Tourism
From Wikipedia
AKINDIPE OLUWABUNMI TOPE
ÀWON OHUN TÓ SO MÓ ÌRÌN ÀJÒ AFÉ (TOURISM)
‘Tourism’ gégé bí ìwé atúmò èdè Gèésì se sàpéjúwe rè ni: Tourist travel and the services connected with it, especially when regarded as an industry.
Ni èdè Yorùbá èyí túmò sí:
Àjò arìnrìnàjò afé àti àwon isé tó so mo, èyí tó se pàtàkì jù ni ìgbà tí a ba wò ó gégé bí ilé-isé kan. ‘Tourist’ náà túmò sí:
A person who travels for pleasure: usually sightseeing and staying in hotels.
Èyí tó túmò sí: Enikéni tó bá n rìnrìn àjò nítorí afé èyí tó sábà máa n jé láti ri àwon ibi ti kò dé ri àti dúró sí àwon ilé ìtura.
Oríkì tí ó ti orí ‘wikipedia’ lórí íntánéètì wà pò sùgbón díè nínú rè ni mà á múlò nínú isé yìí: ó ní ìrìn àjò afé ni ki á kúrò nílé eni lo síbi tí a ko tì í dé rí láti lo gbádùn ara wa àti láti lo mo ibè pèlú. Ìrìn àjò afé ti di gbajúmò kán ayé, ní odún 2004, àwon tí ó to ‘763 million’ ni àkosílè wà pé wón rin ìrìn àjò fé jákè jádò gbogbo orílè-èdè àgbáyé.
Nítorí pé ìrìn àjò afé yìí jé ohun tó n mú kí oró-ajé àwon orílè-èdè kan jí pépé, wón kò kóyán ìrìn àjò afé kéré. Wón tún wá gbà pé kò sí orilè-èdè tí kò ní ohun tí ò n mú àwon ènìyàn rin ìrìn àjò afé wá síbè.
Wón tè síwájú láti so pé kì í se torí ìgbádùn nìkan ni àwon ènìyàn se n rin ìrìn àjò afé, pé wón máa rin àwon ìrìn àjò wònyí láti simi kúrò lénu isé, wón máa n rìn-ín láti lè ri àsà àwon ìlú mìíràn àti láti fi wé tìlú won, láti se ohun mìíràn tí ó yàtò sí èyí ti wón máa n se, láti mo àwon ènìyàn si, àti paríparí rè láti ni ìrírí tí ó jojú.
Wón pé àkíyèsi àwon ènìyàn káàkiri àgbáyé pé, kò di dandan kí ènìyàn kúrò ní orílè-èdè rè kó ó tó rin ìrìn àjò ohun tó se pàtàkì ni pé kí ó kúrò níbí tí ó wà lo síbi ti kò ti ì dé rí láti simi, gbádùn, bá àwon oníurú ènìyàn pade àti láti ní ìrírí.