Ìjọ Jéésù Lótìítọ́
From Wikipedia
“Ìjọ Jéésù Lótìítọ́” ti a da s’ile ni ilu Beyijini, Shaina ni odun 1917, je ijo t’o da duro ninu awon oni-pentokosti. Ijo yi faramo ikoni “okan soso l’Ọlọ́run”. Won gbabgo pe okan l’Ọlọ́run ati pe Jesu je Ọlọ́run. Ijo yi ko ikoni “metal’okan” pe ko to, ko si dogba lati s’apejuwa Ọlọ́run. Ijo gba pe ikoni “metal’okan” ko wa lati inu Bíbélì nikan sugbon lati inu awon orisirisi afikun lehin akojo Bíbélì, eyiti awon olutele “okan soso l’Ọlọ́run” ka si ero eniyan lasan, ti ko ni ase imisi Ọlọ́run bi ti Bíbélì.
Bi o tile je pe a kaasi ijo awon ara Shaina, “Ìjọ Jéésù Lótìítọ́” lode oni ti ntan kale agbaye bi a ti nwasu ihinrere Jesu kari aye. Iye awon olutele “Ìjọ Jéésù Lótìítọ́” je egbajo egberun eniyan ni orile kotinenti mefa ni agbaye.
Translation provided as a public service by: His Royal Highness, The Ọba’lúmò of Òkè-Ìlá Òràngún: Dr. Olúfémi Ọládàpòmádé Babalọlá-Adékéyè.