kùn awo nàjànnàjàn Omo ésàrun gègègè Omo agbéná wojú eégún o Omo abégúnje má ba lòrun Baba yín ló begun sòrò wúyé wúyé bí Olódùmarè Ìyá bí o ní mèje mèjo bí Olú esunsun Àkànì moye àwon ìràwò Enì yó moyè ìràwò Àyìnlá ni yeé bì án bi o dé Gegege nilé e yín se Ìmògùn yará à yó yò Ejídándólá yará n lágbède Omo awúrin túnrin ro Òpò ewìrì semo fàkáfìkì lónà an ìrè




[edit] ÒRÀNGUN TI ÌLÁ OBA

WILLIAM ADÉTÒNÀ AYENI ARÍEÀJOYÈ 1 LÁTI OWÓ ABIGAEL ADENIYI ILÉ OLÚTOJÓKÙ

HUMAANI ABIKE ILÉ OLÚTOJÓKÙ

Adétònà Àkànbí, Aládé-àásá-sí Abiyamo níjò jà iná gerí lé fejú Baba kíkelomo Kò róun fálejò ó fowólabí toro fálágbe Yánbídolú ará èsó éè délé pé Eni mo lérí ikú dogun Àrònì mo tì fà bèwò àrònì gbélé Oníkòyí ò sinmi ogun Nílé òsèsèkòyí mo rínrin rè bá kú lójú Ení mo sú rondogun mo sùn rondogun Mo tà kaka gbáriwo òrun ròrò Àkànbí ni dúó dè mi Omo ogún apó Àkànbí ni dúó dè mí omo erù ofà Dúó dè mi omo Àádórin èsó Omo olúgbón sáakin Mo jàjà diò tidò leyò Orígun mérin le é sígun nínú léeyu Erèrin ni mo mò bálápó bá síwájú Olófà a tèle enímò a lárin Alápàlànpó n ní somo kehìn ogun nílé òsèsèkòyí mo rínrin rè bákú lójú Ení mo kú rondogun mo sùn rondogun Mo tà kaka gbánwó òrun ròrò Àkànbí ni duó dè mí omo ogún apó o Àkànbí ni dúó dè mi omo erù ofà Àkànbí ni duó dè ni omo Àádórin èsó Omo Olúgbón sáarin mo jàjà mi ò tidò leyò Bàbá Àkànbí lomo Òyìnbó gbága làlú Omo egbínrin baba aso àlàárì baba èwù Ilé òyìnbó n be nísò atèkuru nínu ‘lé baba tó bí mi lómo Ilé òyìnbó n be nísò atàkàrà Ilé òyìnbó n be níso atòwú dúdú Ki an gbé n sowó aró kúsu kóse Erí ti bá gbé ni désò atèkuru Erí kó erí ni Erí tó bá gbé ni désò atàkàrà Erí kó erí ni Erí tó bá gbé ni désò atòwúdúdú Erí kó erí ni Obà mi òkò, obà mi sàlè Olójó òní jé n bímo pò tádìye Nínú lé baba tó bí mi lómo Bádìye bá se kókò lagbàlá Omo ní kó je níbe Omo òyìnbó gbága làlú Omo egbírín baba aso Àlàárì baba èwù èrólà Àkànbí Àjíún là rín rín omo Erínwókùnwoyè gbé Omo erínwó gbanra bí okó tuntun Ò gbó kuku òjò dami agbada lore Òjòse tábn è ti rò mó Ayabá wolé án rò mó Lópèpèkun láwéré olómo ofe Òbàrànkàtà mo boyè mole omo òkè wù Omo ìrókò tééré làkànbí Ìyiún be nípadé Òra Nínú ilé ìyá à re ni Ìyíun jé won ó sè won Òra Ìyí èrú jé won ó sè won òkè wù Ìyí èní jé won ó sè won àté lé odán Omo Àdè tutu làkànbí Mo radio bù éri mo somodé, Mo rékuku mo mú sínú isu Òrìsà jé n bade lade, Jé kí n bode lódé Agó è ni è sé jí nínu ‘lé wa Bó bá dòsán ganrín ganrín Won a mótúrù n sàwon nílé odé Òrìsà òkè òrìsà ìsàlè Olójó òní má je n bá gíè lerù nílé odé Ogómodì mo sinmo gaga relé oko Mo jeer ewà bí ení yòwú là ladì Òsèsèkòyí l’Àkànbí mo rínrin rè bákú yájú Elégbà mo fì gbámú jagun Mo gbòn gìrì joyè olòtè Erígun méje lèésígun nínu ‘lé yin Èjèje nì mò Alápó gba wájú nílé kòyí Olórà a gbàrin aláàrin a gbàbon Alápàtàkó òun ní somo ìkéhìn ogun Òsèsèkòyí mósò lènù mo gbàgbé ‘lé Omo a gbòn yéè ríkú sá Nílé olégbà mo dìgbámú jagun Mo gbòn gìrì joyè olòfè Ègbè: Enì yó wí ìkòyí è nílé ogun agbòn Èrùwà nílé ogun Omo akú má jègbin òjó ogun agbòn Èrùwà nílé ogun Omo àsádi eni kòyí ogun agbòn Èrùwà nié ogun agbòn o Èrùwà ní selé kòyí omo agbòn yéè ríkú sá

Omo olósàá èji Eni mo lérí ikú dogun Mo gbon gìrì joyè olòtè Àkànbí loníyàá òkánkán Omo Ajìdágbèdu àkàlà Àkànbí lomo oníyàá òkánkán Omo Asélémuré arógangan Àkànbí lomo oníyàá òkánkán Om òfèlè bókùnrin jà Àkànyé lomo oníyàá òkánkán Omo iso àkàlà yí n je ní mògún òde Afínjú eye ni n je ní gbangba oko Omo ekùn omo ebóse Ìjèsà òsèré lákànbí Mo ká tín ìn léní omo eléní eléwele Jèsà lodú mo pànà dà Ìjèsà ò rídi ìsáná Ilé leru Owá ti n muná rook Omo olóbì kan owówóntiriwó Omo olóbì kan òwòwòntìriwò Ìyó bá wò níjù Omo eranko a mú je Omo ènìyàn ní hè yún un a yáa mú je E jé ká ragun Yánsidolu E dìde e jé ká rogun E kápó lápó Ìkòyí é kofà loaf E dìde e jé ká rogun Ìkòyí o E dìde e jé ká rogun Yánbídolú E dìde e jé ká rogun E kápá lápó Ìkòyí é kofà lofà E dìde e jé ká rogun Bàbá rere Ee o Owá ò Ì-ín la wà Àkànbí lèrò ará dúó dè nisàn Ládéjobí àrán ò félélé Omo mo félélé wogbó awo Àjòjì lè pokùn nisàn Àtòrì wówòwó yó pekùn ni sàn n kó nílée ládéjobí Nílé Àkànbí èsó ò délé pé Elégbà mo sùnde níjó ogún le Àrònì mo tìe lèyò Àrònì è gbélé oníkòyí è sinmi ogun Yàwó eníkòyí èé sèyàn yàwó eníkòyí lòjóró

Òun ló sekú pà báà mi 

Ìkòyí ikú dá gbèdu àkàlà Sìgìdì yéè jepo Wón ti mépo si lénu Sìgìdì yéè jàdí án ti mádìí si lénu Sìgìdì yéè jòrí án ti mórìí si lénu Eníkòyí dìde ogún tó lo ò Eníkòyí bá dapá dasè ‘le níkòyíi lé o Òyí dapá dàsè le níkòyíi lé Ibè logún ti mú bàbá mi Ìkòyí ikú dá gbèdu àkàlà Yàwó Eníkòyí è sé finú hàn Yàwó Eníkòyí è jé gbénú’lé Ikú ti pa bàbá mi Ìkòyí ikú dá gbèdu àkàlà wón se ni Tá ló ni kòyí ò nílé Ogun agbòn o Èrùwà nilé ogun agbòn Ta ló ní kòyí ò nílé Ogun agbòn o Èrùwà nilé ogun agbòn.


Kúléhìn lanà mi Ayeni n be nílè ‘bìkan Okò mi n be nílè ‘bìkan Baba Adétólá e kú ìnáwó, e kú náwó E mà kú àseye Oníkòyi e bá mi kì ká lè lo Òsèsènílékòyí omo agbòn yéè ní bákú yájú


ÌBÉÈRÈ ÌDÁHÙN

(1) Kò róhun fálejò ó Léhin ogun ni àwon alágbe n ki fowólabi toro fálágbe Oba báyìí.

(2) Kíló dé tí e ki Kábíyèsí Òra ni ilé ìy lo sí Òra òra ni

(3) jíló dé tí e tún ki Gbogbo Owá ni ó bá ìjès kábíyèsí lo sí Ora

(4) Erímopópó Bí Okó Ilé Ìyá Oba ní Òkè Ìlá ni à n kì tuntun báyìí

(5) kilo dé ti e fi wón wé Okó Omo alágbède ni wón titun






[edit] ASÁÒNI OF ÒRA

OBA SAMUEL AYANTOYE

LÁTI OWÓ MORÁDÉKÉ SÉRÀ ONÍRÁDÉ- ÒKÈ ÀFIN (ILE ASÁÒNI)


Adétáyégún, baba ‘Dékémi Àrèmú èsin omo Òdùduwà Won è bí e níran ìyà Won è bí e níran ìsé Omo lójà lójà omo ládéládé, Omo Asáòni àbàtà Omo Asáòni ògángán Omo Arémóyèédùn Àbú ni ó omo oyè ifè Àbú t’Onífè àbùré eni a bá bó owó re mo èdìdèdè nífè Oòyè Won èé dúró kíni n’ifè Oòni Won èé bèrè kíni n’ifè Oòyè Tègùn tègùnré ni wón n kíni n’ifè Oòtólú Omo gbábá owó remo Omo ògúntéré, Asákéké débe éè ri bù Amònà èbùdé ti dodo ó dìjà Àbú ni ó omo Odùduwà

Àbú t’Onífè won ò tólú

Eni agbábá owó re mo Omo Asáòni àbàtà Omo Asáòni Ògángán Àdèsí onípònlewù Àdèsi mo kádiyàrán mo pámúlétan Mo rìn rìn lájà mi ò nù Won èé dúró kíni n ‘ Ifè Oòni Won èé bèrè kíni n ‘Ifè Òòyè Tègùn tègùnré ni wón n kíni n ‘Ifè Oòtólú Omo lójàlójà, omo ládéládé Èrèké dìran àbàtà Àbàtà ó dìran èrèké o A wí lóbalóba dìran àn re Omo Àyántóyè, omo Omípónnlé Àbú ni ó omo Oyè Ifè Omo lójàlójà, omo ládéládé Omo òró ló ti móyè Omo ológún adé Ògbóró akánwò olòsì asònà obèjì òsà Gbogbo kòtò yí n se níwo odò yìí Gbogbo re loba Arónpé n tún se Omo panígbó paníjù Baba ìbíyínnká Ayógun má kárúgbó Baba Àyányèbi Àbú ni ó omo oyè Ifè . Ayógun má báwòjé Baba ìbídòkun Àbú ni ó omo Oyè Ifè Àbú t ‘Onífè won ò tólú Omo Asáòni àbàtà Iroko kan teere n be nipade Ora Iroko kan teere n be nipade Okewu E e je se won Ora E e je se won Oke ‘wu E e je se won ote le odán Òtéré eé sàn pásè ròdi Adéróyè má sàngbe re wòwò, ìpàdé eríwo won ò téré Gbogbo eja ní n jó bebe l ‘ójú omi Alágbon débe éè gbodò gbon Amògòrè ló ti dodo orókè ó mòye Ó tirii ó wénu odó ti se Enu odí dùn bánbán ará mi ò sápàgbon Enu odí dùn bánbán ará mi ò té lode Àté ta gèlùwò teníwè é omo ò wè kí lè be sésé, àbèsí ará òkè kèságbé Omo fìtílà kan gogoro Fìtílà kan gàgàrà n be lókè kèságbé Iná èé kú be tòsán tòrú Àsèsí Onípòlowù Omo lèdúndún lèdú omo lèpupa n lèpa Omo lèsáká sàkà sáká ni wón n pè ní nílè àpálóró Omo Oba Òró ló ti m ‘óyè Omo Oba Ológún adé Àbú ni í omo Odùduwà Àbú t ‘Onífè àbùré eni agbábá owó r’emo èdìdè n ‘Ìfè Oòyè Adétáyégún baba Dékémi Arèmú èsí omo Odùduwà Omo mésò móyè, omo afélélé w’adé Omo sèdìbà rán gbó de Abisú ta ní eyin are won Abisú ta bí eyin ara won O mú kan è fegbèje Ó mú kan è fegbèfà Ó mi kan è fegbèédógún, Oko L’apónlé Afínjú wojà ó rìn geere Òbùn wojà a rìn ràìràì Òbùn yéè mòórìn ní rerù afínjú wolé Omo òkándùnmóyè omo Oyínkánolá Omo kúkúndùkú sewé gèrugèru Òpò oògùn rumo gale gàlè Bóo lópò Oògùn Bóo lékèé éè ní jé Abinú ponrangandan Inú ponrangandan bíi fá fore Ifá fore èé béré Opele fore èé béèrè Bí baba ‘Fádkóredé fore abuse bùse Àfàòlélé mo ródò kán làlú Omo eléyinjú efun Omo ò láso n lè búnlè je Omo o ragòjò oyè sotò Ori òle ò le gbé baba Fákóredé Ìbítóyè Oba Atéwógbadé Atéwógbadé Oba Ògbòngó rè tomitomi Òrí róyìí róbìnrin rè láso Ònwòyí wará rè lewù Ó ròyó dùn tajà oko Arísaké Ó délé tejiteji, ò joyè tán fará è gbondò Ìmò ní fi n sèlú Ogbón inú ní fi n kólé baba ré jo Oba yóyìn óyè Oba Aríbidésé Àbú ni ó omo oyè Ifè Àbú t’enífè, a tìlú omo gbábá owó remo Omo ayélóro àtije, omo asòró dà bí àgbà Omo bàbà détì lósinyòlé Omo eja tí ma gbójú omo ríregba Òjíyí mo wí éì gbodò ji Ètùrì ò gbodò lasà Omo ògongo logòó Omo àjànà ti éì jákùn mórùn Omo Arésikéyè omo síjúwolá Arépo Bósè Baba ‘Déolá Àbú ni ó omo oyè Ifè Àbú t ‘enífè abùré eni gbásá owó remo, èdìdèdè n ‘Ifè Òòyè Won èí bí e níran ìyà Won èí bí o níran ìsé Omo lójà, omo Ládéládé Èrèké dìran àbàtà Àsàtà ó dìran èrèké o Awí lóbalóba dìran re Àbú ni ó omo Odùduwà Ìbàbé ni ó Òkóyè kólá Kóláwolé eni a kógun á koto Èlú mo wí èé dire Wòfà ò duyè e jàlùsìn Wofà ò duyè ni tàbé ‘lé Òun ogun ní jo n lo Àkùko mi gàgàrà Ni n é mu kàn ó lórúnkún Omo Olórúnkún abenu yíyi Adédára lórí omo baba Détóun Àbú ni ó omo oyè Ifè Omo Oba Òró ló ti móyè wá Omo Oba Ológún adé Omo Sogbódilé, sogbédìgboro Sàkìtàn dilè ojà Ò sòdí odán dì yá baba Ìbíyínká Panígbó panijù, baba Ìbíyínká Ayógun má kárúgbó, baba Àyányèbi Àbú ni ó omo Oyè Ifè Àbú tenífè àbìy;e, eni agbábá Owó remo, èdìdèdè nífè Oòyè Won èí bí o níran Ìyà Baba ‘Détóun won èé bí e níran ìsé Èrèké dìran àbàtà Àbàtà ó dìran èrèké o A wí lóbalóba dìran àn re Inú ilé Àdèsí ni án dé du oyè sí Bégbòn bá je tan àbúrò a je Bí baba abó je tán omo a máa je nínú ilé Àdèsí i.


Àdèsí wolé m’úyì oyè lé mi lówó.

DÚRÓTADE: Àrèmú le bá mi pè káw ÀJÍDÉ Òkò mí omo Oyèniràn Láyínká òkò mí ògé Láyínká eni ma fínjú eréko Òpìtàn ìrayè lejù Àrèmú lomo ògékolókèé èko Nínú ilé e re Asánlú mi èta òdòpetù mi èjù Àpèránsé leléjù mi òkán nígbó nlá Mo wí éèsì nínú ilé o Ni wón joyè kan léhìn mi N bá be nínú ilé N bá jeléjù majòfé Ma jàkíoró, ma jejemu, ma jòlàlèjù, Omo òpè dárí n kó yùn lejù n kó Kárelé omoge oko dárí n kó réfe N é kó sègi dúdú janjan Sègi làgbà omo okùnlejù Mo wí sè mo gìgí egúngún èko nínú ilé e wa Àlàyè obìnrin èewo gbàlè Ògbóbìnrin wò gbàlè bòrò Éè gbodò mójú keégún Mo gún orórò eni ma rólá yan ní mokin Obìnrin èe làkàkà oyè lejù Omo òpè dárí n kó yùn lejù n kó

           Àdèsí ojú làá mògo nínú ilé e wa

Ìrìn osè òòbùn Ètìtísè omògán nílé odán Ìn a lomo olólo méèta, lo nílé e wa Àdèsí ti mú nnkan sè lota Àdèsí ti mú nnkan se lògì Ókin Àdèsí ti mú nnkan sè wé gúgúrú nílé odán Mo wá fìtílà kan segede o In be lókè kèságbé Mo wí iná èé kú níbè tòru Àdè wolé o gbérù oyè lé mi lówó Eè somo aláketè Omo aládé ni ó Adé mà mà n be l’áadèti àwa Okin Ádé dúdú mo mi Òtéré é é sànpásè odi nínú ilé e wa Adéroyè ma sàngbèrè wòwò Ipàdé eíwò òun ò tééré Ko sá le mò eja gbogbo o n jó bebe lóju omi. Alágbón débe éè gbodò gbon Abògèrè ló ti d’ódò sìn Abo kùrùbúló d’órí orókè óo wòye Ó wénu odí ti se Mo wénu odí dùn gbógbó ará sápàgan Àdè dúdú mo mu yà dín lódán.







ÌBÉÈRÈ KÍNI ÌTUMÒ ÀWON ÒRÒ TI E SO YÌÍ

1. Àbú ni ó omo Odùduwà Ifè ni wón ti wá, wón sá láti je oyè Oòni, ìdí èyí ni a se n pè wón ní ASÁÒNI 2. Òró ló ti móyè, omo Àlàjé orúko ni Ológún Adé 3. Omo panígbó paníjù Àlà jé orúko Oyè won ni. 4. Fitílà kan gàgàrà tí n Oke kesagbe yìí ni igbo be lókè kèságbè logbaloba ti won koko do si i ibe ni a n sin awon Asaoni to ba ku si. 5. Ìjàbé ni o Òkóyè kólá Ìjàbé je ilé ìyá re (asaoni). 6. Oro lo ti moye wa Ibe ni won ko lo nigba ti ogun da won laamu, sugbon lehin ogun won pada sibi ti won wa yii.


[edit] MARIA Àgbémakòyeè, l’ádé omo eye

AJITERU kú torí womi, sègùngùn o mo we lókè ojà Ìyákíyàá è sé bí ni lómo Òbùn ràìràì èé bíni ká yò sèsè Tani é jogún ìsé bó dòlá? Ìyaà mi àdè dúdú eléwà bùjé Tégún búra bóosá dénú igbó Paràká búra bó ò dégbàlè Eníkèépé Àwèlé búra bó ò b ‘Asáòni tan Àwèlé mo Asáòni Òkésé Képéolá omo olódó ide Omo arise lóorò okùnrin Òpò oògùn rumo gàlègàlè bí olóopò oògùn Àsòlá bí o lékèé eè ni jé Baba Fákóredé abinú fonrangandan bí Ifá fore Ifá fore è ti è bééré òpèlè fore eè béèrè B’óyínkánlá Asòlá ti á fore àbùsébùse Ojó è tójó, ojó à n ròsogbo Enífá n gbéfá e té Olórìsà n bòrìsà è níkòkò Òótó inú Àsòlá ló ti kó wa wòlú Òra Àsòlá yará bìba àdó Oyínkánolá omo agbéríodó jagun Èrùjèjèjè n ‘Ifè Oòyè Won èé dúró kíni n’Ifè Oòni

Won èé bèrè kíni n’Ifè Oòyè Gigan tàìbèrè ni á n kíni n’Ifè Oòtólú Oní onífè apàpa dárí oni è Òla onífè apàpa làdò ènìyàn Àpa dárí oni, àpa làdò ènìyàn Ni e è ní jé n dé Ifè Oòni Àsòlá yaráyà wàlé Oyínkánolá omo eléyinjú efun Elèyì ènì sun gbè lopin Ògínyán lé mo wí ée déjì poro nínú ‘lé e yin Èjì poro nì ja òn lopìn, on gúnyán Kórò ni wàlé si é Se bó dijó kú won Se bíjó kú u won làrónò kan pèléyabnlá àsórù kán Lárobù kán omo eníyán yi ó jawo Àsòlá bílé ìyá dùn gbóngbón Baba Fákóredé a bile baba bí eni láyin Àdèsí o pò lewù O n kó lé ó yo lóko N ‘Ídòólilé, Nídòó ère Láré olómo ‘fe òbàràkàrà mo f’oyè mole l’ókè èwù Ayé mò mò n be l’Adèsí yin Bí e bá sàkànpò èwù tán Kí e mélà ebì sénu kéréwú


Ègbè: Èwo omo Odélotán òwo lo n fé se Adékáyégún Baba ‘Dékémi Àrèmú Èsí omo Òrun lààlà Àdèsí mo ká di yàná mo kómú léso Mo rin ìhòhò, mo rin ìhòhò yàlè Eni Àdèsí bá ti bá sùn yéè lóyún n nú Odélotán la bómo sùn kéwà ran mo Àdèsí leléwù wòyí Odélotán bó bá wo dúdú máa wo pupa a wò kan mònàmòmà si à lade

Ègbè: Èwo omo Odelotán èwo lò n fé se E è somo elésèkìí omo aláwé ni yín o Adékáyégún baba ‘Dékémi Àrèmú èsi omo òrun lààrà Adékáyégún baba ‘Dékémi O ò ní fòpá nànànà ko tó mo bi ò n rè láyéláyé O ò ní yan páló sókè gbàdà Adékáyégún baba ‘Dékémi Àrèmí èsí omo òrun lààlà Ayé n be l’Ádèsí ì re o Ayé n be l’Adèsí re Bi o sá sàkànpò ewù tán O mélà obì sénu

Ègbè: Àmín ni ká wí Bòlogbón sòrò tó dára lénu Àmín ni ká wí Adékáyégún Baba ‘ Dékémi Ibi tí o ti n je tí o ti n mu tí ò n wò sìnsìn tínú re n dùn nígbà gbogbo olórun má ba bè jé mó o lówó Ààmín o Àmín Àse Bòlogbón sòrò tó dára lénu Àmín ni ká wí Èmi lomo òkándùnmóyè Omo Oyínkánolá o Omo kúkúndùkú sewé gèrugèru Òpò oògùn rumo gàlègàlè si olópò oògùn Àsòlá bí o ní èké eè ní jé Baba Fákóredé asinú ponrangandan bíi Ifá fore Ifá for eè ti è bééré Òpèlè fore è béèrè Bóyínkánolá Àsòlá ti á fore àbùsébùse Níjó àgàn ti gbágàlà ní kèságbé Mo gún yan’lé mo wí éè gbodò s’odó poro O dìlò téè gbodò solo sìrì Omo tuntun òrùjó, mo wi éè gbodò Até màà n se l’Adèsí yin Àdèsí omo òrun ààlà Ègbè: Ayé n be l’Adèsí àwa Ba bá kàkànpò èwù tán á melà obì sénu kéré Ayé n be l’Àdèsí àwa Ba bá kàkànpò èwù tán á m’írù oyè sówó Adékáyégún Baba ‘Dékémi Èmi lomo erúb idùn képéolá o Èmi lomo èwù òjíjí elékòlé aró gedegede womi Èmi àsùnlé bile ‘yá dùn gbóngbón Moróhunfólá a sílé baba sí eni láyin Èjèjì ló dùn ládùnpò Mo wí ìyá kìíyá è sé sí ni lómo o Òbùn ràìràì èé sí ni ká yò sèsè Tani é jogún ìsé bó dòla Èmi ò nijogún ìsé ni tèmi Emi àsùnle yará bìba àdó Ègbè: Èwp ,próhunfólá Èwo lo n fé se Omo ògésé olójàá Omo ojó gbogbo o bí ofún o Omo àbàtà nlá sojú règírègí Omo adágún omo ti n sojú gbegedede Ó mo d’òkè, ó dusàlè Ó dòkè nílé Asóòni òkésé ALÁYÉ N KI O, KÁBÍYÈSÍ N KÍ O Ò . Ayé n be l’Adèsí èyin Ayé n be l’Adèsí èyin Bí e bá sàk`danpò èwù tán E mélà obì sénu kéré Ibi ti a ti n je, ti a ti n nu Tí a n wo sìnsùn tínú wa n dùn ní’gbà gbogbo Olórun mó bas è jé mó a lówó Àmín ni ké wí, Bologbón sòrò Bó dára lénu àmín ni ká wí Ìpè ti a pé gbogbo wa, ìpò tí a pò lapòjù A à ní tanná wo sàréè omo Omo ni é tanná wo sara baba ra tàwa Jànbá Olórun eè ni a bá láíláí Moróhunfólá o ti dé o Moróhunfólá o tí dé Àbùkù è ní ó kàn ó Eè láburú rí Olórun má je n se ráaráa bí isé ago Ká má fèwòn lògbà, kolóun má jé a gàgótí rojó Àmín ni ká wí Bòlogbón sòrò bó dára lénu Àmín ni ká wí Èmi l’omo Oníbídùn, omo képéolá o Omo Mórìmóyè omo Fákóredé Omo àpéké olósè kèé moyé, ibi tí e wà máa gbó o . Fákórede omo eléo ojú efun Elèjì è ní sungbè lopìn Wón gúnyán fòkú, mo wókùú è je nínú ilé e yin Wón pòkètè f’Okùú wò lopìn Bókù je, bókùú è je Bókùú je bókùú è yó Eníyán a múyán je òkú à di Èsù má se mi omo olòmíì lo se Èsù má se mi omo elòmíì ni o se ò Pèlé yará òkó à wóló L’ókùú àwóló omo eka tééré ojú eerin Elèjì eè ní sugbìn nísàlè òpìn Ibi tí e wà ké máa gbó o Oníbídùn képéolá mórìnwóyè Fákóredé Ibi tí e wà ké máà gbó o Èsù má se mí omo elòmíì ni o se Pèlé yará òkó àwóló Lókùú àwólò omo eníyán yó jawó lo Tìpà mo mà n fà lopìn Omo èsù kán òun èsù kán Ló ti kúndùn pònlá Nílé onírá janjanjan bi o n dunní Ibi wó niwón mú kílé re Èsù kan òun èsùn nílé onírá Ibi búke níwón mú kóle re Omo èsù kán òun èsù kán Ló ti kúndùn sùn nílé onírá Nílé onírá janjanjan bí o ndunni Èsù kán òun èsù kán ló ti kúndùn kola Ibi wó ni wón mú èsù máa se mí omo elòmíì ni o se Pèlè yará bùkú àwóló L’ókùú àwóló omo eléyinjú efun elèjì è ní sùngbè lopìn Ibi tí e wà ké máa ìyákújàá ké sé bí ni lómo Òbùn ràìràì kí bí ni ká yò sèsèsè Mo ti dúpé lówó ìyá à mi òò Àfòlélé yará yobò kàn Lárobòkán omo eníkú olóore Iléjì è ni sungbè lopìn Adékáyégún baba ‘Dékémi Adékáyégún baba ‘Dékémi Àrèmú omo òrun ààlà Omo Lárèbòmi, omo Folásadé o Omo òkè molápà àngbéjó Òké monígbárìgì esè méjéèjì Òké hàn láti wò gbé méjéèjì Omo Àrèmú akéròtòpópótòpópó Sé e rí bába a rè ni Akéwúndíá yelé oge Ìpèlè èé se fárèmú Ajóláyemi kí má se kó wa rèé mòsogbo Omo Àrèmú Amólè mú nnkan Afèhìn olè gbo kàìnkàìn Okún Àrèmú bó o mole bóò mú délé Fádípèé lè póláyemí omo aráyé a wíró l’Olúwá Àdèsí omo òrun lààlà Èwo Moróhunfólá èwo lò n fé se Ayé mà mà n be l’Adèsí èyin ò Bí e bá sàkànpò èwù tán A mélà obí sénu kéréwú

ÌBÉÈRÈ ÌDÁHÙN 1. Agemo górí odó jagun Oríkì Ilé-Ifè ni 2. Àdèsí Odélotán Oríkì Ilé-Asáòni








[edit] OLÓKUKÙ TI ÒKUKÙ

–OBA ABÍÓYÈ OLÚRÓNKÉ TI LÁTI OWÓ RÁFÁTÙ OYÈTÓÚN –ILÉ OLÓKUKÙ

Olúrónké Abíóyè sèsó ará ìbá làlúké Olúrónké omo orunkunkun tí n jé ó sán ngbáa Mo dàgbà n ò tí fòrò loyè Àkànní eníjà mo tòsín mo mú raso Mo tà kòrò mo sìn sosìn sòrò loyè Èmí wá teléfe rà kókó Omo Olúrónké mo teja nlá Mo mú rerú were sókun Omo Olúrónké Àbìrókò gogongo nínú oko Babaà mi Abìrókò kò ní yòyòyò Elékùlé à á pàdé Olúrónké abilé kere níwájú ebu Ibájáde ò tún nlé Abasó gbé kóko hánu Abìrìn aso jèntièlè Elékùlé ànpàdé omo ‘Mówálé Abilé kere níwájú ebu Ìsájáde ò tán n lé omo Olúrónké Abí bó bá máso dúdú a mú pupa A fèyí wìnìwìnì bora sùn Ará odò kòsi Ará odò kòbìnìyàn Mo tólá bí eni tóyin énu Eníjá mo tàsín mo mú raso Mo tà kòrò mo sín sosìn sorà loyè Èmí wá telébe rà kókó Mo teja n lá mo mú rerú were Wón bú mi lárùpè nìjàbé osólú Éràn oyè mo délé mo su kún sí baba wa Ìsèsó ará ìbálà lúké Mo wá délé mo súré telé N ó rè bá gògo lómo àgògo mi sòsò layè mokò lotìn Eni ó kìjàsé tí ò kiwi E máa bá mi ségi gangan lóri olúwa re Eríja mo tàsín mo mú rase Mo tà kòrò yofà loyè Èmi teléèbé ràkókó Mo teja nlá mo mú rerú were lóko Òtònpòrò mí yodà loyè Obukun wá n bá mí relé ìbálàmoko Omo alárá ti n gesín mawo Eèkí eríjà mo tàsín mo mú raso Mo ta kóró mo sìn sosìn sorà loyè Èmí wá telébe rà kókó Igi mélòó ní sowó níran babà re Áwé wón n sowó àràbà kàn mà soyùn Nípópó oníjàbé mo ró o Áwé n sowó o Àràbà mà soyùn nípópó oníjàbé mo ró o Ìsèsó alárá mi won ò ní jewe Mo loòràn òwè jálè nìlàkùn N ò jé polódòó yò símo Omi kúnkún tí n yayaba lénu Ìsèsó ará odò kòbini Ìsèsó ará odò kòbìyàn Ìsèsó ará odò Mòtólání Njó àwéré wón n sòwón lòwó n nú ilé wa Owó wá sun gbeere wa sì tiè lòtìn Njó àwèrè àwèrè wón pàd;e jà n jàbé osólú Eéràn oyè mo teja dúdú mo mú rerú were Mo tà kòrò mo sìn sosìn sorà loyè Èmí wá telébe rà kókó Eéràn oyè mo teja nlá mo mu rerú were Àwé wón sowó o Àràbà kán mà soyùn Áwé sowó ará ìbálàmoko Omo alárá ti n gesin mawo E bá n kárelé ará ìbálàlúké E bá n kárélé omo omifunfun tí n yayaba lénu Ìsèsú tí mo kówè n ò kójó tí mo wá kójó tán tíjó n yo mí lénu Omo Olúrónké omo Òtínkànle Omo Mádòlótìn Ó wá gbòtìn kan kan kan Ìsèsú ará odò orò Ará odò mòtòlénú bí eni tóyin émi Pí tí wón kése sùbú Oba Babà mi àlà agemo òjó gèlè àsò Omo bó di gigùn ó gùn Olúrónké Obá ni bó di gíga ó ga Omo kòga ò bèrè lòkùnrìn kún Omo arógangan gún kèsewà nìyá tó bí mi lómo Ìsèsú ará odò mòtólárí o Aásìn-n nì won ò gbe nílé Oba gòdògògò won ò dé n léràn-án sè Ebúkú wá n sé síin lénu Àbálàlúké omo arunkunkun tí wón n jósán agbáa Ìsèsú ará odò orò E bá n kárelé ará ìbálàwóko Omoalárá tí n gesín mawo Omo alias eníwèé òye Baba mi oòsà won ò gbohùn odì títí òsà sé pàyá ìkókó Mo síbá olá lómo ode a máa súngi so Baba mi Àdìsá lásáré mi èkan kìí se lásán Bí baba ò bá ti lé nìkan Nkan ní baba lo Ará ibú aró ará àgbón ìgbe Ará omi kúnkún tí yayaba lénu Ìrókò tété modé ò gbodò sa Eníjó orí òrìlé baba Oyéédùn Kì í logun ó mó mérú wálé Láganjú à n gbó à n té é n gbopa bí ò lèrin E bá n ká relé o Ìsèsù bí mo kówè lotìn E bá n ká relé o Ará ìbálàmóto E bá n kárelé ìbálàmóko Omo orunkúnkún tí jósán gbáa Mo dàgbà n è tíì bòrò loyè Omo èkè ò jé wí felékèé nòdí Babà mi èsìkà won ò pera è níkà Sápé lode èké n jó Omo won n jó wón n bá ní kòyi Èké ò tètè mò pé tòun là n wi Baba Lápéri Àrèmú Oyèuemí Babà mi Àrèmú enisànpònná se léwà lajàsé Tálájogún wá n wó bí ení gbón ni Ègùn Àjàsé wá n tirí wó tònà Ó ní bárèmú ò bá kú ló tán Baba Lápérí E bá n kárelé ará odò kòbini É bá n kárelé ará odò kòbìyàn É bá n kárelé ará odò mòtólání Omo oríaré àdé sùnyàn ni wón máa n poba Babà mi àgbàlagbà lajò Ònjó àbú bànté Orí aré arókó po wá bì ságbàdo lára babà mi abàgbàdo sòsò legàn Elékùlé ànpàdé Ó ti took Omówálé se Omo ajímá sé n sé sègí babà mi ò jiníkìtùkùtù se hùn Ò sùn jáláte sùn mójúmó Mójúmó sìn bá yowó dúdú á yowó pupa Omo òwàrà Àlàdé tó ti fón sègo dà á gbó Ajímosìn-in nítorí aséwé nítorí aségi Ó ni nótorí ìlàpá ti won n wògbè sùà sùà E bá n kárelé o Ìsèsún ará odò orò E bá n kárelé o Lérìn koko babà mi mòrìwò sara Ògún jìè Olúrónke abilé kiri mò níbòkun Babà mi abòlè kiri mò nílè jèsà Ìbá mómo è rè Jèsà nímòkun nì bá kú sí Oko Lálété Ará ibú aró ará àgbón ìgbe Ará omo kúnkún tí yayaba lénu Ìsèsó ará odò orò Omo p’ptí wón kesè sùsú Oba Babà mi àlà agemo òtó gèlè àsà Omo bó di gúngùn ógùn Olúrónké Obá ní bó di giga ó ga Omo à pè á joyè ogun ará ibú aró o Ará ibú aró ará àgbón ìgbe Níbo nilé yín o Ìsèsún tí mo kómè n ò kójó tí mo wá kójó tán tójó wá n yomí lénu Odò Òtìn le mò E ò mo bú aró o Ibú aró n be Òkóyè kólé Odò Otìn le mò E ò ma bú owó o Ibú owó n be Òkóyè kólá Eníkòyí omo agbònyìn Eníkòyí omo agbòn ti è rikú sá Yánbídolú omo alérí ikú kangun Òsèsèkòyí omo agbonyìn Yánbídolú lóòtó ègin Omo awí bée bógun lo Èsó wón n rode rèé kólé Nígba tó níkòyí é fid é olè kólé è lo Omo akú omo oru Omo akú bi ó dí Omo akú bi ti tèntèré eye ò gbodò dé Omo akú tán gurí è gún sòyìn Òsèsèkòyí eníkòyí dìde Yánbìdolú ogún tó lo Òsèsèkòyí wón n rode rèé kólé Nígbà ti Èníkòyí é ti dé olè kólé è lo Yánbídolú omo a kú tapó torun Òsèsèkòyí omo agbònyìn Eníkòyí o ì dìde Omo a wí bée bógun lo Òsèsèkòyì omo akúmó yànyìn kórí Yánbídoyí olóòótó ègímo Alérí ikú kangan Òsèsèkòyí omo agbònyín Eníkòyí dìde Yánbídolú ogún wá ti lo Òsèsèkòyí omo agbòntíè ríkú sá Eníkòyí dìde ogún tó lo ogún tó lo Èsó ò délé pé ogún tó lo Èsó ò fara rogi Òsèsèkòyí gbapó gbofà tán ogún wá le Eniíkòyí wo ló ti ì le ogún tó lo Ìdí òyélù a ròkún Ìdi oyélù a ròsà Ìdí oyélù a rèkòyi ilé Onikoyi ò í dìde ogun Oba tó lo Òsèsèkòyí omo àgbonyìn Yánbídoyí olóòótó èyin Omo awí lée bógun lo.



[edit] ALICE FADÉRERA

           ILÉ OLÓKUKÙ

Olúrónké Olókukù Oba Abíóyè Àkànní Olókukù Oba ni n se Omo Olúrónké omo òkínkìnrin Omo arógangan bókè segbèra Ikókè ó le ba à sóbùru Omo Oba jánsáí ará àgóì Olúrónké wá doba lé won lóde Babà mi Àkànní o ní n ó là tèmi Omo Olúrónké o ní n ó là tèmi Ìdúó làá sure nínú lé Oba Ìbèrè rèpè tiè ni è Èyàn to bá ní yó là a là Àlàmú Omo Olúrónké eni o bá sébi lé Ibi a bá ‘lúware Àkànní nlé ará Odò Mòside Àkànní nlé ará odò Mòsìlèkè Àkànní lará odò Mòtólá béeni tóyin énu bée ló jo Orotùn-ún jókósó o Abíóyè Àkànní orósì gbádìye tó dúdú janjan Àkùko gàngà Àkànní n láá mú kàn ó lókún Ókún nkó abenu yíyi Abíóyè Àkànní o ní nn ó là tèmi O ní n lówó o ní n bímo Àkànní alárá re ò ni jewe nínú ilé Oba Okòròyè jálè nímùlà Òtìn Oòní gbolódo yò sié láéláé Ooni èjíwera tó borí olóhun Tòtò ní bori àsán bàrà loyè Àkànní níjó Àwéré-Àwèrè-Àwéré Wón pàdé jà níjàbé Osólú E sá tiè wá weja gbogbo bí ti n já bebe lube lójú omi Ojó náà mo tàsín mo mú raso nínú ‘lé Oba Mo tà kòrò mo mà tiè sosìn sorà Èmi wá telébe rà kókó erú Eja nlá tó o rí mo mú rerú were sóko Àkànní o ní n là tèmi Kí n yá a lówó kí n yá a bímo Eni ó k’àgbà ìjàbé ti ó kíwì Eléyun n nì edidandan ni e bá n sé lérí olúware Mo mogi tí n sowó ará àgbónòngbe Àwé ló sawó ará molúgbede Àràbà kán mà soyùn lòtìn Nípópó Oníjàbé mo ró o Àwé sowó o Áwé sowó o Araba kan ma soyùn Nípópó eníjàbé mo ró o Mo ríbà rí bá o Babà mi mo mà mà ya ríbà babà mi Mofúnlúké Olókukù Oba ní n se Babà mi Àlàdé Arójòjoyè À n pàlàdé n ló dihùjé Ilé loko Omítólá n mo bí mo bí aládi Oba tó mú jèjènké rèé mòyó Nofúnlúké Oba ló mú Bebéyejú momi agbo Mo mogi tó n sowó. Ará àgbón ìgbe ará Molúgbede Mo mogi ti n sowó o nílé Oyinlolá o Abórìsàdé Olókukù Oba Ìlú bá n wá yóyin óyè babà mi Àjàlá O má jebà ó hè mi Bàbá ò sáré sésé Babá lo rèé bòsun Ìrìngbèdè mò tiè lo rìn lo mà tiè I bòtìn Kùtùfèlè Àjàlá o sí sanyìn támóri Eégún lé è re mò yo patie tí n lé mi kiri Kòtò pòrò re a sì yodà lotìn babà mi Àjàlá O má jebà ó hè mi Odò Òtìn te mò E ò mobú ow Ibú owó n be Òkóyè kótá Odò Òtìn le mò E ò mobú owó o Ibú owó n be Òkóyè kótá


ÌBÉÈRÈ ÌDÁHÙN 1 Elékùlé Ànpàdé -Baba Olókukù àti bogbo

 lókukù ni à n kì béè. 

2 Ara Odò Kobini - Bo bá se rere won ò ní Ara Odò kobiyan bini bí o sì se búburú Ara Odò Molo lani….. won ò ní béèrè

3 Ará Molúgede - Ibú owó 4 Àkùko gàgàrà la mú - Orò ilé won tí wón máa kàn ó lórúnkún n se nílé Olókukù tómo won bá n lo lé oko 5 Ó mú jèjènké rèé mòyó - Ìyàwó Olókukù ni jèjènké, ìgbà tí ó joba ni ó múu lo o Òyó.




[edit] ÒRÀNGÚN TI ÒKÈ ÌLÁ

– OBA SAMUEL ADÉYEMÍ

LÁTI OWO

Owóyemí Àyìnlá, omo Aródùnjoyè Omo Adélétejiteji Ò pabàbà mésin lese oko èmíolá e Esín joko bàbà n mì pege Bàbà mé è mì mò Ó jé ési Adájalé jóko Òpé ò wón omo Alápó win Omo elétìtísè osùn omo olówó aró Ìya re omo Akéré ma mú peji Mo fòjò aro sùsù lowà Òjò àgbá èé rò lásán Bó bá perú a pomo A pàjòjì a gbòbílè lowà Omo enímolè mérìndinlógún Omo eléri owó ebora Kúlúkúlù sé òjò tí balùwè sé wòwò Omo alágbàá se Omo ètílóyè joyè Adéwolé tílérí Oba ó dórí Oba Ò se kèkè di baba àwon àgbà Wéré nikùn amúnije nílé Adéwolé Oba Sòkòtò nikùn Ajìfà Ikùn Àsòlá jègun o sìfà sí Inú re re rè é pélébé Pélébé nínú se àkótì se Àkótì se rè moba léri o jóko Àímoba ìfá tì Bó mo bàbá o mó padà wale Ológun ádé ni baba ré se Baba enìkán éè róba níjetàdínlógún Ojojúmó ni baba ‘Déwolé n róba Lákòtì se rè é móba lérí o jókòó Gba bàba tòrùlé loyè re dèje Omo erinlolá awúwo bí irin Sèmò tolókùn olà Omo Adébáyò omo Foláwolé Omo òpóre kí máa bónísu lo Òkè àlobò lonà rè Oyèdépò omo Erínfolámí Omo Àrìndé a pé láyà mò so Oníbànté ògbegede omo Òbesòrò wojà mòjò Omo baba agbógúnbò níjó ayé rójú Omo awúwo bí irin Eléwù wòyí Bó ti n wo dúdú ní n wo pupa Ó wòyí mònàmònà lókè ojà Omo baba agbógùnnbò níjó ayé rójú Omo awúwo bí irin sèmò tolókùn olà Omo Ajíbésí Adéwolé Àsòlá Ó sèdì sùsùsù bí ewé ìgbá Alárá jojojo bí esú oko Baba Rádéké ìwà pèlé ni fi n sèlú Onínúure ní í káyé jo Ojúódì baba Àjidé Omo Amétíkowá aróbasá ni bí ogada Àbèfè mo jorì lotùn omo Akínlabí Omo Àjàmú ebí jàre òle Omo Apète ènìyàn lojò Omo Ajàmú ti méte òle mójú fa Ó gùn táso ó lò baba Àyánfúnmiké


==TINÚOLÁ ADÉDAYÒ== - ILÉ OBAJÒKÒ

Oba tó tó bí ení daró o Òba nì nì bí ení gbon òwu èfunfun tó tó bat ó ni èmí dásà oba ko lé nìní ni tejò ta yìnìyìnì N é kó berúlè léré wó Àmóyìnké ma buúlè léèrè wò Omo Efádùnmóyè omo Moróhunkádé Bé e bá jé n kégbe làlú un lo Lé nìnì mo tejò ta yìnìyìnì Aródùnjoyè, Adélé tejiteji Ò pa bàbà mésin lese oko èmíolá Esin n joko bàbà n mì pegepege Bàbà má e mì mó Yésé Adéyalé joko Mòpéòrún omo lápó olóore Àyìnlá lomo gbàgìdó Adínjú eye tí n je ní gbangba oko Omo ògòngò balè kó sèru Babá jà nígbón mo ló jà léyìníìgbo Ó ri n léhìn Obàtélá Ó lé abuké here kánú oko Lé nìní mejò mejò Bólúmolé sago sàgemo tolówó ru bí ose Sàkòsè lonà Tàpà Omo Ajàmí onísé ògún yàn áyé Adéyalé baba ‘Dédoyin Èrò sá árè mó igi n pejò lépò àpà Òní lejò é rìn lápà nílá Agbólúoká Òla n loká é yan Bóká bá sé é jú ténìní pamólè a tèle Èjòlá n wó rurú bò nísàlè àpà Erú e kàn bì mí mo mí pomo àbèrè àpà Gbálègbálè àpà kí an má mà gbaràwé Kí an wí be loká ti kómó je Bólúmolé sàgbó sàgemo tolówó ru bí ose Sàkòsè lonà Tàpà Ègbè: O mò sosriire o O soríire O mò soriire o A soríire Ifé dayò lókè’lá o A soriire Àyìnlá lomo ògbàgìdá mo níyà sonú Omo alérú omo kó Baba enìkán o mà tètè dáyé ko lá won jáyà orùn won Bo pa nì n é kàyìnlá sí Kí pa mó bà bè jo Wón bí o ní bèje bejo bí olú esunsun O nì ó moye ìràwò òkè Adéyemí Àyìnlá Ni é mo bì wón bí o dé Àyìnlá bile ìyá dùn gbóngbón Baba Moròhunrádé Se lé baba bí ení láyin Àdùndùntán báyìí nilé mòwó re Aródùntádé ‘mo Adéríefun èwù nílè mi òjè Òjó pa mí o Baba Moróhunfádé Àyìnlá Ó yé òjó pèmi nínú lée yin Ójò ò pewà mi dànù Ójó pa tápà o pàboki Ó ponoge ó kó tomú e Òjò yó pamí è mì dìn mí Mo wó bù kéwá mi ni Mo bóko délé àròjò dádé Ilé ìyá Oba là á mò Adéymí ta ní molé baba omo Ògbé lànlá motájàlá mògún Adèyemi omo àtérí eléri mo gbà mí o Baba Moróhuntádé Kó bá mi tájàlá mò mi se Mo bá o délé àfójò dádé E tété bèlè jé o Baba Moróhunfádé o gbóhùn lénù mi Ibí gbòkán ni mo wà yi n é è lo be Wón bí o ní tèje tèjo bó olú esunsun O nì ó moye ìràwò òkè Àyìnlá kèé mobì wón bí o dé Bo pa nì n é kayìnlá sí Ki pa mó bá bè jo Lé nìní no pejò pa jìnìjìnì Èjolá ní n jésà lápa nílé Agbólúoká Bólúmolé oká n ní jejemu okin Abìrù sóóró débè éè róyè je ló bá bílésanmí Ó je bílésamí sàjé sòsó Mo pani tán mo béso síra Mo mùjè ènìyàn sihàn lapà N è ní mùjè ènìyàn kí han má ba pè mí lósó Bólúmolé, ebora ‘lé eni ní ma mú ni Bólúmolé sàgbó sàgemo tolówó ru bí ose Sùkòsè lónà tàpà Eléyìí á nsini Baba Móróhunfádé ire la pábe bá lo Àyìnlá bá tile mòmó rò lo ni Arójòdádé ‘Mo adéri efun sewù nílè ní òyè kúlúkulú sé o òjò o mà ti bàlùwè sé o n náà ló yará lorò Atótésèré mo ké séji séran Àkùrò Tónà mi òjò Bónílé n lé lé Àyìnlá bolónà n rònà Fúlàní n relé rè lálágbo idè Òjò àgbá ee fòórò yin Òjò àgbá èé rò lásán Akéekúyá bó bá perú a pomo A pagùntàn a pòdílè lowà Òjó pa mí Àyìnlá Mo wó yá bòjó père Òjò ò pewà mi dànù Ojò pa tápà mi pàbókí Ó p’omoge ó kó tomú o Òjò yó pa mí è mà dùn mí Mo wó bù kéwà mi ni Mo book délé Aròjòdádé

Ègbè: Lórùjó aye rójú o Lórùjó aye Adéyemí seun rere Lórùjó ayé rójú Kábíyèsí Aláyé o Kábíyèsí Aláyé Oba reere Kábíyèsí Aláyé Adéyemí mo se kábíyèsí lódò oba Ìfédayò lókè ìlá o soríire Òkè ìlá soba ìlú Òkè ìlá kékeré Oko ìlú bàntátá Kékeré ata èé se fi bójú Oko ìlú bàntátá Orí burúkú se tìe fa Àyìnlá Òràngún omo Ògoyè Ègbè: O mò soriire obá soríire Ìfédayò lókè ìlá O soríire Ìfédayò lókè ìlá o O soríire Láyè Aláyé Èmí ti kéborùn méje N è ma fì wé lérin Ayé Arèsà Lade ‘borùn A è ma fìwé lérin Aáyé àyìnlá Èmí ra léèsì, mo ràrán Mo regbínrín, baba aso Àfòle, ló le woke ìlá ò dùn Láye a Arójo kábíyèsí o máa gbó o Adéyemí ma gbóhùn lénù mi dáadáa Omo Moróhunfádé ma gbóhùn lénù mi Àyìnlá lomo Àjàmú enísé ògúnrìn áyé Adéyelé baba ‘Dédoyin Èro sáa rìn mó ebi n pejò lókè àpà Ìgbà gbogbo bí ojó o Adéyemí Àyìnlá N é máa pè ó nígbà gbogbo Ìgbà gbogbo là á pelédùmarè tó dá mi sáyé È è ní rú o lójú o Lòlá Olùwa kè ní rú o lójú Kènírè ó, Agara è ní dólórun Oba òsì è ní wò ó , oò ní mòsì Orí adáni oò ní sìse Lòlá Olùwa kè ní rú o lójú Ègbè: Lórùjó Ayé rójú o Lónìjó Ayé Adéyemí seun rere Lórùjó Ayé rójú Mo súnmó Oba níwòn ebè kan oso N è jinnà sóba lébè mefà Nítorí aróbafín lobá máa n pa Kóba mó baà pa mi Oba è ní pa mí mo dìmó ‘dà Oba lmi Lè nìní mo pejò pa jìnìjìnì Bólúmolé lónà sàgbó tolówó ru bí ose. Sàkòsè lónà tàpà Gbálègbálè ònà àpà kí an má gba ‘ràwé Òní lejò é rì lápà nílé Agbólúoká Òla loká é yan bóká bá sí é jú Bí lénlénìní pamólè a tèle Èj`p;á n wó ruru bó nísàlè Àpà Bóká bá sí é jú bólúmolé pamólè a tèle Èjòlá n wó ruru bò nísàlè àpà Èru è kàn bà mí mo méjò lagbàjá Lálánké mo móká mo mú pon ‘mo yóko Mo fìrù àwòn báyìí lalè omo àbèrè àpà Èjòlá n ní jésà lapà nílé Agbólúoká Oká n ní jejemu okín ibe Abìrù sóró débè éè róyè je Ó je bílé sanmí Sàgbó sàgemo tolówó ru bí ose Sàkòsè lónà tàpà Ó deléèkínní o nílé Agbólúoká Adá má yóko má yódò lápà nílé Agbólúoká Alápa búra bógùn a rook Àlùsì obìnrin Àpà ó wálá pàndetí Mo wó bù kéwà mi ni Mo book délé àwòpòdádé B ‘Éji ba n pa ra yòókù o È ma pèyókù be Èjòlá wonú òkun kò sé mú Èjòlá wonú òkun kò sé mú Adéwolé Òràngún náà se sáà nígbà tie Àgámògún molókó titun òkè àlobò lonà ‘rè Olóun yóò delè fénìyàn eníní ‘re Ògún gàn-án mo mírin túnrin ro Òkè àlobò lónà rè Baba náà se sáà nígbà tie fa Àgbámògún olókó titun òkè àlobò lónà ìrè Ògá nisu won ‘jomu nílé akéyemó Oba Àlòkò nisu àwon òkè ‘rèbè Eè kilo fárá òkè’rèbè kí an má yí gbàgá mó Enírè osìn akéyemó Oba Eléyinsú wón ti táyàba wón je mògún Lórò mokín fón ‘ná mògún wò jannje Àgámògún molókó titun òkè àlobò nirè Èjòlá wonú òkun kò sé mú Adéwolé náà se sáà nigbà tie Mánukàn a mókófon ‘ná tiwájú re a máa jé Folámodi Elénà ní modi ògùn lágbède Omo rówòròwòrówó bí alágbèe ì bá rówó Tolóló taládàá ni an é máa pè lónà oko An á ní baba won múrin je níwájú enírin Èyin ògbèrì e jòjó wò e ó mò béyín Alágbèe è ran ‘rin Èjìdá lomi n nájà a mògbon nínu ‘lé yin tòtò bá n nájà tòrò Àtoji àti tòtò kí bá n nájà mògún N é b’ówó alé leléyi mògún lórò mokin Amókó fon ‘ná mògún yè jan nje Olúwa é delè fánìyàn olóló ire Ègbè: Olúwa é delè fún bàbà tó lo láyé Kábíyèsí aláyé o Kábíyèsí aláyé Èyin Oba rere Kábíyèsí aláyé Oba tó ó bi eni baró o Oba nìnìnì bi eni gbònwúo èfunfun Adéyemí Àrìndé se sáà nígbà tie Àrómòjé ‘mo ajá se bí olóko Àrìndé náà se sáà nígbà tie Àrìndé ‘mo alápò fún ògún Adéyemí omo aní n lákese abògó kè bí àlà Baba ló torí àgbàyèwò ó ti kégbàá rèkó Ontóyè Oyèyemi sowó gegege nílé yín ni Adéyemi Àrìndé se sáà nígbà tie Àrómòyé ‘mo ajá se bí Olóko À nò se gìlò mo dekùn nibà Olúdékùn n è jeni nínú ‘lé yin Àmòtékùn mi è jènìyàn N è jeni n è jènìyàn kí an baà pè mí lósó Oló ní è máa ráni ‘re àró ò re Oló ni è máa rá nì re àrómòjé Àrómòjé mo mégbàá jó Àrómòjé mo mégbàá wòran Òjò kú bénílù mi eè lù Òjò kú bégbàá mi eè jó N é máa mégbàá mi lelé Omo a já se bí olóko Ènìyàn yè bá nn lóré rí Ki ká lo sójúde bàbá à re lo Òjó kú elégbèrìn òsúnsún Mò férè sodún o Mò fore sódún Òjó kú tolú jokò Mò fore sódún o Mò fore sódún o Òjò kù Olámoyè Mo fore sódún o Oba tóo bí ení aróo Oba nìnìnì bi eni gbònwú èfunfun Tótó ‘ba tó ni èmi dásà Oba ko Akóláwolé mògún ò jó Èyídùnmádé se sáà nígbà tie Àyàndáao Èyídùnmádè Akóláwolé Àyàndá se sáà nígbà ti e Ó mò pa má mò ón jú Baba jidé ó pa níjó ògún kola Baba Odéye Òbe tì ló n tojú o, àní ò mú Ó mú tán ó ko wón lápá gengele Àgánwògún mo olókó tuntun Òkè àlobò nirè Omo Ayéróso Omo Ayépolá se sáà nígbà tie Tótó bat ó ni èmí eásà Oba ko Kóláwolé mògún n gán Mògún gán ‘mo olóló tuntun òkè Àlobò nirè Èmún ni jesà nirè nílé Amókó fon’ná Ewé ni jejemu ‘kin won Ewìrì ògún dé bè éè róyè je Ewìrì ògún la mu jè ‘yálóde won Mókó fon’ná mògún n gán Tótó ‘ba tó ni èní dásà Oba ko Amókó fon’ná mògún eè ní bínú

Omo èjìdá lónìi n nája màgbon nínú ‘lé won 

Tòtò bá n nájà tòrò Àteji àti tòtò ki bá n nájà mògún n é bówó alé relé o Mògún lórò nmokin a mókó fon ná mògún mè jan n je Irin owú kó mo gbó mo yà lágbède ni N è mò bókó ni wón ro nírè won èé roké Amókó fon ‘ná arámògún lórò mo kin Mókó fon ‘ná mògún n ján Kábíyèsí náà se sáà nígbà ti e Kóláwolé Ayàndá se sáà tie Tótó ‘ba tó ni èmi dásà Oba ko Amókó fon ‘ná mògún n jan Omo Ajíbùlúyò omo Ajíbésidé awúwo bí irin Omo Olódùmò àpà omo alee ‘lá Omo òpa se sí isí sé lu sèmò tolókùn olà Pélénbé nikùn amúnje sòkòtò báyìí nikùn ajìfà Ikùn Àyòndá jìfà sinú re rè é pélébé Pélébé nínú se Àkótì se, n é kótì se Ma rèé moba lórí odópon Àìmoba eè sìyàn Bé è bá moba ke mó padà wálé oko woléyelá Mo mo baba eléwù sègidi Mo mo bàbá eléwù Sègèdè Èmi mo bàbá eléwùwòyí Babá ní bó bá wo dúdú a wo pupa A wòyí mònàmònà dókè ojà Kóláwolé mògún n ján Ègbè: Èyin Oba rere mo se Kabvíyèsí aláyé Gbogbo Oba mo se kábíyèsí aláyé

ÌDAHUN ÌBÉÈRÈ 1. Èjòlá ní jeésà lápà, -Nínú ilé won won kò goódò oká ní je jemi ‘kin je ejò oká. 2. Nílé Agbólúoká -Gbogbo ilé Alápà ni won n ki

                                                                                     béè

3 Òjò àgbá èé rò lásán - Orò tí wón máa n se tí òjò yóò rò ní ìgbà èèrùn tàbí òjò,

          tí eni tí kò bá bímo yóò sì 

bímo ní àsìkò yen. 4 Èjòlá wonú òkun kò -Àlàjé tí wón fún un torí pé ó seé seé mú ó sanra. 5. Amóko fon’ná Gbogbo eni tí a bá bí ní

                                                                                   Ìrèmògún .


[edit] Kábìyèsí Aláyé o

Kábíyèsí Aláyé Oba rere Kábíyèsí Aláyé Ìgbà gbogbo bí ojó o Adéyemí Àrìnlá la é mo pe nígbàgbogbo Ìgbàgbogbo la pelédùmarè tó dá ni sáyé Àyìnlá lomo onílé èdí òre Òre rèrèrè lóke ‘Jìgbò Àrìnlá lomò dí Ò gbélánlá ‘mo tájàlá mògún Adéyemí lomo Atísí elérí mo Ò gbé gbà mí erí mi o gbàgbàhgbà Àyà mi ò tiè gbà kòkò Ò gbé sù mí kìrìbìtí Adéyemí Àrìnlá kó gbé mi rèé s`dagbo Erí awo ò gbàmí erí òsanyìn ni o gbémi lé Omo Fágbe Olúmo Kábíyèsi Aláyé o káyèsí aláyé Oba rere kábíyèsí aláyé Oba rere kábíyèsí aláyé Tótó bat ó ni èmí dásà Oba ko Èmi è ní á rásà dèsò so Sàjé sò ró ladéyemí Mo pani tán mo bóso jóra Mo mùjè ènìyàn siyàn lapà Orí re dára ò Orí rè dára ò Àrín làá ri lapà Orí rè dára ò Àrín làá rí lapà Orí rè dára ò Nítorí ìgbà Olúgbón Èmí ti dáborùn méje N ó ma fìwé lórin Ìgbà areas Mo ní borùn méfà N é ma fìwé lórin Láyé Ayìnlá Èmí ra léèsì mo ràrán mo ra sányán baba aso À fòle, lo lé poke ìlá o dùn laye Àrójo A fòle, lo ló póko ìlá ò dùn laye Àrójo.



[edit] TIMI EDE

A à ní joyin, ká tún gbàgbé adùn.

Òrúmo gégé láoyè ako ekùn akùnyùngbà.

Gbóyè ólá Àkànjí ì mi Láoyè tó tóyèse.

Àgbàdá tolómù omo kélébe .

Àre lágbà lóyè bí ògèdè.

Àkànjí omo Àjénjù

Àyà mi kò pé méjì, n bá fi òkan fún omo Ojo.

Àgbàdá ta lómù omo kélébé.

Ò ránmo ní isé fàyàtí.

Àkànjí ì jí lo .

A ò rí okùnrin Ogun.

Àgbàdá talómù omo kélébé.

Ìgbà tí ò sí láyé mó tó kú.

Fólórunsó, Ajífòní baba

Baba Bólánlé Oláníyì

Ajítòní Ajàgbé.

Olá à re ì ‘dèra ni

Fólórunsó omo lórí demo

Àjàgbé omo Béllò

Àjítòní aran ee deyin.

Béèni àgbo o won

A sì ti àn ti ròrò ti ròrò

Ajítòní Ajàgbé.

Síyán ti e dé pinnu ara.

Fólórunsó omo lórí demo .

Fólórunsó.

Orí Oba ni ó bi wón.

Eni tí n bá Obá á je .

Tí n sòrò Oba léyìn .

Ori Oba ni ó bi wón .

Fólórunsó Àjàgbé Oládòkun.

Orí Oba ni ó bi wón.

Eni tí n bá Oba á je.

Tí n bá Oba á mú.

Orí Oba ni ó bi wón .

Ajítòni Fólórunsó.

Àjàgbé mo gbà fún Oládòkun.

Tìmì Oba Ede

O kú mèye ìbàdàn .

Ajítòní baba wa.

O kú mèye Òsogbo.

Fólórunsó omo Béllò

Kò sí ibi owó ìjà erin ò mà mà tó.

Owó tó Sókótó.

Owó tó ìlorin.

Owó tó ìmèsí olójà òkè.

Àjàgbé owó tó ìlú Èbó.

Oláníyì ìwo lomo Eégúnjobí .

A ó lese tàì leè kó .

Bée bá dé ilée wa lóhùú.

A ó le se tàì le kose kó o

A ó lese

Fólórunsó lerí yen.

Àlaré aláwàdà.

Àjàgbé lerí yen.

Àlaré aláwàdà.

Àjàgbé lerí yen.

Àwàdà laré yìí.

Aremo n be lówó o e e e e

Aremo n be lówó.

Àwàdà laré yìí o .

Aremo n be lóó o eeeee

Aremo n be lóla.

Ikúmóruwá Olórun ló lóògùn.

Kò mò sónísègùn tó ju Olórun lo.

Olórun lo lóògùn

Ikúmoruwá, Àjàgbé Oladokun.

Iró, Iró. Iró ni wón n pa.

èké, èké ni won n sa.

Iró enìkan kì í bá Oba á jà, iró.

È báà pa àgùntàn, àgùntàn

È báà pa tòló tòló olórí eye.

Omo tí Olórun yó se, ó ti sé.

Àjàgbé Oládòkun.

Ìyá àjé kú è n yò sèsè

Omo tí àjé fi sílè, ó lè pani je.

Àjàgbé Oládòkun.

A wí, wí, wí wón ò fé.

Won ò fé.

Won ó fé.

A fò fò, fò, won ò gbà.

A bólù sílè a fi enu wí.

Àpótí alákàrà ká bí á wó.

Abánise mó sì bánise mo.

A jìnnà sátákètè kété kété.

Ojú ti babaláwo yín.

Ibi e gbé ojú lé ònà ò gba ibè lo.

Ojú ti babaláwo yín.

Ikúnrúwá, Àjàgbé Oládòkun.

Kùkùté ò mira jìgì.

Kùkùté ò mira jìgì.

Ení mi kùkùté ara è lómì o.

Kùkùté ò mira jìgì,

Fólórunsó Àjàgbé Oládòkun

Kùkùté ò mira jìgì.

Kùkùté ò mira jìgi.

Eni ó mi kùkùté ara è lónìmo.

Kùkùté ò mira jìgì.

Fólórunsó Ajàgbé Oládòkun.

Orí Oba ni ó bi yín.

Orí Oba ni ó bi yín.

Eni tí n bá Oba á je

Ti n bá Oba léyìn.

Ajitòni.

Orí Oba ni ó bí yín.

Ikúnrúwá, Àjàgbé Oládòkun.

Orí Oba ni ó bi yín.

Eni tí n bá Oba á je.

Ti n bá Oba á mu.

Tí n sòrò Oba léyìn.

Orí Oba ni ó bi yín.

[edit] ATAOJA OSOGBO

A kì í joyin ká gbàgbé adùn. Enu àgò bàbá ìbà o. Oòmulè o. Àjàní Òkín. Mo juba baba à mi. Pópóolá omo Adédoyin Àjàní Òkín. Mo fé kí oba ìlú òsogbo. Morónkólá omo òkè bí Oba aláyélúwà. ‘Ládiméjì omoàkógbé. Àlàmú ÒKín, Làdiméjì Lálékan. Ìranolá Morónkólá a bi baba joba. Taani ì bá lóba méjì tí ò fáyé lójú. Àlàmú Òkín lóba méjì O tún n sènìyàn rere. Morónkólá Oba Olóríire. A bà gbàlá tó kokò sáré. Àgbàlá Àlàmú ju Oko baba elòmíràn lo. Omo ìjèsà tó gun làlú. Morónkólá Oba Olóríire. Elégòdòmì aso ìgbájo. Elégòdòmì aso ìyèlà. Èyí tó dùn ni e rà fún mi wá. Kí n ró n jó ló yè ìjèsà Ò sere adé eléní ewá. Béwùúlè o má so bora. Omo Ajólówu. E wòó nílé ìré. E wòó nílé Olórò níjèsà abé. A ríléwó ní mòkun. A bèdè kirimì ní ìjèsà. Láì jé mo ro Àlàmú. Láì ro Morónkólá. A bi baba je Oba A bile gbágà léyìn. Àlàmú Òkín. A bilé gbágà láàrin. Ojó ojó kan ò dùn. Ni ojó a fé yan omo oyè ní Òsogbo. Gbogbo omo Oba dúró gégé bí Ogun. Jagun Akínsòwòn di aláfèyìn tì. Ìyìolá Morónkólá. A bi baba jóba. Akogun Òsogbo àgbàlagbà oyè Omo Folásodé Lólá. Salátìléyìn Oba Morónkólá. A bi baba j’oba. Òsà Àkàndé lalátìléyìn Oba. Morónkólá a bi baba j’Oba Ìyálóde Òsogbo . Omo Adélékè. N náà ló salátìléyìn Oba. Morónkólá a bi baba j’Oba. Àti awo àti Ògbèrì. Won ò tètè mò pé. Jagun Akínsòwón sòtító. Pé Lápàdé lobá kàn. Omo Aládéyófin. Àlàmú Òkín j’Oba ìlú tòrò kin kin. Morónkólá Oba Olóríire. Àlàmú omo Mátànmí lósogbo. Mótànmí aní Kanngúndù Omo àkógbé alágbàborò. Mufúolájé baba Mówunní. Amúgbùrùwá fúo. Baba Olúgbèjà. Láyànféélé baba Oyin dà. Olá aláyélúwà j’Oba káyé ó leè rójú. Ò joyè lógun omo Oba. Ò joyè tán fará è módò. Ará níu gbe ni. Egbàá ò gbe ni. Àtélewó kì í pé Lájobí. Lójó Mátànmí n fò de sòkan. Baba béeni àtànpàkò kò yara è lótò o. Òde gbangba kò sé dààsè sí. Lásojú ìlú kan diè-lójú òde. Àwìrì omo selé oko owó e dan. Àwìrì tanwì oko owo e dan. Ò gbó èlùbó Òsèlú orí emo oko Arinkékànbi. Alátise ò rómo róye. Ò rómo róye baba Olúgbèjà. Oba ò rómo ìlekò. Aláyélúwà baba ‘Lábímtán. Ò joyè jogún omo Oba. O joyè tán fará è módò. Ará ní n gbe ni. Egbàá ò gbe ni. B’Oobásùn bóobá jí. Àlàmú Òkín, Móojúbà baba à re. Àjànà kan ó mó pefòn léjó mó. Oláa baba kálukún ni kálukú n je. Àlàmú n je Oláa Mátànmí láàfin. Morónkólá abí baba j’Oba. A bi àgbàlá tó ìkookò sáré. Àgbàlá Àlàmú ju oko baba elòmíràn lo. Èmòilègùnlè baba Gbógbéjó. A dàgbà Ládìgbéjó. Baba Ládàpò. Bàbá à mi Àlàmú. A à mo ibi tí yó mo ilé yìí dé. Omo Mopé. Àlàmú Òkín. Bó parí òkanmòkan. Morónkólá abi baba j’Oba . Kábíyèsaí Oba Òsogbo Oba to léducátìon. Tó lógbón lórí. Kábíyèsí Oba Òsogbo. Iyìolá omo Mákànjúolá. Kábíyèsí Oba Òsogbo. Oba tó léducátìon. Tó lógbón lórí. Kábíyèsí Oba Òsogbo. Iyìolá omo Ládéjobi. Kábíyèsí Oba Òsogbo.



[edit] ORÍKÌ OLÚWÒ

OBA ÁSÍRÙ OLATUNBOSUN TADESE LÁTI OWO ÒGBENI GÀNÍYÙ ÀKÀNO ARIWÀJOYÈ  1


Olátúnbòsún Oba o 

Olátúnbòsún Àlàgbé Oba alèwílèse Àìrédùn òràn Àlàgbé oko Fàlílátù Bí Olórun Oba ò bá d’ánitán Enìkan o le fìkánjú se n T’Olórun Oba o yònda Látúnbòsún Oba tí í jí yo bí egbin Adùn ún bá rìn wokò ká má s’awo omo Àsìáwù Àlàgbé. Àwa Látúnbòsún lajo d’élésà Lajo d’Osogbo, Látúnbòsún Oba Onímúúre Ìgbín tenu mógi ógùn ún Olátúnbòsún tenu móyè o si muje Atilè yanrí wa, o sayé é ‘re Àlàgbé omo bé ò nítèté kú, Ásírù Alolo mágbagbé ilé, Atì’bàdàn wa gboyè lówó eni ti n be nílé. Omo Àsìáwù, Àlàgbé, Olátúnbòsún Àlàgbé léni ti n be n le o r’óyè je. Bí t’atílé-yanrí wá o sayéé re Àlàgbé omo bé o ni tèté ku Ásírù ololo má gbàgbé ilé. Àlàgbé omo Tádése Àlàgbé oko Fáúsá Ìgbín tenu mógi ó gùn-ún Olátúnbòsún, Àlàgbé tenu móyè Ó sì mu je. Atilé yanrí wa Oba onínúure. Àlàgbé ti n se ìlú bò lójó tó ti pé Àlàgbé omo Àsìáwù, Àlàgbé je alága, Àlàgbé tún je kánsílò. Àlàgbé omo bé o ní tètè kú Àsírù alolo ma gbagbé ilé Ìwó nilé odíderé Ìbàrà nilé àwón awodi Sókótó ìbàbá n’ilé Àtíòro Látúnbòsún Oba tí ji yo bi egbin Dáralóyè o, Àlàgbé Olátúnbòsún Alagbe, o dáralóyè o oye baba re Atilé yanrí wá, o sayéé re Àlàgbé oko mùnrátù Àlàgbé, Latunbosun, Àlàgbé Oba àlàfíà ara. Adùn bá wokò ká má sawo Omo Àsìáwù Àlàgbé Àwa Látúnbòsún lajo d’élésà Lajo d’Òsogbo, Atilé yanri wá Oba Onínúure Òun tani, torí Erínfolámí Erínfolámí omo Mìínátù Àjàní Baba kárónwí, Oba aláyélúwà Bíàná, Adégoróyè baba Àrèmo Erínfolámí, Oba Onínúure Adìe y’ógún o p’ogún Agbábíàká Bíàká Ajàní won a l’ádìe o pomo re. Adìe baba sídì, Biaka won a l’ádìe o p’omo re. A gbádìe tà a fowó re yelé Eyelé ta kólé káàsè fún Bíàká, Ajaní, eyelé yé méjì O pà kan soso, Erínfolámí Oba ti ji yo bi egbin Baba eni tó j’Oba tí o k’ádún Baba re ni Àjàní Bíàká Àjàní yá ju baba eni tí o je lo Erínfolámí, Oba omínúure Baba eni o joba tí o k’ásù Alibi oko Bàrìkíìsù Elémòsó Ìgè Àdùbí Èsínrógunjó e boo dólá a kola Abímbólá Oba lomo lámúye Kédú n gboro gàràbara nídì olote. O dé bè o gbè gbón Abímbólá délé ó fi baba fóní baba Àwon ìbàdàn kìí bèrù Oba be lásán Elémòsó ìgè Àdùbí Èsínrógunjó tori ogun n’Ìbàdàn Fi féràn Oba Abímbólá Oba lomo lámúye Tó báyè lónísé Àláàfin Tó báyè lónsé ará ìbàdàn N o reni baba wa Àlàbí o Torí ogun doable kí mó láíláí Olórí olókò omo ni mokun Esínrógunjó, gbóládalé, sáání Sáríà Onìsòkòtò òdòdò Baba Sàláwù, Elémòsó Ìgè Àdùbí, Esínrógunjó Ládíípò, Lániyonu omo Abimbolá So wa tori tani Tori Akéréburu Àdìgún òpó, Àdìgún òpó, Oba àlàáfìá ara Akéréburú, omo Láníyonu Oti Ìkìrun wa gboyè Lówó eni ti n be n lé Àdìgún léni ti n be n lé o róyè je Baba Adégbóyèga, Àdìgún Ni baba Gbóládalé, Akéréburú omo Lámúye Àdìgún olórò loko wèmímó Ajùlégbojó, Àdìgún Oba àlàáfíà ara (1) Alèwílèse o ma n mu ìlérí se (2) Atiléyanrí ori re rò mo. (3) aìlódìn òràn – O kájú rè (4) Awo o so lókó, gbòòrò o fa loja – Oríkì Alaka


[edit] ALAPOMU

Omo Òpómúléró mòjaàlekàn Omo rírí ti n máso womi Omo òpó róso, omo òpó gbàjá Omo òpó kàn níwájú ológun Omo báso ò bárí, ki là bá fò lódò? Bi ò si aso, bí ò sí òwú Omo elòmíì ìbá bóra lè a jòmòdò Omo lámúkúderin, àjefèyìn tì n la jesu ègbodò Omo òpó korobítí-korobítí- korobíti Omo òpó korobìtì –korobìtì Lámúkúderin, ajagaàsè Àwa lomo olórí igbó, omo adúrójà Omo okùnrin tán, a móbìnrin regbó ode Àwa lakólé aroro tó kojú è sóòni Àwa lomo oní apá òtún nígbà táabá n roko Awa lomo apá òsì nígbà táabá n took bò Omo àtòtun àtòsì, igbó baba wa ‘ Omo onítòtò wééré igbómolè Èétórò tó pani, tó jeeji lo Èmi lomo eni tó tètè dé, ilé tiè lójà Àwon eni tí ò tètè dé, ilé tiè lónà oko Àwa lomo èse tín seni, àwa lomo ègbà tí n gbààyàn Àjàgbé òpó, Olásùpò Òbe Mósemí gbigbà ni kó o gbàmí oko wúlè Baba Tinúké, baba Ràmónì Oko Sídíkátù, Baba Bùkólá, baba Àkéèmù Àwa lomo òpó tikò gbóràn, wón ní ká kojú è síná Omo iná tí ò gbóràn, e jé ká kojú è sómi Omo omi ti ò gbóràn, ká kojú è eí èèrùn baba gbedògbedò Baba mi náà ló méni méfà re Mòòsà O mú hóró kan soso bò á lé Omo onígbó ruru, àjòjì ò gbodò wò Ajòjì tó bá wogbó ìyá a wá, egbora là á mú se Omo èse ti n seni, ègbà tí n gbà à yàn.


Àwpm òrò kan àti ìtumò won (1) Omo Lámúkúderin Lámúkúderin jé orúko tí a lò fún alágbára (2) Ajagaàsè Èyí ló n fi ìbátan àwon ará Apòmù pèlú àwon ará ìlú bí ilé-ifè, ìwó hàn tí àwon náà jé jagunjagun ní ayé àtijó. (3) Àwa lakólé aroro tó kojú è sóòni Èyí ni ibi tómo onísòbòró ti rapá kan bóòni tan. (4) Omo onítòtò wééré igbó mole Ní ayé àtijó, ibgó mole yìí wà ní ààrin ìlí. Ìgbó sì kún bòó. Molè yìí sì jé tako tabo. (5) Èmi lomo eni tó tètè dé ilé tiè lójà Pé àwon Oba bí i Alápòmù, Aláàfin, Olówu àti Àwùjalè ni wón jé àwon Oba tó tètè te ilè won dó. (6) Àwon eni tí ò tètè dé ilé tiè lónà oko Jásí [é kò sí eni tó le bá Alápòmù du ilè tó tèdó sí torí pé ó ti gba ilè tipé tipé. (7) Àwa lomo èse tí n seni, àwa lomo ègbà tí n gbààyàn Pé àwon ará ìlú yìí jé alágbára.





[edit] AKIRE

– OBA OLÁTÚNDÉ FÁLÀBÍ ÒRÌSÀTÓLÁ II 


Ewínwìn-ín, omo asagbogbo yíwaká

Níwìn-ín omo asogbàkárì sà

Erú file hàn mí, Erú mònà a fònà hàn mi

N ò jé fàbùjá ilé ìkirè han ni

Oba sákúmawò mòróòyìn

Omo apehinlá bajé ilé Ìkirè, omo a rómo se

Omo olórìsà kan, òrìsà kàn

Táà n mú ni méjì sèbo lójó gbogbo

Òrìsà tóbá dojú kini àlùwó

Lóòsà tóbá dojú koni àlórò

Baba mí mòmò n re Mòrìsà, ó ní n jókò ó dè n n gbà tó ti Mòrìsà dé

Ló bá rún n léèsébì, òhun hóró atare

Ataré bá dowó mo dìlókò

Èsébì ló bá sì domo

Baba mi mo o jéyán un, omo sùnbò

Oba sá à yánjú omo a jà ní bèbè ònà

Oba sá à yánjú omo a jà ní mòpèsoro

Erú ì í menu ò, ògìyán ì í jogòngò òpè

Kínnì gbábó òpè, tí ó [è n mó ròm lálède baba mi se?

Baba mi erú kú morè mope àyè

Akínfálàbí, Adégbénlé, gògómò

Baba mi areso asúbieji

Didú tó dúó ò wùmí, olúfàlàbí bí jíjà tó n jà were

Omo ajéyàn hun, omo sùnbò

Fálàbí, Adégbénlé

Omo olórìsà kan, òrìsà kàn

Tá à n mú n méjì sèbo n lé wa

Omo erúkú morè, mope àyè

Erú mònà a fònà hàn mí o

Èmi ò jé fàbùjá ilé Ìkirè han ni

Baba mi erú kú morè mope àyè

Lámómi tó Fàlàbí , Adégbénlé, gògómò

Baba mi areas a sú bí eji, a rò bi òjò

Dídú tó dúó ò wùmí, bi jíjà tó n jà gbere

N bá mo Lábérinjo, omo Àkànbí àrán

Erú filé hàn mi, erú mònà a fònà hàn mi

N ò jé fàbùjá ilé Ìkirè han ni

Baba mi oba sákúmawo mòróòyìn

Omo aleegun, omo alàjà

Omo apehinlá bajé ilé ìkirè, baba mi omo arómo se


Ikú-jè-kí-n-láyò, n ló tèkirè dó

Baba mi tobo Olábérinjo, toba Àkànji àrán

Jíjé ló ti male sunòn, àìjé àlè abisun gbaagba baba mi abàyà kòtò

Abirun wínrìn kàn túrú morólókò Baba mí fèhìn takòko, ó n ta kókó lójà òkò

Ó faso bàábòkò bora

Omo eléégún e, omo eléégún kan

Tómófun mósùn, tó gbòde lo

Kòtònpòrò lóbí bàmí, ìbà Olábérinjo

Ìbà Àkànji Àrán, Ìbà Sáyànjú omo a jà ní bèbè ònà o

Oba sáyànjú oba jà ní mope soro


Baba mi Oba apàma jàre

Oba onísé ní kábì ònà

Omo kújèkín-Láyò tó bí bàmí

Ìbà síso ní yèyèré ògán, àìso ò yèyèré

Jíjé ló ti máàlè sunòn àìjé àlè abigun gbaagba

Baba mi abàyà kòtò, erú file hàn mi

Erú mònà a fònà hàn mi

Erú ti ò jé fàbùjá ilé ìkirè han ni

Baba mi Oba Sákú mawo mòróòyìn malegun

Omo alèjà, omo apehinlá bajé ilé ìkirè

Òsògìyán ló bí bàmi, a róyó ya yán a bù bí ògì kan obè, a rópón nlá jiyán oko Láye

Oba a sòòsà lósù agàn, oba a sebo bí ení n seku

Ona onísé ní kábì ònà, baba mi oba pàna jàre

Oba a tata bí àkun

Omo olórìsà tá n mú n méjì sèbo lójó gbogbo nile wa erú kú morè mope àyè

Eru file hàn mí, erú mòla fònà hàn mi

Baba mi ò jé fàbùjá ilé ìkirè han ni

Baba mi erú kú morè mòpé àyè

Olúfálàbí, Adégbénlé, gògómò


Baba mi areso asúbíeji, a rò bí òjò

Didú tó dúó ò wùmí

Olúfàlàbí bí jíjà to n jà gbere

Omo jéyán-un, omo sùnbò

Olúfàlàbí, Adégbénlé, gògómò

Baba mi areso asú bí eji, a rò bí òjò

Dídú tó dúó ò wùmí

Olúfàlàbí bíu jíjà tó n jà gbere

Omo Lábérinjo, omo Akàngbé àrán

Kújè-kinláyò tó bi bàmi, Ìbà Olábérinjo

Ìbà Akànjí àrán, ìbà síso ní yèyèré ògán

Àìso ò yèyèré

Jíjé ló ti máàlè sunòn, àìjé àlè abigun gbaagba

Baba mi abàyà kòkò

Abirun wínrìnkàn lúrú moróolókò

Tó n ta kókó lójà òkò, o faso bàábòkò bora

Omo elégúngún rèé, èyí tó n jó mòrìwò òpè

Omo elégún kan to méfun mósùn

Tó gbòde ayéye lo

Baba mi mo Lábérinjo, omo Àkànjí àrán

Omo kólúdìsàmú, moólá akápò osìn

Baba mi ti tihún nígba, tí fòrún sònì

Taláso ní ràjò jéjé, èèjé, èèyàn ti ò ráso ró ó sòfin òde

Baba mó mò ráso ró, ó sì réwù wò

Kinní ó sòfin òde se omo jéyán-un omo sùnbò

Gólótó ni mí, náà ló laso di mi

Oko mó tàmi yarú o, oko mó mò ya tàmí yògìdì

Oko tó nimí n náà ló laso ìdí ni

Tóò bá tàmi yanrú

Erí ní wìnrin ma kànkú èjìgbò

Erú ní wìnrín ma kànkú olómò láì re teni

Onlé jéjì oko òké, alákòdì òkéké baab Òrìsà-dáàre

Baba mi lanídìí níwòn esin

Òrokoroko gbówó fújà lé kùkùté o

Baba mi lòrokoroko gbówó fújà lóbìnrin

Onlé jíjì oko òké, alákòdì òkéké baba jìnmádé

Anídìí níwòn esin omore Abídolá

Láìwón lésin-lóyè omo ògìyán

Baba mi lòrokoroko gbówó sílè lóbìnrin

Abayá jó morè mòrí o lómò, èyí tó bómò tan

Ìgbà tí bàbá mí bérú tan tán lò n béèrè oro

Èyí n tó o , sé mo padà bìri o

Mo book ibòmí lo, èmi olm erú file han mi

Erú mònà a fònà hàn mi o

Erú ti ò jéfàbùjá ilé ìkirè han ni

Ba sákú mawò, mòrí o lóyìn

Èyì tó bóyìn tan more láìwón

Lésin líyè anídìí níwòn esin

Baba mí lòrokoroko gbówó sílè lóbìnrin

Abayá jómorè mòri o lómò

Oko Oyínkánólá ò. O ní sòkòtò bèpéjé

Bi ò bá tójú aré kòní jade abayá jómorè

Baba mí lomo oba dúdú kandú

Omo oba ò dú mì nnì kanlè

Èyí tó dú feyin sèjí, èjí òpéréngédé

Eyin para è télè, èyí n tó o o ò

Aláàwé mo pàdà, mo padà séyìn baba mí

Èmi lomo ení tètè dé, aláwèé ilé tiè ógbójà Oba

Ìgbà àwon ìyá mi ò tètè dé

Ni ón bá rówó jo sole lókè ade

Èmi lomo Oba lóò jé, alápè lóòde

Ìyá mi abodán kefòn, abosè gbà rèrè

Ewé odán wéréwéré yíò

Aláwèé bí kásè lobe jé, abará jó morè

Èyí n tó o ò, ín mo book bìmí lo

Ìyálé re lomo owó lé ò, omo bókó bòmí lo

Béèni Àlàbí, àtowó àtìlèkè náà ni n so níkùlé yámi

Omo owó kégbélé, ó kefùn nisà

Omo òkú yalé sùn, nígbèji gbéjo

Àwon yámi yalé sùn, nígbèje gbèìndínlógún

Eni owó báso ni ìran rè kó wáá wí

Àtowó àtìlèkè náà ní n so lájùlé yámi mowó gbélé ókefun

Ìdí ìyá láà serú o, ti baba làá sèwòfà o

Olúfálàbí, Adégbénlé omo Òrúnmò

Alákànmú, orí re ó mò sere

Omo Oba dúdú kandú, omo oba òdú mìnnì kanlè

Alákànmú, ìdi ìyá là á serú

Ti mo bá pè ó léèkan, o dáhùn lóùn léèmejì

Omo oba dúdúkandú, omo oba òdú mìnnì kanlè

Ìwo lomo Akínoró, kínoró èyìnbó mo kinróyìn

Kínróyìn abòrìsà o, ìlí mi àgbágbá

Baba mi ni n fowó olá gbábìnrin yoyo lóri esin

Akinfàlàbí, Lúfàjoyè, Dégbénlé

Baba mi òrokoroko gbówó fújà lé kùkùté o


Baba mi lòrokoroko gbówó sílè lóbìnrin abarájómorè

Alákànmú mo pè ó léèkan, dáhun lóhùn léemejì

Omo Akínoró Òyìnbó mokúnróyìn abòrìsà

Ìlú mí agbágbá

Bábá re ló n fowó àlá gbábìnrin yoyo lórí esin

Onlé jéjì oko òké

Alákòdì òkèké baba òrìsà-dáàre

Ìmore Fájìnmádé, Mímàjìnmádè

Aròlókùn o, baba mi

Alájómorè mòri o lókò, èyí tó bómo tan ò

Ìgbà tí bàbá mi bérú tan tan lóún bèèrè

Omo won kì í bágì tan

Omo òpè bópè rin, omo ológòngò ò

Tí won fi n jé e bàmí ò gbodò memu

Béè lòrìsà ò gbodò mu

Ògòngò òpè náà ni ón fi n sebè lájùlé èyin

Alákànmú, omo oba dúdú kandú

Omo oba òdú mìnnì kanlè, tódú feyín sèjí o

Èjí òpéréngéjé, eyín pare è télè

Èyí n tó o o o ò, e pé mo book bòmí lo ò

Alakanmu, omo oba dúdú kandú

Omo oba ò dú mìnnì kanlè

Èyí tó dú feyì sèjí, èjí òpere

Eyín pare télè

Kin n book bòmi lo, à béyi n náà tó o ò ?

Omo Adégbénlé, ìdí ìyá ni bálo ni

Àbí ti bàbá?

Ìyá mi lomo Àágberí ògágá ilé mo yòórò

Omo òrá n wón kólé ewé kiribítíbiribíti o

Omo òrá n wón yòdèdemò kelemò-kelemò

Wón gbéyàwó ògbéngbé won ó gbà lowo èyin

Omo onílù bánbántibá o, omo onílù bànbàntibà

Omo òfesè méjèèjì di yèyè wojà

Omo òsán pón ganrin-gànrín

Omo òòrùn pón gàngàn wojà

Baba mi lomo òsán pón ganrí-ganrín o

Omo òfesè méjèèjì di yèyè, ó di yèyè wojà

Ìyá mi lomo kálomò, káláìmò ó kúò

Omo ò fomo rúbo kí yèyè è ó dúpé àná

Ìyá mi lomo mowá gbèjé mo wáà gboògun

Aláwèé mo wá sìkejì ebora lórópo

Omo mo wá gbèjé, mo wáà gboogùn

Ìgbà téwé ò jémó, mo kóbì méjì

Ará mo kóbì méjì mo pewé lójú lolo ìrayè

Ìyá mi lomo àágberi ògáká ilé mo yòórò

Níjòórò ma sibo mójú lele

Omo béwé ò bájè, ma pobì méjì ma pewé lóhú olo

Àwon àrá n wón kólé ewé kiribití-kiribítí

Àwon àrá n wón yòdèdemò kelemò-kelemò

Àrá n wón gbéyàwó ògbéngbé

Sebi wón gbàá lówó, omo e jé a sinmi

Omo àrá o ò, ìgbàkan ìgbàkan

Sé mo kóbì méjì, mo pewé lójé olo

Àlògbà lolo ìrayè

Àfìgbà ti mo kóbì méjì, tí mo pewé lójú olo

Àrá mo wá gbèjé, mo wáà gbòògùn

Igba ewé ní n jé n lójú olo

Ìyá mi lomo àágberí ògáká ilé mo yòórò

Omo àrá n wón kólé ewé kiribítí-kiribítí o

Omo àrá n wón yòdèdemò kelemò

N bí wón gbéyàwó ògbéngbé, won ó gbàá lówó èyin

E jé a sinmí, ìlú jáwé omo ajínájà oògùn

Omo òsán pón ganrínganrín

Omo oòrùn n yò sèsè omo àrá o ò

Alákànmú, bí mo bá pè ó léèkan

Ìlú jáwé omo ajínájà oògùn

Ìyá re lomo ò fesè méjèèjì di yèyè wojà

Alákànmú, dáhun lóhùn o ò

Ebí wo ni mò n kéésí

Omo àrá n wón kólé ewé kiribítí-kiribítí o

Omo àrá n wón yòdèdemò kelomò

Àrá wón gbéyàwó ògbéngbé

Won ó gbàá lówó èyin, e jé á sinmi

Omo òsán pón ganrín-ganrín

Omo oòrùn n pón sèsè wojà

Èyi n tó o, omo mo wá gbèjé

Kárelá mo wáà gbóògùn

Àtìgbàkan ìgbàkàn tí mo kóbì méjì

Ti mo pewé lójú olo, igba ewé ní n jé n lójú olo

Àlògbà loloòrayè, èyí n tó o ò

Alákànmú, omo oba dúdú kandú

Omo oba òdú mìnnì kanlè, èyí tó dú feyín sèjí

Èjí òpéréngédé

Onlé jééjì oko òké

Alákòdì òkéké baba òrìsà-dáàre

E mó pèéní àpèjù mó, èmi lo moore Láìwón

Lájìnmádé aròólókùn

Baba mi lòrokoroko gbówó sílè lóbìnrin

Lájìnmádé lòrokoroko gbówó sílè lóbìnrin

Momoore Alákànmú n be n lé àbóròde ni ò ?

Oko Oyínkánólá ò , onlé jéjì oko òkó n

Alákòdì òkánkán baba Òrìsà-dáàre

Omoore láìwón lésinlóyè omo ògìyán

A nídìí níwòn esin

Baba mi lòrokoroko gbówó fújà lóbìnrin

Omo mo wáàgbèjé mo wáà sòògùn

Mo wá sèkejì oba tó je, omo jáwé sere

Omo tèégbèlè, omo ògbá yìgìytígí wolé òsaìn lo

O wá jeun lójú o lojò so

Seyín lósòó omo yòórò, o sùó mo mójúle

Èdìdà mo pè lógùró, igba ewé n ló jémi lójú olo

Àlògbà olo mi rayè

Ò b á tètè fún mi lérùúgùdùgbà

Ma bùn o lébòótòró

Nlá-nlá lajo n gbóri fúnra wa

Omo mo wá gbèjé, mo wá sòògùn

Mo wá sìkejì oba tó je lórópo

Olúfálàbí, oba ìkirè

Olúfálàbí, Olúfàjoyè

Oba dúdú modú, obaòdú mùmùmù kanlè

Oba òrokoroko gbówó sílé óbìnrin

O n be n lé àbórède,

Etí were n tèkúté ilé, àsùnparadà n tigi àjà

Abiamo ì i gbékún omo rè bó mó mò seti were

Gberínlógàá, omo aròtorò

Mo sùó mo mójúle

Èdìdà n ò gbodò dahùn òràn

Omo mo ha gbèjó, mo wá sìkejì oba tóje lórópo

Omo gberí olúmólá, omo ògbá yìgìyígí

Ó wonnlé òsaìn le, omo gberíogó

Omo a yòórò, mo sùó mo mójúle

Mo wáá gbèjé, mo wáà soògùn

Omo ògbàyìgìyígí mo wolé òsaìn lo

Omo lórópo, pere ti mo gbó mi yà lágbède

Omo mo á gbèjé, mo wá à soògùn

Iwo á jóun o n lejò n sò

Olúdìsàmí, ,moólá akápò osìn

Baba mi tiún nígba, tí forum sènì

Taláso ní ràjò jéjè, èèyàn tí ò raso ró ó sòde dòla

Baba mí mò ráso ró ó réwù wò

Kínni ó sòdo dòla se ?

Mojéyán-un, omo sùnbò

Òrìsáwùmí. Olúbánké Ògólò

Oba kòkòrò lábé oge, atómúlé tilédè oko Èdú

Oko Èdúwándé,

Èdú omo ò gbókàn, Èdú nìkan ní ó fale baba

Bóládalé, Oyègúnle omo Akinbóedé

Òjílòjo baba mi ahúnnúgba afòrun sènì

Omo Akínnoró èbó, omo Akínróyìn abòrìsà lúùmí ògbàgbà

Baba mi n fowó àlá gbábìnri yoyo sínú ago.




[edit] ORIKI OBA ALÓKÒ TI ÌLOKÒ

OBA LASHORE


Omo ògbágbà sami sile

Àgbágbá Ilé ria se é sun

Kí an fònìyàn le ki an mérèé dú

Omo òréré kóni níjanu

Omo àgbágbá sami sílé

Àgbágbá ilé ria see sun

Mesi oko ri wa

A kìí bani jeku kan abàyà suésùé

A kìí báni in sisré òjá finfin nílokò

Oso ìgbà mo fi gbígbin n sèye òkè ilokò

Wón nit ó bá gbin níbòmíràn won a ni ogun ló dé

Ogun ò mò dé Àgùntan ni

Àgùntàn oke bàbá lashosre ló n joko nígbà náà

Omo olórò kan òrò kan

Tí won fi n se lóròlórò ìbà tetè

Ilórò agba aiku ile wa nílokò

Èje ló bí fún wa

Omo òréré ko ni nijami

Ko dàíjù kó dá ni ní kòró boko

Omo oréré o pojú wode ìjèsà míbò

O ni ti won kò bá poju wò ó

À remo nílé re

Omo agbagba sami síle lo sélé yà ònà ìlokò

Àgbágbá Ilé ria se é sun

Ibi ti won feniyan sile ti won gberee ru

omo olójà àlténí fún

Àwon to bójà ni be ki ni won o se

O ni bi mo boja ki ni màá se nítèmi

Se ni n bá ro pòsí ide

Ti n bá ròyìyà iyùn

Se ni a ba gbóità kalé ki an to ru ìlokò ka lo gba’run

Omo ògúnyán baba ba lérí ota kólórun bùje nígbórò

Éyin lómògbà lómógba rí yèyé ria nígbó òsé

Se ni méwàá ní fobi aperiri wò mí

Obì aperiri Ilé gbara oso ùsì ònà Ìlokò

Obi apèrírí lúpaa ra nólè kale

Omo olóro a fii gbágùnmòkèkè kalè

Omo olórò an fi í sori èsí wonin nígó òké

Èsí Ilémi ko bàmí àbàyè ni e rè

Kó bá ti la ba omo elomirin ke wa je èsí

Esi pajá je o fegbe laa seun ni mùrè ògègè ria

Omo olórò un fi i se hóròhórò ìbàtetè

Iloro a bolórò a remo nílé re

Iloro agba aiku ria nílokò èje lo bí kò á

Omo olorere kó ni níjanu ‘

O daiju kí an dá ni ni kòró bo ko

Iba mi kára oní mure Agege a

Baba mi kare oní mùrè àgègè o

Ajagun si òtè wonrin wónrin 

Òjagbáríigba òkè Ìlokò

Omo oboko jà padìye oko je

I be si ti sájí oko àgbò n ba gbà

N ba gbagbo tó sàmù rederede

N ba gbòbídìye bàyà péke

Omo olúygbó aré o

Asébi gbodidi emi

Èlúsémusé

Elufagba sile ka ma ba silé yà o

Agba gòkè bèrè mole

Kómo alókò mó baà nà toto lórí omi

Àgbágba òkè nawó kanlè é mú ohun oni í je

Oní mùrè àgègè n lé

Bàbá mí káre onimùrè àgègè o

Me mo roni kebì a pè run òní

Obi o peru ni para e jólè kíká

Omo asoro de mèkun kèkun

Omo olórò a fi í kun olójà lóta e fun

Omo olórò a fi í kun hóròhòrò ìbà tetè

Horo a boyún

Hóró a remo

Hórò a gànyìn bì meje lo bi n Ilòkò

Onìmùrè agegé nlé

Bàbá mi káre onimùrè àgègè o

Omo obóko já padiye oko je

O ni bi ko si ti saji oko agbo n bá gbà

N bá gbagba kò í bàmú rederede

N bá gbòbídìye bàyà péke

Mo ra gbagiri o

Olugbo are o

Asebi gbogogo okun

Asebi gbodidi eni

Elusemuse

Elu fògbàgbà o sami súlé

Ka ma ba sulé ya o

Onímùrè agege nle

Bàbá mi káre onímùrè agege o

Omo oloro a fi pa hórò hórò ìbàtetè

Hórò á boyún horo á remo

Horo a gànyìn bí meje lóbí

Onímùrè àgègè nlé

Bàbá mi káre onimùrè àgègè o

Omo Ajagun sia ko omo ló reni

Àjàgúnsi lo lereja to fi wa bogun níjèsà obokun

Owá mò ni n jíle ní ogboní lásòrè

Baba mi káre oni mure Àgègè o.

Omo okeinísà Ategboro esu

Ki mo ro poke inias nisu tii ta

Mé ra méwùrà dé bè.

Tori kísu mo baà tàtawòde

Kí mo jògèdè aigbo loko

Ki me ba ti jalè

Se ni a jo a jígbo

Omo Alágádá kilo fólè

Àgádá farumo

Ó fa rùmò

Eni bá ti pé loko nijo náà

A je wí pé ó ni ohun tí n se

Alákàtàkì á kilo fólè

Selége tìrege légbòrò

Òrò sí bá yèpè

Ó tun fi báyín erinlá

Ó wá fi mu okuta látìbà

Oloro lo làtìbà

Ogboni oge lo lodò agidi

Àgbàrá atiba gbómo paroko sórí òsé

Ara ojúgboro ò gbó

Èrò àtìbà ò mò

Omo arí herehere enu gbéde yàde

Oníjukùn so agogo mo ìrókò

Àgbà iwoye so agogo mó kun

Eran yòkòkò mù

Omo ògbùrùkù yàkè

Ogbùrú yàkè o dabi kò papò somijè

Oníjùkù àgbé

Omo abìdèdè ònà omi

Obi ko wò ó séun eni

Yè é é hò sénu eni

Kó hò síjù

Omo eranko á fije


Omo olobi yèé ó ho

Kó petu nígbó àgbó

Tòótó lobi hò

Tòótó letu kú nílé ni Irin kí mía rin


Kí màa bóba relé ògún àlròtélè

Oba dirù sílè

Ojú roni koro koro bi uwo

Omo bàtá kumirin babe gèru nílé ògbóni oyé

Loro lo latiba

Ogboni lo lodo agigi nílé mi

Omo elékùn ònà kí an kàn fide se nílé ògbòni

Omo elékùn ìgbòrò àwíhò

Èkùn ònà kóó fòó san ni bí òyìyè

Bàbá mi káre onímùrè àgègé o.

[edit] ORIKI APETU ÌLÚ ÌPETU

Omo Arámora bí ahéré Jìganjìgan tònà Aránláyè bí ìkookò A – sòróó gùn bí igi òbobò Eè ri i èmi Àjàní ìkó ògírì gbèdu Emi ló se mí mo rìn mó baba mi Emi ló se mí mo rìn mó bàba mi Adéyemí ògbodò gboko lówó won Òsìkà èèyàn tí ri ara rè mó bèbè ònà Bàbà mi pa òkan Ó mú méjì wá inú ilé oko ìyálóde Eè ri bàbá mi ni òbóbìnrìn sùn tomútomú Omú kì í sí lo láyà obìnrin Eè ri bàbá mí wá fàkóbí olórò bí obinrin Eè ri i Eè rí èmi bákóbí òbogiláwo Mo ríba sànpònná igbó nlá Omo esì lóògùn Oògùn tí ò boí ti jé lágbo ilé lágbo ilé baba mi Tori ikòyí ni mí Ìkòyí èsó omo ogun ìbirò Omo Ajègbíyèkarahun omo afìkarehun fóri mù Ìkòyi èsó kò nkú sá Okùnrin ilé oníkòyí tó bá ti dúró Tó bá ti pagbòn lágbòn Ní jó ti obìnrin ilé oníkòyí B á ti pagbòn lágbòn Legan obá tó lo Okùnrin ilé oníkòyí tó bá ti dúró Tó bá gbofà léhìn ojo ló se Eè rí i , omo won lérú owá lèmi Àwa náà kúú nù un A dé bàa se mó on dé náà kúkú nù un Eè ri kì n tó menu ba ìlú ìpetu Ma kókó ríbá Tori ìbà ìbà ni no fòní jé Sebáré mí dòla Ìbà kí n ríbà lódò Ajunilo Kékéré Ìpetu mo kàn lódò won Apetu ìlú ìpetu mo kàn lódò won Àgbàlagbà tí n be nílú ìpetu Mo kàn lódò won Omode tí n be nílú ìpetu Mo ní mo kàn lódò won Eè rí i Aje ile Ajè ode Tí n be nílú ìpetu Mo ní mo kàn lódò won Àwon lomo Apetu je báà mù Eè rí i ìbà lódò won Ìbà lówó awónránwón kan bí èsù ònà Ìbà lódò ìyá iyè tí n be nílú ìpetu Adéri lólá kò ilègùn Òdèdè sèré ni lólá rìn káàdè Obalúayé rin lólá rèé kí tòrun Kó tó máa lo Eè rí i erin tó n be lówó Tótún ni t’olúwo Òpì rè ni Apènà Ògangan ònà-án ni okó n se lobo obìnrin Ìyá ilé mo kàn lódò won Obalúayé mo ní mo kàn lódò won Òsoòsò Àkànní mo ní mo kàn lódò won Omo atérí kí wón gbeji Torí sápósáp;o ni sawo Atórígbeji Òpòrònpòrò ní sawo lébá lébá ònà Òpá tó wonú forí so ìlú Orúko béè ni ònà mi je o Ona yii naa ni mo to to Ti mo fid é ìlú òsorongíso Abuké ni mí n ò séé sá lógbe Abuké ni mí n ò séé lù mí kùnmò Eè rí i eré ògún mí jawó jasè ríkùn mi Ìbù lówó olóde ni mògún òjòjò Iba lowo olóde ni mògún ojojo Tori Asípa ló lògún ilé o Ònà ògègè ode àárò Sebí òun ló lògún òde gan-an Tí wón n bé fún won Ibi tí wón petu sí Là n pè ní ìpetu Eè rì i, mo wá fé délé bàbá mi o Omo won ni petu modù àárò mi Mo fe denu ile baba mi sapetu Eè ri i, sebí ode ni bàbá mi Se délè ibèun gan-an Ode ni Sàpetu se délè bè gang an Tí mo bá paró Kí wón máa yèlé Odù mi Éè rí i ayó kò ni má mi Ayó o n má o mú ohùn enu re Yóó se yóó se kò ní sàláì se Torí àwise ni ti’ifá náà gan-an Àfòse ni t’orúnmilà Eè ri ti kéeekéee ni se láwùjò òwú Ti ìjímèrè ní se Láwùjo Obogi nú aso Eè rí i, èyí tí a bá ti wí Níbà ibìkan ni arò á rò mo Eè rì í torí gbangba loró n pa eran Ìbà lówó kábíyèsí ikú babá yèyé Aláse èkèji òrìsà, Eè rì í, ìbà lódò won Ìbà lówó sápetu ti ìlú ìpetu Ìbà lówó lórí awo ìlú ìpetu Ìbà lówó owátóyè ìlú ìpetu Eè rí Látóyè ìlú ìpetu Olórí onímolè ìlú ìpetu Olórí awo mo kan lódò won Àgbàlagbà awo, mo ni mo kàn lódò won Omo eku, a kàn láyà eku Omo eja won a kan láya ejà Eè rí i àfòfànù náà lobìnrín n foso àlèjo N ó gbórí oró rì òtá mi, ma memu Ìbà lówò owá bòkun bùsì Sebí àwon lomo owa omo ekun Tíí dérú bojo Eè rí ì, ìjèsà kò rídí ìsáná Ìlú ìpetu ni mo wà mé tì lo Eè rí í, ìjèsà won ò rídí ìsáná Omo owá bòkun bùsi ni gbogbo won Nílú ìpetu Níbikan nìbìkàn ló pa ìpetu ìjèsà Pèlú Ìjèsà òsèré onílè obòkun pò níhà ibè hun Sapetu ìlú ìpetu, ìwo lomo Àgbà tí ò jobi Yòkòtòyokùn, Àgbà tí kò bá yokùn Ahun ló se Àwon lomo erú owá bòkun bùsì Omo owá, omo owa àárò gan-an ni Owa Ajíbógun ló bí bàbá sàpetu Eè ri í sepetu n be níhà ibìkan Owá ló gbé adé fún won nílú ìpetu Eè rí, baba tí mo ni Owájàká ògírì gbedu Ikú babá yèyé, aláse èkèji òrìsà Oba baba won ni káárò oò jíi re nì Eè ri i, òun ló mi wa fi esè kan Fi so pe oríkògbófo ni baba gbé fún Atáoja ni ìgbà àárò gan-an Omo òwá ‘binrin ni Òhun náà ló wá gbé fún sapetu ilú ìpetu Oríkògbófo òhun náà gan-an ni Ni gbogbo won n gbé kiri Iyen tún di sìí níbèhun Ti a bá n lo sílú ìpetu Àwon lomo onísèrú àjèjì Tí won ò gbodò wesè Àjèjì tó bá wesè níbè a deni ebora Omo omi sa lo legbetegbe Omo àsáàsinmi àgbàrá Eè rì i, omo omi kàn tó sàn térégun Tó sàn térègun Eè rí i tónígèrú tí won ò gbodò wesè Àjòjì tó bá wesè níbè a deni ebora Eè rí i , omo amómo rúbo niwón Nílú ìpetu Àrúfín ebo àrúdà ebo ni Eè rí i , omo ekùn tí dérù bojo Eè ri ì, omo ekùn n pa wón Omo ekùn jeran tòun tìrù Omo ekùn tí kò gbodò jèran kèran há won lénu Mo tun se sìì níbehun Kábíyèsí, kábíyèsí kébíyèsí ò Kábíyèsí ni n o moo kì nígbà gbogbo Kábíyèsí amóroro nínú aso Akólesè bí àlàárì Oba ikú bàbá yèyé aláse èkèji òrìsè Òrìsà wá rìn wá Omo lrínmolè lokè Mo on gbo o Kábíyèsí oba ìpetu Èèméta ni won n pe òtìtè nítè Nítorí tani, Nítorí ki ebora òrun le gbó Oko Adéyebá máa gbó òrò enu mi Ègbón rere legbón mi Téti sí mi gbóhùn enu mi Omodé ló lorin àgbà ló nìtàn Ìgbà tí o bà kómi lórin ode díè Ma sòtàn Ìbà méta làá jé nílé ayé Ìbà ònàje ìbà ònàmu Ibà ìnà se wòrùko wojà Mo ríbá mo ríbà baba Má so pé mo bá o lóyè mo pè ó lórúko Ikú bàbá yèyé Aláse èkejì òrìsà Ìlú ìpetu la wa aà tí ì lo Ìtàn tó te ìpetu dó Ibi tí won petu sí ni wón n pè ni ìpetu Eè ri, omo owá àrólé Ló je oba fun won nílú ìpetu Bó bà se rí ni o máa kì mí lódù Wón ní bó bá ti bá Alárá kó pa á Won nib ó bá ati b’Ajerò kó pá Wón ní bó bá ti bá ògún ilé ilá Kó pa a gan gan . Nígbà tí owá dè Tí bàbá dé Àkùre Ibè ló ti fade òhún jì wón Bàtà esè bàbá ló bo kale sódò won Òhun ló wá di Deji Àkúré A fade òjhún jì wón lona ibe gan Òhun logun ò se kó Àkúré Oò rí mi báyìí, òbegi nínú awo Eè ri i mo ti kì wón sàràsàrà Torí a ìí béléye jeye Tàgbà ojé ní se níjù o jàre Tòni ní ó se láwùjo Akorin Èmi Àjàní ìkó sánmo léwòn mòlà Èmi Àjàní ìkó ògírì gbèdu Èmi Àjàní ìkó igí dókè a ya pàkàlà Eè rí mi báyìí, ìkòyí ni mi Ìkòyí èsò ogun ibiro Ìyén tún se sii níbèhun Torí bó bá di ojó míràn Tori àá mèhìn èrò A kìí mojá àí sí nílé Wón á ní ta ni ó n se eré òhún Àjàní Ìkó, sánmo léwón jànnìjìnnì.


[edit] ORIKÌ OWÁ OBÒKUN TI ILÈ ÌJÈSÀ

Ìn pèlé o gbogbo ìjèsà Eee Ìn pèlé o gbogbo ìjèsà Eee Ìn pèlé o gbogbo ìjèsà Mo dé mo fé lo rebile mi Kabiyesi, Oba abiri ye ade Aborun ye Ejigba Okun Aromolaran ojiji omo Akeji Ekutu lua Omo amomo rubo ki yeye re la dupe ana Omo ògòngò lérunwá yìó gbágùntàn mèri Oní se háà níbè Ògòngò ló gbe se Kaka I ju koo jimigbe Ò mò lá gbàgùntàn kàn ó kù Omo eléko onà an fidese Owá, an wí ìwo igi O wí o í somo igi Owá an wí ìwo lomo eye O wí o i somo eye O wí ìwo lomo elérugèru Àjòjì o wesè Àjòjì ó wesè níbè ebo ni o fi se Kábíyèsí bàba mi ò Bá báá ní pá níró Mo molé momònà mo mo ibi An bí bàba mi Òtùtù bí òsùn Òsùpá ìledì Amóroro lójú agbo Fúlàní ìjèsà kéé mómo ní pèlépèlé Ilá gorí egbón rè so Omo bépo Òyìnbó enù re kònkò Bí ení fàdá bani ni Owá ti mí je mé tì rí yèé rí Oba kéé fobaá je Olórí aládé ajìwàjiwa ìlèkè Bó ti wù o daa to E si un an fògèdè je ní ìlekì Eran léé jé Ògèdè sòkàn mo ra gaga békan nì Ògèdè bàjé nílé bépo lórùn bàba mi O pon bí oni an fàrín lò Bàba re ló bí o Eranko ó jo òbo ò sí nígbò A fi ìjímèrè kó mí pe ara rè lélóògùn Kábíyèsí mo foríbalè kí bàba mi o Bí á bá ní pá níró Mé le kì nì yàn sàrà Kí mí sài ki’lukù mi Lábá owó Oko ògbóni Àlàbá, oko ògbóni Omo aláyere yèrè àdidùn Omo aláyèrè yìnkàrà dánì Kóni má file jigba ori Kábíyèsì òun ògbóni méji Ló mo ohun an dì sérù ara Ó dé onígboro sègboro jéjé Ikú abidodo gbóògùn pòn Àràbà lílá omo abèrú gbàáké Takutaku o see fokóré Ògbóni adúlójú omo ajòmúkàn ejire Bó ti wu ògboni dáa tó Ìyèmògùn ni an bi Lárìkú èkìrì, yè só je faworè dá gbèdu Ògbóni abánnijà abániré Àkéekèé wá di gàárì O ku baba oni áa gesin Mo tún ya aká òhun nù bètè Oba alábarísà òrun àga Omo arégberin òlèlè soro Ebèrin òlèlè ni an fii sodún ìdó oko Obaálá mò i sònìyàn béè Ìgòdan a là komo lórùn Bi òsùmòrè Lárìkú èkìrì mé réní á fawo rè dá gbèdu O káre ò Kábíyèsí Maa gbo È sóba mélekì àfi yè ó je Kí an i sè bí mi Adelékun Omo ajímókó bí Òyìnbó An wí kí lówá mí se Kó laa dáládiri An wí làjànàkú mí se Kó làa gòkè àyésò Àjàká kólé òtútù ó kó tòrinrin Òun nìkan ló bímo méfà Ò see fèfèèfà dodo Alábá, un o moo pè ó nígbàgbogbo Òun ló bí olúmobì Bàba mi lóinà ìwàrà Mopo omo ànára Omo epo sese lórí ebo An roni pòyùnkún igbó oridì ó ni Lónà ìwàrà ò Yèe nì i sì Báá bá ní pá níró Gbogbo rè ló mí se “HY” níkùn mi Oba tó je tí ò bólèse nílésà Ìwàrà mèkún omo ànarà Omo bepo sese lórí ebo Ìn lé o bàba mi Abínú gbadé Takutaku ò séé fokó ré Mo rí o lókánkán mo yò bí èse Bàba mi Baa ba ni pa niro Oba tíi je mé tì rí yèé rí Ó se mí lore mé le gbàgbé láéláé Oba Ìjèsà mèkún omo ànaràn Omo abepo sese lórí ebo Lári kú èkìrì Yèsí láá fawo rè dá gbèdu Ìn pèlé o Ìjèsà Èee Ìjèsà òbèní Akábì sorò Omo eléníu ewele Omo eléní àtéèká Baa ba ni pa niro Àgbà Ìjèsà ò rídí ìsáná Ile lomo Owa tii muna rook Ìjèsà modù apònàdà Omo eléní ewele Omo olóbì kòkòrò gbágò Obì ó forí màró lèmí á je Nílé kábíyèsí Oba ìlú Ìjèsà A – Múni – má parò – oko- eni Kówá mú ni Kí tàparò oko oni ti jé Omo ogbegùrù lòlò sórí ugi Kóbo bù je lórìgbò Àsá ké èrù beye oko Eye lápó nu omo rè lárà òtò Oba tii foba je Gbogbo Ìjèsà Tilétoko ní jèsà o Ìwo ni Ìwo náà ni Eye lápó nu omo rè lárà òtò Mo fé móo lo rìjérìjé Bí igbá nlá tií lo lórí omi Àlàní omo onílé iré Òkú ègbele oji Ìgèdè bérí olósà sonù Lárì kú èkìrì, mé róní Aá fawo rè dá gbèdu Gbogbo alare tií be níbòkun. Àlàní un o mo gùn wón Nígùn eran ni Kábíyèsí O sée Mé le kìbìyàn sàrà Kí mi i sè kiràmi Onílé uré ni bàbà mí Omo òbàrá òpo nídì okùn Omo olówó alétìlé ònà ígílá Níbi erùkòyè ògùrù lèlèèlè Kí an í sè so ònà ìgílà In òbàrá ló bàba mi o II yèsí e níbòdì

           I à fi lógán 

II akòkò ìbòdì Yèé a fórí gbadé oun Ogbara dè yà yúnbè Un o mo pè ó nígbàgbogbo

Láti ùdí òro òkèèsà

Ní an ti bóní méjì méjì laa dónígèrú oba Omo elénugèrú àjòjì kò wèse Òbàrá ló bí bàba mi o II yèsí e níbòdì Osiiri ja nibodi An gbádé owá rìgbájo Ibi ó wù ó wù An gbáde owá yà sí Òsììrì làà túbè Kábíyèsí bàba mi o Eranko bí òbo ò sí óko Owá ló bí bàba mi níjèsà o Àlàní omo onílé iré Mé le kìniyàn sàrà Kí mi í sè ki bàba mi Dúdú oko ìyálóde Igi jégédé ìgbórò kó mí yayoo dabò Onílé iré ìjé egbele omi Gègè àgbò tíí bí ìkokò nínú Oko gbóláborí Oko béjidé n lé o Àlàní mo jíbà bàba mi to jade Bekòló bá ti juba ilè léé lanu Emi Àlàní olóhùn iyò O sé ògèdèngbé Bàbá ìjèsà Dáná fógun yé Bàbá ògúnléye Ò pa sótún ó bòtún jé Ó pa sósì ó dèè bòsì jé pè Ogedengbe baba ijesa N óó mo pè ó nígbàgbogbo Owó ògèèngbé ti níyi jù Yèé an fi mí rota Yèé só màsìkò ìgbeè Ògèdèngbé se die lokunrin Kó tó bónítoni lo Jagunjagun eranko bí obo ò sí kóko Mo tínbá, mo kúnlè Mo dòdòbálè Olórí akéwejè Ògèdèngbé ogun obá datunlo ò Eranko bí òbo ò sí lóko Olóògùn éé jé bí iná Kèe dàrà lotò Akeran se béè O bólórun lo Bàbá babalolá Ko móo fi gègé léròmi Akeran ti lo Ko sígi méjì obì nínú igbó Kii tíì bá jo bí obì Ó jábìdan Ògèdèngbé le rí Leè kúnlè ki Kán bèrè Kí an yíìká An kaà dúró gbangban An bélésin dógba Ìyà – á je án omo tálikà Ono oko Ògèdèngbé èrù re yólè í bà mí Gbóagungbórò okùnrin dain-dain Kò sólúwarè Tó le tèsó mó mo rè, lórí o Kò sólúwarè Omo olúgbó mòrónsògún Omo ajísomo Omo asélú gbodidi oni Omo akólòsó làgbàyè ejì Akólòsó tòrò kí mi lá ponmi Mo bójì àmù níbè Ìwòfà bàbà fákanyé jé mi ponmi Lákólòsó Ìwòfà bàbà fákanyé gbewù kòmí wò Òjò ló pèwù dúdú oba lórò Kó di kele nílé re Íi kími gbékùn sóyì bíi Elégbe ùgbarí. Èkí lade ugbó Èkí jagun Èki ii jewé uran Èkí ii jàdò ùdí rè Àárín rian lèkí gbà la i lo Omo aríla pekòrò ukù Omo arílà mefà bówá sèye Ògbùrugbàlá omo arílà mefà bówá sèye II kí mé mò II kí mé í kúkú yeni Kí n ba fekoro la re Omo aríkòko dìyà pàrokò II kòko dìyà an fi fáboyún ijabo Èkí á bí tibitire II arúgbó oni kí a mo mu sàgbágbà Onílé ure kí a mó mú sèrókò Kí e í sè gbádùn oni je Se ni an fomo ílè Kí nan bèrè ugi II àgbágbá tèléni Lódò ùrò Èkí dárà omo oni.



[edit] ORIKI OWÁ ÌLÚ ÌGBÁJO

Ibá, kí n ríbà se Osó ìlú mo kàn lódò won Kékeré ìlú mo kàn lódò won nì Àjé ìlú mo kàn lódò won Tomodé tàgbà tí n be nílú A kàn lódò won nì Ìbà ni o fòní jé o Aré àwá dòla kátó maa lo Ìbà lówó owá ìlú ìgbájo Náà kúkú nù un Ìgbájò ní ìlórò gan-an Ee rí i omo aloagogo memu Nígbájo nílórò, Ìgbájo nílórò omo alagogo memu Omo ìgbájo tí n pé Jèresì Gèní òké n pé Ìresì máa sé o maa se. Ìresì ni n o se lóní náà kúkú nù un Sún mó mi kóo rìn mó mi Ti ìresì ni màá se lóní Kí n mú ìgbá dòla nì Omo Owá, omo Òwá otìn yéye Eè rí i , Ìjèsà modù apònàdà Omo won nígbájo lèmí n là gan-an ni Torí ó rìn mo baba rè náà gan-an ni N se ló fesè kan jògbájo Tó wa fesè náà jòjèsà Ee n bàbá re bàbá mi Ma bínú pé mo bá o lóyè Ma pè é lórúko Owá Ìgbájo, dákun dábò Mo fìdòbálè mo pàgúnmó Mo forí okó balè lódò Ajunilo Kádé pé lórí kí bàtà pé lésè Oba Eè rí i nínú ilé, nínú ilé bàbá mi gan-an Àwon lomo Owá òtún yéye Ìjèsà modù apònàdà Ilé lerú owá tí wón ti n múná yóko Ee rí i omo owá òjí alágogo àárò ni Omo owá òjí, owá amúniníbo Ee n i omo owá a mú àparò yóko Yòkòtòyokùn, àgbà tí ò yokùn ahun ní n se Àgbà Ìjèsà tí `ko yokùn, ahun ni Eè rí i , omo yèyé rí lókè dodo naa ni Omo kíúkú fun, kérù ba olójà Omo amómomúmú Omo amómomójèé náà kúkú nù un. E ma gbo O fi oníbàdàn joyè náà kúkú nù un Ó gún lóyè bí òyìnbó Ó gún lóye bí òyìnbó níhà ibìkan Òsùpá ojú ògún Tó là rororo lágbo tiwon. Nínú ilé won nínú ilé bàbá mi A gbá won bí ení jò Òsùpá ojú ògún Nínú ilé bàbá àwon Omo a gbá won bí ení jo Omo a i wo o Omo ojó oyè rè àti ojó Oba Ojó ire ni Mú wò o, ojo tí won n sorò rè Ojó náà ojó ire ni Bólóko n rook, bólódò n rodò náà gan-an ni Towá Ìgbájo náà ni maa se Kábíyèsí, kádé pé lórí Kí bàtà pé lese oba wa Ìgbájo la wà a ò tíì lo Háa gbó, eré ògún n jawójasè Níkùn àwa, ní a se dúró Tí a n memu Àwa Àjàní ìkó Ògín gbèdu Àwa lomó erú owá Omo Ìjèsà modù apònàdà Omo eleni ateeko, omo eléní ewele Omo Ìjèsà, ìbèrèkòdó ará ìlú èní A mo oye wa Omo owá bòkun bùsì Eè rí i omo owá ni ìlòrò omo alagogo memu Ìgbàjo nínú ilé bàbá àwa gan-an E máa gbó A kì i mèhìn òrò A kì í mojó à í sí nílé Tí wón a ní kí a wa sòtàn ìbílè baba wa Ni won se fi le wa lowo gan gan Kí baba wa to lo sájùle òrun Ló ti so ìtàn náà fún wa Bí oní ìlówá, ìlú ìlówá Bí onígbájo ti ìlú Ìgbájo, bí onírèsì Bí won se déle Obòkun gan-an ni Ee n mi báyìí òbogi nlá nínú awo Mo rí sànpònná igbó nlá domo esì lóògùn nù Àbúrò kékere léhin mi bó bá ti rí Koo là á mole gan an ni. Tòótó ni béè náà ni Ìbà lódò àgbà, ìbà lódò Ajunilo Mo ríbá mo nbà lódò Ajunilo Ìbà, ìbà lówó Òkó tó foríkodò tí kò somo Ìbà lówó Òbò tó soríkodò tí kò sèjè Ìbà meta laa jé nile aye Ìbà ònà je ìbà ònmu Ìbà ònà se wùrùkù wojà Mo nba, mo ríbà lódò baba tí bí mi lómo Ìgbájo ni Ìlórò omo Alagogo memu Bàbá re bàbá mi, Àgbà tí kò yokùn Ahun ló ní, Yòkòtòyokùn nikùn Ajèpà Níbè gan-an. Àgbà tí kò yokùn sebí ahun ló se Tòótó ni béè náà ni Ìràwé igbó ló n bo àsírí igbó Irun orí ní n bo àsirí orí Bí kò bá ní pe a níró Kínní òhún jo ara won àbi kò jo ara won Bàbá mi lomo àmòmòmúmú Tíí dékù bomo nínú igbó gangan Omo ekùn tíí ké tí àgbà n bèrù Tará ilé tará oko ní bèrù won Béè ní, tóótó ní béè náà ni Kínní òhún jo ara won náà gan-an in Kée wenu okó, kee wenu òbò Kée wenu ìgbín o jora àbí ò jora Maa gbo òótó nì béè kúkú nù un Òkan bíi ikun bí ikun kì í tùn lobo àgbèrè Òkan bí èjè bí èjè kì í tán lobo abiyamo Omo owá, omo ekùn tí àáwò jelè Omo ekùn múnije gbáriwo Ere gbénimì tí kò je nnkan Omo ekùn ajèran tòun tìrù Eè rí i, bàbá mi bàbá mi Ìbà ònàje, ìbà ònànu Ìbà ònàse wòròkò wojà Ìbà lówó àwon ìya ni òsòròngà Ìbà lówó elúpekún Èyí tí n somo yèyé òrun Àjànpèkun èyí tí i somo yèyé òná Ìbà kí a nbà kíbà wa máa se Torí bi èkòló ba tí ríbà ilè a lanu Omodé ò gbodo morúko eleye kí eleye pa á Àgbàlagbà ò gbodò morúko eleye kí eleye pa á Èmi morúko àwon ìyáà mi Se e rí i mo di ewé òji lónìí Kí won o máa fi tèmi jìn mí náà gan-an. Bó bá ti n ni o máa là á lè gan-an II Tìóótó ni béè náà ni gan-an Ìbà lódò bàbá mi Adéríbigbé o Ògúnnìbon Nítorí a ri sànpóna pa wón tèwetèwe Ìràwé òrà tó n to titi kitòrìn Àgbà ìmòle ni kò sí fìlà lòrí Ta ló ní n sí ìbòrí mi memu o Kábíyèsí oba ní ìlórò Ta ló pé o sí ìbòrí re Se bí emu ni won n fí mu ní ìlòrò Omo alagogo memu ni won gan ní ìlórò Ìgbájo ní ìlórò omo alagogo memu Ilé Onígbájo mo wà n ò ì lo Awon lomo agúnlòyè bi Òyìnbó Omo òsùpá tí ò gún ojú là rorooro Mo rí won ní tèpó, mo ri won Ní tolóógun tolóógun. Mo kí won ní ti ìjòyè, ti ìjòyè E bá mi kí bàbá mí, Adé á pé lérí Bàtà á pé lésè Àsodúnmódùn ni sawo àsodúnmódùn Àsoròmorò ni sawo àsoròmorò Bàbá oó pé lórí oróyà gan ni Bàbá mí pé lórí oróyà gan ni Omo alagogo memu O lóhun tó selè níbè gan-an tí won fi n lagogo memu Èmi Àjànì ìkò o kéwòn sómo lórùn Somo di jinni jinni Omo ilé ò gbodò gboko lówó won Òsìkà èèyàn tí ri ara pè mó bébè ònà Bó bá ti ri i ni o móo tè mì lódù Gbangba ni oró n pa eran Lónìí nil ala á lù gongo á so E sé, mo n gbò Etí mí ò dì èrìgì mí ò se gèdègbè Ìwòsí ehín kò sí lénù mi Ègbón ere lègbón mi Kábíyèsí o, kábíyèsí, E ti sodún odún yìí Ee se tèmìn táyátomo Isu omo a jinna fun yin jè Èrè lobìnrín n jè lábò ojà Máa gbó mi gbórò enu mi Olúyawó orúko Ìyá ònà Orítaméta abìdí pèré Sekete pérè lorúko èsù tí n be lóríta méta I Okùnrin dúdú tí won fi n la ìlú wo Ìgboro O seun àbúrò mí, Èsù ò ní se ó, Èsù kó dákun mó se omo enìkòòkan Èsù ló se ìyàwó ojo kerìndínlógún Tó lo gbé tóró lórí ebo Iyen tun se sii nibe Èsù éè ní se omo èni kóòkan nínú wa Torí àwa ti mo orúko tí won n pe èsù Nígbà àárò gan Eè rí i eré ògún làwá n se látàárò gan Ògún dákun dábò má kanwó kansè Nílé àwa Eè rí i ògún onírè jasìn gan gan Ògún ilé làá bé ká tó bé tòde Ìrè kì í se ilé ògún N se lògún yà nírè lo memu Ìlé Ògún n be ní ìlájèrin Eni e bá rí e bi Méta nìyá ògún bí nígbà àárò gan A moye won tí wón bi gan-an ni Ìyan tun se sii níbèun Òtító òrò kò pé a mó so òun Eni a bá tenu rè gbó Ni yóó di ìjàngbòn Erin máa gbó òrò enu mi Baba rere bàbá mi Amólésè bí Òyìnbó baba ìbítóyè Oba ìlú ìgbájo nílórò omo alagogo memu Pándèré fò na omi na òkìtì Kí eye máa dárá léhìn eye Ìgbájo nílórò Omo alagogo memu Eye kékeré gbére rè yìí gòkè àgbà Bàbá rere bàbá mi Awon lomo ma wo o Ó jo baba àbí ó jo yeye re Nílú Ìgbájo, nílórò omo alagogo memu Omo onígèrú àjòjì kò wesè Àjòjì tó bá wesè níbè a deni ebora Omo a rìn wéréke a rìn wérèke Omo a rìn wérèke wòlú Orin: Gbogbo òrò ta ti mí so látòórò Ògún ló ní Gbogbo òrò tá ti mi so látòórò Ògún ló ní , Ògún onírè jasin oko mi Lákáyé ejemu olúwinrin àjàngbólóngò Ògún dákun dábò má kanwó kanse nílé mi Ògún ò ní kanwó kansè nílé àwa Yanpon bi ogbé Ayánpon níràn a sòwó èjè Ìpètè tii jori aláìgboràn omo ni Olúlànà lorúko ògún láárò kùtù E má je á se o . Èèyan tó bá mògún onírè kó yànírè ko lo memu Ìgbàgbé ò ní se omo èni kóòkan nínú wa. Oò rí mi báyí òbogi nínú awo E máa gbó nàsíà lénu omo olóde O nse báyìí làá se é tórò yìí fi a gbà o Báyìí làa se e tórò yìí fi a yóò Owá òjií lowá Igbájo Won a pe èèyàn jo Wón a lu agogo fún èèyàn Emu tí oníkálukú bá da Ní ìgbà ti ìgbà bá jo Ìgbà yìí má jo nìgbájo Omo owa igbájo ni òtín yéye Omo òjìí ni òtín yéye Akínkonjú èèyàn làwon ìgbájo Esó làwon Ìgbájo Ìgbájo ló mú ìbàdàn joyè Omo- a – mú ìbàdàn joyè Ìkòyí èsó omo ogun ìbìro Ìkòyí ni mi Àjàní ìkó Omo oníkòyí bó bá gbofà létùn Ojo ló se Omo Ogún burú èsó ò déléwì Omo ogún burú èsó ò pe ara won lóóko Bí mo bá n rónú Ilé bàbá mi Èsó ni mí èsó làwon Ká jo máa só ara wa ni Ìkòyí èsó ni mi omo agbòn sú bèlèjà Bí a kò bà ní pa á níro Ká pa teré ti kò pa àwàdà tì O ní ohun èsó Ìkòyí òun Owá Ìgbájo Tí won jo di sérù ara won Ìgbájo náà kúkú nù un Sùgbón n kò fé káwon omodé wònyí Ó kó mi sájàgbón òru ni Tórí a bàá mèhìn òrò A bàá mojó à í sí níle Tí wón a so pé kómo eni Ó wá sorò léhìn eni ni Torí omo eni ní sorò léhìn eni A baa mehin oro Tí won á ní kó mo eku ó wá sarò lehìn oku Torí omo eku ní sorò léhìn eja Omo eja ní sorò léhìn eja Torí omo eja ni sorò léhìn eja Torí bája bá lo níbú Omo eja ní sorò léhìn eja Omo tèmi ní ó sorò léhìn mi Omo ti gbogbo yin náà ní ó sorò léhìn yin Yóó se yóó se kò ní gbáláìse Torí mo bólósé lónà mo dè wese Torí àwíse ni tifó Àfèse ni tosanyin Tìjínmèrè náà ní se láwùjo òboginínú awo Èyí táa bá ti wí lóní larò ó rò mó Ó ti di dandan pé kíbà wa ó se Torí a ti se iba Kí a tó wonú ilé odù lágbàde Ìyen tún se sì níbèun Ológbò n lo Oyin a gba kókó igi E má ko mi sájàgbón òru Ó n se ògún ló ní ò Ogun lo ni Orí ló pé mo ti bi Yémisí o Ògún ló ní Orí ló pé mo ti bí yémisí ò Orí ló pé

[edit] ORIKI OBA ÌJÈBÚ-JÈSÀ

Oba Ajífolókùn sayà Nlé Obà Ajífolókùn sayà o Ijebu Ògbòrò omo awúre fàse banu Omo aborí yedé Aborùn yejigba okùn Abiségógó owo yìn-ni-yìn-ni Nlé Oba Ajifolókùn sayà o Òkú ìjèbú ò sunlè pèpè Ki an kú lomode À sokò won rebete Eran kuku jumolè Kan yòkòkó nù Mo mi re yalè re Onile mi relé Ìjèbú ni mo mí rè o Ìjèbú mò í sàrùn Kán lo bugbá rè fún bábá re Oba Ajífolójùn sayà ò Bi a à bá pa niro Oba Ajifolokun, Láìkú èkìrì E si eni a fawo re sín gbèdu Ó jo bàbà rè tojú tenu Omo ó jo bàbá rè ló gbèrí ìyá jé Pele ògùrò, bí a sínlà sègi Omo dára ó jegbin lo Mo ba o milo bi ibi ekòló bójò Lójó o joyè níjèbú jèsà Emi ni o Onílé òkun ègbele omi Àlàní baba ìyábo o Èdùmàrè mo mò jékú poníyì léyìn gbogbo wa. Ebá mi sàmi Àse Torí pé kí n tó jáde nílé Mo ti gúnyán lálò Mo yanko látupa Iba iyami òsòròngà Apani mo wàágún òlókìkí òru E jé kóde òní ó aan mí Bekolo bá ti juba ilè se ni í lanu Nlé oba Ajífolókùn sayà o O dára díè jobìnrin lo Okunrin lúbúlúbú bí emó òyìnbó O bómosùn fewà remo Ògbòrò omo Awúre fàse banu Erán mò kúkú jumolè Kán yòkòkò nù. Òkù ìjèbú ò sunlè pèpè Ki an kú lomode À sokò rian rebate N ó mo o pè ó nigba gbogbo Oba Ajifolokùn sayà o. Méle kìnìyàn sàrà Ki mí mó sè kirà mi Oba máa gbó Irú mí kojá Ajeèfiyin ni Oba aborí yedé Aborùn-ún yèjìgbà okun Abigba emu kàrándudu Omo Akólé ebora méyìn rè sefun Bílé á reni reni Labalaba ó bá dìgbò lègún Aso rè á fàya Etí wonran ló bóyin Emi mi mo n pe ó N ó mó o pe ó bí ológún erú N ó mó o pè ó bí olójì owòfà O jo bàbá rè tojútenu Ò sùn sílé fèrán tìkùn Bí ò si nílé egbé rè n bèèrè rè Labalábá ó bá ti dìgbò lègún aso rè á fàya Ó ye ko mò wí èmi ni Kábíyèsí máa fi kèké lérò mi Mo mo jámi sílé bí ìbì isòbò jéyìn Torí àgbàlagbà ó bá ti dé òbòn-nbon-ùn mó fìlà, Etí rè á gbáriwo Tègbá tijesa ló mo kékùú otan Sebí o mò wí èmi ni A jo je lórí ewé A jo sùn lórímò A jo falawe aso kan bora bi aso Láìkú èkìrì me reni a fawo rè sín gbèdu Mómò rook tuntun lójà ko so èkùkù èsí nù Ò a pé bí ara ìsaájú Ò a dàgbà bí ará òórò Gbogbo ara lalágemo fi hulú Owo olubi ò ní térù re Mo dé, mo fé mó o lo rèjérèjé Bígbá seé lo lójú omi Òréere òré mi ni Ògbó ológbó omo olómo Ogunlaye n be ti o mo o sèdárò mi gidigidi Kabiyesi òbóra sílè sobìnrin lóore Akoki onímolè okùnrin dan-in-dan-in Ope sigidi lótí òrúbe Jagun aró mó bèrù òtè Ekùn méfà ló wà nílé odi Loro lo pèfèèfà-a –nì Yeye re má a dele oni Ki obìnrin ròrò mó nù Omo onigo tíí dán bí ide Ki mo bá tètè mo wí ògùrùgàgà n lò ó ró memu ní ìjámò N ba ragogo sile dèkími Omo ejìwòwo Eye lákó nu o mo re lónà àrà lótò N ó móo pè ó nígbà gbogbo ni Ajá a gbàgbé olóore Aja a jámo léyìn ekùn Omo ra já sonù léyìn re Ijebu òtín sìn Lábáawú Omo a là kílè mó Omo a làkàkà kéé jèrú ebo Ìjèbí ò sunlè pèpè Kí an ku lómodé An sokò rian rebete Onijebu fakóto múròóko Eran kúú jumolè Kan yòkòkó nù Òkòkó bìrìkìti lé é yemolè níjèbú Ota fori yeje Kabi an ko níjèbú nígbà to n ti àwòdìí bò Agboja ona ni mo ko níjèbú Omo egbùrù kò yàgàn Omo egbùrúyà kéé rí bí eni bake làá somiye Òkú ìjèbú ò sunlè pèpè Ó ní bi an kú lómodé an sokò ri an rebate. Omo afun ni ni ohun je nígbà an an fìkèlè kàn pòrúndúnrún Omo mórà mora ó ra igba eni lórijó Ekun méfà lée nílé odi Lóórò ló pèfèèfà rè. Àtijé Àtìjè ni lóógun ti í fawo ekùn dìlèbé ìdí Gbògbòrò bi esia iyawo Ajikosun bi iya egbin Omo onígèrú Àjòjì kò wesè Àjòjì tó bá wesè níbè á ti eni ebora Omo Alágbòójà Àgbòjàkàn tó forí jeja Omo Àgbójà omo Afejagbori Omo oniroko ó sagogo mokun yinbon ode Àgbà ìjèbú sagogo mókun Ìrókó kan n be nílé Ìrókò kan n be loja Omo oniroko méjì takotabo Omo Àgbà ìjèbú o sagogoo mókun yìnbon nigbo eerin Omo arogogo igbó pónyè, isin ebora ni Iba lowo omode Iba lódò àgbà Ìbà loso Ajídolókùn náà gan ni Ìbà lówó kékeré Iba lodo àgbà ti n be lodo jàgan Nijèbú-jésà Ìbà lódò won ode tí n wón n be níjèbú-jèsà Torí ògbóni ló leréjà Abíódún móo gbo nàsíà orin mi Ìjèbú jèsà sebí àwon lomo onigeru àjòjì ti mo ní won O gbodò wesè náà gan. Àjòjì tó bá wesè níbè A deni ebora Omo Arógògò pon-ón-ni ebora ni se Ogun n be níwá Ogun n bò léyìn Ògògó wón wá gbojú ònà rere-mù reremù O lóhun tijebu-jèsà pèlú ìwó se Tí wón jo papò níbèun Ìwòyè ò jìnnà síjèbú-jèsà E e ri omo Amookin yìnbon nígbó eerìn Oye ode ti wón lo síbè gan won ò dénú ilé mó. Ode tí wón lo síbè won ò padà bò Ìbà lówó oniroko gan Sebi ogboni lo lereja á rè gan Tó fi wá fààyè fówá bokun gbùsì To ní kó móo mó mi sorò nibè gan N ó mo o sòrò, N ó mó o yo kòmóòkun ni Tori emi o ni si ninu ilé Sùgbón ohun tí inu bá ti wí sílè omo náà ni o bò ba ni Ise orí bá ti ránmi lemi ó móo jé Ònà tóòsà là á le N lèmi ó mo o to Ònà ni mo tò tò tò Ti mo fi délùú òsorogíso Abuké ni mí, n ò ni seé sá lógbé Ìbà lódò baba Ìbà ìbà lódò baba ba bàbá mi Ìbà lódò pétélé owó Ìbà lódò pètèlè àtesè Ìbà lódò àtélesè tí ò hunrun dójúgún Ìbà ìbà, ìbà lódò òpó ilé Arerù mósò Oríta méta pèré mo juba lódò baba bàbá mí Akátá nlá tí dá gbòrò sìrìn okùn Kìí fowo lùdí pèpèpè Elékùn un gbàmí babá dé omo yà léyò Ò ò ní san kú Kómo bá pe o mó se ti e Bí légédé bá yowó ìjà Ilè níí fi í nà Iwase tìyìnsé lomi agbò mí jo dánù Àfòdànù lobinrin n foso àlejò Òtún òde àbà Ló lífá fún Alálàde Àbà Òsìri Àse ló tun dífá fun Alálàde Àse Àtòtún Àtòsì ló dífá fún won lóde mòsé ewélé ríjósí Eran tóká bá ti so Enu oká níí kú sí Ako lo bá perí awa nibi ni Jìrìn jirin báyìí lese n bò ojà Àwa won la ó sorò olúwa re Aho ní bá pérí àwa nibi Òdómodé ni bá perí àwa nibi Olokùnrin olobìnrin ni ba peri tèmi Àjàní nibi Emi won la ó sorò oluwa re Yíò se yíò se kò ní sàì se.



[edit] ORÍKÌ OBA ÈRÌN-ÌJÈSÀ

O sé Akínlà bàbà mi Òré mi ni òré mi Akínlà o Akínlà ló lèrìn Akínlà èrìn ó joba Ibòmírìn lo Èló èrìn kí an mí je léjà méfà sí Wón je nire àlúà An jèhà Àlúà Ó ku dedere lódò ojà Ìgbeè ni wón je lémèdó Lemedo èrìn Abòmo esè bí ìwo etu Akínlà ó ti mí je Mé ti ri yèé rí Omo Àjíké Àjígè lódò ìyá rè Regbodo bí ìyàwó Ajikosun bi ìyere jéje Akinla’N o mo sèdárò re gidi Tori ajá à a gbàgbé olóore Emi re meji wèwé Ore re òré mi ni Oba tó je tí ò bole se lérìn Akeekèé wá di gàárì Baba ta ni yíò gbé e sin Wón pè ó lorun o ò jé O feso finfin so hun sí an Kórí e máa dàwón ká Orí Efòn a degba eran káko Won ì í pé jiyán àná Òtá rè ò ní rójú sojú Akíríboto kìí lójú awé Èlè ìlèkè kìí lójú àtokùnbò Èyí tí mo wí Arò á rò mó ò Àlàní o mo ebora gbàgbé eni Tí a ò gbódò rójú rè Odùduwà ló bí ìyá mi Erin de tipè tipè Àgbààgbà àgbórín mo dé tòun tòwo Aja kìí gbàgbé olóore O mo oloke ojà níbi igi gbé já lósàn án gang an Kaka kígi dá pami Màá ròkè ojà Kabiyesi mo juba lódò re Kí n tó máa lo Bekolo bá ti juba ilè Se ló ó lanu fun Èmi re méjì wèwè Bí ojú, Bí inú bi àtélesè òhun ònà pimù Orò baba yínká nlé o O sodún odún yìí o a sèrèmírìn Odoodún làá bágba obì lórí àte Ìyen béè Igbo oba odò lo fìyà jomo arágan Bi ko bá sí tìyen Ta ló n jáláta Tí ata rè n tani Gbogbo aláré tó wà nílè obòkun Àlàní n ó mó o gùn wón nígùn eran ni Tori ekukéku kìí borí asín Eèrà kéèrà kìí borí Ìkamùdù Àlàní mo ti juba bàbá mi Bekolo bá ti juba ilè Se lóó lanu Eye tó máa beje ké Enu re á béjè sere sere sere Se ní won bí eyìn mó èètán Se ní wón bí soso mó odi Ìbà bàbá mi onile òkun egbele omi

Orin: Kó rorí kó pé o Kó rorí kó pé Eni máa bá wa rin A rorí á pé. Kábíyèsí oba o Kábíyèsí oba o Kábíyèsí oba o Oba Ajínkà lóbòkun Oba nlá Akínlà lóbòkun Oba nlá Akínlà lóbòkun Àpèlé Àpèlé lorú à n poba Won kìí poba lápèdín láàfin Kábíyèsí Owá máa gbádùn ara re lo Kábíyèsí Owá máa gbádùn ara re lo Ìjèsà ni mo mo wà Kí mo ti mí pakínlà mo mò so Mo bínú pé mo bá o lóyè Mo pè ó lórúko Mó bínú O dodún odunni o O ó se tèèmírìn O ó se tèèmirin taya tomo Tàìkú bale orò Isu omo á jinná fún o je Èrè lobìnrin mí je lábò ojà gan ni O dá mi lójú o Òpá eku kan láyà eku Òpá eja kan láyà eja Ina lo mi siwaju òpàná Iná tó ràn ló n síwájú eni tí ó pa ohun Kànrìnkàn to bá ti búsulésò Won a fisu sínú ilé ayé lo Inu ilé ayé o lota a fi ó sile tí á lo sorun alákeji Inú ilé ayá lá padà wá bá o Kaka kó o gbélé mó o sin nígbà gbogbo Kò séwu légbèrin èko Kábíyèsí oba o Kábíyèsí oba o Kábíyèsí oba o Ìbà lówó Aklínlà tó lèrìn òkè Ìbà lówó Aklínlà to tèrìn òkè Ògún ló ni mi Ógún ló se mi Ògún náà ló ni didi mi tí mo fi n soko Abiyamo Báà bá ní pá níró Sebí Akínlà lo lèrìn òkè Akínlà lérìn òkè Ikú ò ní rójú pa ó Ikú ò ní rójú gbomo re lówó pe Àmó sá iré tiwa juré Àdàmò A ní ká feré Adamo Ká fi jálùbósà orin si ni To ba se díè sí Ò á máa gbó nàsía omo ode Akínlà lérìn òkè Wón níwo lo nìlú bàbá re Ìwo lo niwón tadétadé Ìwo lo lojà kan òjà kàn Ti wón pa ti ríbè gan Iye lérìnmo Ìbà lódò re Iye mi lérìnmo Iba lódò re Iba lódò bàbá mi lórí awo lèrínmò gun Lori awo mo kàn lodo re o Kékeré èrìn mò gan Àgbàlagbà Èrìnmò mo ni mo kàn lódò yin Torí ààtan kò ní lo kìí kódèdè Odede ko ni lo láì ki àdeun Obalúyé kìí lo lai ki tòrun Kó tó mó o lo Ìyá ayé mo kàn lódò won Orin: Obalúayé o Obalúayé o Mó mò jógbìgbà gbé si lóhùn o Ó tó onílù mó lè le À ì tó onílù a dìjà È è rí mi báyìí nù-un Mo mí sere ìhímàgbon mi fákínlà Sùgbón ògún ló bí Ajínlà nigbà ààrò gan o Bó bá ti wí ni ko tè lódù Ìjálá ni ko fi máa wi

O o ó o Akínlà kínlà kínlàdé Náa gbóhùn enu mi Akínlàdé o Akínlàdé o Akínlàdé Ìtì ògèdè kò pé kí won mó fòun sòpó Eni màa dúró lábé re mó sàfira Ó ye kí mi kókó máa juba lódò bàbá mi Akínlà Akínlàdé o Òsùpá Ìlekì A dénú ilé kìji kìji Akínlà ò Akínlà o Akínlàdé o Akínlàdé se bi òun ho nìlú èrìnmò o Èrìnmò osere omo onílè obi o Omo Ajipori ori nì ni bóse dára ni láwùjo Orí bá mi se o Mé mò le nìkàn se ó Oba mímo Akínlà lérìn Ìjèsà o Bá mi se o me mò le níkàn da se Ko séwu légbèrin èko Ìbà lowo okó to doríkodò tí kò somi Iba lowo obo to doríkodò tí ò sèjè Ìbà lówó pétélé owó ni láwùjo Ìbà lodo pètélè àtesè o Ìbà ìbà Iba sá n o moo fòní jú nígbà gbogbo O dá mi loju o Oluwonkoko mo wi pe mo wonkoko mórò enu mi Mo roar n kì béènì gan Torí wípé o Bàbá ire bàbá ni Akínlà Won lómodé ló lori Àgbà ló nìtà Àgbà ni mo dà yìí Ijó mo bá da dé Màá relé oko Èrù ò bà mí Mo dérù barà mi Mo wá tejo mólè Mo se bomo eku lasan ni Emi Àjùní mo tún wá dúró gbofà bí ògiri gbígbe Ilé Akinla ni mo wá, n ò ì lo Nílé Akínlà tó lèrìn Mo ni sebí Akínlà ló lèrìn ìjèsà Omo won lerú owá bòkun gùsì Owá owá Ajímókò náà gan an ni baba won E è ri Akínlà to lèrìn Tí n bá n le sílé Akinla tó lèrìn Ko sénìyàn tí jé tepo nìlú Èrìn Ko sénìyàn fí ó tepo nìlú Èrìn Èyìn odi làá pade o Ho léyìn odi làá pàdé E è ri ikú oníkú kìdán n gbàákú Ikú eníkú lèdìdè á gbà Èhìn odi ni n ó mo o pòtá mi Akinla omo odo Àgbà Ehin odi ni won o mo o pòtá re Tori ehin odi ni won ti n tepo nilu Èrìn Iyen tun se si ni yen Ìbà lówó owarí esèsù Ìbà lówó owarí esèsù Sèbí owari náà lo tèlú kan To se were, tó se wèrèjè Ìpólé ni mo tun lo re e ni Ìpólé ni owári ti dìde ogun nígbà gan To ti le sí ìlú èrìn Òhun ni won kìí se é polówó epo nílùú Èrìn Bee ni ko sénìyàn tó jé polowo epo nísókùn náà gan Erú owá bòkun gùsì Àwon lomo bépo lorun A bèjè sórí ògún sùrù Akinla dákun dábò Mo bínú pe mo bá o lóyè Mo pè ó lóruko Ògún ló so mi dòdájú gbagara Tí mo fi pe bàbá mi lórúko E ò rí mi báyìí bi obo igi nú awo Sanponna igbo la domo esì lóògùn nù Òògùn tí ò bá ti jé Ewé è ló kù kàn E è ri emi Àjàni òpò oògùn rumo gàlè rumo gàlè Mo gbójú lóògùn títí Mo somo Àjé níkòó Mo ni kí làjé ayé fé fomo Àjá òrun se E è ri mo lákínlà ló lérin Ke dákun dábò ko mo mò bánú ni Akínlà ló ponifa aare gan an Ó ni onírá, ìlú n dàrú Kini òhún ò tilè rorùn gan Akínlà dákun dábò fiyè dénú o Bí mo ba puro kóo móo te mi lódù láàfin oba O ni ilu dàrú titi O ní kí ló dé gan an Tori àdàgbà kúkómo lodo ló lèrìn E e ri onífá òhún wá dífá fún won Ifa ti won da lagogo jegele ti so mó won logbob iperin Lonifa ba difa O ni o dijo ti won bá lo Mojòkótèje Ìbà lodo won Àdàgbà kúkó mo lódò ló lerin Iba lodo won E e ri Orin: Ó mí se ma fomo sáyé mi lo o Emí ò ni se bayìí ku o

Ègbè: Ma fomo saye mi lo Kini kan selè lerin in mo fe so Nijo gbóun níjó gbòn un Ewúré fòpá ti Wón pa lóró kún Won se pé kò si nnkan Àgùntàn fòpá ti Wón pa lórúnkún Wón so pé kò si nnkan Ohun to sowa lo yo náà Se erí i kini kan selè nílé Akínlàdé nijo si Kabiyesi kabiyesi Oba nílùú Erin Bee ni béè tòótó ni Béè náà ni o ò O nijo ijó náà ni àtìyàwó rè porogodo pátá wón lo símú oko Won teme si ààlà won lo sínú oko tí wón ti n sise Won ò mò pe ìgbín ti rin mó aso ìyàwó akinle nijo hun Mo o gbo Etu igbó ri mi o tadi reke o Sebi etu ijósí mo eni o pà hun Etu òbèjé alawo tó wu ni Abikoko gbon ni Ipere lo dìjà Sùgbón omode o gbodo pìtàn ìpòrí o E e ri tán bá ni ka móo só ó O lohun ti won fii so níhà ibìkan ni E e ri Akínlà se bí won báyàwó òun se ni to moo be won le E e rí, Ìyàwó ojó kìíni meni tó pa òun Torí Akínlà ló lèrìn Se bi omo Ìyàwó ijo kìíní Tomo tomo ni won fi rubo níbè E mo ko mi sájàgbon ni Tori oro n be lódò ikù mi Emi Ajani ko sánmò mewon jìnnì Orin mi náà ko orin bàbá mi ni Aranme agé é Jigab jigan ni tèrìn Òsòroógùn bí igi òbobò , Kábíyèsí oba Akínlà béè ni Kabiyesi mo ríbá mo ríbè Ajunilo Mo forí balè lódò àgbà Kábíyèsí oba o Oba nlá Akínlà béè ni Tooto ni béè náà ni Kìí bá ran won ón règbé Afi kóo ran won kí wón lo peran wánú ilé gan-an Kabiyesi bee ni Oba Akínlà lèrìn òkè Sebi Akínlà ló lerin ilé Akínlà lo lèrìn òkò O gbodo gboko lowo won ni Sebi Akínlà yi lomo Aloso modìí gbagbon lówó omo ojo Eè ri èrù ò bà mí mo dérù barà mi ni Omo amomo rubo niwon Omo bibi inú oduduwa ni gbogbo won Omo Olofin ni Iyen tu se si nibe yen Atoto arere Atòtò arere Ale ò ni le komo ejò mó rìn Tomo eku ló nira.



[edit] ORIKI OBA OWA OMIRAN ESA-OKE

Omo Owá ùn mí bèrù Omo Owá tó n ba teni Kí mo kánlè yánhú nílé Owá Kí mo fèwù ògbò telè I èwù ogbo mo fi telè I é dùn mí I èdú a máa bá tègbe mi lo Omo Owá bìdí òbèlèsékè Omo Owá bìdí etu ganganran láàfin I gbèrin opó ló mú tile O bèfèèfà luyì Omo elégbèrin àtùpà Omo elégbèrin àtoro Omo elégbèrin àwò Kí an fi gbogbo rè sobè sí láàfin Omo olúlé kí an gbúkú àjòjì í wò Kójú á ro omo alòmírìn Omo apàgbò sójú obo mú tòúrò lo ààfin Àgbà ìkà án I jeran rian lórìjé Omo apódìyé dìkàrà sokè Omo apódìyé romi apata Omo òkè kike oke apata Tí won n pèyè òwè lowè I se ni mo dàgbà Kí mi ya susé èyo mèsíò Ibi an pèyò bí eni pesú èyo yéye Omo olókè ìyòdú I òkò rú ìyò kí mi lá forí òkè í kàn Òkè rú ìyò, kí mi lá sulé òké sara dota nílé mi. Omo àkàràkàsà nílé oko Mó jé èyìn òbùn yílè Omo elébíbó oko kee yó àgbùnrín Omo ìgbàdo dì órí ó pomo bò Omo akébìyé ra ìkàrà sókè. Omo akébìyé romi apata Alè igbó ota ni òmìràn í jà le omo onímògù. Òmìrán ló ni igbó ota Òun náà ló ni alèpèpè ìtómì Àlè bàbà ni a fi dáni Igi oko afín bí dáni Igi mo bá jí gàdà òkon Ki mo bá jí gàdà rolé soji Má rìnà òru bò Àbùjá ulé oní mò Ará ulé oni obibo Ó jí dàgbà ògèdè O bómodé yìnbon ìdájí I mo gòkè ògèdè Mo dojú ulé ùkirè àkàlà gbojú òhún I jíje jíje é sí Àkàlà bà I ùsí àkàlà bà titi O relé ùkirè ria lópé òjé I òtún ulé ria ní tíkire Omi ni I oní bá ti sàbùjá ulé ria nírikirè I ùgbèe láá bá apá òjé lo Eye ba lori ugi Ugbeè lòmìrán yagba ode Ubí ìbòbó dúró sí Ùbòbó bòdì àkankà I àrìmòtíta lúbè ló ta Òríndín èjo Omo èlùjé ùsà Omo èlápó í ta bi èsúru Omo alápó ípa ni Sílè kó kèìyò sílè Í koni mo nikan sun Kóni mó sìkejì oni II kóni mó tùmò sùn ÍI kóni mó sùn úlé Kóni mó sùn alè II èrù òmùjé léé bà mi Omo asaújì ùgbì òsùpá là Omo asáújì òsùpá jère Ugbi obinrin gia goroni Kókùnrín kàn tia se I kí mé ba rolúgi I mèbá rònà èsà laa yà I kígí yà ke yà I òmùjé a figi narùn Omo olúmòjò Omo owa omiran Omo olúmòjò Omo otafatafa Ta ihò okinni Omo loupe ekutu Kían jí fon túùrú Taara lónà Efon Ìbílè obòkun ni èsà òkè wà Ìbásepò wà láàrín Ilésà àti èsà òkè Ìyàtò àárín won nip e láti Ilé Ifè Ni èsà òkè ti yà wá tààràtà Owá òmìrán jé òkan lára àwon tó te Ìlú Èsà Òkè dó Pelu ojòkò ati Òsòdì. Agbo Ilé Àdàgbá ni àdúgbò láfogbó Ní ifè ni òmìrán ti wá Òmìrán kúrò ní ifè ó gba ìgbájo lo O kúrò ni ígbájo ó lo tèdó si òkè òwu Ó jagun ni òwu labe Owa àjàká Léhin èyí ni won tún tèdó sí Orókè ní ìhà gúúsù Èsà Òkè Lóbé wà ní òkè ìtá Lósì wà ni ìlórò Asába je babaláwa kan láti Ilé Ifé Wà ní Òkè Eèsún Èmìlà náà sì wà ní Tòsí Owá òmìrán wá sí Èsà òkè ni ìgbà ogun èkìtì paràpo Ku bí igba odún Won jagun lábé pákú Àsìkò Owá òmìrán ni a tó ní agbo ilé tí ó n joba Olumokò mi àbúrò òmìrán Olúmoko lo tèdó sí Èsà Odò Agbo ilé Èsà ní Ìlú Ilé Ifè Ni àwon méjèèjì ti wá Owá òmìrán bá òpòlopo èèyàn sore Láti mú ìlosíwájú bá ìlù Lára won ni: Olóyè Ògbóni láti ìnísà Olóyè Asálú Ìsálú Odobaja náà dúró sí òdó Obafin ni Èsà Odò Obafin ni Olórí Agbo Ilé Ìdòfin Owá òmìrán yan Olórí nÀdúgbò Àti Olórí Ogbon Láti máa ràn án lówó Láti se ètò Ìlú



[edit] ORIKI OBA ERIPA

Eléripa e n lé n bé un Àbíyèsí Oba Sákì Oba tí n ba lóyè n lèmi n ké sí. Oba tótó mo lémi o kò perí Oba Oba ná n perí re ní Sókótó Mo lémì kò perí Oba Eléripa àbíyèsí ni wón n perí rè ní Sàbàrà. Àbíyèsí ni wón perí níbi gbogbo . Apórógunjó omo akúnlè bógùn sòrò Onílànlá omo erù Ofà. Omo Òdógbó ní Ìkòyí Ilé. Béè ní omo Òdógbò ni gboro. Omo ò síjú yoyo mó kolé ìkòyí. Omo eranko méta ò lásán Líiìlí ò lásán. Béè ni Òpá àkèrè won ò loaf. Ábòsìnbósín alábà abèyìn jáyìn ó Omo igbó dídá n o lo re de ògba Béè omo ònà se rìbìtì Àní n o lo rè ko òrúnlá sí. Omo ogun lósàn-án omo olè lóru Olè tí kó aso kéwù kó Omo gbórógunjó onílànlá Olè tí gbé obìnrin eni tí fi saya nì ! Bí Obìnrin kò bá se omún rògbòdò Tí kò bá se Ìdí rùwonwon nílé ajikánle Tí kò bá lábe lórùn mó fe Pórógunjó onílànlá omo erù Ofà. Ìkòyí tí ròde rè kólé Sebí ìgbà tí yóò fi dé olè kólé e lo. Óní yoo bàyá Olè tí ó kólé òun lo. Oníkòyí ogun ìbirò n lé mo bénlé òsùn. Yekan ará ilé Ilá-esè ní Ìkìrun wa ní. Yekan eni olá Yekan atibire somo Apórógunjó omo Oba tí kú tapá torùn. Onílànlá omo arerù tú bèlè ìjà Omo pórógunjó e wà ní bèun Omo bénlé ò sùn Wón ní kí á pe lékùlé títí. Apórógunjó tí ó bá di alé won a maa dun lo. Oníkòyí omo arerù tú bèlè ìjà. É é sà o o o kú ìnáwó ojó O kú àfi omonìyàn se kòmí ògé Omo oyè niran omo tí o tó kò ní kú mó o lójú Orí re kò ní darúrú Ilé tí o kó. Kò ní jé àsemo fún o Eésà ajàdí awemo gaga reléko. Omo bàgé fújà ma tósìsà Òkòmí omo oyè niràn wá jòfé ará igbó télé. Eésà ni n ké sí baba léripa wá jòfé ará igbó télé Bérú molé Oba. Oba tí n jí wewó wesè nísàlè òràn Òkòmí elédè won a sèsó yányán Oba tóní wéré jeje Òkòmí mo lérè lómi Èjè òkòmí mo bèjè lódò Tawá lóni elédè lókòmí Ilé Tawá lo lorí ota. Ta lóni èsìsí tí símo lódò tòjò tèrùn . Ewúré ólóun oun a joyè ni kómì Ilé Nílé eésà léripa wón gbéwù kalè Won kó yan bí babanlá won ti n yan Ewúré wèwè é lè wè tán Tó fi pón yanyan lójú omi ará Ilé mi Èjè bàràbìrì léyìn orùn E bi mí ení taní joyè ní òkòmí Ilé. Ògà ni o joyè ní òkòmí Ilé Wón gbéwù kale ó wá yan bí babánla won se n yan Nílé èdùn òkòmí omo oyè nísàlè òràn. Kòmí onílè won ròdúdú Oba torí ni ó ni weréjéjé Òkòmí omo oyè niràn ará jóba jí O kun ará légùdu àyàbù èrò N lé ará òpa òpe àánú. Ésà mo mò dúpé ojó. Mo dúpé ójó o nírare omo Làlùrí re kò ní dajúrú Ohun tí gbé tò le gbé bàbá re yoo bá o gbé. Mo yìbírì mo tún padà ní be un. Mo tún lo ilé baba léripa Àgbérií Ògà olórò edùn Torí tí a bá n korin a n juba eni tó lórin Afínjú ológun tó mótò Ilè lo. Omo gbérí olá o kú ìnáwó ojó O kú àfi omo nìyàn se Ojó ò tójó tí won sìkú baba léripa Owó tí mo gbà jékan Gbérí olá omo gbérí olómo Alámò omo akúnlè bá óògùn sòrò. Èmi wá tún yè wèrè Mo kúrò nílé ògúndìran baba léripa Torí tí a n ba korin a n juba eni tó lorin Àdìó mo juba orin mí Orímodélé wí mo juba orin mí Gbangba lásà a soro pàdé oníbodè lápèrò N só léripa n só léripa Pórógunjó nlanlá n só léripa.

[edit] ORÍKÌ OBA ÌKÌRUN

Òláwálé akìnrun Àbíyèsí akìnrun o Oláwálé arékùjó oko Adéyolá Oríburúkú kò ní jé tire. Ánlàgbá omo Ojà Obì Gbólérù lakìnrun oba gbóléké olúgba Ob èyó atòrò Omo èyò tí ó ti mú ìkirun dòkun Omo èyò tí ó ti mú ìkirun dòsà Omo èyò tó ti mú ìkìrun dùn gbóngbón Igbó ò lérù mó gbogbo igbó ni wón di lómi lómi Ánlàgbá omo ojà obì Àgùnbé aágbòró pète a pósí dórí aágbòró mó Oláwálé orí òkúta latí pète ara wa. Tile oníláà omo ojà obì. Omo òkan kómi lésè ní pèté yányán Òkan ní kíni mo wá dé ìlú ète Òkan ní kíni mo wá dé ìlú èrò. Òkan ní kíni mo wá dé ìlú òdájú yányán Oláwálé ibi tí won tí dáyó ara won. Onílàá omo ojà obì àbíyèsí Oba. Oba tótó mo lémi kò perí oba. Oba ní wón n pe orí re ní Sókótó Oba ni wón perí rè ní Sàbàrà oko Adéyóólá Oko Adéyóólá ni wón n peri rè ní ìkirun wa. Àgùn-toní-jà omo ojà ebì Mo tún yí yun tì gédéngbé Kábíyèsí Oba àná tó wàjà Àkànjí tí wo mótó Ilè lo. Omo amólà oyè Àkànjí omo erin jogún olá Omo àdó bákan làdífá Erin jogún olá ebo ní ju eboó lo Àkànjí omo a rí léwò ní ìkìrun. Omo abi òdèdè làdífá Erin jogún olá ebo ni ju ebo lo Kábíyèsí oba èyí tó wò àjà. Kábíyèsí lásúnkánmì ni ò n pè mi mu gòrò. Olásúnkànmí ojó ò tó tó ójó tí oba náà wàjà Mo rówó mo rómo Mo jeran títí eyín mi kán. Mo ni odidi ojó mérìndínlógún Epo kò tán létè mi Àbíyèsí akìnrun arísekóilá Oba Kòsámótù Oba Àbíyèsí erin sí erin lo. Àjànàkú wón tí jákùn arà lo. Oba tí ó jé ní ìjerin ni n ké sí Àbíyèsí baba làmídì Ògìrìgìdì ayí ti káà wá Àbíyèsí mo lémi kò perí oba Baba jíyì mo lémi kò peri oba Oba ni wón n perí rè ní Sókótó Baba làmídì oba náà ni won n perí re ni Sàbàrà Oba ni wón n perí ní ìkirun Anal omo ojà obì gbólérù akìnrun Oba gbóléké olúgba E wá wo onílé oríoke tí ri àfòpin eye Àgùn tonílàá omo Ojà Obì Ará làyè esun alátíse e rook Oba Ará Ilé mi Òbùn won kò tagìrì sòwò. Oláyiwólá tó joba tán Ilè n tòró Adédeji tó joba tán roko Oba Òbùn won kò tagìrì sòwò Òbùn tí kò ta gìrì sòwò Àkàní ti ní kó jòkó de ìsé yányán Kó wo jábálá ebi bí tí mó já mó baba won lára. Olójà tí fi òdòdó jagun won kò wówò bòrò Baba b ólájì ti gbé òdòdó wo kógun Adédeji lóti gbé òdòdó wo òkun ogun. Àbí èyìn orùn gbé òdòdó rù fùkèfùkè Àwon onilànlá omo ojà obì Oko Adéyóólá Adédeji àkàní ire owó re kò ní bó. Eni tó bá lóun yoo bà ó lórí jé Orí re yóò ju bà ó lórí jé Orí re yóò ju tirè lo. Ti gbólérù akìnrun Oba gbóléké olúgba Oba èyò atòrò omo èyò tí ó tí mú Ìkirun dòkun Omo èyò tó mú Ìkirun dòsà. Omo Oláwálé omo arékù jó Ìlú kò ní dàrú mó o lórí Wágùnùn tí n be léyìn re kò ní já. Òsó náà n kó sé n be ní àláàtì ara. Oba Oláwálè Adédeji onílànlá omo ojà obì . Igbólerù mode igbólerù mo dé. Gbóléké igbólerù mode.


[edit] ORÌKÌ OBA ÒRÒRÚWÒ

Olóròrúwò oba Oba tótó mo forí balè lódò re Ìlú kò ní dàrú mó o lórí Òràngún omo Ògboyè Lángbóyè gbólá omo orubu Tí wá sámo láàké é Pàkàn lokun pàkàn lónà tèdè, Ewúré Olóràngún ní je lónà gbàgede Àgùntàn Olóràngún ní je lésè yàrà. À je wèyìn ló ba selédè jé yányán . E woo mo Adéjoorìn ní màgbon Yangadá bí eni wemo relé oko Bàgéfúj`da omo èjìjà yekan Olórúwò ni gbogbo won Omo Oba bi wón perin sí Ni wón n pè ní ìta aperin Ibi tí won pa àgùntàn si Ni wón n pè ní Òkè àgbò Ibi wón pa elédè sí Ni wón n pè ní òkè èdè Ni wón fi n pe ní òràngún ará ìlá màgbon Òràngún omo ògbóyè gbólá Gbóyè gbólá omo orubu Tí sámo láàké e Béè ni bàtà logun Bata lónà tèdè Tile Olóràngún omo ògbóyè gbólá Ibi mo mònà dé ni n o je dé Ibi emi sì kún mí dé ni n o kì mo. Mo bá Olóràngún relé Òròrúwò ni mo lo. Géndé lawa kábíyèsí Oba, Olóròrúwò Oba Kábíyèsí Oba èyí tó wàjà Orokun tápà bèlé èsun Òtèté omo afi àróò dáná kúlíkúlí Tèté omo a fi àróò dánà kúlíkúlí Mo kí ìgunun, ìgunun rojú kókó À bí òré tápà tí n se ni. Bàmún lóye tápà bonàákó yányán Olúbísí omo aláwo ló lesin Mo mèdì okò telè ni mògàmògà Mo kí yekan wa tí jé òdòfín wa Akéréburé omo oláníyanun Àdìgún omo mòmóódù Ìdáméjì àgùnbé tí won n pè ní enìkan soso Ni wón fi n pe Olúbísí ará lódò oya Sebí yakan Olóròrúwò ni òràngún omo okù òkáyá Iyekan ti bimo ogun òsìngìndìn Olúbísí mo kí òyagadá mo yí omi Omo igbá Òdí ni mí mo dé Odò mo rìn gerere. Ìkòkò òdí ni mí dé odò mo rìn tàràràrà Omo bíbí òdí ni mí mode odò mo pa òdódó orí Olúbísí omo káló káló ni wón sekú pèja. N lè yekan le láyé yekan menu gún ola, Omo òkánkán Ilé la sìbi Olúbabi kébísí olú ará Ilé mi gògò la sìbi ìmùlè Tàbí ránti Ìbi láyé Ojó tí a bá kú ará Ilé eni ní gbé ni sin Òtèté omo a fi àróò dáná kúlíkúlí Omo káló ni wón sekú peja Omo Olúbanké ìbòsí mo bá ònà odò lo. E kú bè láàsín ekú bèláàsin Yé wo naa ekú bàláàsin.

[edit] ORIKI OBA ÌRÁGBÌJÍ

Kábíyésí Oba Oba tótó Oba ìrágbìjí Àbíyèsí Oba Oba mo fé pè n kò ní mu emu Oba ni mo fé pè n kò mu gòrò Àbè togún ràlú onmo ará lósìn Téní wíjó ará lóbòkun sá loba ìrágbìjí n jé. Ònkókóló omo oníyán kónkólóyo Omo bárígídí níyán ògún Omo arílù mó lulu fún ìrà Àrílá ílànkí mo gbé òkè je nàmùn Gbéléwadé mo gbélé se bí Oba Omo Òké gbélé wùsì lónà tòrà Anal mo kéde jègbe Ará mú lege ará òkun esè kè Omo òkan ti yí lulè Ó kù okan Omo olórò kan òrò kàn Èyí tí fáwù lógànjó yányán Gódógódó Ilé won kò gbodò sowó odó poro Béè ni alògì kan won kò gbodò solo ògì sàrà Omo kékèké Ilé won o gbodò sunkún omú Èyì tí ò bá sunkún mo lórò ni yoo mo gbe lo. Omo òkè kékéké ni yíkè yíkè yí láyé. Àbè togún ràlú omo arà lósìn Téní wíjò ìjèsà kò rídìí ìsáná Ilé loní Owá ti mú iná roko Àbè togún ràlú omo arà lósìn. Mo tún yí yun tì kédéngbé Ònyín mo tún lo re dé òkè àgbò. Oba tótó mo lémi kò perí Oba Oba won n perí e ní Sókótó Oba ni wón n perí rè ní Sàbàrà Oba ni wón n perí rè nílè ìrágbìjí Oba olókùn esin Ará Ilé mi abi ìrù esin mi tìèmì A gbún esin ní késé à ló mò jó édòko Gbogbo ara esin wón wá koná sasa Oba kólérán tí n retí eni tí yoo tè fun. Oba n náà ní í be lónà ti òkè àgbò. Àbè togún ràlú omo arà lósìn Téni wíjó ará lódó kánkán Èyin lomo olóyè nílé omo olóyè lóde. Oyè náà won kò ní pare mó yin lówó. Orí àpéré yoo gbé yín dòyè baba èyin Èyí tó n be níbè won kò ní kú mo yin lówó Oba tótó àágbìgí mo lémi kò perí oba Oba ni n be lónà ti ìjèsà àbè Ìjèsà àbè togún ràlú omo arà lósìn Téní wíjó ará lódò kánkán. Mo onípokítí Ide Ikú kò ni pa Oyàdókùn wa Ìjèsà ìsèrè onílè obi Omo ojú rábe sá mó gbódó pea be lórúko. Omo ojú réjò ata wàrà Sòbòrò la bí ìgbín kò fi abe kan ara. Àwon ni omo olóbìkan òbìkàn Èyí tí ó kò bá fé won ní wò sílé Èyí tí ò kò bá fé won a wò síjù Eranko igbó á mu soko je A kì ki Ìjèsà kí a má je Obi tógbó. Tí e kò bá rí obì tógbó Kí e wá gba Obì lówó mi Àwon lomo olódò kan òdò kan Tósàn wéréke tó sàn wèrè ke. Tí ó dé èyìn èkùlé osólò tó di àbàtà Èyin lomo tí e bá jáwé kan Eègbá kan ni Bí e bá já méjì Eègbá méjì ni. Tí e bá já méta Eègbá méta ni Ò pé pep e aso won lóde ìgbájo Elégbòdò ni aso àwon ìjèsà Èyí tí e bá ri lójà ni kí e rà nfún wá Kí n ró jó Olóye lo Torí a kà jò olóye dun ìran baba yin Àbè togún ràlú omo arà lósìn Mo bá àágbìjí relé Mo bá àágbìjí relé.

Static Wikipedia (no images)

aa - ab - af - ak - als - am - an - ang - ar - arc - as - ast - av - ay - az - ba - bar - bat_smg - bcl - be - be_x_old - bg - bh - bi - bm - bn - bo - bpy - br - bs - bug - bxr - ca - cbk_zam - cdo - ce - ceb - ch - cho - chr - chy - co - cr - crh - cs - csb - cu - cv - cy - da - de - diq - dsb - dv - dz - ee - el - eml - en - eo - es - et - eu - ext - fa - ff - fi - fiu_vro - fj - fo - fr - frp - fur - fy - ga - gan - gd - gl - glk - gn - got - gu - gv - ha - hak - haw - he - hi - hif - ho - hr - hsb - ht - hu - hy - hz - ia - id - ie - ig - ii - ik - ilo - io - is - it - iu - ja - jbo - jv - ka - kaa - kab - kg - ki - kj - kk - kl - km - kn - ko - kr - ks - ksh - ku - kv - kw - ky - la - lad - lb - lbe - lg - li - lij - lmo - ln - lo - lt - lv - map_bms - mdf - mg - mh - mi - mk - ml - mn - mo - mr - mt - mus - my - myv - mzn - na - nah - nap - nds - nds_nl - ne - new - ng - nl - nn - no - nov - nrm - nv - ny - oc - om - or - os - pa - pag - pam - pap - pdc - pi - pih - pl - pms - ps - pt - qu - quality - rm - rmy - rn - ro - roa_rup - roa_tara - ru - rw - sa - sah - sc - scn - sco - sd - se - sg - sh - si - simple - sk - sl - sm - sn - so - sr - srn - ss - st - stq - su - sv - sw - szl - ta - te - tet - tg - th - ti - tk - tl - tlh - tn - to - tpi - tr - ts - tt - tum - tw - ty - udm - ug - uk - ur - uz - ve - vec - vi - vls - vo - wa - war - wo - wuu - xal - xh - yi - yo - za - zea - zh - zh_classical - zh_min_nan - zh_yue - zu -

Static Wikipedia 2007 (no images)

aa - ab - af - ak - als - am - an - ang - ar - arc - as - ast - av - ay - az - ba - bar - bat_smg - bcl - be - be_x_old - bg - bh - bi - bm - bn - bo - bpy - br - bs - bug - bxr - ca - cbk_zam - cdo - ce - ceb - ch - cho - chr - chy - co - cr - crh - cs - csb - cu - cv - cy - da - de - diq - dsb - dv - dz - ee - el - eml - en - eo - es - et - eu - ext - fa - ff - fi - fiu_vro - fj - fo - fr - frp - fur - fy - ga - gan - gd - gl - glk - gn - got - gu - gv - ha - hak - haw - he - hi - hif - ho - hr - hsb - ht - hu - hy - hz - ia - id - ie - ig - ii - ik - ilo - io - is - it - iu - ja - jbo - jv - ka - kaa - kab - kg - ki - kj - kk - kl - km - kn - ko - kr - ks - ksh - ku - kv - kw - ky - la - lad - lb - lbe - lg - li - lij - lmo - ln - lo - lt - lv - map_bms - mdf - mg - mh - mi - mk - ml - mn - mo - mr - mt - mus - my - myv - mzn - na - nah - nap - nds - nds_nl - ne - new - ng - nl - nn - no - nov - nrm - nv - ny - oc - om - or - os - pa - pag - pam - pap - pdc - pi - pih - pl - pms - ps - pt - qu - quality - rm - rmy - rn - ro - roa_rup - roa_tara - ru - rw - sa - sah - sc - scn - sco - sd - se - sg - sh - si - simple - sk - sl - sm - sn - so - sr - srn - ss - st - stq - su - sv - sw - szl - ta - te - tet - tg - th - ti - tk - tl - tlh - tn - to - tpi - tr - ts - tt - tum - tw - ty - udm - ug - uk - ur - uz - ve - vec - vi - vls - vo - wa - war - wo - wuu - xal - xh - yi - yo - za - zea - zh - zh_classical - zh_min_nan - zh_yue - zu -

Static Wikipedia 2006 (no images)

aa - ab - af - ak - als - am - an - ang - ar - arc - as - ast - av - ay - az - ba - bar - bat_smg - bcl - be - be_x_old - bg - bh - bi - bm - bn - bo - bpy - br - bs - bug - bxr - ca - cbk_zam - cdo - ce - ceb - ch - cho - chr - chy - co - cr - crh - cs - csb - cu - cv - cy - da - de - diq - dsb - dv - dz - ee - el - eml - eo - es - et - eu - ext - fa - ff - fi - fiu_vro - fj - fo - fr - frp - fur - fy - ga - gan - gd - gl - glk - gn - got - gu - gv - ha - hak - haw - he - hi - hif - ho - hr - hsb - ht - hu - hy - hz - ia - id - ie - ig - ii - ik - ilo - io - is - it - iu - ja - jbo - jv - ka - kaa - kab - kg - ki - kj - kk - kl - km - kn - ko - kr - ks - ksh - ku - kv - kw - ky - la - lad - lb - lbe - lg - li - lij - lmo - ln - lo - lt - lv - map_bms - mdf - mg - mh - mi - mk - ml - mn - mo - mr - mt - mus - my - myv - mzn - na - nah - nap - nds - nds_nl - ne - new - ng - nl - nn - no - nov - nrm - nv - ny - oc - om - or - os - pa - pag - pam - pap - pdc - pi - pih - pl - pms - ps - pt - qu - quality - rm - rmy - rn - ro - roa_rup - roa_tara - ru - rw - sa - sah - sc - scn - sco - sd - se - sg - sh - si - simple - sk - sl - sm - sn - so - sr - srn - ss - st - stq - su - sv - sw - szl - ta - te - tet - tg - th - ti - tk - tl - tlh - tn - to - tpi - tr - ts - tt - tum - tw - ty - udm - ug - uk - ur - uz - ve - vec - vi - vls - vo - wa - war - wo - wuu - xal - xh - yi - yo - za - zea - zh - zh_classical - zh_min_nan - zh_yue - zu

Static Wikipedia February 2008 (no images)

aa - ab - af - ak - als - am - an - ang - ar - arc - as - ast - av - ay - az - ba - bar - bat_smg - bcl - be - be_x_old - bg - bh - bi - bm - bn - bo - bpy - br - bs - bug - bxr - ca - cbk_zam - cdo - ce - ceb - ch - cho - chr - chy - co - cr - crh - cs - csb - cu - cv - cy - da - de - diq - dsb - dv - dz - ee - el - eml - en - eo - es - et - eu - ext - fa - ff - fi - fiu_vro - fj - fo - fr - frp - fur - fy - ga - gan - gd - gl - glk - gn - got - gu - gv - ha - hak - haw - he - hi - hif - ho - hr - hsb - ht - hu - hy - hz - ia - id - ie - ig - ii - ik - ilo - io - is - it - iu - ja - jbo - jv - ka - kaa - kab - kg - ki - kj - kk - kl - km - kn - ko - kr - ks - ksh - ku - kv - kw - ky - la - lad - lb - lbe - lg - li - lij - lmo - ln - lo - lt - lv - map_bms - mdf - mg - mh - mi - mk - ml - mn - mo - mr - mt - mus - my - myv - mzn - na - nah - nap - nds - nds_nl - ne - new - ng - nl - nn - no - nov - nrm - nv - ny - oc - om - or - os - pa - pag - pam - pap - pdc - pi - pih - pl - pms - ps - pt - qu - quality - rm - rmy - rn - ro - roa_rup - roa_tara - ru - rw - sa - sah - sc - scn - sco - sd - se - sg - sh - si - simple - sk - sl - sm - sn - so - sr - srn - ss - st - stq - su - sv - sw - szl - ta - te - tet - tg - th - ti - tk - tl - tlh - tn - to - tpi - tr - ts - tt - tum - tw - ty - udm - ug - uk - ur - uz - ve - vec - vi - vls - vo - wa - war - wo - wuu - xal - xh - yi - yo - za - zea - zh - zh_classical - zh_min_nan - zh_yue - zu